Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
A ti fi iṣẹ́ tó jẹ mọ́ ilé tàbí ilẹ̀ ìjọsìn lọ àwọn kan tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ojú wo ni Ìwé Mímọ́ fi wo irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀?
Ọ̀ràn yìí lè dojú kọ àwọn Kristẹni tó jẹ́ pé lóòótọ́, wọ́n fẹ́ tẹ̀ lé ohun tí 1 Tímótì 5:8 sọ, èyí tó tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì pípèsè nípa ti ara fún agboolé ẹni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ kí Kristẹni fi ìmọ̀ràn yẹn sílò, ìyẹn ò sọ títẹ́wọ́gba iṣẹ́ èyíkéyìí láìka irú iṣẹ́ tí ó jẹ́ sí, di ohun tó dára. Àwọn Kristẹni mọrírì ìjẹ́pàtàkì títètè mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ lórí àwọn ọ̀ràn kan. Fún àpẹẹrẹ, a kò lè dá ọkùnrin kan láre tó bá ré ìlànà Bíbélì nípa ìṣekúṣe tàbí ìpànìyàn kọjá, kìkì nítorí pé ó fẹ́ gbọ́ bùkátà ìdílé rẹ̀. (Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 39:4-9; Aísáyà 2:4; Jòhánù 17:14, 16.) Ó tún ṣe pàtàkì kí àwọn Kristẹni tẹ̀ lé àṣẹ náà láti jáde kúrò nínú Bábílónì Ńlá, ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé.—Ìṣípayá 18:4, 5.
Jàkéjádò ayé, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ń dojú kọ ìpèníjà nípa irú iṣẹ́ tó yẹ kí wọ́n ṣe. Kò ní nítumọ̀, agbára wa kò sì ní lè ká a, tí a bá ń gbìyànjú láti to gbogbo ohun tó lè ṣẹlẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ, kí a sì wá gbé àwọn òfin pàtó kalẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 1:24) Bó ti wù kí ó rí, ẹ jẹ́ ká mẹ́nu kan àwọn kókó díẹ̀ tí àwọn Kristẹni lè gbé yẹ̀ wò, bí wọ́n bá fẹ́ ṣe ìpinnu nípa iṣẹ́ tó yẹ káwọn ṣe. A mẹ́nu kan àwọn kókó wọ̀nyí ní ṣókí nínú Ilé Ìṣọ́ January 15, 1982, nínú àpilẹ̀kọ kan tó sọ̀rọ̀ nípa jíjàǹfààní nínú ẹ̀rí ọkàn tí Ọlọ́run fún wa. A béèrè ìbéèrè méjì nínú àpótí kan, a sì kọ àwọn kókó tó lè ṣèrànwọ́ síbẹ̀.
Ìbéèrè pàtàkì àkọ́kọ́ nìyí: A ha ka iṣẹ́ yìí ní pàtó léèwọ̀ nínú Bíbélì bí? Nígbà tó ń ṣàlàyé lórí èyí, Ilé Ìṣọ́ náà sọ pé Bíbélì ka olè jíjà, àṣìlò ẹ̀jẹ̀, àti ìbọ̀rìṣà, léèwọ̀. Kristẹni kan ní láti yẹra fún iṣẹ́ tó jẹ́ pé ní tààràtà, ó ń gbé àwọn ìgbòkègbodò tí Ọlọ́run kò fọwọ́ sí lárugẹ, irú àwọn tí a ṣẹ̀ẹ̀ mẹ́nu kàn tán.
Ìbéèrè kejì rèé: Ṣíṣe irú iṣẹ́ yìí yóò ha sọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ di agbódegbà fún àwọn ìwà tí a kà léèwọ̀ bí? Ó ṣe kedere pé, ẹnì kan tí a gbà síṣẹ́ ní ilé tẹ́tẹ́, ní ọsibítù ìṣẹ́yún, tàbí ilé aṣẹ́wó yóò jẹ́ agbódegbà fún irú ìwà bẹ́ẹ̀ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Àní kó tiẹ̀ jẹ́ pé ilẹ̀ gbígbá lásán ni iṣẹ́ tó ń ṣe níbẹ̀ lójoojúmọ́ tàbí kó jẹ́ pé ìpè orí tẹlifóònù nìkan ló ń bá wọn dáhùn, ó dájú pé òun pẹ̀lú ń kópa nínú ìwà tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kà léèwọ̀.
Ọ̀pọ̀ Kristẹni tí wọ́n dojú kọ ṣíṣe àwọn ìpinnu tó jẹ mọ́ iṣẹ́ ti rí i pé gbígbé àwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn yẹ̀ wò dáadáa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dorí ìpinnu.
Fún àpẹẹrẹ, láti inú àwọn ìbéèrè méjì yẹn, a lè rí ìdí tí olùjọsìn tòótọ́ kò fi ní lè jẹ́ òṣìṣẹ́ àjọ ìsìn èké, kó máa bá ṣọ́ọ̀ṣì ṣiṣẹ́ tàbí kó máa ṣiṣẹ́ nínú ṣọ́ọ̀ṣì. Nínú Ìṣípayá 18:4, a pàṣẹ pé: “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn mi, bí ẹ kò bá fẹ́ ṣàjọpín pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.” Ẹnì kan yóò máa pín nínú iṣẹ́ àti ẹ̀ṣẹ̀ Bábílónì Ńlá bó bá jẹ́ òṣìṣẹ́ ìsìn kan tó ń kọ́ni ní ẹ̀kọ́ ìsìn èké. Òṣìṣẹ́ náà ì báà jẹ́ aṣọ́gbà, atilẹ̀kùn, atún-nǹkan-ṣe, tàbí olùṣírò owó, iṣẹ́ rẹ̀ yóò gbé ìjọsìn tó tako ìsìn tòótọ́ lárugẹ. Ní àfikún sí i, àwọn ènìyàn tó bá rí òṣìṣẹ́ yìí tó ń roko àyíká ṣọ́ọ̀ṣì, tó ń tún ṣọ́ọ̀ṣì ṣe, tàbí tó ń ṣiṣẹ́ fún ìtẹ̀síwájú ẹ̀sìn náà, lè gbà gbọ́ lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu pé ọmọ ìjọ náà lonítọ̀hún jẹ́.
Ṣùgbọ́n, ẹnì kan tí kì í ṣe òṣìṣẹ́ déédéé pẹ̀lú ṣọ́ọ̀ṣì kan tàbí ètò àjọ ìsìn kan ńkọ́? Bóyá tó jẹ́ pé wọ́n kàn pè é fúnṣẹ́ pàjáwìrì lórí páìpù omi kan tó bẹ́ nínú ṣọ́ọ̀ṣì. Ṣé ìyẹn kò ní yàtọ̀ sí pé kí ẹni bẹ́ẹ̀ fẹ́ kí ṣọ́ọ̀ṣì gbéṣẹ́ kan fóun, irú bíi kíkan òrùlé ṣọ́ọ̀ṣì tàbí fífi nǹkan bò ó?
Yàtọ̀ sí ìyẹn, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ onírúurú ipò ni a lè finú rò. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò kókó márùn-ún tí Ilé Ìṣọ́ náà là sílẹ̀:
1. Iṣẹ́ náà ha wulẹ̀ jẹ́ iṣẹ́ àfiṣèrànwọ́ tí Ìwé Mímọ́ kò ta kò? Gbé àpẹẹrẹ apínlẹ́tà yẹ̀ wò. Ó ṣòro láti gbà pé pípín tí ó ń pín lẹ́tà kiri túmọ̀ sí pé ó ń gbé ìwà burúkú lárugẹ bí ṣọ́ọ̀ṣì tàbí ọsibítù ìṣẹ́yún bá wà lára àwọn ilé tó ń pín lẹ́tà dé ní àgbègbè náà. Ṣe bí Ọlọ́run ló ń pèsè oòrùn tí ń ràn wọnú gbogbo ilé, títí kan ṣọ́ọ̀ṣì tàbí ọsibítù ìṣẹ́yún bẹ́ẹ̀. (Ìṣe 14:16, 17) Kristẹni kan tí ó jẹ́ apínlẹ́tà lè parí èrò náà sí pé, iṣẹ́ àfiṣèrànwọ́ fún gbogbo gbòò, láti ọjọ́ dé ọjọ́ ni òun ń ṣe. Ọ̀ràn náà tún lè rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Kristẹni kan tí ń ṣiṣẹ́ pàjáwìrì—oníṣẹ́ omi ẹ̀rọ tí a pè láti dáwọ́ omi tó ya wọnú ṣọ́ọ̀ṣì dúró tàbí òṣìṣẹ́ ọkọ̀ ìtọ́jú pàjáwìrì kan tí a pè láti wá tọ́jú ẹnì kan tó dákú sínú ṣọ́ọ̀ṣì nígbà tí ìsìn ń lọ lọ́wọ́. Onítọ̀hún lè wulẹ̀ ka èyí sí ṣíṣèrànwọ́ pàjáwìrì fún ẹ̀dá.
2. Báwo ni ẹni náà ṣe ní àṣẹ lórí ohun tí ó ṣe náà tó? Kò dájú pé Kristẹni kan tó ní ilé ìtajà yóò gbà láti máa ta ère òrìṣà, ońdè, sìgá, tàbí ṣìnkín. Gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ni ilé ìtajà náà, ọwọ́ rẹ̀ ni agbára wà. Àwọn èèyàn lè rọ̀ ọ́ láti máa ta sìgá tàbí ère òrìṣà kí èrè lè máa wọlé, ṣùgbọ́n yóò hùwà ní ìbámu pẹ̀lú Ìwé Mímọ́ tí ó gbà gbọ́. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Kristẹni kan tí a gbà síṣẹ́ nínú ilé ìtajà ńlá kan lè máa gba owó, ó lè máa fọ ilẹ̀, tàbí kó máa pa àkọsílẹ̀ káràkátà mọ́. Kò ní agbára lórí ohun tí wọ́n rà wọlé tàbí tí wọ́n tà, kódà bí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ kò tilẹ̀ gbà kí wọ́n máa ta díẹ̀ lára àwọn nǹkan wọ̀nyí, irú bí sìgá tàbí àwọn ohun èlò fún ọdún ìsìn.a (Fi wé Lúùkù 7:8; 17:7, 8.) Èyí kan kókó tí a óò jíròrò tẹ̀ lé e.
3. Báwo ni ọ̀ràn náà ṣe gbún ẹni náà tó? Ẹ jẹ́ ká padà sórí àpèjúwe ti ilé ìtajà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kanlọ́gbọ̀n ni ẹni táa ní kò máa gba owó tàbí kó ọjà sórí pẹpẹ ń fọwọ́ kan sìgá tàbí àwọn ohun èlò ìsìn; kékeré nìyẹn jẹ́ lára iṣẹ́ gan-an tó ń ṣe. Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, òṣìṣẹ́ kan tó wà nílé ìtajà kan náà tó jẹ́ pé ibi tí wọ́n ti ń ta sìgá gan-an ló ti ń ṣiṣẹ́ ńkọ́! Gbogbo iṣẹ́ rẹ̀, lójoojúmọ́, dá lórí ohun kan tó ta ko ìgbàgbọ́ àwọn Kristẹni. (2 Kọ́ríńtì 7:1) Èyí ṣàkàwé ìdí tó fi yẹ láti ṣàgbéyẹ̀wò bí ọ̀ràn náà ṣe kan ẹni náà tó, nígbà tí a bá fẹ́ ṣèpinnu lórí ọ̀ràn iṣẹ́.
4. Kí ni orísun owó tó ń gbà tàbí ibo ló ti ń ṣe iṣẹ́ náà? Gbé ipò méjì yẹ̀ wò. Kí àwọn èèyàn lè máa sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, ọsibítù ìṣẹ́yún kan pinnu láti máa sanwó fún ọkùnrin kan tí yóò máa tọ́jú òpópónà tó wà ládùúgbò. Lóòótọ́, ọsibítù ìṣẹ́yún ló ń sanwó oṣù rẹ̀, ṣùgbọ́n kò ṣiṣẹ́ lọ́sibítù, kò sì sẹ́nì kan tó ń rí i lọ́sibítù náà. Dípò èyí, wọ́n ń rí i tó ń ṣiṣẹ́ fún ará ìlú, èyí kò sì ta ko Ìwé Mímọ́, láìka ẹni tó lè máa sanwó fún un sí. Gbé òmíràn tó yàtọ̀ sí ìyẹn yẹ̀ wò. Ní orílẹ̀-èdè kan tí ìjọba ti fọwọ́ sí iṣẹ́ aṣẹ́wó, ilé iṣẹ́ tó ń bójú tó ìlera àwọn ará ìlú ń sanwó fún nọ́ọ̀sì kan tí ń ṣiṣẹ́ nílé aṣẹ́wó, òun ló ń yẹ̀ wọ́n wò láti lè dín àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń tàtaré rẹ̀ kù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé iṣẹ́ tí ń bójú tó ìlera àwọn ará ìlú ló ń sanwó oṣù fún un, ilé àwọn aṣẹ́wó ló ti ń ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ̀, ó ń mú kí ìṣekúṣe di ohun tí ewu rẹ̀ dín kù, tó sì túbọ̀ di ìtẹ́wọ́gbà. Àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí ṣàkàwé ìdí tí ibi tí owó tí a ń san fúnni ti ń wá àti ibi tí iṣẹ́ náà wà fi jẹ́ apá tó yẹ ká gbé yẹ̀ wò.
5. Ipa wo ni ṣíṣe iṣẹ́ náà ń ní lórí ẹni; ṣé yóò mú kí ẹ̀rí ọkàn ẹni máa dáni lẹ́bi tàbí yóò mú kí a mú àwọn ẹlòmíràn kọsẹ̀? A gbọ́dọ̀ gbé ọ̀ràn ẹ̀rí-ọkàn yẹ̀ wò, tiwa àti ti àwọn ẹlòmíràn. Kódà bí iṣẹ́ kan (títí kan ibi tí wọ́n ti ń ṣe é àti àwọn tí ń sanwó iṣẹ́ bá dà bí ohun tí kò burú fún Kristẹni kan láti ṣe, ẹnì kan lè ronú pé yóò da ẹ̀rí-ọkàn òun láàmú. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tí ó fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀, sọ pé: “Àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé a ní ẹ̀rí-ọkàn aláìlábòsí, gẹ́gẹ́ bí a ti dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.” (Hébérù 13:18) Ó yẹ kí a yẹra fún iṣẹ́ tí yóò máa da ọkàn wa láàmú; síbẹ̀, kò yẹ kí àwa pẹ̀lú máa ṣe lámèyítọ́ àwọn ẹlòmíràn tí ẹ̀rí-ọkàn wọn yàtọ̀ sí tiwa. Ní ọ̀nà kejì, Kristẹni kan lè máà rí i pé Bíbélì ta ko iṣẹ́ tí òun ń ṣe, ṣùgbọ́n ó mọ̀ pé yóò da ọ̀pọ̀ àwọn tó wà nínú ìjọ tàbí tó wà ládùúgbò láàmú. Pọ́ọ̀lù sọ irú ẹ̀mí rere tó yẹ kí a ní nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Kò sí ọ̀nà kankan tí àwa gbà jẹ́ okùnfà èyíkéyìí fún ìkọ̀sẹ̀, kí a má bàa rí àléébù sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa; ṣùgbọ́n lọ́nà gbogbo, a ń dámọ̀ràn ara wa fún ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run.”—2 Kọ́ríńtì 6:3, 4.
Wàyí o, ẹ jẹ́ ká padà sórí ọ̀ràn ṣíṣiṣẹ́ lórí ṣọ́ọ̀ṣì kan, irú bí bíbá wọn so fèrèsé tuntun, bíbá wọn fọ kápẹ́ẹ̀tì, tàbí títún ẹ̀rọ amúlémóoru ṣe. Báwo ni àwọn kókó tí a ti mẹ́nu kàn wọ̀nyí ṣe lè wúlò?
Rántí ọ̀ràn ọlá àṣẹ. Ṣé Kristẹni náà ló ni ilé iṣẹ́ náà tàbí òun lọ̀gá tó lè pinnu láti bá ṣọ́ọ̀ṣì ṣiṣẹ́ náà tàbí láti má ṣe é? Ǹjẹ́ Kristẹni tó ní irú ọlá àṣẹ bẹ́ẹ̀ yóò ha fẹ́ láti bá Bábílónì Ńlá da nǹkan pọ̀ nípa fífẹ́ gbaṣẹ́ ṣe lọ́wọ́ rẹ̀ kí ó lè ran àwọn ẹ̀sìn kan lọ́wọ́ láti gbé ìjọsìn èké lárugẹ? Ìyẹn kò ha ní jọ pípinnu láti ta sìgá tàbí ère òrìṣà nínú ilé ìtajà ẹni bí?—2 Kọ́ríńtì 6:14-16.
Bí Kristẹni bá jẹ́ òṣìṣẹ́ tí kò lẹ́nu ọ̀rọ̀ lórí iṣẹ́ tí wọn yóò gbà, àwọn kókó mìíràn wà tí a lè gbé yẹ̀ wò, irú bí ibi tí iṣẹ́ náà wà àti bí yóò ti ṣe lọ́wọ́ nínú rẹ̀ tó. Ṣé wọ́n kàn ní kí òṣìṣẹ́ náà kó àga tuntun síbẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ni tàbí kó tò ó tàbí kó ṣe iṣẹ́ àfiṣèrànwọ́, irú bí òṣìṣẹ́ panápaná kan tó lọ paná nínú ṣọ́ọ̀ṣì kó tó tàn kálẹ̀? Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni yóò rí i pé èyí yàtọ̀ sí òṣìṣẹ́ kan tí ń lo àkókò gígùn láti kun ṣọ́ọ̀ṣì tàbí tó jẹ́ aṣọ́gbà, tó ń mú kí ṣọ́ọ̀ṣì náà túbọ̀ fani mọ́ra. Irú iṣẹ́ tí a ń ṣe déédéé bẹ́ẹ̀ tàbí èyí tí ó jẹ́ ọlọ́jọ́ pípẹ́ yóò mú kí ó túbọ̀ ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ láti máa fojú wo Kristẹni náà gẹ́gẹ́ bí apá kan ẹ̀sìn tí ó sọ pé òun kò fara mọ́, ó sì lè ṣeé ṣe kó mú wọn kọsẹ̀.—Mátíù 13:41; 18:6, 7.
A ti gbé ọ̀pọ̀ kókó pàtàkì yẹ̀ wò ní ti iṣẹ́. A gbé ìwọ̀nyí kalẹ̀ ní dídáhùn ìbéèrè kan pàtó tó jẹ mọ́ ti ìsìn èké. Síbẹ̀, a tún lè gbé wọn yẹ̀ wò nínú ọ̀ràn tó bá kan irú iṣẹ́ mìíràn. Nínú ọ̀ràn kọ̀ọ̀kan, a gbọ́dọ̀ gbé e yẹ̀ wò tàdúràtàdúrà, kí a ronú lórí àwọn ohun pàtó—tí ó sì lè jẹ́ pé wọ́n ṣàrà ọ̀tọ̀—nínú ipò kan tí a ń jíròrò. Àwọn kókó tí a ti gbé yẹ̀ wò wọ̀nyí ti ṣèrànwọ́ fún ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni olóòótọ́ láti ṣe ìpinnu tí wọ́n gbé ka ẹ̀rí-ọkàn wọn, èyí tó fi ìfẹ́ ọkàn wọn hàn láti máa rìn tààrà láìpẹ́kọrọ níwájú Jèhófà.—Òwe 3:5, 6; Aísáyà 2:3; Hébérù 12:12-14.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn Kristẹni kan tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní ọsibítù ti ní láti gbé kókó ti ọlá àṣẹ yìí yẹ̀ wò. Dókítà kan lè ní ọlá àṣẹ láti sọ pé kí aláìsàn lo irú egbòogi kan tàbí kí a lo ọ̀nà kan láti tọ́jú rẹ̀. Kódà, bí aláìsàn náà kò bá bìkítà, báwo ni Kristẹni kan tó jẹ́ dókítà yóò ṣe ṣètò pé kí a fa ẹ̀jẹ̀ síni lára tàbí kí a bá ẹnì kan ṣẹ́yún, tó sì mọ ohun tí Bíbélì sọ lórí irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀? Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, nọ́ọ̀sì kan tí a gbà sí ọsibítù lè má ní irú ọlá àṣẹ bẹ́ẹ̀. Níbi tó ti ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀, dókítà kan lè sọ pé kí ó yẹ ẹ̀jẹ̀ ẹnì kan wò fún ète kan tàbí kí ó tọ́jú ẹnì kan tó wá ṣẹ́yún. Ní ìbámu pẹ̀lú àpẹẹrẹ tí ó wà nínú 2 Àwọn Ọba 5:17-19, ó lè parí èrò sí pé níwọ̀n bí ṣíṣètò fún ìfàjẹ̀sínilára náà tàbí ṣíṣẹ́yún náà kò ti ti ọwọ́ òun wá, iṣẹ́ àfiṣèrànwọ́ lásán lòun ń ṣe fún aláìsàn náà. Àmọ́ ṣá o, ó ṣì ní láti ro ti ẹ̀rí-ọkàn rẹ̀, nítorí kí ó lè “hùwà níwájú Ọlọ́run pẹ̀lú ẹ̀rí-ọkàn mímọ́ kedere.”—Ìṣe 23:1.