Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ibo làwọn ẹ̀mí èṣù máa wà nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi?
Bíbélì ò ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé lórí ìbéèrè yìí. Àmọ́, a lè mọ ibi tí àwọn ẹ̀mí èṣù máa wà nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi.
Nígbà tí àpọ́sítélì Jòhánù ń sọ ohun tó rí tẹ́lẹ̀ tó máa wáyé ní ìbẹ̀rẹ̀ Ẹgbẹ̀rún Ọdún náà àti ní òpin rẹ̀, ó sọ pé: “Mo . . . rí áńgẹ́lì kan tí ń sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run wá pẹ̀lú kọ́kọ́rọ́ ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ àti ẹ̀wọ̀n ńlá ní ọwọ́ rẹ̀. Ó sì gbá dírágónì náà mú, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí í ṣe Èṣù àti Sátánì, ó sì dè é fún ẹgbẹ̀rún ọdún. Ó fi í sọ̀kò sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà, ó tì í, ó sì fi èdìdì dí i lórí rẹ̀, kí ó má bàa ṣi àwọn orílẹ̀-èdè lọ́nà mọ́ títí ẹgbẹ̀rún ọdún náà yóò fi dópin. Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, a gbọ́dọ̀ tú u fún ìgbà díẹ̀.” (Ìṣípayá 20:1-3) Bí a óò ṣe ju Sátánì sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ àti bí a óò ṣe tú u sílẹ̀ fúngbà díẹ̀ lẹ́yìn náà nìkan ni àwọn ẹsẹ wọ̀nyí sọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹsẹ yẹn ò sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀mí èṣù, ó bọ́gbọ́n mu láti sọ pé nígbà tí áńgẹ́lì tó mú kọ́kọ́rọ́ ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà lọ́wọ́, ìyẹn Jésù tá a ti ṣe lógo, bá gbá Èṣù mú tó sì jù ú sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, yóò ju àwọn ẹ̀mí èṣù pẹ̀lú sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀.— Ìṣípayá 9:11.
Gbàrà tí Jésù Kristi di Ọba ní ọ̀run lọ́dún 1914, ó ṣe ohun kan tó fi Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ làkàlàkà. Ìṣípayá 12:7-9 sọ pé: “Ogun sì bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀run: Máíkẹ́lì àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ bá dírágónì náà jagun, dírágónì náà àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ [àwọn ẹ̀mí èṣù] sì jagun ṣùgbọ́n kò borí, bẹ́ẹ̀ ni a kò rí àyè kankan fún wọn mọ́ ní ọ̀run. Bẹ́ẹ̀ ni a fi dírágónì ńlá náà sọ̀kò sísàlẹ̀, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì, ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà; a fi í sọ̀kò sísàlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé, a sì fi àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sọ̀kò sísàlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀.” Látìgbà yẹn la ti sé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ mọ́ sàkáání ilẹ̀ ayé. Ó bọ́gbọ́n mu ká gbà pé nígbà tí Jésù Kristi bá tún máa ká Sátánì lọ́wọ́ kò kó má bàa máa da ayé rú, yóò ká àwọn ẹ̀mí èṣù lọ́wọ́ kò pẹ̀lú.
Tún gbé àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ nínú Bíbélì yẹ̀ wò. Ó kà pé: “Èmi [Ọlọ́run] yóò sì fi ìṣọ̀tá sáàárín ìwọ [Sátánì] àti obìnrin náà [ètò Jèhófà ti ọ̀run] àti sáàárín irú-ọmọ rẹ [Sátánì] àti irú-ọmọ rẹ̀ [ìyẹn Jésù Kristi]. Òun yóò pa ọ́ ní orí, ìwọ yóò sì pa á ní gìgísẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Fífọ́ ejò ní orí kan jíju Sátánì sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi. Àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣàlàyé síwájú sí i pé ìṣọ̀tá wà láàárín Ẹni tó máa fọ́ Sátánì lórí àti irú ọmọ Sátánì. Àwọn áńgẹ́lì búburú tàbí àwọn ẹ̀mí èṣù téèyàn ò lè fojú rí, wà lára irú ọmọ tàbí ètò àjọ yìí. Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu ká gbà pé nígbà tí Jésù bá ju Sátánì sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, yóò de àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ náà, á sì jù wọ́n sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀. Ẹ̀rù ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ tó ń ba àwọn ẹ̀mí èṣù gidigidi fi hàn pé wọ́n mọ̀ pé ibẹ̀ làwọn ń lọ tó bá yá.—Lúùkù 8:31.
Ṣé ó wá ṣeé ṣe kó jẹ́ pé nítorí pé àwọn ẹ̀mí èṣù máa pa rún pọ̀ mọ́ irú ọmọ Sátánì tó wà láyé ní Amágẹ́dọ́nì ni Ìṣípayá 20:1-3 ò ṣe sọ̀rọ̀ nípa wọn? Bíbélì fi hàn pé ó ṣeé ṣe kó máà rí bẹ́ẹ̀. Ohun tí Bíbélì sọ nípa ohun tó máa gbẹ̀yìn Sátánì rèé: “A sì fi Èṣù tí ń ṣì wọ́n lọ́nà sọ̀kò sínú adágún iná àti imí ọjọ́, níbi tí ẹranko ẹhànnà náà àti wòlíì èké náà ti wà nísinsìnyí; a ó sì máa mú wọn joró tọ̀sán-tòru títí láé àti láéláé.” (Ìṣípayá 20:10) Àwọn olóṣèlú ni ẹranko ẹhànnà àti wòlíì èké náà dúró fún, ara ètò àjọ Sátánì tó wà láyé sì ni wọ́n. (Ìṣípayá 13:1, 2, 11-14; 16:13, 14) Gbogbo wọn ló máa pa run ní Amágẹ́dọ́nì nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run yóò fọ́ gbogbo ìjọba ayé yìí túútúú tó sì máa fòpin sí gbogbo wọn. (Dáníẹ́lì 2:44) Bíbélì mẹ́nu kan “iná àìnípẹ̀kun tí a ti pèsè sílẹ̀ fún Èṣù àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀.” (Mátíù 25:41) Jésù á ju Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sínú “adágún iná àti imí ọjọ́” tí ẹranko ẹhànnà àti wòlíì èké náà wà ní ti pé, wọ́n á pa run títí láé. Ká ní Amágẹ́dọ́nì máa pa àwọn téèyàn ò lè fojú rí lára irú ọmọ Sátánì, ìyẹn àwọn ẹ̀mí èṣù, tí wọ́n lágbára ju irú ọmọ Sátánì tó wà láyé ni, Bíbélì ì bá ti sọ pé àwọn ẹ̀mí èṣù náà wà nínú adágún iná tí ẹranko ẹhànnà àti wòlíì èké náà wà nínú rẹ̀. Bí Ìṣípayá 20:10 ò ṣe mẹ́nu kan àwọn ẹ̀mí èṣù fi hàn pé Amágẹ́dọ́nì ò ní pa wọ́n.
Bíbélì ò sọ pàtó pé a óò ju àwọn ẹ̀mí èṣù sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, kò sì sọ pé a óò tú wọn sílẹ̀ kúrò níbẹ̀. Àmọ́, ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Èṣù ló máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn náà. Lẹ́yìn tá a bá ti tú àwọn ẹ̀mí èṣù àti Èṣù sílẹ̀ tí àwọn ẹ̀mí èṣù sì bá Èṣù fọwọ́ sowọ́ pọ̀ lákòókò ìdánwò tó kẹ́yìn fún aráyé, a ó ju àwọn ẹ̀mí èṣù náà sínú adágún iná, wọ́n á sì tipa bẹ́ẹ̀ pa run títí láé.— Ìṣípayá 20:7-9.
Nítorí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sátánì nìkan ni Ìṣípayá 20:1-3 sọ pé a óò gbá mú tí a ó sì jù sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ níbi tí kò ti ní lè ta pútú, ó bọ́gbọ́n mu ká gbà pé a óò de àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ náà a óò sì jù wọ́n sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀. Kò ní sáyè fún Sátánì tàbí ẹgbàágbèje àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ láti dí Ọlọ́run lọ́wọ́ kó má ṣe ohun tó fẹ́ ṣe, ìyẹn láti sọ ayé di párádísè, kó sì sọ aráyé di pípé nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi.