ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìbínú Ọlọ́run Parí
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
    • 17. (a) Báwo ni ìdàjáde ohun tó wà nínú àwokòtò karùn-ún ṣe jẹ mọ́ òkùnkùn nípa tẹ̀mí tó ti fi ìgbà gbogbo bo ìjọba ẹranko ẹhànnà náà mọ́lẹ̀? (b) Kí làwọn èèyàn ṣe lẹ́yìn tí áńgẹ́lì náà da ìbínú Ọlọ́run tó wà nínú àwokòtò karùn-ún jáde?

      17 Ìjọba ẹranko ẹhànnà yìí ti wà nínú òkùnkùn nípa tẹ̀mí láti ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀. (Fi wé Mátíù 8:12; Éfésù 6:11, 12.) Àwokòtò karùn-ún túbọ̀ mú kí ìkéde gbangba nípa òkùnkùn yìí rinlẹ̀ sí i. Àní, ó jẹ́ kó túbọ̀ ṣe kedere sí i, ní ti pé orí ìtẹ́ ẹranko ẹhànnà ìṣàpẹẹrẹ náà gan-an ni áńgẹ́lì náà da àwokòtò ìrunú Ọlọ́run yìí sí. “Ìjọba rẹ̀ sì ṣókùnkùn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gé ahọ́n wọn jẹ nítorí ìrora wọn, ṣùgbọ́n wọ́n sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run ọ̀run nítorí ìrora wọn àti nítorí egbò wọn, wọn kò sì ronú pìwà dà àwọn iṣẹ́ wọn.”—Ìṣípayá 16:10b, 11.

  • Ìbínú Ọlọ́run Parí
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
    • 19. Gẹ́gẹ́ bí Ìṣípayá 16:10, 11 ṣe sọ, kí ni títú Sátánì fó ní gbangba gẹ́gẹ́ bí ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yóò fà?

      19 Sátánì tó jẹ́ alákòóso ayé ti fa ìbànújẹ́ àti ìyà púpọ̀ bá aráyé. Ìyàn, ogun, ìwà ipá, ìwà ọ̀daràn, lílo oògùn olóró, ìṣekúṣe, àwọn àrùn tí wọ́n ń kó látara ìbálòpọ̀, àbòsí, àgàbàgebè àwọn ẹlẹ́sìn àti ọ̀pọ̀ nǹkan mìíràn jẹ́ ká mọ bí ètò àwọn nǹkan tí Sátánì ń ṣàkóso ṣe burú tó. (Fi wé Gálátíà 5:19-21.) Àní, títú Sátánì fó ní gbangba gẹ́gẹ́ bí ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí tún ń fa ìrora àti ìtìjú fáwọn tó ń tẹ̀ lé ìlànà Sátánì. “Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gé ahọ́n wọn jẹ nítorí ìrora wọn,” pàápàá jù lọ láwọn ilẹ̀ tí ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti gbilẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ò nífẹ̀ẹ́ sí bí ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì ṣe ń tú ìwà tí wọ́n ń hù fó. Ṣe ni ẹ̀kọ́ òtítọ́ yìí ń dáyà fo àwọn kan, wọ́n sì ń ṣe inúnibíni sí àwọn tó ń kéde rẹ̀. Wọ́n ṣá Ìjọba Ọlọ́run tì wọ́n sì kẹ́gàn orúkọ mímọ́ Jèhófà. Títú tá a tú wọn fó pé ipò aláìmọ́ ni wọ́n wà nípa tẹ̀mí mú kí wọ́n sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run ọ̀run. Wọn “kò . . . ronú pìwà dà àwọn iṣẹ́ wọn” rárá. Nítorí náà, a ò lè retí pé kí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn yí ọkàn wọn padà ṣáájú òpin ètò àwọn nǹkan yìí.—Aísáyà 32:6.

Yorùbá Publications (1987-2026)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́