ÀFIKÚN
Bá A Ṣe Dá “Bábílónì Ńlá” Mọ̀
ÀWỌN ọ̀rọ̀ kan wà nínú ìwé Ìṣípayá tó jẹ́ pé kì í ṣe bí wọ́n ṣe kọ wọ́n gan-an ló yẹ ká lóye wọn. (Ìṣípayá 1:1) Bí àpẹẹrẹ, ó sọ nípa obìnrin kan tí orúkọ kan wà ní iwájú orí rẹ̀, orúkọ náà sì ni “Bábílónì Ńlá.” Ìwé Ìṣípayá sọ pé obìnrin yìí jókòó lórí ‘ogunlọ́gọ̀ àwọn èèyàn àti orílẹ̀-èdè.’ (Ìṣípayá 17:1, 5, 15) Níwọ̀n bí kò ti sí obìnrin kan tó lè ṣe bẹ́ẹ̀, ó ní láti jẹ́ pé ńṣe ni Bábílónì Ńlá jẹ́ àpẹẹrẹ nǹkan kan. Nítorí náà, kí ni aṣẹ́wó ìṣàpẹẹrẹ yìí dúró fún?
Ìṣípayá 17:18 fi hàn pé obìnrin ìṣàpẹẹrẹ yìí jẹ́ “ìlú ńlá títóbi tí ó ní ìjọba kan lórí àwọn ọba ilẹ̀ ayé.” Ọ̀rọ̀ náà, “Ìlú,” tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí tọ́ka sí àwùjọ àwọn èèyàn kan. Níwọ̀n bí “ìlú ńlá” yìí ti ń darí “àwọn ọba ilẹ̀ ayé,” obìnrin tí Ìwé Ìṣípayá pe orúkọ rẹ̀ ní Bábílónì Ńlá gbọ́dọ̀ jẹ́ àjọ kan tó nasẹ̀ dé orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé. A lè pè é ní ilẹ̀ ọba àgbáyé. Irú ilẹ̀ ọba wo nìyẹn? Ilẹ̀ ọba ìsìn ni. Wo bí àwọn ẹsẹ Bíbélì tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ yìí nínú ìwé Ìṣípayá ṣe fi hàn bẹ́ẹ̀.
Ilẹ̀ ọba kan lè jẹ́ ti ìṣèlú, ó lè jẹ́ ti ètò ìṣòwò, ó sì lè jẹ́ ti ìsìn. Obìnrin tí ìwé Ìṣípayá pe orúkọ rẹ̀ ní Bábílónì Ńlá kì í ṣe ilẹ̀ ọba ìṣèlú. Ìdí ni pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé ‘àwọn ọba ilẹ̀ ayé bá a ṣe àgbèrè.’ Lédè mìíràn, àwọn ọba ilẹ̀ ayé yìí ni àwọn olóṣèlú ayé. Ohun tí àgbèrè tó ṣe fi hàn ni pé ó bá àwọn alákòóso ayé da nǹkan pọ̀. Abájọ tí Bíbélì fi pè é ní “aṣẹ́wó ńlá.”—Ìṣípayá 17:1, 2; Jákọ́bù 4:4.
Bákan náà, Bábílónì Ńlá kò lè jẹ́ ilẹ̀ ọba ètò ìṣòwò nítorí pé ‘àwọn oníṣòwò ayé’ yóò kédàárò nígbà tó bá pa run. Kódà, ìwé Ìṣípayá sọ pé àwọn ọba àtàwọn oníṣòwò yóò máa wo Bábílónì Ńlá láti “òkèèrè.” (Ìṣípayá 18:3, 9, 10, 15-17) Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mù ká gbà pé Bábílónì Ńlá kì í ṣe ilẹ̀ ọba ìṣèlú tàbí ti ètò ìṣòwò, bí kò ṣe ilẹ̀ ọba ìsìn.
Ohun tó túbọ̀ fi hàn pé ilẹ̀ ọba ìsìn ni Bábílónì ni ohun tí ìwé Ìṣípayá sọ, pé ó ń fi “iṣẹ́ ìbẹ́mìílò rẹ” ṣi gbogbo orílẹ̀-èdè lọ́nà. (Ìṣípayá 18:23) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn ẹ̀mí èṣù ló wà nídìí gbogbo onírúurú ìbẹ́mìílò, kò yà wá lẹ́nu pé Bíbélì pe Bábílónì Ńlá ní “ibi gbígbé àwọn ẹ̀mí èṣù.” (Ìṣípayá 18:2; Diutarónómì 18:10-12) Bíbélì tún fi hàn pé ilẹ̀ ọba yìí ń ta ko ìsìn tòótọ́, ó ń ṣenúnibíni sí “àwọn wòlíì” àti “àwọn ẹni mímọ́.” (Ìṣípayá 18:24) Bábílónì Ńlá kórìíra ìsìn tòótọ́ débi pé, ó ń ṣenúnibíni tó burú jáì sí “àwọn ẹlẹ́rìí Jésù,” kódà ó tún ń pa wọ́n. (Ìṣípayá 17:6) Nítorí náà, obìnrin tí Bíbélì pè ní Bábílónì Ńlá yìí dúró fún ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé, tí gbogbo ìsìn tó ń ta ko Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ ara rẹ̀.