Iwọ Yoo Ha Kọbiara si Ikilọ Ọlọrun Bi?
AWỌN eniyan kìí sábà fiyesi awọn ikilọ ti ń gbà iwalaaye là. Ọpọ julọ awọn olugbe Pompeii yàn lati ṣaifiyesi ikilọ ariwo kikan tí Oke Vesuvius mu jade. Ni iru ọ̀nà kan-naa, opọ julọ awọn eniyan loni ń kọ̀ lati fiyesi ikilọ nipa ajalu kari-aye kan ti ń bọ̀wá. Ṣugbọn fun awọn wọnni ti wọn muratan lati dojukọ otitọ, ikilọ naa jẹ gidi gẹgẹ bi awọn ìtànyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ ati iná ti o wá lati ori Oke Vesuvius ni ọrundun kin-in-ni. Awọn ogun agbaye meji, ọgọrọọrun awọn iforigbari oníhàámọ́ra ogun, ìyàn, isẹlẹ ńláǹlà, ajakalẹ-arun, igbi iwa ọdaran nibikan tẹle omiran, ati ipolongo iṣẹ iwaasu yika-aye lapapọ jẹ ikilọ agbayanu pe eto-igbekalẹ araye ń yara kankan sunmọ yanpọnyanrin oníjàábá ojiji.
Bibeli sọ asọtẹlẹ amunironu jinlẹ yii: “Ipọnju nla yoo wà, irú eyi ti kò si lati ìgbà ibẹrẹ ọjọ ìwà di isinsinyi, bẹẹkọ, irú rẹ̀ kì yoo sì sí.” (Matteu 24:21) Gẹgẹ bi ọ̀ràn ti ri nigba jamba Pompeii, awọn ti yoo laaja yoo wà—“ọpọlọpọ eniyan ti ẹnikẹni kò lè kà; lati inu orilẹ-ede gbogbo, ati ẹya, ati eniyan, ati lati inu ede gbogbo wá,” yoo laaja, iyẹn ni pe wọn “jade lati inu ipọnju nla.”—Ìfihàn 7:9, 14.
Ibeere naa ni pe, Nigba wo ni iparun yii yoo de? Idi ti ń fi agbara muni wa lati gbagbọ pe iparun naa ti sunmọle. O ṣe kedere pe nini ero akoko lọkan, awọn ọmọ-ẹhin Jesu beere pe: “Ki ni yoo ṣe ami wíwàníhìn-ín rẹ ati ti ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan?” (Matteu 24:3, NW) Ṣakiyesi idahun ti Jesu Kristi fifun wọn.
Ogun—Apa Pataki Lara Ami Alápá Pupọ Naa
Jesu kò wulẹ sọ asọtẹlẹ iṣẹlẹ kanṣoṣo ti o gba afiyesi. Kaka bẹẹ, o sọrọ nipa oniruuru awọn iṣẹlẹ ti ó jẹ́ pe, bi a bá kó wọn pọ̀ lodindi, wọn yoo papọ jẹ ikilọ atọrunwa—àmì alápá pupọ ti ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan. Iṣẹlẹ akọkọ ti a sọtẹlẹ ni a ṣapejuwe rẹ̀ ni Matteu 24:7 pe: “Orilẹ-ede yoo dide si orilẹ-ede, ati ilẹ-ọba si ilẹ-ọba.” Ninu asọtẹlẹ ti o farajọra ni Ìfihàn 6:4, Bibeli sọ asọtẹlẹ pe ‘a o gba alaafia kuro lori ilẹ̀-ayé.’ Eyi tumọsi ogun ni iwọn ti a kò rí iru rẹ̀ rí.
Ìtàn sọ fun wa pe asọtẹlẹ yii nipa ogun yika-aye ti rí imuṣẹ rẹ̀ lati ọdun manigbagbe naa 1914. Iwe naa American Adventures sọ nipa awọn ọdun ti o wà ṣaaju 1914 pe: “Ọpọ julọ awọn eniyan ilẹ America ti wọnu ọrundun titun naa pẹlu ẹkunrẹrẹ ireti. Iwọnyi ni awọn ‘ọdun ti o yabo’ ti wọn sì wà titi di ẹwadun keji ọrundun naa. . . . Lẹhin naa, ni July 28, 1914, ireti yii ni a mì jìgìjìgì pẹlu gbolohun ọ̀rọ̀ kanṣoṣo: ogun.” Bẹẹ ni Ogun Agbaye I bẹrẹ, eyi ti o wà lati 1914 si 1918 ti awọn kan si pè é ni “ogun lati fopin si gbogbo ogun.” Awọn orilẹ-ede 28 ni wọn lọwọ ninu ogun naa ni taarata. Bi iwọ bá si fi awọn orilẹ-ede ti wọn ń ṣakoso le lori kun-un, awọn orilẹ-ede ti ń jagun naa jẹ ipin 90 awọn olugbe ayé ni akoko yẹn.
Ogun Agbaye I pẹlu tun niriiri ifisilo awọn ohun-eelo ogun ti ń panirun lọna kíkàmọ̀mọ̀, bi ibọn ojo ọta, afinásọ̀kò awọn agbá ogun, ọkọ̀ ofuurufu, ati awọn ọkọ̀ abẹ-omi. O tó million mẹwaa awọn jagunjagun ti a pa—iye ti o ju gbogbo awọn jagunjagun ti wọn kú ninu awọn ogun kàǹkà kàǹkà ti a jà ni 100 ọdun ti o ṣaaju! Nǹkan bii million 21 ni a ṣe leṣe. Niti tootọ, o jẹ ogun kan yika-aye, ni sisami si 1914 gẹgẹ bi ibẹrẹ “awọn akoko ikẹhin.” (2 Timoteu 3:1, NW) Bi o ti wu ki o ri, ogun wulẹ jẹ apakan lara àmì Jesu ni.
Awọn Apa Miiran Lara Àmì Naa
Jesu fikun un pe: “Ìyàn, ati ajakalẹ-arun, ati isẹlẹ yoo sì wà ni ibi pupọ. Gbogbo nǹkan wọnyi ni ipilẹṣẹ [iroragogo idaamu, NW].” (Matteu 24:7, 8) Luku 21:11 fi “ajakalẹ-arun” kun akọsilẹ yẹn. Ṣaaju ki Ogun Agbaye I to pari, arun gágá ti ń ràn kalẹ ti bẹ́ silẹ yika-aye. Ni kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, o pa iye ti o ju 20 million eniyan, iye ti o ju awọn ti ogun naa ti pa lọ.
Nigba ogun ati lẹhin ogun naa, ọpọ million eniyan miiran kú nitori ijiya lọwọ ebi. Isẹlẹ tun fi iku pa ọpọlọpọ eniyan. Ni 1915 iye ti o ju 30,000 ni a pa ni Italy; ni 1920 nǹkan bii 200,000 ni wọn ṣègbé ni China; ni 1923 iye ti o tó 143,000 ni wọn ku ni Japan. Sibẹ, gẹgẹ bi Jesu ti fihàn, gbogbo iwọnyi wulẹ jẹ ipilẹṣẹ iroragogo idaamu, ni. Iwe atumọ ede kan tumọ iroragogo gẹgẹ bi “irora òjijì wiwọnilara onigba kukuru” kan. Nipa bẹẹ ayé yii ti ń jàràpà lati inu irora òjijì kan si omiran lọna kíkankíkan ati ni lemọlemọ sii lati 1914 wá. Fun apẹẹrẹ, ni kiki ọdun 21 pere lẹhin Ogun Agbaye I ni ogun agbaye keji bẹsilẹ, eyi ti o pa 50 million eniyan ti o si mú iran eniyan wọnu sanmani alagbara atọmiki.
Ni awọn ọdun lọọlọọ pupọ ni a ti sọ nipa okunfa idaamu miiran sibẹ: pipa ti eniyan ń pa ayika run. Bi o tilẹ jẹ pe Jesu kò mẹnuba eyi ni pato ninu asọtẹlẹ rẹ̀, Ìfihàn 11:18 fihàn pe ṣaaju ki iparun naa tó dé, awọn eniyan yoo maa “pa aye run.” Ẹ̀rí pe iparun yii ń ṣẹlẹ pọ rẹpẹtẹ. Ni fifa ọ̀rọ̀ yọ lati inu iwe naa State of the World 1988, olugbaninimọran nipa ayika Norman Myers funni ni isọfunni amunigbọnriri yii: “Kò sí iran kan ni akoko ti o ti kọja ti o tii dojukọ ireti imuwalaaye gbogbogboo wa sopin nigba ayé rẹ̀. Ko si iran ọjọ iwaju ti yoo dojukọ iru ipenija kan bẹẹ lae: bi iran ti akoko yii bá kuna lati wá ojutuu si ọ̀ràn lilekoko naa, ibajẹ naa ni a o ti ṣe ti kì yoo sì sí ‘anfaani ẹlẹẹkeji.’”
Ronu nipa irohin ti ó wà ninu itẹjade iwe-irohin Newsweek ti February 17, 1992, nipa idinku ozone ninu afẹfẹ ayika. Ogbontarigi nipa ozone Alexandra Allen ti ajọ Greenpeace ni a fa ọ̀rọ̀ rẹ yọ pe o funni ni ikilọ pe ipadanu ozone “nisinsinyi ti ń halẹ mọ ọjọ-ọla gbogbo iwalaaye lori ilẹ̀-ayé.”—Wo apoti ti o wà ni oju-iwe yii fun ẹ̀rí siwaju sii nipa pipa ayika ilẹ̀-ayé run.
Àyè kò tó fun kulẹkulẹ alaye nipa oniruuru awọn apa pataki lara asọtẹlẹ Jesu. (Wo itolẹsẹẹsẹ isọfunni ti o wa ni oju-iwe 5 fun alaye kukuru nipa awọn apa asọtẹlẹ pataki miiran.) Bi o ti wu ki o ri, apa ti a kò lè gbojufoda ni a ṣapejuwe ni Matteu 24:14 pe: “A o si waasu ihinrere ijọba yii ni gbogbo ayé lati ṣe ẹ̀rí fun gbogbo orilẹ-ede; nigba naa ni opin yoo sì de.” Kò si iyemeji nipa awọn wo ni wọn ń ṣe iṣẹ iwaasu kari-aye yii. Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní 229 ilẹ lo iye ti o ju billion kan wakati ninu iṣẹ yii ni ọdun 1992 nikan. Iṣẹ wọn tipa bẹẹ jẹ apakan lara ẹ̀rí ti o ṣeefojuri pe a ń gbe ni awọn ọjọ ikẹhin.
Maṣe Jẹ Ki A Tàn Ọ́ Jẹ!
Bi o ti wu ki o ri, awọn kan le jiyan pe gbogbo ọ̀rọ̀ yii nipa “ikẹhin ọjọ” wulẹ jẹ nini ero ibi ni. ‘Ki ni nipa iwolulẹ ijọba Kọmunist ni lọọlọọ yii ni Ila-oorun Europe?’ ni wọn beere, ‘tabi isapa awọn alagbara ogbontarigi lati ṣeto alaafia? Eyi kìí ha ṣe ẹ̀rí pe nǹkan ń dara sii bi?’ Bẹẹkọ. Ṣakiyesi pe Jesu ko sọ pe ayé lodindi yoo figba gbogbo wà ninu ogun, isẹlẹ, ati ìyàn ni ikẹhin ọjọ. Ki a baa lè waasu ihinrere naa jakejado ayé, o keretan awọn saa akoko ìparọ́rọ́ niwọnba kan nilati wà.
Ranti, pẹlu, pe Jesu fi awọn ọjọ ikẹhin wera pẹlu awọn ọjọ ti o wà ṣaaju Ikun-omi Noa. Ni akoko yẹn awọn eniyan ni ọwọ wọn di jọjọ fun jijẹ, mimu, ati gbigbeyawo—awọn igbokegbodo titọ ninu igbesi-aye. (Matteu 24:37-39) Eyi yoo fihàn pe nigba ti awọn ipo nǹkan ni awọn ọjọ ikẹhin yoo jẹ eyi ti ń muni rẹwẹsi, awọn nǹkan ki yoo buru debi pe awọn ilepa igbesi-aye ti wọn wà deedee kò ni ṣeeṣe. Gẹgẹ bi o ti ri ni ọjọ Noa, eyi ti o pọ julọ ninu awọn eniyan ni ọwọ wọn di jọjọ fun awọn alamọri ọjọ de ọjọ tobẹẹ ti wọn ko fi mọ ijẹpataki awọn akoko.
Nitori naa, yoo lewu lati ṣubu sinu idagunla kiki nitori ohun ti o farahan bi awọn idagbasoke didara ninu iṣelu. (Fiwe 1 Tessalonika 5:3.) Ẹ̀rí naa pọ jaburata pe asọtẹlẹ Jesu ń ni imuṣẹ nisinsinyi—ikilọ ni o jẹ́ pe iparun sunmọle!
Akoko Ologo Lẹhin Iparun Naa
Iparun Pompeii mu iku ati irora wa. Bi o ti wu ki o ri, opin eto-igbekalẹ isinsinyi yoo pa ọ̀nà mọ́ fun ìyè ayeraye lori paradise ilẹ̀-ayé ẹlẹwa. (Ìfihàn 21:3, 4) Ijọba eniyan ti ń pinniniya kì yoo tun fi ogun ba ilẹ̀-ayé jẹ mọ. Awọn eniyan kì yoo tun bẹru ìparun deérú alagbara atọmiiki mọ́. Awọn ilé-iṣẹ́ ẹrọ ti ń da awọn kẹ́míkà oloro sinu afẹfẹ yoo ti wábi gbà.—Danieli 2:44.
Ni akoko yẹn gbogbo ẹni ti o bá walaaye yoo jẹ olufẹ ododo ati ọ̀rẹ́ tootọ, wọn yoo jẹ́ oluṣegbọran patapata si ilana Ijọba naa. (Orin Dafidi 37:10, 11) Awọn ile-iwosan, awọn yara ààtò isinku, ati awọn ibi isinku yoo ti di awọn ohun ìtàn. Ikọsilẹ, ipinya, isorikọ, ati ilokulo awọn ọmọde kì yoo sí mọ́ bakan-naa.—Isaiah 25:8; 65:17.
Iwọ ha fẹ lati la awọn ọjọ ikẹhin ja ki o sì walaaye lati rí ayé titun ologo ti Ọlọrun bi? Nigba naa ‘wà lójúfò nitori ti iwọ kò mọ̀ ìgbà ti akoko naa yoo de.’ (Marku 13:33) Bi o tilẹ ri bẹẹ, awọn iṣẹlẹ ayé mu ki o ṣe kedere pe akoko ti a yàn naa ti sunmọle—ó sunmọle lọna ti o léwu fun ọpọlọpọ. Kò si ìfàkókò ṣofo. Nitori naa, gbe igbesẹ ti ń gba ẹmi la, ki o sì wá awọn wọnni ti ń kọbiara si awọn ikilọ yika aye nipa awọn ọjọ ikẹhin rí. Awọn wọnyii ṣeedamọ tirọruntirọrun, nitori pe awọn nikan ni wọn ń ṣegbọran si aṣẹ Jesu lati waasu ihinrere Ijọba naa jakejado ayé. Papọ pẹlu iru awọn ẹni bẹẹ, ǹjẹ́ ki iwọ gbe igbesẹ lati da araarẹ pọ mọ Ọba naa, Kristi Jesu, ẹni ti a sọ nipa rẹ̀ pe: “Orukọ rẹ̀ ni awọn Keferi yoo maa gbẹkẹle.”—Matteu 12:18, 21.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]
Awọn Apa Mẹrinlelogun Ninu Àmì Naa
1. Ogun ti kò ni afiwe—Matteu 24:6, 7; Ìfihàn 6:4
2. Isẹlẹ—Matteu 24:7; Marku 13:8
3. Àìtó ounjẹ—Matteu 24:7; Marku 13:8
4. Ajakalẹ-arun—Luku 21:11; Ìfihàn 6:8
5. Iwa ailofin ti ń pọ sii—Matteu 24:12
6. Pipa ayé run—Ìfihàn 11:18
7. Ifẹ ti ń di tútù—Matteu 24:12
8. Awọn ohun ẹ̀rù—Luku 21:11
9. Ifẹ fun owó rekọja ààlà—2 Timoteu 3:2
10. Aigbọran si awọn òbí—2 Timoteu 3:2
11. Fifẹran adùn ju Ọlọrun lọ—2 Timoteu 3:4
12. Ifẹ fun ara-ẹni ń dari awọn eniyan —2 Timoteu 3:2
13. Aini ifẹni ẹda ni gbogbogboo—2 Timoteu 3:3
14. Awọn eniyan jẹ́ aláìládèéhùn—2 Timoteu 3:3
15. Aini ikora-ẹni nijaanu kò si ni gbogbo ipele ẹgbẹ́ awujọ—2 Timoteu 3:3
16. Ìtànkálẹ̀ ainifẹẹ ohun rere—2 Timoteu 3:3
17. Ọpọlọpọ fi agabagebe sọ pe Kristian ni awọn—2 Timoteu 3:5
18. Ọpọ ń jẹ ajẹju ati amuju—Luku 21:34
19. Awọn ẹlẹgan kọ àmì naa—2 Peteru 3:3, 4
20. Ọpọ awọn wolii èké ń gbeṣẹṣe—Matteu 24:5, 11; Marku 13:6
21. Wiwaasu Ijọba Ọlọrun ti a ti fi idi rẹ̀ mulẹ—Matteu 24:14; Marku 13:10
22. Ṣiṣenunibini si awọn Kristian tootọ—Matteu 24:9; Luku 21:12
23. Igbe alaafia ati ailewu lati fi ogogoro-opin si ọjọ ikẹhin—1 Tessalonika 5:3
24. Awọn eniyan kò ṣakiyesi jamba—Matteu 24:39
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
Awọn Iṣoro Ayika—Àmì Awọn Akoko
◻ Ibori ozone ti ń daaboboni ń di kekere sii ni ilọpo meji ju bi awọn onimọ ijinlẹ ti rò lọ ni iha Ariwa Ilaji Aye ti awọn eniyan kunfọfọ.
◻ O keretan 140 eweko ati oniruuru ọ̀wọ́ ẹranko ni wọn ń poora lojoojumọ.
◻ Iwọn afẹfẹ carbon dioxide ti ń gbooru duro ninu afẹfẹ ayika ti fi ipin 26 ninu ọgọrun-un ju bi o ti wa ṣaaju itankalẹ ile-iṣẹ ẹrọ, o si ń baa lọ ni lilọ soke.
◻ Ilẹ̀-ayé tubọ gbona ni 1990 ju ọdun eyikeyii lọ lati ìgbà ti a ti bẹrẹ si pa akọsilẹ mọ lati ilaji ọrundun kọkandinlogun; mẹfa ninu awọn ọdun meje ti o gbona julọ ti waye lati 1980.
◻ Awọn ẹgàn ń pòórá ni iwọn 17,000,000 sarè lọdun kan, àyè ilẹ ti o fẹrẹẹ tó ilaji iwọn itobi Finland.
◻ Iye awọn olugbe ayé ń bisi pẹlu million 92 eniyan lọdọọdun—iye ti o fẹrẹẹ tó ríro awọn olugbe Mexico miiran mọ lọdọọdun; ninu aropọ yii, million 88 ni a ń fikun un ni awọn ilẹ ti ń goke agba.
◻ Nǹkan bii billion 1.2 eniyan ni kò ni omi ti o dara lati mu.
Gẹgẹ bi iwe naa State of the World 1992, lati ọwọ Worldwatch Institute, oju-iwe 3, 4, W. W. Norton & Company, New York, London ti sọ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Lẹhin iparun ni aye titun ologo Ọlọrun yoo de