Ẹ̀KỌ́ 13
Ẹ̀sìn Èké Kò Ṣojú fún Ọlọ́run
Tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa lóòótọ́, kí nìdí tí àwọn ẹlẹ́sìn tó sọ pé àwọn ń ṣojú fún Ọlọ́run fi ń hùwà ìkà tó burú gan-an? Ìdí ni pé ẹ̀sìn èké làwọn ẹ̀sìn yẹn, ńṣe ni wọ́n kàn ń parọ́ pé Ọlọ́run làwọn ń ṣojú fún. Kí ló fi hàn pé Ọlọ́run kọ́ ni wọ́n ń ṣojú fún? Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo ohun tí wọ́n ń ṣe yìí? Kí ló sì máa ṣe sí i?
1. Báwo ni ẹ̀kọ́ àwọn ẹlẹ́sìn èké ṣe fi hàn pé Ọlọ́run kọ́ ni wọ́n ń ṣojú fún?
Ẹ̀sìn èké ti “fi irọ́ pààrọ̀ òtítọ́ Ọlọ́run.” (Róòmù 1:25) Bí àpẹẹrẹ, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ẹ̀sìn ni kò kọ́ àwọn èèyàn ní orúkọ Ọlọ́run. Àmọ́ Bíbélì sọ pé a gbọ́dọ̀ máa lo orúkọ Ọlọ́run. (Róòmù 10:13, 14) Tí ohun burúkú bá ṣẹlẹ̀, àwọn olórí ẹ̀sìn kan máa ń sọ pé àmúwá Ọlọ́run ni. Ṣùgbọ́n irọ́ ni. Ọlọ́run kọ́ ló ń fa aburú. (Ka Jémíìsì 1:13.) Ó bani nínú jẹ́ pé irọ́ táwọn ẹlẹ́sìn ń pa ti mú káwọn èèyàn jìnnà sí Ọlọ́run.
2. Báwo ni ìwà àwọn ẹlẹ́sìn èké ṣe fi hàn pé Ọlọ́run kọ́ ni wọ́n ń ṣojú fún?
Àwọn ẹlẹ́sìn èké kì í hùwà tó dáa sáwọn èèyàn torí wọn ò fìwà jọ Jèhófà. Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn èké, ó sọ pé “àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ti ga dé ọ̀run.” (Ìfihàn 18:5) Ọjọ́ pẹ́ táwọn ẹlẹ́sìn ti ń lọ́wọ́ sí ìṣèlú, wọ́n ń ti ogun lẹ́yìn, wọ́n sì ń pa àìmọye èèyàn tàbí kí wọ́n fọwọ́ sí ikú wọn. Àwọn olórí ẹ̀sìn kan ń jayé ọba, wọ́n sì ń náwó yàlàyòlò, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń fọgbọ́n gba owó lọ́wọ́ àwọn ọmọ ìjọ wọn láti fi ṣara rindin. Àwọn nǹkan tí wọ́n ń ṣe yìí fi hàn pé wọn ò mọ Ọlọ́run rárá, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé kí wọ́n máa ṣojú fún un.—Ka 1 Jòhánù 4:8.
3. Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo ẹ̀sìn èké?
Tínú bá lè máa bí ẹ torí nǹkan táwọn ẹlẹ́sìn èké ń ṣe yìí, báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára Jèhófà? Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn, àmọ́ inú ẹ̀ ò dùn sáwọn olórí ẹ̀sìn tí wọ́n ń parọ́ pé òun làwọn ń ṣojú fún, tí wọ́n sì ń hùwà ìkà sáwọn ọmọ ìjọ wọn. Ọlọ́run ṣèlérí pé ẹ̀sìn èké máa pa run, “a ò sì ní rí i mọ́ láé.” (Ìfihàn 18:21) Láìpẹ́, Ọlọ́run máa pa gbogbo ẹ̀sìn èké run.—Ìfihàn 18:8.
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Kẹ́kọ̀ọ́ sí i kó o lè mọ bí ìwà àti ìṣe àwọn ẹlẹ́sìn èké ṣe rí lára Ọlọ́run. Wàá tún mọ ohun tí kò dáa táwọn ẹlẹ́sìn èké tí ṣe àti ìdí tí kò fi yẹ kí ìyẹn dí ẹ lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà.
4. Kì í ṣe gbogbo ẹ̀sìn ni Ọlọ́run fọwọ́ sí
Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ńṣe ni gbogbo ẹ̀sìn dà bí oríṣiríṣi ọ̀nà tó ń sinni lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run. Àmọ́ ṣóòótọ́ ni? Ka Mátíù 7:13, 14, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàlàyé ọ̀nà tó lọ sí ìyè?
Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Ṣé Bíbélì sọ pé ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ló ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run?
5. Ẹ̀sìn èké kò ṣe ohun tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu
Ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn aṣáájú ẹ̀sìn èké ń ṣe tó fi hàn pé kì í ṣe Ọlọ́run ni wọ́n ń ṣojú fún. Ọ̀kan lára ohun tí wọ́n ń ṣe ni pé wọ́n ń lọ́wọ́ sí ogun, ìyẹn sì burú gan-an. Kó o lè rí àpẹẹrẹ kan, wo FÍDÍÒ yìí. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Ipa wo ni ọ̀pọ̀ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì kó nínú Ogun Àgbáyé Kejì?
Báwo ni ohun tí wọ́n ṣe yẹn ṣe rí lára ẹ?
Ka Jòhánù 13:34, 35 àti 17:16. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára Jèhófà bó ṣe ń rí i táwọn ẹlẹ́sìn ń lọ́wọ́ sí ogun?
Ẹ̀sìn èké ló ń fa ọ̀pọ̀ lára àwọn nǹkan burúkú tó ń ṣẹlẹ̀ láyé yìí. Àwọn nǹkan wo ló ti kíyè sí tó fi hàn pé àwọn ẹlẹ́sìn kò ṣe ohun tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu?
6. Ọlọ́run fẹ́ káwọn èèyàn kúrò nínú ẹ̀sìn èké
Ka Ìfihàn 18:4,a lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Báwo ló ṣe rí lára ẹ bó o ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run fẹ́ gba àwọn èèyàn lọ́wọ́ ẹ̀sìn èké tó ti ṣì wọ́n lọ́nà?
7. Máa kẹ́kọ̀ọ́ nìṣó nípa Ọlọ́run tòótọ́
Ṣé ó yẹ kí ìwà àti ìṣe àwọn ẹlẹ́sìn èké mú kó o wá jìnnà sí Ọlọ́run? Rárá. A lè fi ọ̀rọ̀ yìí wé bàbá kan tó ń tọ́ ọmọ ẹ̀ sọ́nà tó sì ń fún un ní ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n, àmọ́ tí ọmọ náà kò tẹ̀ lé ìmọ̀ràn bàbá rẹ̀. Nígbà tó yá, ọmọ náà fi ilé sílẹ̀, ó sì wá ń gbé ìgbé ayé burúkú. Ó dájú pé inú bàbá náà ò ní dùn sóhun tọ́mọ ẹ̀ ṣe. Àmọ́, ṣó bọ́gbọ́n mu ká dá bàbá yẹn lẹ́bi torí ìwà burúkú tọ́mọ ẹ̀ hù?
Ṣó yẹ ká máa dá Jèhófà lẹ́bi torí ohun táwọn ẹlẹ́sìn èké ń ṣe, kí ìyẹn wá mú ká sọ pé a ò ní kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà mọ́?
ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Mi ò fẹ́ ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú Ọlọ́run, torí pé ẹ̀sìn ló ń fa ọ̀pọ̀ lára àwọn ìṣòro tó wà láyé.”
Kí lèrò tìẹ?
Kí nìdí tí kò fi yẹ ká jẹ́ kí ìwà àti ìṣe àwọn ẹlẹ́sìn èké mú ká jìnnà sí Jèhófà?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Ọlọ́run kọ́ ni àwọn ẹlẹ́sìn èké ń ṣojú fún, torí pé ẹ̀kọ́ èké ni wọ́n fi ń kọ́ni, wọ́n sì ń hùwà burúkú. Ọlọ́run máa pa ẹ̀sìn èké run.
Kí lo rí kọ́?
Kí lèrò ẹ nípa ẹ̀kọ́ àwọn ẹlẹ́sìn èké àti ìwà tí wọ́n ń hù?
Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo ẹ̀sìn èké?
Kí ni Ọlọ́run máa ṣe sí ẹ̀sìn èké?
ṢÈWÁDÌÍ
Ka ìwé yìí kó o lè rí méjì lára ohun tí èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ẹlẹ́sìn ń ṣe tí inú Ọlọ́run kò dùn sí.
“Ṣé Ọ̀kan Náà Ni Gbogbo Ìsìn? Ǹjẹ́ Gbogbo Rẹ̀ Ni Ọlọ́run Tẹ́wọ́ Gbà?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)
Kí nìdí tí Jèhófà fi fẹ́ ká máa pé jọ pẹ̀lú àwọn míì láti jọ́sìn òun?
“Ṣé Ó Pọn Dandan Kéèyàn Máa Dara Pọ̀ Mọ́ Ẹ̀sìn Kan Pàtó?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)
Ohun tí àlùfáà kan rí nínú ẹ̀sìn rẹ̀ kò dùn mọ́ ọn nínú. Àmọ́, ó ṣì kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run.
“Ohun Tó Mú Kí Àlùfáà Kan Fi Ṣọ́ọ̀ṣì Rẹ̀ Sílẹ̀” (Jí!, February 2015)
Ọjọ́ pẹ́ táwọn ẹlẹ́sìn èké ti ń pa oríṣiríṣi irọ́ tó ń mú káwọn èèyàn máa rò pé ìkà ni Ọlọ́run, èyí sì ti mú káwọn èèyàn jìnnà sí Ọlọ́run. Wo mẹ́ta lára àwọn irọ́ náà.
“Àwọn Irọ́ Tí Kò Jẹ́ Káwọn Èèyàn Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run” (Ilé Ìṣọ́, November 1, 2013)
a Tó o bá fẹ́ mọ ìdí tí Bíbélì fi pe ẹ̀sìn èké ní obìnrin kan tó ń jẹ́ Bábílónì Ńlá, lọ wo Àlàyé Ìparí Ìwé 1.