ORÍ KEJÌ
“Ọ̀nà àti Òtítọ́ àti Ìyè”
1, 2. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé bá a bá fi dídàá wa, kò lè ṣeé ṣe fún wa láti sún mọ́ Jèhófà, kí sì ni Jésù Kristi ṣe fún wa nípa rẹ̀?
ǸJẸ́ o ti ṣìnà rí? Ó ṣeé ṣe kó o rántí ìgbà kan tọ́nà dà rú mọ́ ẹ lójú nígbà tó o fẹ́ lọ kí ọ̀rẹ́ rẹ tàbí mọ̀lẹ́bí rẹ kan. Nígbà tọ́nà yẹn ò fẹ́ yé ọ mọ́, ǹjẹ́ o ò dúró láti béèrè ọ̀nà lọ́wọ́ ẹnì kan? Ìgbà tó o sì béèrè, dípò kí aláàánú tó o béèrè ọ̀nà lọ́wọ́ rẹ̀ ì bá fi júwe bó o ṣe máa rìn ín fún ọ, ńṣe ló ní: “Ṣáà máa tọ̀ mí lẹ́yìn. Màá mú ọ débẹ̀.” Wo bí ara ṣe ti ní láti tù ọ́ tó!
2 Lọ́nà kan, irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ jọ ohun tí Jésù Kristi ṣe fún wa. Bá a bá fi dídàá wa, kò sí bá a ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run. Ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé tá a jogún ti kó gbogbo aráyé ṣìnà, ó ti “sọ wọ́n di àjèjì sí ìyè tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run.” (Éfésù 4:17, 18) A nílò afinimọ̀nà. Kì í ṣe pé Jésù, ẹlẹ́yinjú àánú tó fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wa kàn fún wa nímọ̀ràn àti ìtọ́ni nìkan ni, ó ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe rí i ní Orí 1 ìwé yìí, Jésù pè wá pé: “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.” (Mátíù 4:19) Àmọ́, ó tún jẹ́ ká mọ ìdí tó fi pọn dandan láti jẹ́ ìpè yẹn. Ìgbà kan wà tó sọ pé: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè. Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.” (Jòhánù 14:6) Ẹ jẹ́ ká wá gbé àwọn ìdí mélòó kan yẹ̀ wò tó fi jẹ́ pé ipasẹ̀ Jésù, tó jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run, nìkan la lè gbà sún mọ́ Baba. Lẹ́yìn tá a bá ti mọ àwọn ìdí náà tán, a óò wá jíròrò ọ̀nà tí Jésù gbà jẹ́ “ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè.”
Ipa Pàtàkì Ló Kó Nínú Mímú Ìfẹ́ Jèhófà Ṣẹ
3. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ipasẹ̀ Jésù la lè gbà sún mọ́ Ọlọ́run?
3 Ìdí àkọ́kọ́ ni pé Jèhófà ti yan Ọmọ rẹ̀ sí ipò tó ṣe pàtàkì jù lọ, torí náà ipasẹ̀ Jésù la fi lè sún mọ́ Ọlọ́run.a Òun ni ẹni tí Bàbá máa lò láti mú gbogbo ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ. (2 Kọ́ríńtì 1:20; Kòlósè 1:18-20) Ká tó lè lóye ipa pàtàkì tí Ọmọ fẹ́ kó yìí, a ní láti kọ́kọ́ ṣàgbéyẹ̀wò ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì, níbi tí àwọn èèyàn àkọ́kọ́ tí wọ́n jẹ́ tọkọtaya ti lẹ̀dí àpọ̀ pọ̀ pẹ̀lú Sátánì láti ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà.—Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17; 3:1-6.
4. Ọ̀ràn pàtàkì wo ni ọ̀tẹ̀ tó wáyé nínú ọgbà Édẹ́nì mú kó jẹ yọ, kí sì ni Jèhófà pinnu láti ṣe torí àtiyanjú ọ̀ràn pàtàkì tó wà nílẹ̀ náà?
4 Àìgbọ́ràn tó wáyé nínú ọgbà Édẹ́nì mú kí ọ̀ràn pàtàkì kan tó kan gbogbo ìṣẹ̀dá Ọlọ́run jẹ yọ. Ọ̀ràn pàtàkì ọ̀hún sì ni pé: Ǹjẹ́ ọ̀nà tó tọ́ ni Jèhófà Ọlọ́run ń gbà ṣàkóso àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀? Nítorí àtiyanjú ọ̀ràn pàtàkì tó délẹ̀ yìí, Jèhófà pinnu pé òun á jẹ́ kí ọ̀kan lára àwọn ọmọ òun tí wọ́n jẹ́ áńgẹ́lì pípé lọ sórí ilẹ̀ ayé. Ohun tó ṣe kókó gbáà sì ni ẹni tó bá lọ lára àwọn ọmọ Ọlọ́run yìí máa gbé ṣe, ìyẹn ni pé ó máa lọ yọ̀ǹda ẹ̀mí rẹ̀ láti fi hàn pé òótọ́ ni Jèhófà jẹ́ ọba aláṣẹ. Ó sì máa lọ fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe pàṣípààrọ̀ láti gba aráyé là. Nítorí pé ọmọ Ọlọ́run yìí á jẹ́ adúróṣinṣin títí tó fi máa kú, ó máa jẹ́ ká rí ojútùú sí gbogbo ìṣòro tí ọ̀tẹ̀ Sátánì dá sílẹ̀. (Hébérù 2:14, 15; 1 Jòhánù 3:8) Ṣùgbọ́n ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn áńgẹ́lì pípé tó jẹ́ ọmọ ni Jèhófà ní. (Dáníẹ́lì 7:9, 10) Èwo lára wọn ló yàn pé kó ṣe iṣẹ́ bàǹtàbanta yẹn? “Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo” tá a wá mọ̀ sí Jésù Kristi ló fiṣẹ́ náà rán.—Jòhánù 3:16.
5, 6. Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà fi hàn pé òun ní ìgbọ́kànlé nínú Ọmọ òun, kí ló sì jẹ́ kó nírú ìgbọ́kànlé bẹ́ẹ̀?
5 Ǹjẹ́ ó yẹ kó yà wá lẹ́nu pé Jésù ni Jèhófà yàn? Kò yẹ kó yà wá lẹ́nu rárá! Ọkàn Jèhófà tí í ṣe Bàbá balẹ̀ pátápátá lórí Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo. Ọ̀pọ̀ ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún kí Ọmọ náà tó wá sáyé ni Jèhófà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé Ọmọ òun á jẹ́ adúróṣinṣin bó ṣe wù kí ìṣòro tó bá kójú nira tó. (Àìsáyà 53:3-7, 10-12; Ìṣe 8:32-35) Ìwọ wo ohun tíyẹn túmọ̀ sí. Ọmọ yẹn ní òmìnira bíi tàwọn ańgẹ́lì àtàwọn èèyàn onílàákàyè mìíràn, ó sì lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ohun tó bá wù ú. Síbẹ̀ Jèhófà ṣì fọkàn tán an débi tó fi lè sọ tẹ́lẹ̀ pé Ọmọ òun á jẹ́ adúróṣinsin. Kí ló mú kí Jèhófà lè fọkàn tán an bẹ́ẹ̀? Lọ́rọ̀ kan, ìmọ̀ ni. Jèhófà mọ Ọmọ rẹ̀ dáadáa, ó sì mọ bó ṣe ń wù ú tó láti ṣe ohun tí Òun bá fẹ́. (Jòhánù 8:29; 14:31) Bí Ọmọ yìí ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Bàbá rẹ̀ ni Jèhófà náà ṣe nífẹ̀ẹ́ Ọmọ náà. (Jòhánù 3:35) Ìfẹ́ tó wà láàárín Bàbá àti Ọmọ yìí ló jẹ́ kí irú ìṣọ̀kan àti ìgbọ́kànlé tí mìmì kan ò lè mì bẹ́ẹ̀ wà láàárín wọn.—Kólósè 3:14.
6 Pẹ̀lú ipa pàtàkì tí Ọmọ kó yìí, ìgbọ́kànlé tí Bàbá rẹ̀ ní nínú rẹ̀ àti ìfẹ́ tó so àwọn méjèèjì pọ̀, ǹjẹ́ ó yẹ kó yà wá lẹ́nu pé ipasẹ̀ Jésù nìkan la fi lè sún mọ́ Ọlọ́run? Síbẹ̀, ó ṣì ku ìdí mìíràn tó fi jẹ́ pé Ọmọ yìí nìkan ló lè fi wá mọ̀nà dé ọ̀dọ́ Bàbá.
Ọmọ Nìkan Ló Mọ Baba Dáadáa
7, 8. Kí ló dé tá a fi lè sọ pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé kò sí ẹlòmíì tó mọ Bàbá “bí kò ṣe Ọmọ”?
7 Ká tó lè sún mọ́ Jèhófà, àwọn nǹkan kan wà tá a gbọ́dọ̀ ṣe. (Sáàmù 15:1-5) Ta ló mọ béèyàn ṣe lè ṣe ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ àti béèyàn ṣe lè rí ojú rere Ọlọ́run tó Ọmọ Rẹ̀? Jésù sọ pé: “Ohun gbogbo ni Baba mi ti fi lé mi lọ́wọ́, kò sì sí ẹnì kankan tí ó mọ Ọmọ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ bí kò ṣe Baba, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò mọ Baba ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ bí kò ṣe Ọmọ àti ẹnikẹ́ni tí Ọmọ fẹ́ láti ṣí i payá fún.” (Mátíù 11:27) Ẹ wá jẹ́ ká wo ohun tó lè mú kí Jésù fi gbogbo ẹnu sọ ọ́ láìsàsọdùn pé, kò sẹ́ni tó mọ Baba dáadáa “bí kò ṣe Ọmọ.”
8 Ọmọ náà sún mọ́ Jèhófà ju ẹnikẹ́ni mìíràn lọ torí pé òun ni “àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá.” (Kólósè 1:15) Wo bí ọ̀rọ̀ àárín Bàbá àti Ọmọ rẹ̀ yìí á ṣe wọ̀ tó látìgbà tẹ́nì kankan ò mọ̀, ìyẹn láti ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà ìṣẹ̀dá títí di àkókò tí wọ́n dá àwọn áńgẹ́lì mìíràn. (Jòhánù 1:3; Kólósè 1:16, 17) Tiẹ̀ wo àǹfààní ńláǹlà tí Ọmọ yẹn ní nígbà tó fi wà pẹ̀lú Bàbá rẹ̀, bó ṣe ń mọ èrò Bàbá rẹ̀ lórí àwọn nǹkan kan, tó sì ń lóye ohun tí Baba fẹ́, tó tún ń mọ àwọn òfin rẹ̀ àtàwọn ọ̀nà rẹ̀. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, kì í ṣe àsọdùn láti sọ pé Jésù mọ Bàbá rẹ̀ ju ẹnikẹ́ni mìíràn lọ. Bí òun àti Bàbá rẹ̀ ṣe sún mọ́ra yìí ló jẹ́ kí Jésù lè fi irú ẹni tí Bàbá rẹ̀ jẹ́ hàn wá lọ́nà tẹ́nikẹ́ni ò lè gbà fi hàn wá.
9, 10. (a) Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà fi irú ẹni tí Bàbá rẹ̀ jẹ́ hàn? (b) Kí Jèhófà bàa lè fojúure wò wá, kí la gbọ́dọ̀ ṣe?
9 Àwọn ẹ̀kọ́ tí Jésù fi kọ́ àwọn èèyàn jẹ́ ká rí i pé ó lóye bí Jèhófà ṣe ń ronú, bí nǹkan ṣe máa ń rí lára Jèhófà àti ohun tó ń fẹ́ káwọn olùjọsìn Rẹ̀ máa ṣe.b Jésù tún fi irú ẹni tí Bàbá rẹ̀ jẹ́ hàn lọ́nà pàtàkì mìíràn. Jésù ní: “Ẹni tí ó ti rí mi ti rí Baba pẹ̀lú.” (Jòhánù 14:9) Nínú gbogbo ohun tí Jésù ṣe àti nínú gbogbo ohun tó sọ ló ti fara wé Bàbá rẹ̀ lọ́nà pípé. Nítorí náà, nígbà tá a bá ka ìtàn Jésù nínú Bíbélì nípa bí àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ nígbà tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ṣe lágbára tó àti bó ṣe wọni lọ́kàn tó, tá a kà nípa bí ìyọ́nú ṣe mú kó wo àwọn aláìsàn sàn tá a sì kà nípa bó ṣe yọ omi lójú nítorí pé ó fi ọ̀ràn ẹlòmíràn ro ara rẹ̀ wò, a lè fojú inú wò ó pé Jèhófà ló ń ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyẹn. (Mátíù 7:28, 29; Máàkù 1:40-42; Jòhánù 11:32-36) Àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọmọ Ọlọ́run sọ àtohun tó gbé ṣe jẹ́ ká rí àwọn ọ̀nà Ọlọ́run àtohun tí Ọlọ́run fẹ́. (Jòhánù 5:19; 8:28; 12:49, 50) Nípa báyìí, bá a bá fẹ́ rí ojúure Jèhófà, a ní láti ṣègbọràn sí àwọn ẹ̀kọ́ tí Jésù fi kọ́ni ká sì fìwà jọ ọ́.—Jòhánù 14:23.
10 Níwọ̀n bí Jésù ti sún mọ́ Jèhófà tímọ́tímọ́ tó báyìí, tó sì tún fìwà jọ ọ́ lọ́nà pípé, a wá lè rí ìdí tí Jèhófà fi pinnu láti mú kó jẹ́ pé nípasẹ̀ Ọmọ yìí nìkan la fi lè sún mọ́ ọ̀dọ́ Òun. Nísinsìnyí tá a ti wá lóye pé ipasẹ̀ Jésù nìkan ṣoṣo la lè gbà sún mọ́ Jèhófà, ẹ wá jẹ́ ká jíròrò ohun tí ọ̀rọ̀ Jésù yìí túmọ̀ sí, èyí tó sọ pé: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè. Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.”—Jòhánù 14:6.
“Èmi Ni Ọ̀nà”
11. (a) Báwo ló ṣe jẹ́ pé ipasẹ̀ Jésù nìkan la fi lè ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run? (b) Ọ̀nà wo ni ọ̀rọ̀ tó wà nínú Jòhánù 14:6 gbà tẹnu mọ́ ipò àrà ọ̀tọ̀ tí Jésù wà? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
11 A ti kẹ́kọ̀ọ́ pé kò sí bá a ṣe lè sún mọ́ Jèhófà láìṣe pé a lọ nípasẹ̀ Jésù. Ẹ jẹ́ ká tú iṣu gbólóhùn yìí désàlẹ̀ ìkòkò, ká mọ ohun tó ń béèrè pé ká ṣe. Jésù ni “ọ̀nà” ní ti pé ọ̀dọ̀ rẹ̀ nìkan la lè gbà ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run. Kí nìdí tó fi jẹ́ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé Jésù dúro ṣinṣin dójú ikú, èyí tó túmọ̀ sí pé ó fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ẹbọ ìràpadà. (Mátíù 20:28) Bí kì í báa ṣe ti ìràpadà yìí ni, ì bá má ṣeé ṣe fún wa láti lè sún mọ́ Ọlọ́run. Ẹ̀ṣẹ̀ ti pa ààlà sáàárín èèyàn àti Ọlọ́run, nítorí jíjẹ́ tí Jèhófà sì jẹ́ ẹni mímọ́, kò fara mọ́ ẹ̀ṣẹ̀. (Aísáyà 6:3; 59:2) Ṣùgbọ́n ẹbọ Jésù mú ààlà yẹn kúrò; ẹbọ yẹn bo ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀, lédè mìíràn, ó ṣètùtù fún un. (Hébérù 10:12; 1 Jòhánù 1:7) Bá a bá lè fara mọ́ ètò tí Ọlọ́run tipasẹ̀ Kristi ṣe yìí, tá a sì lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, a máa rí ojúure Jèhófà. Àbùjá ò sí, òótọ́ ibẹ̀ ni pé kò sí ọ̀nà mìíràn tá a fi lè “bá Ọlọ́run rẹ́.”c—Róòmù 5:6-11.
12. Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ “ọ̀nà”?
12 Jésù ni “ọ̀nà” tó bá dọ̀rọ̀ àdúrà. Lọ́lá Jésù nìkan la fi lè tọ Jèhófà lọ nínú àdúrà pẹ̀lú ìdánilójú pé Jèhófà á gbọ́ á sì dáhùn àwọn ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wa. (1 Jòhánù 5:13, 14) Jésù alára sọ pé: “Bí ẹ bá béèrè fún ohunkóhun lọ́wọ́ Baba, yóò fi í fún yín ní orúkọ mi. . . . Ẹ béèrè, ẹ ó sì rí gbà, kí a lè sọ ìdùnnú yín di kíkún.” (Jòhánù 16:23, 24) Nítorí náà, lórúkọ Jésù, a lè bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nínú àdúrà ká sì pè É ní “Baba wa.” (Mátíù 6:9) Ohun míì tún wà tó mú kí Jésù jẹ́ “ọ̀nà,” ìyẹn ni àpẹẹrẹ tó fi lélẹ̀. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ ṣáájú, Jésù fara wé Bàbá rẹ̀ lọ́nà pípé. Nípa bẹ́ẹ̀, àpẹẹrẹ Jésù jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó máa wu Jèhófà. Nítorí náà, ká tó lè sún mọ́ Jèhófà, a gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Jésù.—1 Pétérù 2:21.
“Èmi Ni . . . Òtítọ́”
13, 14. (a) Ọ̀nà wo làwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ gbà jẹ́ òótọ́? (b) Kí Jésù tó lè di “òtítọ́,” kí ló gbọ̀dọ́ ṣe, kí sì nìdí?
13 Òtítọ́ ni Jésù máa ń sọ nígbà gbogbo nípa ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Bàbá rẹ̀. (Jòhánù 8:40, 45, 46) A ò rí ẹ̀tàn kankan lẹ́nu rẹ̀ rí. (1 Pétérù 2:22) Kódà àwọn alátakò rẹ̀ gan-an jẹ́wọ́ pé ó máa “ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú òtítọ́.” (Máàkù 12:13, 14) Síbẹ̀, nígbà tí Jésù sọ pé “Èmi ni . . . òtítọ́,” kì í ṣe bó ṣe máa ń sọ òtítọ́ nígbà tó bá ń sọ̀rọ̀, nígbà tó bá ń wàásù tàbí nígbà tó bá ń kọ́ni nìkan ló ní lọ́kàn. Ohun tó ní lọ́kàn jù bẹ́ẹ̀ lọ dáadáa.
14 Má gbàgbé pé ní ọgọ́rọ̀ọ̀rùn ọdún ṣáájú, Jèhófà mí sí àwọn tó kọ Bíbélì láti sọ ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ẹni tó máa jẹ́ Mèsáyà tàbí Kristi. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí dá lórí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ìgbésí ayé rẹ̀, iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ àti irú ikú tó máa kú. Láfikún sáwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyẹn, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ẹni tó máa jẹ́ Mésàyá wà nínú Òfin Mósè. (Hébérù 10:1) Ṣé Jésù á jẹ́ adúróṣinṣin títí tó fi máa kú, kó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú gbogbo ohun tí wọ́n ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ ṣẹ? Àfi tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan ni Jèhófà tó lè di Ọlọ́run àsọtẹ́lẹ̀ tòótọ́. Kékeré kọ́ ni ẹrù tó wà lọ́rùn Jésù yẹn o. Pẹ̀lú ọ̀nà tí Jésù gbà gbé ìgbé ayé rẹ̀, ìyẹn nípa gbogbo ọ̀rọ̀ tó sọ àti gbogbo ohun tó ṣe, ó fi hàn gbangba pé òótọ́ ni gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ tàbí ohun tó dà bí òjìji wọ̀nyẹn látòkèdélẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 1:20) Nípa báyìí, Jésù ni “òtítọ́.” Ńṣe ló dà bíi pé dídé tí Jésù dé gan-an ló mú káwọn àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà di òótọ́.—Jòhánù 1:17; Kólósè 2:16, 17.
“Èmi Ni . . . Ìyè”
15. Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn lo ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ, kí sì nìyẹn máa yọrí sí?
15 Jésù ni “ìyè” torí pé nípasẹ̀ rẹ̀ nìkan la fi lè ní ìye, ìyẹn “ìyè tòótọ́.” (1 Tímótì 6:19) Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ ní ìyè àìnípẹ̀kun; ẹni tí ó bá ń ṣàìgbọràn sí Ọmọ kì yóò rí ìyè, ṣùgbọ́n ìrunú Ọlọ́run wà lórí rẹ̀.” (Jòhánù 3:36) Kí ló túmọ̀ sí láti lo ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ Ọlọ́run? Ohun tó túmọ̀ sí ni pé a ní ìdánilójú náà pé láìsí Jésù, kò sí ìyè. Yàtọ̀ síyẹn, ó túmọ̀ sí pé à ń fi iṣẹ́ ti ìgbàgbọ́ wa lẹ́yìn, à ń bá a lọ láti máa kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Jésù, a sì ń ṣe gbogbo ohun tó yẹ, ká lè máa fi àwọn ẹ̀kọ́ Jésù ṣèwà hù ká sì máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. (Jákọ́bù 2:26) Nípa báyìí, lílo ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ Ọlọ́run ló máa jẹ́ ká wà láàyè títí láé. “Agbo kékeré” tó jẹ́ àwọn ẹni àmì òróró á gba ìyè gẹ́gẹ́ bí ẹni ẹ̀mí tí kò lè kú ní ọ̀run, àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tó jẹ́ àgùntàn mìíràn á gba ìyè pípé gẹ́gẹ́ bí èèyàn nínu ayé tí gbogbo nǹkan á ti rí bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí.—Lúùkù 12:32; 23:43; Ìṣípayá 7:9-17; Jòhánù 10:16.
16, 17. (a) Báwo ni Jésù ṣe máa jẹ́ “ìyè” fáwọn tó ti kú pàápàá? (b) Ìdánilójú wo la lè ní?
16 Ti tàwọn tó ti kú wá ńkọ́? Jésù máa jẹ́ “ìyè” fáwọn náà. Nígbà tó kù díẹ̀ kó jí ọ̀rẹ́ rẹ̀ Lásárù dìdé, Jésù sọ fún Màtá ẹ̀gbọ́n Lásárù pé: “Èmi ni àjíǹde àti ìyè. Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè.” (Jòhánù 11:25) Jèhófà ti fi “kọ́kọ́rọ́ ikú àti ti Hédíìsì” lé Ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, èyí tó túmọ̀ sí pé ó ti fún un lágbára láti jí òkú dìde. (Ìṣípayá 1:17, 18) Látọ̀run, Jésù á fi àwọn kọ́kọ́rọ́ wọ̀nyẹn ṣí ibodè Hédíìsì, á sì tipa bẹ́ẹ̀ mú gbogbo aráyé tó wà nípò òkú padà wá sí ìyè.—Jòhánù 5:28, 29.
17 Jésù ṣe àkópọ̀ ohun tí ìgbésí ayé rẹ̀ àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé dá lé lórí nígbà tó sọ ní ṣókí pé: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè.” Gbólóhùn yẹn ní ìtumọ̀ tó ṣe pàtàkì gan-an fún wa lónìí. Rántí ohun tí Jésù sọ tẹ̀ lé gbólóhùn yẹn, ó ní: “Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.” (Jòhánù 14:6) Bí gbólóhùn Jésù yẹn ti ṣe pàtàkì lákòókò tó sọ ọ́ náà ló gbà ṣe pàtàkì lónìí. Ká jẹ́ kó dá wa lójú hán-únhán-ún pé bá a bá ń tẹ̀ lé Jésù, láé a ò ní ṣìnà. Kò sí ẹlòmíràn, àfi òun nìkan ṣoṣo ló lè fọ̀nà tó lọ “sọ́dọ́ Baba” rẹ̀ hàn wá.
Kí Lo Máa Ṣe?
18. Kí ló túmọ̀ sí láti máa tẹ̀ lé Jésù ní ti gidi?
18 Pẹ̀lú ipa pàtàkì tí Jésù kó yìí àti bó ṣe jẹ́ ẹni tó mọ Baba ju ẹnikẹ́ni mìíràn lọ, ó tọ́ ká máa tẹ̀ lé e. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe kẹ́kọ̀ọ́ ní Orí 1 ìwé yìí, ẹni tó bá máa tẹ̀ lé Jésù gbọ́dọ̀ fi hàn nínú ohun gbogbo tó bá ń ṣe, kò gbọ́dọ̀ mọ sórí ọ̀rọ̀ tó ń sọ tàbí èrò tó ní. Títẹ̀lé Jésù kan fífi àwọn ẹ̀kọ́ tó fi kọ́ni sílò ká sì fìwà jọ ọ́. (Jòhánù 13:15) Ìwé tó ò ń kà yìí á ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.
19, 20. Kí ló wà nínú ìwé yìí tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ nínú bó o ṣe ń sapá láti máa tẹ̀ lé Kristi?
19 Ní àwọn orí tó kàn, a máa fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ ìgbésí ayé Jésù àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Ìsọ̀rí mẹ́ta la pín àwọn orí náà sí. Ní ìsọ̀rí kìíní, a máa ṣàkópọ̀ àwọn ànímọ́ àti àwọn ọ̀nà tó gbà ń ṣe nǹkan. Ní ìsọ̀rí kejì, a máa jíròrò bó ṣe fìtara ṣiṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ kíkọ́ni. Ní ìsọ̀rí kẹ́ta, a máa jíròrò ọ̀nà tó gbà fìfẹ́ hàn. Bẹ̀rẹ̀ láti Orí 3, wàá bẹ̀rẹ̀ sí í rí àpótí ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tá a pè ní “Báwo Lo Ṣe Lè Máa Tọ Jésù Lẹ́yìn?” Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ àtàwọn ìbéèrè tó wà níbẹ̀ á ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàṣàrò nípa bá a ṣe lè máa tẹ̀ lé àpẹerẹ Jésù nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe.
20 Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ tí Jèhófà pèsè yìí, kò yẹ kó o tún ṣìnà mọ́, ìyẹn ni pé kó o padà di àjèjì sí Ọlọ́run nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún. Ohun kékeré kọ́ ló ná Jèhófà nígbà tó fìfẹ́ rán Ọmọ rẹ̀ pé kó wá fi ọ̀nà hàn wá ká bàa lè sún mọ́ Ọlọ́run. (1 Jòhánù 4:9, 10) Ǹjẹ́ kí àwọn nǹkan wọ̀nyí mú kó o lè fi ìmọrírì hàn fún ìfẹ́ ńlá yẹn nípa jíjẹ́ ìpè Jésù, kó o sì lè ṣe ohun tó ń tìtorí rẹ̀ pè ọ́ pé: “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”—Mátíù 4:19.
a Nítorí bí ipa tí Ọmọ Ọlọ́run kó ti ṣe pàtàkì tó ni wọ́n ṣe fi àwọn orúkọ àti oyè kan pè é nínú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì.—Wo àpótí tó wà lójú ìwé 23.
b Bí àpẹẹrẹ, wo àwọn ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Mátíù 10:29-31; 18:12-14, 21-35; 22:36-40.
c Nínú Bíbélì tí wọ́n fi èdè Gíríìkì ìpilẹ̀sẹ̀ kọ, bí wọ́n ṣe lo ọ̀rọ̀ náà “ọ̀nà” nínú Jòhánù 14:6 yàtọ̀. Ó fi hàn pé àyè tí Ọlọ́run gbé Jésù sí ṣàrà ọ̀tọ̀. Fún ìdí yìí, ìtumọ̀ gbólóhùn náà “Èmi ni ọ̀nà” ni pé, ipasẹ̀ Jésù nìkan ṣoṣo la fi lè sún mọ́ Baba.