ORÍ KÌÍNÍ
Ta Ni Ọlọ́run?
1, 2. Àwọn ìbéèrè wo ni àwọn èèyàn sábà máa ń béèrè?
ÀWỌN ọmọdé máa ń béèrè ìbéèrè gan-an. Tó o bá tiẹ̀ ṣàlàyé ohun kan fún wọn, síbẹ̀ wọ́n á béèrè pé, ‘Kí nìdí?’ Tó o bá sì gbìyànjú láti dá wọn lóhùn, wọ́n tún lè béèrè pé, ‘Kí nìdí tẹ́ ẹ fi sọ bẹ́ẹ̀?’
2 Bóyá àgbàlagbà ni wá tàbí ọmọdé, gbogbo wa la máa ń béèrè ìbéèrè. Ó lè jẹ́ ìbéèrè nípa ohun tá a fẹ́ jẹ, ohun tá a fẹ́ wọ̀ tàbí ohun tá a fẹ́ rà. Ó sì lè jẹ́ àwọn ìbéèrè pàtàkì nípa ìgbésí ayé àti ọjọ́ ọ̀la wa. Àmọ́ tá ò bá rí ìdáhùn tó tẹ́ wa lọ́rùn, ó lè má wù wá láti béèrè ìbéèrè mọ́.
3. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi rò pé àwọn ò lè rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì tí wọ́n ní?
3 Ṣé Bíbélì lè dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì tá a máa ń béèrè? Àwọn kan gbà bẹ́ẹ̀, àmọ́ wọ́n rò pé Bíbélì ti le jù láti lóye. Wọ́n lè rò pé àwọn olùkọ́ tàbí àwọn olórí ẹ̀sìn nìkan ló lè dáhùn àwọn ìbéèrè náà. Àwọn míì kì í fẹ́ béèrè ìbéèrè torí wọ́n gbà pé kò yẹ kó jẹ́ irú àwọn ni kò mọ ìdáhùn àwọn ìbéèrè náà. Kí ni èrò tìẹ?
4, 5. Àwọn ìbéèrè pàtàkì wo lò ń wá ìdáhùn sí? Kí nìdí tí kò fi yẹ kó sú ẹ láti máa wá ìdáhùn àwọn ìbéèrè náà?
4 Ó ṣeé ṣe kó o fẹ́ mọ ìdáhùn àwọn ìbéèrè bíi: Kí nìdí tí mo fi wà láyé? Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí mi tí mo bá kú? Irú ẹni wo ni Ọlọ́run? Jésù tó jẹ́ olùkọ́ tí gbogbo èèyàn mọ̀ sọ pé: “Ẹ máa béèrè, a sì máa fún yín; ẹ máa wá kiri, ẹ sì máa rí; ẹ máa kan ilẹ̀kùn, a sì máa ṣí i fún yín.” (Mátíù 7:7) Má ṣe jẹ́ kó sú ẹ títí wàá fi rí ìdáhùn tó jẹ́ òótọ́.
5 Ó dájú pé tó o bá ń “béèrè,” o máa rí ìdáhùn nínú Bíbélì. (Òwe 2:1-5) Wàá rí i pé ìdáhùn àwọn ìbéèrè náà kò ṣòro láti lóye. Ohun tó o bá kọ́ máa jẹ́ kó o láyọ̀ ní báyìí, ọkàn rẹ á sì balẹ̀ pé ọjọ́ iwájú rẹ máa dùn. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ìbéèrè kan tó ta kókó tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń béèrè.
ṢÉ ỌLỌ́RUN NÍFẸ̀Ẹ́ WA ÀBÍ ÌKÀ NI?
6. Kí nìdí táwọn kan fi rò pé Ọlọ́run kò nífẹ̀ẹ́ wa?
6 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló rò pé Ọlọ́run kò nífẹ̀ẹ́ wa. Wọ́n gbà pé tí Ọlọ́run bá nífẹ̀ẹ́ wa, kò yẹ kí ayé rí báyìí. Ogun, ìkórìíra àti ìnira ló kún inú ayé. Àwọn èèyàn ń ṣàìsàn, wọ́n ń jìyà, wọ́n sì ń kú. Ìdí nìyẹn táwọn kan fi máa ń sọ pé, ‘Tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa ni, ó yẹ kó ti fòpin sí ìyà tó ń jẹ èèyàn.’
7. (a) Báwo ni àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ṣe mú káwọn èèyàn rò pé ìkà ni Ọlọ́run? (b) Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run kọ́ ló ń fa àwọn ohun burúkú tó ń ṣẹlẹ̀?
7 Nígbà míì, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn máa ń mú kí àwọn èèyàn gbà pé ìkà ni Ọlọ́run. Tí nǹkan burúkú bá ṣẹlẹ̀, wọ́n lè sọ pé àmúwá Ọlọ́run ni tàbí kí wọ́n sọ pé bí Ọlọ́run ṣe kọ ọ́ nìyẹn. Bí wọ́n ṣe ń sọ irú àwọn ọ̀rọ̀ yìí, ńṣe ni wọ́n ń dá Ọlọ́run lẹ́bi. Àmọ́ Bíbélì kọ́ wa pé Ọlọ́run kọ́ ló ń fa àwọn ohun burúkú. Jémíìsì 1:13 sọ pé Ọlọ́run kì í fi ohun burúkú dán ẹnikẹ́ni wò. Ó sọ pé: “Tí àdánwò bá dé bá ẹnikẹ́ni, kó má ṣe sọ pé: ‘Ọlọ́run ló ń dán mi wò.’ Torí a ò lè fi ibi dán Ọlọ́run wò, òun náà kì í sì í dán ẹnikẹ́ni wò.” Èyí fi hàn pé tí Ọlọ́run kò bá tiẹ̀ tíì fòpin sí àwọn ohun burúkú tó ń ṣẹlẹ̀, ká fi sọ́kàn pé òun kọ́ ló ń fà á. (Ka Jóòbù 34:10-12.) Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan.
8, 9. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká dá Ọlọ́run lẹ́bi nítorí àwọn ìṣòro wa? Sọ àpẹẹrẹ kan.
8 Ká sọ pé ọmọkùnrin kan ń gbé ilé pẹ̀lú àwọn òbí rẹ̀. Bàbá rẹ̀ fẹ́ràn rẹ̀ gan-an, ó sì ti kọ́ ọ bó ṣe lè ṣe àwọn ìpinnu tó dáa. Nígbà tó yá, ọmọkùnrin náà kò gbọ́ràn sí bàbá rẹ̀ lẹ́nu mọ́, ó sì fi ilé sílẹ̀. Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà burúkú, ó sì kó sí wàhálà. Ṣé ó yẹ ká dá bàbá rẹ̀ lẹ́bi nítorí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọmọ náà, torí pé kò dá ọmọ náà dúró nígbà tó fẹ́ kúrò nílé? Rárá o! (Lúùkù 15:11-13) Bíi ti bàbá yẹn, Ọlọ́run kì í dá àwọn èèyàn dúró tí wọ́n bá pinnu láti ṣàìgbọràn tí wọ́n sì hùwà burúkú. Tí àwọn nǹkan burúkú bá wá ṣẹlẹ̀, ó yẹ ká máa rántí pé Ọlọ́run kọ́ ló fà á. Torí náà, kò yẹ ká máa dá Ọlọ́run lẹ́bi.
9 Ó nídìí pàtàkì tí Ọlọ́run ò fi tíì fòpin sí àwọn nǹkan burúkú tó ń ṣẹlẹ̀. Wàá mọ ohun tí Bíbélì sọ lórí kókó yìí nínú Orí 11 ìwé yìí. Àmọ́ jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa àti pé òun kọ́ ló ń fa àwọn ìṣòro wa. Kódà, òun nìkan ṣoṣo ló lè bá wa yanjú wọn.—Àìsáyà 33:2.
10. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé Ọlọ́run máa ṣe àtúnṣe ohun tí àwọn èèyàn burúkú ti bà jẹ́?
10 Ọlọ́run jẹ́ mímọ́. (Àìsáyà 6:3) Mímọ́ ni gbogbo iṣẹ́ rẹ̀, kò ní àbààwọ́n, ó sì dára. Torí náà, a lè gbẹ́kẹ̀ lé e. Ṣùgbọ́n àwa èèyàn ò rí bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń ṣe àṣìṣe. Kódà, ẹni tó jẹ́ olóòótọ́ jù lọ nínú àwọn aláṣẹ kò lágbára láti ṣe àtúnṣe gbogbo nǹkan burúkú tí àwọn èèyàn ń ṣe. Kò sẹ́ni tó lágbára tó Ọlọ́run. Ó lágbára láti ṣe àtúnṣe ohun tí àwọn èèyàn burúkú ti bà jẹ́, ó sì máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ó máa fòpin sí gbogbo ìwà ibi títí láé.—Ka Sáàmù 37:9-11.
BÁWO LÓ ṢE MÁA Ń RÍ LÁRA ỌLỌ́RUN TÁWA ÈÈYÀN BÁ Ń JÌYÀ?
11. Báwo ló ṣe máa ń rí lára Ọlọ́run tó o bá ń jìyà?
11 Báwo ló ṣe máa ń rí lára Ọlọ́run tó bá rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé àti ìyà tó ń jẹ ọ́? Bíbélì kọ́ wa pé Ọlọ́run “nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo.” (Sáàmù 37:28) Torí náà, ọ̀rọ̀ nípa ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ ṣe pàtàkì lójú rẹ̀ gan-an. Ọlọ́run kórìíra kí àwọn èèyàn máa jìyà. Bíbélì sọ pé ‘ọkàn rẹ̀ bà jẹ́’ nígbà kan tó rí i pé ìwà ibi pọ̀ gan-an láyé. (Jẹ́nẹ́sísì 6:5, 6) Ọlọ́run kò yí pa dà. (Málákì 3:6) Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ń bójú tó ẹ.—Ka 1 Pétérù 5:7.
12, 13. (a) Kí nìdí tá a fi nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, báwo sì ni ìyà tó ń jẹ aráyé ṣe rí lára wa? (b) Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé Ọlọ́run máa mú gbogbo ìyà àti ìrẹ́jẹ kúrò?
12 Bíbélì tún sọ pé Ọlọ́run dá wa ní àwòrán rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Èyí túmọ̀ sí pé Ọlọ́run dá àwọn ànímọ́ [ìyẹn ìwà àti ìṣe] bíi tiẹ̀ mọ́ wa. Torí náà, tí inú rẹ ò bá dùn bó o ṣe ń rí i tí àwọn èèyàn rere ń jìyà, gbà pé ó máa ń dun Ọlọ́run jù bẹ́ẹ̀ lọ! Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀?
13 Bíbélì kọ́ wa pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Ìfẹ́ ló mú kí Ọlọ́run máa ṣe gbogbo ohun tó ń ṣe. Torí pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ni àwa náà ṣe máa ń fi ìfẹ́ hàn. Rò ó wò ná: Tó o bá lágbára láti mú gbogbo ìyà àti ìrẹ́jẹ tó wà láyé kúrò, ṣé wàá ṣe bẹ́ẹ̀? Ó dájú pé wàá ṣe bẹ́ẹ̀, torí pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Ṣé o rò pé Ọlọ́run náà máa ṣe bẹ́ẹ̀? Nítorí pé ó lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì nífẹ̀ẹ́ wa, ó dájú pé ó máa mú gbogbo ìyà àti ìrẹ́jẹ kúrò. Ó dájú pé gbogbo àwọn ìlérí Ọlọ́run tá a sọ ní ìbẹ̀rẹ̀ ìwé yìí máa ṣẹ! Àmọ́, kó lè dá ẹ lójú pé àwọn ìlérí yẹn máa ṣẹ, ó yẹ kó o mọ púpọ̀ sí i nípa Ọlọ́run.
ỌLỌ́RUN FẸ́ KÓ O MỌ ÒUN
14. Kí ni orúkọ Ọlọ́run, báwo la sì ṣe mọ̀ pé ó yẹ ká máa lò ó?
14 Tó o bá fẹ́ kí ìwọ àti ẹnì kan di ọ̀rẹ́, kí lo máa kọ́kọ́ sọ fún un nípa ara rẹ? Orúkọ rẹ, àbí? Ṣé Ọlọ́run ní orúkọ? Ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ló sọ pé Ọlọ́run tàbí Olúwa ni orúkọ rẹ̀, àmọ́ orúkọ rẹ̀ gangan kọ́ nìyẹn. Orúkọ oyè bí “ọba” tàbí “ààrẹ” ni wọ́n jẹ́. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ sọ fún wa pé Jèhófà ni orúkọ òun. Sáàmù 83:18 sọ pé: “Kí àwọn èèyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ayé.” Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje (7,000) ìgbà ni àwọn tó kọ Bíbélì lo orúkọ Ọlọ́run. Jèhófà fẹ́ kó o mọ orúkọ òun kó o sì máa lò ó. Ó sọ orúkọ rẹ̀ fún ẹ, kó o lè di ọ̀rẹ́ rẹ̀.
15. Kí ni ìtumọ̀ orúkọ náà Jèhófà?
15 Orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà, ní ìtumọ̀ tó jinlẹ̀. Ó túmọ̀ sí pé kò sí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe tí kò ní mú ṣẹ, ó sì lè mú gbogbo ohun tó bá ní lọ́kàn ṣẹ. Kò sí ohun tó lè dá a dúró. Jèhófà nìkan ló lè jẹ́ orúkọ yìí.a
16, 17. Kí ni àwọn orúkọ oyè yìí jẹ́ ká mọ̀ nípa Ọlọ́run (a) “Olódùmarè”? (b) “Ọba ayérayé”? (d) “Ẹlẹ́dàá”?
16 Sáàmù 83:18 tá a kà lẹ́ẹ̀kan sọ nípa Jèhófà pé: “Ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ.” Bákan náà, Ìfihàn 15:3 sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run, Olódùmarè, àwọn iṣẹ́ rẹ tóbi, ó sì kàmàmà. Òdodo àti òótọ́ ni àwọn ọ̀nà rẹ, Ọba ayérayé.” Orúkọ oyè náà “Olódùmarè” jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà lágbára ju ẹnikẹ́ni lọ láyé àtọ̀run. Bẹ́ẹ̀ sì ni orúkọ oyè náà “Ọba ayérayé” jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ti wà kí ohunkóhun tó wà. Sáàmù 90:2 ṣàlàyé pé ó ti wà láti ayérayé dé ayérayé. Ìyẹn mà yani lẹ́nu gan-an o!
17 Jèhófà nìkan ni Ẹlẹ́dàá. Ìfihàn 4:11 sọ pé: “Ìwọ ló tọ́ sí láti gba ògo àti ọlá àti agbára, torí ìwọ lo dá ohun gbogbo, torí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.” Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà ló dá àwọn áńgẹ́lì tó wà ní ọ̀run, àwọn ìràwọ̀, oríṣiríṣi èso, àwọn ẹja inú òkun àti àwọn nǹkan míì tó o tún lè ronú kàn!
ṢÉ O LÈ DI Ọ̀RẸ́ JÈHÓFÀ?
18. Kí nìdí tí àwọn kan fi rò pé àwọn ò lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run? Kí ni Bíbélì sọ nípa èyí?
18 Nígbà tí àwọn èèyàn bá kà nípa àwọn ìwà àti ìṣe Jèhófà tó wúni lórí gan-an, ẹ̀rù máa ń bà wọ́n, wọ́n sì máa ń ronú pé, ‘Ọlọ́run mà lágbára o, ó mà tóbi lọ́ba o, ọ̀run ló tún ń gbé, ṣé ó lè rí tèmi rò ṣá?’ Àmọ́, ṣé bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ ká máa ronú nìyẹn? Rárá o. Jèhófà fẹ́ sún mọ́ wa. Bíbélì sọ pé Ọlọ́run “kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.” (Ìṣe 17:27) Ọlọ́run fẹ́ kó o sún mọ́ òun, ó sì ṣèlérí pé òun náà ‘á sún mọ́ ẹ.’—Jémíìsì 4:8.
19. (a) Báwo lo ṣe lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run? (b) Èwo nínú àwọn ànímọ́ Jèhófà lo fẹ́ràn jù?
19 Báwo ni wàá ṣe di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run? Jésù sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, pé kí wọ́n wá mọ ìwọ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo àti Jésù Kristi, ẹni tí o rán.” (Jòhánù 17:3) Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nìṣó, wàá mọ Jèhófà àti Jésù dáadáa. Ìyẹn sì lè mú kó o ní ìyè àìnípẹ̀kun. Bí àpẹẹrẹ, a ti kẹ́kọ̀ọ́ pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:16) Àmọ́, ó tún ní ọ̀pọ̀ ànímọ́ míì tó fani mọ́ra. Bíbélì sọ fún wa pé Jèhófà jẹ́ ‘aláàánú, ó ń gba tẹni rò, kì í tètè bínú, ìfẹ́ rẹ̀ kì í yẹ̀, òtítọ́ rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi.’ (Ẹ́kísódù 34:6) Jèhófà jẹ́ ‘ẹni rere, ó sì ṣe tán láti dárí jini.’ (Sáàmù 86:5) Ọlọ́run jẹ́ onísùúrù àti adúróṣinṣin. (2 Pétérù 3:9; Ìfihàn 15:4) Tó o bá ń ka Bíbélì, wàá túbọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa àwọn ànímọ́ Ọlọ́run tó fani mọ́ra gan-an.
20-22. (a) Báwo la ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run bá ò tiẹ̀ lè rí i? (b) Kí ló yẹ kó o ṣe tí àwọn kan ò bá fẹ́ kó o kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ́?
20 Báwo lo ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run tó ò bá tiẹ̀ lè rí i? (Jòhánù 1:18; 4:24; 1 Tímótì 1:17) Tó o bá ń kà nípa Jèhófà nínú Bíbélì, á túbọ̀ dá ẹ lójú pé Ọlọ́run wà lóòótọ́. (Sáàmù 27:4; Róòmù 1:20) Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa rẹ̀, ìfẹ́ rẹ̀ á máa jinlẹ̀ lọ́kàn rẹ, wàá sì túbọ̀ sún mọ́ ọn.
21 Wàá rí i pé Baba wa ni Jèhófà. (Mátíù 6:9) Ó fún wa ní ẹ̀mí, ó sì fẹ́ kí ayé wa ládùn kó lóyin. Ohun tí bàbá tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ máa ń fẹ́ nìyẹn. (Sáàmù 36:9) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé o lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà. (Jémíìsì 2:23) Jèhófà Ẹlẹ́dàá ọ̀run àti ayé fẹ́ kó o jẹ́ ọ̀rẹ́ òun. Àǹfààní ńlá nìyẹn o!
22 Àwọn kan lè fẹ́ kó o dá ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ò ń kọ́ dúró. Wọ́n lè máa bẹ̀rù pé o ti fẹ́ yí ẹ̀sìn rẹ pa dà. Àmọ́ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni dí ẹ lọ́wọ́ láti di ọ̀rẹ́ Jèhófà. Òun ni ọ̀rẹ́ rẹ tó dáa jù lọ.
23, 24. (a) Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa béèrè ìbéèrè? (b) Kí la máa kẹ́kọ̀ọ́ ní orí tó kàn?
23 Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn ohun kan wà tí kò tíì lè yé ẹ. Má ṣe jẹ́ kí ojú tì ẹ́ láti béèrè ohun tí kò bá yé ẹ. Jésù sọ pé a gbọ́dọ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, bíi ti àwọn ọmọdé. (Mátíù 18:2-4) Àwọn ọmọdé sì máa ń béèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè. Ọlọ́run fẹ́ kó o rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè rẹ. Torí náà, fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kó o lè rí i pé òótọ́ ni ohun tó ò ń kọ́.—Ka Ìṣe 17:11.
24 Ọ̀nà tó dáa jù lọ láti mọ Jèhófà ni pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nínú orí tó kàn, a máa rí ìdí tí Bíbélì fi yàtọ̀ sí àwọn ìwé míì.
a Tí kò bá sí orúkọ náà Jèhófà nínú Bíbélì rẹ tàbí tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa ìtumọ̀ orúkọ Ọlọ́run àti bá a ṣe ń pè é, wo Àlàyé Ìparí Ìwé 1.