Ẹ Wà Ní Ìmúratán De Ọjọ́ Jèhófà
“Ẹ wà ní ìmúratán, nítorí pé ní wákàtí tí ẹ kò ronú pé yóò jẹ́, ni Ọmọ ènìyàn ń bọ̀.”—MÁTÍÙ 24:44.
1. Kí nìdí tó fi yẹ ká fiyè sí ọjọ́ Jèhófà?
ỌJỌ́ ogún àti ìbínú kíkan, ọjọ́ wàhálà àti làásìgbò, ọjọ́ òkùnkùn àti ìsọdahoro ni ọjọ́ Jèhófà yóò jẹ́. Ó dájú pé “ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù” Jèhófà yóò dé sórí ètò àwọn nǹkan burúkú yìí gẹ́gẹ́ bí Ìkún Omi ṣe gbá ayé burúkú ọjọ́ Nóà lọ. Ó dájú pé ọjọ́ yẹn yóò dé. Àmọ́, “olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni yóò yè bọ́.” (Jóẹ́lì 2:30-32; Ámósì 5:18-20) Ọlọ́run yóò pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ run yóò sì dáàbò bò àwọn èèyàn rẹ̀. Ẹ̀mí ìjẹ́kánjúkánjú ni wòlíì Sefanáyà fi kéde pé: “Ọjọ́ ńlá Jèhófà sún mọ́lé. Ó sún mọ́lé, ìyára kánkán rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi.” (Sefanáyà 1:14) Ó dára, ìgbà wo tiẹ̀ ni Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́ yẹn?
2, 3. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká múra sílẹ̀ de ọjọ́ Jèhófà?
2 Jésù sọ pé: “Ní ti ọjọ́ àti wákàtí yẹn, kò sí ẹnì kankan tí ó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ọ̀run tàbí Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba nìkan.” (Mátíù 24:36) Níwọ̀n bí a kò ti mọ àkókò yẹn ní pàtó, ó ṣe pàtàkì nígbà náà pé ká máa fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2004 sọ́kàn, tó sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà . . . Ẹ wà ní ìmúratán.”—Mátíù 24: 42, 44.
3 Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà àìròtẹ́lẹ̀ tí a ó gbà dáàbò bo àwọn tó wà ní ìmúratán, tí a ó sì fi àwọn tí kò sí ní ìmúratán sílẹ̀, ó sọ pé: “Àwọn ọkùnrin méjì yóò wà nínú pápá: a óò mú ọ̀kan lọ, a ó sì pa èkejì tì; àwọn obìnrin méjì yóò máa lọ nǹkan lórí ọlọ ọlọ́wọ́: a óò mú ọ̀kan lọ, a ó sì pa èkejì tì.” (Mátíù 24:40, 41) Nígbà tọ́rọ̀ náà bá dé ojú ọ̀gbagadè tá à ń wí yìí, ipò wo ló yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa wà? Ṣé a óò wà ní ìmúratán ni àbí ọjọ́ náà yóò bá wa láìròtẹ́lẹ̀? Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí sinmi lórí ohun tá a bá ń ṣe nísinsìnyí. Tá a bá fẹ́ fì hàn pé a wà ní ìmúratán de ọjọ́ Jèhófà, a gbọ́dọ̀ yàgò fún àwọn ìwà kan tó gbòde kan lónìí, ká dènà jíjìn sínú ọ̀fìn ipò ti kò dára nípa tẹ̀mí, ká sì yẹra fún àwọn ọ̀nà ìgbésí ayé kan pàtó.
Yẹra fún Ẹ̀mí Àìka-Nǹkan-Sí
4. Irú ìwà wo làwọn èèyàn ọjọ́ Nóà ń hù?
4 Jẹ́ ká gbé ọjọ́ Nóà yẹ̀ wò. Bíbélì sọ pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni Nóà, lẹ́yìn fífún un ní ìkìlọ̀ àtọ̀runwá nípa àwọn ohun tí a kò tíì rí, fi ìbẹ̀rù Ọlọ́run hàn, ó sì kan ọkọ̀ áàkì fún ìgbàlà agbo ilé rẹ̀.” (Hébérù 11:7) Ohun àjèjì kan tí kò fara sin ni ọkọ̀ áàkì náà jẹ́ nígbà yẹn. Ìyẹn nìkan kọ́ o, Nóà tún jẹ́ “oníwàásù òdodo.” (2 Pétérù 2:5) Síbẹ̀, ọkọ̀ tí Nóà kàn àti ìṣẹ́ ìwàásù tó ṣe kò yí àwọn èèyàn ọjọ́ rẹ̀ lọ́kàn padà. Kí ló fà á? Nítorí pe wọ́n ń “jẹ, wọ́n sì ń mu, àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó, a sì ń fi àwọn obìnrin fúnni nínú ìgbéyàwó.” Gbogbo àwọn tí Nóà ń wàásù fún nígbà yẹn ni ọ̀ràn ti ara wọn àti ayé jíjẹ́ gbà lọ́kàn débi pé “wọn kò sì fiyè sí i títí ìkún omi fi dé, tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ.”—Mátíù 24:38, 39.
5. Irú èrò wo làwọn olùgbé Sódómù ní nígbà ayé Lọ́ọ̀tì?
5 Bákan náà lọ̀rọ̀ rí láwọn ọjọ́ Lọ́ọ̀tì. Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé: “Wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń rà, wọ́n ń tà, wọ́n ń gbìn, wọ́n ń kọ́lé. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ tí Lọ́ọ̀tì jáde kúrò ní Sódómù, òjò iná àti imí-ọjọ́ rọ̀ láti ọ̀run, ó sì pa gbogbo wọn run.” (Lúùkù 17:28, 29) Lẹ́yìn tí áńgẹ́lì ti kìlọ̀ fún Lọ́ọ̀tì nípa ìparun tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀, òun náà sọ nípa ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀ fún àwọn ọkùnrin tó jẹ́ àna rẹ̀. Bo tilẹ̀ jẹ́ pé lójú tiwọn, Lọ́ọ̀tì “dà bí ọkùnrin tí ń ṣàwàdà.”—Jẹ́nẹ́sísì 19:14.
6. Irú ìwà wo la gbọ́dọ̀ yàgò fún?
6 Jésù sọ pé gẹ́gẹ́ bó ṣe rí láwọn ọjọ́ Nóà àti Lọ́ọ̀tì, “bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn yóò rí.” (Mátíù 24:39; Lúùkù 17:30) Láìṣe àní-àní, ìwà tó gbòde kan lónìí ni ìwà àìka-nǹkan-sí. A gbọ́dọ̀ wà lójúfò kí èèràn yẹn má bàa ràn wá. Kò sí ohun tó burú nínú ká gbádùn oúnjẹ aládùn, ká sì mu ọtí níwọ̀nba. Bákan náà, Ọlọ́run ló ṣètò ìgbéyàwó. Àmọ́ ṣá o, tó bá jẹ́ pé irú àwọn ọ̀ràn wọ̀nyẹn la kà sí ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé wa, ta a wá gbé ire tẹ̀mí jù sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ǹjẹ́ a lè sọ pé àwa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan wà ní ìmúratán de ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù Jèhófà?
7. Ìbéèrè pàtàkì wo ló yẹ ká béèrè ká tó dáwọ́ lé ohunkóhun, kí sì nìdí tó fi yẹ ká béèrè irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀?
7 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àkókò tí ó ṣẹ́ kù ti dín kù. Láti ìsinsìnyí lọ, kí àwọn tí wọ́n ní aya dà bí ẹni pé wọn kò ní.” (1 Kọ́ríńtì 7:29-31) Àkókò tó ṣẹ́ kù láti parí iṣẹ́ wíwàásù Ìjọba náà tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́ kò tó nǹkan mọ́. (Mátíù 24:14) Kódà Pọ́ọ̀lù gbà àwọn lọ́kọláya níyànjú pé kí wọ́n má fi gbogbo àkókò wọn máa gbọ́ ti ọkọ wọn tàbí ti aya wọn débi tí wọ́n á wá fi ire Ìjọba náà sí ipò kejì nínú ìgbésí ayé wọn. Ó ṣe kedere pé, ńṣe ni Pọ́ọ̀lù ń gbà wá níyànjú pé kí a má ṣe dẹra nù. Jésù sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo [Ọlọ́run] lákọ̀ọ́kọ́.” (Mátíù 6:33) Nígbà tá a bá fẹ ṣèpinnu kan tàbí tá a bá fẹ́ lépa ohun kan, ìbéèrè pàtàkì tó yẹ ká béèrè ni pé, ‘Báwo ni èyí yóò ṣe kan fífi ire Ìjọba náà sí ipò kìíní nínú ìgbésí mi?’
8. Bá a bá ti ki ara bọ kòókòó jàn-án-jàn-án ìgbésí ayé jù, kí ló yẹ ká ṣe?
8 Ó dára, tó bá jẹ́ pé a wá ṣàkíyèsí pé a ti ki ara bọ kòókòó jàn-án-jàn-án ìgbésí ayé débi pé ó tí fún ire tẹ̀mí wa pa ńkọ́? Ṣé kì í ṣe pé ìyàtọ̀ díẹ̀ ló wà nínú bá a ṣe ń gbé ìgbésí ayé wa àti báwọn aládùúgbò wa tí kò ní ìmọ̀ Ìwé Mímọ́ tó péye, tí wọn kì í tún ṣe olùpòkìkí Ìjọba náà ṣe ń gbé ìgbésí ayé wọn? Bọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká fi sínú àdúrà. Jèhófà yóò jẹ́ ká ní ẹ̀mí ìrònú tó tọ́. (Róòmù 15:5; Fílípì 3:15) Ọlọ́run yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fi ire Ìjọba náà sí ipò kìíní, ká sì ṣe ohun tó tọ́, ká sì tún ṣe ojúṣe wa sí Ọlọ́run.—Róòmù 12:2; 2 Kọ́ríńtì 13:7.
Dènà Títòògbé Nípa Tẹ̀mí
9. Ní ìbámu pẹ̀lú Ìṣípayá 16:14-16, kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti dènà títòògbé nípa tẹ̀mí?
9 Àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ nípa “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè” tó ń bọ̀ ní Amágẹ́dọ́nì kìlọ̀ pé àwọn kan lè má wà lójúfò. Jésù Kristi Olúwa sọ pé “Wò ó! Mo ń bọ̀ bí olè. Aláyọ̀ ni ẹni tí ó wà lójúfò, tí ó sì pa ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ mọ́, kí ó má bàa rìn ní ìhòòhò, kí àwọn ènìyàn sì wo ipò ìtìjú rẹ̀.” (Ìṣípayá 16:14-16) Ẹ̀wù àwọ̀lékè tí a mẹ́nu kàn lókè yìí ń tọ́ka sí àmì tó ń fi wa hàn gẹ́gẹ́ bí Kristẹni Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lára àmì yìí ni iṣẹ́ wa tí à ń ṣe gẹ́gẹ́ bí olùpòkìkí Ìjọba náà àti ìwà wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. Bí a bá dẹra nù tí a sì tipa bẹ́ẹ̀ di aláìṣiṣẹ́ mọ́ nítorí pé a ti bẹ̀rẹ̀ sí tòògbé, ó ṣeé ṣe ká má ní àmì tá a fi ń dá wa mọ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristẹni mọ́. Ìtìjú ńlá gbáà ló máa jẹ́, ìyẹn sì léwu. A gbọ́dọ̀ dènà àwọn ohun tó lè mú wa máa tòògbé nípa tẹ̀mí. Báwo la ṣe lè dènà irú nǹkan bẹ́ẹ̀?
10. Báwo ni kíka Bíbélì lójoojúmọ́ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa wà lójúfò nípa tẹ̀mí?
10 Lemọ́lemọ́ ni Bíbélì tẹnu mọ́ ìdí tí a fi ní láti wà lójúfò ká sì pa agbára ìmòye wa mọ́. Bí àpẹẹrẹ, àkọsílẹ̀ Ìhìn Rere rán wa létí pé ká “máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà” (Mátíù 24:42; 25:13; Máàkù 13:35, 37); ká “wà ní ìmúratán” (Mátíù 24:44); ‘ká máa wọ̀nà, ká wà lójúfò’ (Máàkù 13:33); ká sì “wà ní ìmúratán” (Lúùkù 12:40). Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ọjọ́ Jèhófà yóò dé lójijì sórí ayé yìí, ó wá rọ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a máa sùn gẹ́gẹ́ bí àwọn yòókù ti ń ṣe, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a wà lójúfò, kí a sì pa agbára ìmòye wa mọ́.” (1 Tẹsalóníkà 5:6) Nínú ìwé tó kẹ́yìn Bíbélì, Jésù Kristi tí a ti ṣe lógo tẹnu mọ́ ọn pé òun yóò dé lójijì, nígbà tó sọ pé: “Mo ń bọ̀ kíákíá.” (Ìṣípayá 3:11; 22:7, 12, 20) Ọ̀pọ̀ lára àwọn wòlíì Hébérù pẹ̀lú tún ṣàpèjúwe ọjọ́ ìdájọ́ ńlá Jèhófà, wọ́n sì ṣèkìlọ̀ nípa rẹ̀. (Aísáyà 2:12, 17; Jeremáyà 30:7; Jóẹ́lì 2:11; Sefanáyà 3:8) Kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí í ṣe Bíbélì lójoojúmọ́, ká sì ronú jinlẹ̀ lórí ohun tá a bá kà nínú rẹ̀ yóò ràn wá lọ́wọ́ gan-an láti máa bá a lọ ní wíwà lójúfò nípa tẹ̀mí.
11. Kí nìdí tí dídákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé fi ṣe pàtàkì ká bàa lè wà lójúfò nípa tẹ̀mí?
11 Bẹ́ẹ̀ ni o, ohun tó lè mú ká wà lójúfò nípa tẹ̀mí ni ìdákẹ́kọ̀ọ́ aláápọn nínú Ìwé Mímọ́, nípa lílo àwọn ìtẹ̀jáde tá a gbé karí Bíbélì, èyí tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń pèsè! (Mátíù 24:45-47) Àmọ́ ṣá o, bá a bá fẹ́ kí ìdákẹ́kọ̀ọ́ wa jẹ́ èyí tí yóò ṣe wá láǹfààní, a gbọ́dọ̀ máa ṣe é déédéé kó sì múná dóko. (Hébérù 5:14–6:3) A gbọ́dọ̀ máa jẹ oúnjẹ líle nípa tẹ̀mí déédéé. Ó lè gba akitiyan ká tó lè rí àkókò fún ìdákẹ́kọ̀ọ́ láyé òde òní. (Éfésù 5:15, 16) Síbẹ̀síbẹ̀, kò yẹ kí ó jẹ́ kìkì àkókò tó bá rọrùn fún wa nìkan la ó máa ka Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde tá a gbé karí Ìwé Mímọ́. Ìdákẹ́kọ̀ọ́ tó ṣe déédéé ṣe pàtàkì tá a bá “fẹ́ jẹ́ onílera nínú ìgbàgbọ́” ká sì wà lójúfò.—Títù 1:13.
12. Báwo ni àwọn ìpàdé Kristẹni àtàwọn àpéjọ ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti borí títòògbé nípa tẹ̀mí?
12 Àwọn ìpàdé Kristẹni àtàwọn àpéjọ tún máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti borí títòògbé nípa tẹ̀mí. Lọ́nà wo? Nípasẹ̀ ìtọ́ni tá à ń rí gbà níbẹ̀ ni. Láwọn ibi ìkórajọ yìí, ǹjẹ́ kì í ṣe ìgbà gbogbo la máa ń rán wa létí nípa bí ọjọ́ Jèhófà ti sún mọ́lé tó? Àwọn ìpàdé Kristẹni tá à ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ tún fún wa láǹfààní láti “ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà.” Bá a ṣe ń ru ara wa sókè yẹn gan-an ló mú kó rọrùn láti máa wà lójúfò nípa tẹ̀mí. Abájọ tá a fi pa á láṣẹ fún wa pe ká máa pé jọ pọ̀ déédéé níwọ̀n “bí [a] ti rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.”—Hébérù 10:24, 25.
13. Báwo ni ìṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti wà lójúfò nípa tẹ̀mí?
13 A tún ń rí ìrànlọ́wọ́ gbà láti wà lójúfò nígbà tá a bá ń ṣe ìṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni wa tọkàntọkàn. Bí a kò bá fẹ́ gbàgbé àwọn àmì àkókò tá a wà yìí àti ìtumọ̀ wọn, ọ̀nà mìíràn wo ló tún dára ju ká máa sọ nípa wọn fún àwọn ẹlòmíràn? Nígbà tá a bá tún rí àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ń tẹ̀ síwájú tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi ohun tí wọ́n ń kọ́ ṣèwà hù, ẹ̀mí ìjẹ́kánjúkánjú tá a ní yóò túbọ̀ máa pọ̀ si. Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Ẹ mú èrò inú yín gbára dì fún ìgbòkègbodò, ẹ pa agbára ìmòye yín mọ́ lọ́nà pípé pérépéré.” (1 Pétérù 1:13) Ọ̀nà àbáyọ dídára kan tá a fi lè bọ́ kúrò lọ́wọ́ títòògbé nípa tẹ̀mí ni pé “kí [á] máa ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ Olúwa.”—1 Kọ́ríńtì 15:58.
Sá fún Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tó Lè Ṣàkóbá Nípa Tẹ̀mí
14. Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Lúùkù 21:34-36, ìrù ìgbésí ayé wo ni Jésù sọ pé ká sá fún?
14 Nínú àsọtẹ́lẹ̀ kíkàmàmà tí Jésù sọ nípa àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀, ó tún fún wa ni ìkìlọ̀ mìíràn. Ó sọ pé: “Ẹ kíyè sí ara yín, kí ọkàn-àyà yín má bàa di èyí tí a dẹrù pa pẹ̀lú, lójijì tí ọjọ́ yẹn yóò sì dé bá yín ní ìṣẹ́jú akàn gẹ́gẹ́ bí ìdẹkùn. Nítorí yóò dé bá gbogbo àwọn tí ń gbé ní ojú gbogbo ilẹ̀ ayé. Ẹ máa wà lójúfò, nígbà náà, ní rírawọ́ ẹ̀bẹ̀ ní gbogbo ìgbà, kí ẹ lè kẹ́sẹ járí ní yíyèbọ́ nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ láti ṣẹlẹ̀, àti ní dídúró níwájú Ọmọ ènìyàn.” (Lúùkù 21:34-36) Ọ̀nà tí Jésù gbà ṣàpèjúwe bí àwọn èèyàn lápapọ̀ ṣe ń gbé ìgbésí ayé wọn ṣe kedere, àwọn ọ̀nà náà nìwọ̀nyí: àjẹjù, ìmutíyó kẹ́ri àti ìgbésí ayé tó kún fún àníyàn.
15. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ yàgò fún àjẹkì àti ọtí àmujù?
15 Àjẹjù àti ìmutíyó kẹ́ri kò bá ìlànà Ìwé Mímọ́ mu, a sì gbọ́dọ̀ sá fún un. Bíbélì sọ pé: “Má ṣe wá wà lára àwọn tí ń mu wáìnì ní àmuyó kẹ́ri, lára àwọn tí ń jẹ ẹran ní àjẹkì.” (Òwe 23:20) Àmọ́ ṣá o, kò dìgbà tá a bá jẹ oúnjẹ lájẹkì tàbí tá a bá mu ọtí yó kẹ́ri kó tó pa wá lára nípa tẹ̀mí. Oúnjẹ jíjẹ àti ọtí mímu lè mú oorun kunni tàbí kó sọ ẹnì kan di ọ̀lẹ kí àṣejù tó wọ̀ ọ́ pàápàá. Òwe Bíbélì kan sọ pé: “Ọ̀lẹ ń fọkàn fẹ́, ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ kò ní nǹkan kan.” (Òwe 13:4) Irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè fẹ́ láti ṣèfẹ́ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kó má lè ṣe é nítorí pé ọ̀lẹ ni.
16. Báwo la ṣe lè yẹra fún dídi ẹni tí ṣíṣàníyàn nípa ìdílé bò mọ́lẹ̀?
16 Kí ni àwọn àníyàn ìgbésí ayé tí Jésù ní ká sá fún? Lára wọn làwọn nǹkan tó ń jẹ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lọ́kàn, pípèsè fún ìdílé ẹni àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹ wo bí yóò ti jẹ́ ìwà òmùgọ̀ tó láti jẹ́ káwọn nǹkan wọ̀nyí dẹ́rù pa wá! Jésù béèrè pé: “Ta ni nínú yín, nípa ṣíṣàníyàn, tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ìwọ̀n gígùn ìwàláàyè rẹ̀?” Ó gba àwọn olùgbọ́ rẹ̀ níyànjú pé: “Ẹ má ṣàníyàn láé, kí ẹ sì wí pé, ‘Kí ni a ó jẹ?’ tàbí, ‘Kí ni a ó mu?’ tàbí, ‘Kí ni a ó wọ̀?’ Nítorí gbogbo ìwọ̀nyí ni nǹkan tí àwọn orílẹ̀-èdè ń fi ìháragàgà lépa. Nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan wọ̀nyí.” Bá a bá fi ire Ìjọba náà sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé wa, tá a sì ní ìgbọ́kànlé pé Jèhófà yóò pèsè àwọn ohun tá a nílò fún wa, ìyẹn á jẹ́ kí àníyàn wa mọ níwọ̀n, yóò sì jẹ́ ká lè wà lójúfò.—Mátíù 6:25-34.
17. Báwo ni lílépa àtilà ṣe lè mú kí ẹnì kan máa ṣàníyàn?
17 Ṣíṣe kìràkìtà láti di ọlọ́là tún lè fà àníyàn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan ń dágbá lé ohun tágbára wọn ò ká. Àwọn mìíràn tí lọ́wọ́ nínú okòwò tó ń sọni dolówó òjijì àtàwọn okòwò mìíràn tó léwu. Ní tàwọn mìíràn, ẹ̀kọ́ ìwé nínú ayé ti di ìdẹkùn fún wọn nítorí kí wọ́n lè lówó lọ́wọ́ bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀. Lóòótọ́, kíkàwé dé ààyè kan lè jẹ́ kéèyàn tètè ríṣẹ́. Àmọ́ ṣá o, òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, níbì táwọn kan tí ń fi ọ̀pọ̀ àkókò lépa ẹ̀kọ́ ìwé gíga, díẹ̀ nínú wọn ti ṣe ara wọn léṣe nípa tẹ̀mí. Ẹ ò rí pé ó léwu gan-an láti wà nínú irú ipò yìí bí ọjọ́ Jèhófà ti ń sún mọ́lé! Bíbélì kìlọ̀ pé: “Àwọn tí ó pinnu láti di ọlọ́rọ̀ máa ń ṣubú sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn àti ọ̀pọ̀ ìfẹ́-ọkàn tí í ṣe ti òpònú, tí ó sì ń ṣeni lọ́ṣẹ́, èyí tí ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé.”—1 Tímótì 6:9.
18. Kí ni a gbọ́dọ̀ ṣe bí a kò bá fẹ́ dẹni tí ìlépa ọ̀rọ̀ àlùmọ́ọ́nì gbà lọ́kàn?
18 Ohun pàtàkì tó lè ṣèrànwọ́ fún ẹnì kan tí kò fi ní dẹni tí ìlépa ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì gbà lọ́kàn ni pé, kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ mọ bí a ṣe lè fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ nígbà tó bá fẹ́ ṣèpinnu. Ẹnì kan lè ṣe èyí nípa jíjẹ́ ‘oúnjẹ líle tó jẹ́ ti àwọn ènìyàn tó dàgbà dénú’ àti nípa ‘tí tipasẹ̀ lílò ó kọ́ agbára ìwòye’ rẹ̀. (Hébérù 5:13, 14) Ohun mìíràn tí kò tún ní jẹ́ ká ṣèpinnu tí kò tọ́ nípa ohun tó yẹ kó gba ipò kìíní nínú ìgbésí ayé wa ni pé, kí a “máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.”—Fílípì 1:10.
19. Bá a bá rí i pé à kò ní àkókò tó pọ̀ tó fun lílépa àwọn ohun tẹ̀mí, kí ló yẹ ká ṣe?
19 Ọ̀nà ìgbésí ayé onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì lè fọ́ wa lójú débí pé kò ní sí àyè fún lílépa ohun tẹ̀mí mọ́. Báwo la ṣe lè ṣàyẹ̀wò ara wa tí a kò fi ní dẹni tó ń gbé ìgbésí ayé rẹ̀ lọ́nà yẹn? A ní láti gbé ìgbésí ayé wa yẹ̀ wò tàdúràtàdúrà ká má bàa walé ayé máyà. Sólómọ́nì ọba Ísírẹ́lì ayé ìgbàanì sọ pé: “Dídùn ni oorun ẹni tí ń ṣiṣẹ́ sìn, ì báà jẹ́ oúnjẹ díẹ̀ tàbí púpọ̀ ni ó jẹ; ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ tí ó jẹ́ ti ọlọ́rọ̀ kì í jẹ́ kí ó sùn.” (Oníwàásù 5:12) Ṣé a kì í lo ọ̀pọ̀ àkókò láti bójú tó àwọn ohun ìní tara tí kò pọn dandan tó sì tún ń tánni lókun? Bí ohun ìní wa bá ṣe pọ̀ tó náà ni ohun tí a ó máa bójú tó, tá ó máa sanwó ìbánigbófò lé lórí àtàwọn ohun tá ó máa dáàbò bò yóò ṣe pọ̀ tó. Nígbà náà, ṣé kò wá ní ṣàǹfààní fún wa láti dín àwọn ohun ìní wa kù ká má bàa wa ilé ayé máyà?
Ní Gbogbo Ọ̀nà, Ẹ Wà Ní Ìmúratán
20, 21. (a) Kí ni ohun tí àpọ́sítélì Pétérù mú dá wa lójú nípa ọjọ́ Jèhófà? (b) Àwọn ìwà àti iṣẹ́ wo ló ń fi hàn pé a wà ní ìmúratán de ọjọ́ Jèhófà?
20 Ayé ìgbà ọjọ́ Nóà pa run, ó sì dájú pé ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí náà yóò pa run ṣáá ni. Àpọ́sítélì Pétérù mú un dá wa lójú pé: “Ọjọ́ Jèhófà yóò dé gẹ́gẹ́ bí olè, nínú èyí tí àwọn ọ̀run yóò kọjá lọ pẹ̀lú ariwo tí ó dún ṣì-ì-ì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ìpìlẹ̀ tí ó ti gbóná janjan yóò di yíyọ́, ilẹ̀ ayé àti àwọn iṣẹ́ tí ń bẹ nínú rẹ̀ ni a ó sì wá rí.” Bóyá ọ̀run ìṣàpẹẹrẹ, ìyẹn àwọn olùṣàkóso búburú tàbí ayé ìṣàpẹẹrẹ, ìyẹn ìran ènìyàn tó ti sọ ara wọn dọ̀tá Ọlọ́run ni o, kò sí èyíkéyìí nínú wọn tí yóò la gbígbóná ìbínú Ọlọ́run tó ń jó bí iná já. Nígbà tí Pétérù ń ṣàlàyé bá a ṣe lè wà ní ìmúratán de ọjọ́ náà, ó sọ̀rọ̀ tìtaratìtara pé: “Níwọ̀n bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ti di yíyọ́ báyìí, irú ènìyàn wo ni ó yẹ kí ẹ jẹ́ nínú ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run, ní dídúró de wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà àti fífi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí!”—2 Pétérù 3:10-12.
21 Lílọ sí ìpàdé Kristẹni déédéé àti kíkópa nínú wíwàásù ìhìn rere náà wà lára àwọn ìwà àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run tá à ń sọ yìí. Ǹjẹ́ kí a máa báa lọ ní ṣíṣe àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run bá a ti ń fi sùúrù dúró de ọjọ́ ńlá Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká ‘sa gbogbo ipá wa kí Ọlọ́run lè bá wa nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín ní àìléèérí àti ní àìlábààwọ́n àti ní àlàáfíà.’—2 Pétérù 3:14.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ fi hàn pé a wà ní ìmúratán de ọjọ́ Jèhófà?
• Bá a bá ti ki ara bọ kòókòó jàn-án-jàn-án ìgbésí ayé jù, kí ló yẹ ká ṣe?
• Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti dènà títòògbé nípa tẹ̀mí?
• Ọ̀nà ìgbésí ayé búburú wo la gbọ́dọ̀ yàgò fún, báwo ni a ṣe lè ṣe é?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20, 21]
Àwọn èèyàn ọjọ́ Nóà kò fiyèsí ìdájọ́ tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ nígbà yẹn, ṣé ìwọ́ ń fiyèsí i lónìí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ṣé o lè yàgò fún fífi ohun tí kò pọndandan dí ara rẹ lọ́wọ́ kí o lè túbọ̀ rí àkókò sí i fún lílépa àwọn ohun tẹ̀mí?