Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Kí ni “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè” ní Ha–Mágẹ́dọ́nì túmọ̀ sí, kí ló sì máa jẹ́ àbájáde ogun náà?—Ìṣípayá 16:14,16.
Láìdéènàpẹnu, Ha–Mágẹ́dọ́nì jẹ́ ogun kan tó máa jà kárí ayé lọ́jọ́ iwájú nínú èyí tí Jésù Kristi tí í ṣe ọba tí Jèhófà yàn ti máa pa gbogbo àwọn ọ̀tá Ọlọ́run rẹ́. Bíbélì ṣàlàyé pé “àwọn àgbéjáde tí àwọn ẹ̀mí èṣù mí sí,” mú kí “àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé” tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run wọ̀nyí kóra jọ pọ̀ “sí ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè . . . sí ibi tí à ń pè ní Ha–Mágẹ́dọ́nì lédè Hébérù.”—Ìṣípayá 16:14, 16.
Kì í ṣe ibì kan ní pàtó làwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé wọ̀nyí kóra jọ pọ̀ sí o. Orúkọ náà Ha–Mágẹ́dọ́nì tàbí “Amagẹdọni” bá a ṣe lò ó nínú àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì kan, túmọ̀ sí “Òkè Ńlá Mẹ́gídò.” (Ìṣípayá 16:16) Kò tíì sí òkè kankan rí tó ń jẹ orúkọ yẹn. Yàtọ̀ síyẹn, kò ṣeé ṣe kí “àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé àti àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn” wọ̀nyí kóra jọ pọ̀ sójú kan náà. (Ìṣípayá 19:19) Ní ti gidi, “ibi” táwọn ọba ilẹ̀ ayé wọ̀nyí kóra jọ pọ̀ sí ń tọ́ka sí ipò táwọn ọba wọ̀nyí àtàwọn amúgbálẹ̀gbẹ̀ wọn fi ara wọn sí, ìyẹn ipò ṣíṣòdì sí Jèhófà àtàwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ń bẹ ní ọ̀run lábẹ́ Jésù Kristi tó jẹ́ olórí ajagunṣẹ́gun “Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa.”—Ìṣípayá 19:14, 16.
Ó yẹ ká kíyè sí i pé, ọ̀rọ̀ náà, “Ha-Mágẹ́dọ́nì,” ní í ṣe pẹ̀lú ìlú kan láyé ọjọ́un tó ń jẹ́ Mẹ́gídò. Mẹ́gídò wà ní apá ìlà oòrùn Òkè Kámẹ́lì, ó sì láṣẹ lórí àwọn ọ̀nà ńlá táwọn oníṣòwò àtàwọn ológun ayé ọjọ́un máa ń gbà. Mẹ́gídò tún jẹ́ ibi tí wọ́n ti ja àwọn ìjà àjàmọ̀gá. Bí àpẹẹrẹ, “lẹ́bàá omi Mẹ́gídò” ni Bárákì tó jẹ́ Onídàájọ́ Ísírẹ́lì nígbà kan rí ti ṣẹ́gun Ọ̀gágun Sísérà àtàwọn ọmọ ogun kénáánì tó lágbára gan an. (Onídàájọ́ 4:12-24; 5:19, 20) Lágbègbè kan náà yìí ni Gídíónì ti ṣẹ́gun àwọn ará Mídíánì yán-ányán-án. (Onídàájọ́ 7:1-22) Nítorí náà, bí Bíbélì ṣe lo Mẹ́gídò fún ogun ọjọ́ ńlá Jèhófà ń fi dá wa lojú pé Ọlọ́run yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́nà tí wọn ò fi ní lè gbérí mọ́ láé nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀.
Kí ló máa wá jẹ́ àbájáde rẹ̀? Ogun Ha–Mágẹ́dónì yìí yóò mú ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà ibi kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Yóò mú àkókò tó dára jù lọ tí ò tíì ṣẹlẹ̀ rí wá. (Ìṣípayá 21:1-4) Nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso, ayé yóò di Párádísè níbi tí àwọn olódodo yóò máa gbé títí láé.—Sáàmù 37:29.