Tẹ́ḿpìlì Ńlá Jèhófà Nípa Tẹ̀mí
“Àwa ní irúfẹ́ àlùfáà àgbà kan bí èyí, . . . ìránṣẹ́ gbogbo ènìyàn ní ibi mímọ́ àti ní àgọ́ tòótọ́ náà, èyí tí Jèhófà gbé ró, kì í sì í ṣe ènìyàn.”—HÉBÉRÙ 8:1, 2.
1. Ìpèsè onífẹ̀ẹ́ wo ni Ọlọ́run ṣe fún aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀?
JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN, nítorí ìfẹ́ ńlá tí ó ní fún aráyé, pèsè ìrúbọ kan láti kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ. (Jòhánù 1:29; 3:16) Ó béèrè fún títàtaré ìwàláàyè Ọmọkùnrin rẹ̀ àkọ́bí láti ọ̀run sínú ilé ọlẹ̀ wúńdíá Júù kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Màríà. Áńgẹ́lì Jèhófà ṣàlàyé ní kedere fún Màríà pé, ọmọ tí yóò lóyún rẹ̀ ni “a óò pè ní mímọ́, Ọmọkùnrin Ọlọ́run.” (Lúùkù 1:34, 35) A sọ fún Jósẹ́fù, tí ó ń fẹ́ Màríà sọ́nà, nípa ọ̀nà ìyanu tí a gbà lóyún Jésù, ó sì gbọ́ pé ẹni yìí yóò “gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”—Mátíù 1:20, 21.
2. Kí ni Jésù ṣe nígbà tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ẹni 30 ọdún, èé sì ti ṣe?
2 Bí Jésù ṣe ń dàgbà, yóò ti lóye díẹ̀ nínú àwọn òkodoro òtítọ́ nípa bí a ṣe bí òun lọ́nà ìyanu. Ó mọ̀ pé Bàbá òun ní ọ̀run yan iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà kan fún òun láti ṣe lórí ilẹ̀ ayé. Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bíi géńdé ọkùnrin tí ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ẹni 30 ọdún, Jésù wá sọ́dọ̀ Jòhánù, wòlíì Ọlọ́run, kí ó lè batisí òun ní Odò Jọ́dánì.—Máàkù 1:9; Lúùkù 3:23.
3. (a) Kí ni Jésù ní lọ́kàn pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ náà, “Ẹbọ àti ọrẹ-ẹbọ ìwọ kò fẹ́”? (b) Àpẹẹrẹ títayọ wo ni Jésù fi lélẹ̀ fún gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?
3 Jésù ń gbàdúrà lọ́wọ́ nígbà ìbatisí rẹ̀. (Lúùkù 3:21) Ó ṣe kedere pé, láti àkókò yìí lọ nínú ìgbésí ayé rẹ̀, ohun tí Sáàmù 40:6-8 wí ni ó ń mú lò, gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé: “Ẹbọ àti ọrẹ-ẹbọ ìwọ kò fẹ́, ṣùgbọ́n ìwọ́ pèsè ara kan fún mi.” (Hébérù 10:5) Nípa báyìí, Jésù fi hàn pé òun mọ̀ pé Ọlọ́run “kò fẹ́” kí fífi ẹran rúbọ máa bá a nìṣó ní tẹ́ḿpìlì Jerúsálẹ́mù. Dípò èyí, ó mọ̀ pé Ọlọ́run ti pèsè ara ẹ̀dá ènìyàn pípé fún òun, Jésù, láti fi rúbọ. Èyí yóò mú àìní èyíkéyìí fún fífi ẹran rúbọ kúrò. Ní fífi ìfẹ́-ọkàn rẹ̀ hàn láti juwọ́ sílẹ̀ fún ìfẹ́ inú Ọlọ́run, Jésù ń bá a nìṣó ní gbígbàdúrà pé: “Wò ó! Mo dé (nínú àkájọ ìwé ni a gbé kọ ọ́ nípa mi) láti ṣe ìfẹ́ inú rẹ, Óò Ọlọ́run.” (Hébérù 10:7) Ẹ wo irú àpẹẹrẹ gíga lọ́lá ní ti ìgboyà àti ìfọkànsìn aláìmọtara-ẹni-nìkan tí Jésù fi lélẹ̀ ní ọjọ́ náà fún gbogbo àwọn tí yóò di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn!—Máàkù 8:34.
4. Báwo ni Ọlọ́run ṣe fi hàn pé òún tẹ́wọ́ gba fífi tí Jésù fi ara rẹ̀ rúbọ?
4 Ọlọ́run ha fi hàn pé òún tẹ́wọ́ gba àdúrà tí Jésù gbà nípa batisí rẹ̀ bí? Jẹ́ kí ọ̀kan nínú àwọn àpọ́sítélì tí Jésù yàn fún wa ní ìdáhùn: “Lẹ́yìn tí a batisí rẹ̀ Jésù jáde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti inú omi; sì wò ó! àwọn ọ̀run ṣí sílẹ̀, ó sì rí tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń sọ̀kalẹ̀ bí àdàbà bọ̀ wá sórí rẹ̀. Wò ó! Pẹ̀lúpẹ̀lù, ohùn kan wá láti inú àwọn ọ̀run tí ó wí pé: ‘Èyí ni Ọmọkùnrin mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti fi ojúrere tẹ́wọ́ gbà.’”—Mátíù 3:16, 17; Lúùkù 3:21, 22.
5. Kí ni pẹpẹ tẹ́ḿpìlì tí a lè fojú rí ṣàpẹẹrẹ?
5 Títẹ́wọ́ gbà tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba fífi tí Jésù fi ara rẹ̀ lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìrúbọ túmọ̀ sí pé, nípa tẹ̀mí, pẹpẹ kan tí ó tóbi ju èyí tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù lọ ti wá sójútáyé. Pẹpẹ tí a lè fojú rí, níbi tí a ti ń fi ẹran rúbọ ṣàpẹẹrẹ pẹpẹ nípa tẹ̀mí yẹn, tí ó jẹ́ “ìfẹ́ inú” Ọlọ́run ní ti gidi tàbí ìṣètò fún títẹ́wọ́ gba ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn Jésù gẹ́gẹ́ bí ìrúbọ. (Hébérù 10:10) Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi lè kọ̀wé sí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Àwá ní pẹpẹ kan láti orí èyí tí àwọn wọnnì tí ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ níbi àgọ́ [tàbí, tẹ́ḿpìlì] kò ní ọlá àṣẹ láti jẹ.” (Hébérù 13:10) Ní èdè míràn, àwọn Kristẹni tòótọ́ ń jàǹfààní láti inú ẹbọ gíga lọ́lá jù lọ fún ètùtù ẹ̀ṣẹ̀, tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn àlùfáà Júù kọ̀ sílẹ̀.
6. (a) Kí ni ó wá sójútáyé ní àkókò tí a batisí Jésù? (b) Kí ni orúkọ oyè náà Mèsáyà, tàbí Kristi, túmọ̀ sí?
6 Fífi ẹ̀mí mímọ́ yan Jésù túmọ̀ sí pé, Ọlọ́run ti gbé ìṣètò tẹ́ḿpìlì rẹ̀ nípa tẹ̀mí látòkèdélẹ̀ kalẹ̀ nísinsìnyí, tí Jésù sì ń ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà. (Ìṣe 10:38; Hébérù 5:5) A mí sí ọmọ ẹ̀yìn náà, Lúùkù, láti tọ́ka sí ọdún náà gan-an tí ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé náà wáyé, pé ó jẹ́ “ní ọdún kẹẹ̀ẹ́dógún ìgbà ìjọba Tìbéríù Késárì.” (Lúùkù 3:1-3) Ìyẹn bá ọdún 29 Sànmánì Tiwa mu—69 ọ̀sẹ̀ ọdún géérégé, tàbí 483 ọdún, láti ìgbà tí Ọba Atasásítà ti pàṣẹ pé kí a tún odi Jerúsálẹ́mù kọ́. (Nehemáyà 2:1, 5-8) Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe sọ, “ọmọ aládé Ẹni òróró náà” yóò fara hàn ní ọdún tí a ti sọ tẹ́lẹ̀ náà. (Dáníẹ́lì 9:25) Ọ̀pọ̀ Júù mọ èyí dájú. Lúùkù ròyìn pé “àwọn ènìyàn naa ti wà nínú ìfojúsọ́nà” fún ìfarahàn Mèsáyà náà, tàbí Kristi, àwọn orúkọ oyè tí ó wá láti inú ọ̀rọ̀ èdè Hébérù àti ti Gíríìkì tí ó ní ìtumọ̀ kan náà, “ẹni-àmì-òróró.”—Lúùkù 3:15.
7. (a) Nígbà wo ni Ọlọ́run fi òróró yan “Ibi Mímọ́ Jù Lọ,” kí sì ni èyí túmọ̀ sí? (b) Kí ni ó tún ṣẹlẹ̀ sí Jésù nígbà tí a batisí rẹ̀?
7 Nígbà ìbatisí Jésù, ibùjókòó Ọlọ́run ní òkè ọ̀run, ni a fi òróró yàn tàbí ni a yà sọ́tọ̀, bí ‘Ibi Mímọ́ Jù Lọ’ nínú ìṣètò tẹ́ḿpìlì ńlá nípa tẹ̀mí. (Dáníẹ́lì 9:24) “Àgọ́ tòótọ́ náà [tàbí, tẹ́ḿpìlì], èyí tí Jèhófà gbé ró, [tí] kì í sì í ṣe ènìyàn” ti wà lẹ́nu iṣẹ́. (Hébérù 8:2) Bákan náà, nípasẹ̀ fífi omi àti ẹ̀mí mímọ́ batisí rẹ̀, a tún ọkùnrin náà, Jésù Kristi, bí gẹ́gẹ́ bí Ọmọkùnrin Ọlọ́run nípa tẹ̀mí. (Fi wé Jòhánù 3:3.) Èyí túmọ̀ sí pé, ní àkókò yíyẹ, Ọlọ́run yóò mú Ọmọkùnrin rẹ̀ padà sí ìyè ti ọ̀run, níbi tí yóò ti máa ṣiṣẹ́ sìn ní ọwọ́ ọ̀tún Bàbá rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba àti Àlùfáà Àgbà “ní ìbámu pẹ̀lú irú ọ̀nà ti Melkisédékì títí láé.”—Hébérù 6:20; Sáàmù 110:1, 4.
Ibi Mímọ́ Jù Lọ ti Òkè Ọ̀run
8. Àwọn apá tuntun wo ni ìtẹ́ Ọlọ́run ní ọ̀run ní nísinsìnyí?
8 Ní ọjọ́ ìbatisí Jésù, ìtẹ́ Ọlọ́run ní òkè ọ̀run ní àwọn apá tuntun. Ohun tí Ọlọ́run là sílẹ̀ nípa fífi ẹ̀dá ènìyàn pípé rúbọ láti ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ aráyé fi hàn bí ìjẹ́mímọ́ Ọlọ́run ti ṣe pàtàkì tó ní ìyàtọ̀ pátápátá sí ipò ẹ̀ṣẹ̀ ènìyàn. A fi àánú Ọlọ́run pẹ̀lú hàn ní ti pé, ó fi ìmúratán rẹ̀ hàn nísinsìnyí pé a lè tu òun lójú, tàbí pẹ̀tù sí òun lọ́kàn. Nípa báyìí, ìtẹ́ Ọlọ́run ní ọ̀run wá dà bí ibi tí ó wà ní iyàrá ìkélé ti inú lọ́hùn-ún nínú tẹ́ḿpìlì, níbi tí àlùfáà àgbà máa ń wọ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ẹran láti ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ ní ọ̀nà ìṣàpẹẹrẹ.
9. (a) Kí ni aṣọ ìkélé tí ó wà láàárín Ibi Mímọ́ àti Ibi Mímọ́ Jù Lọ ṣàpẹẹrẹ? (b) Báwo ni Jésù ṣe ráyè wọnú ibi aṣọ ìkélé ti tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run nípa tẹ̀mí?
9 Aṣọ ìkélé tí ó pín Ibi Mímọ́ àti Ibi Mímọ́ Jù Lọ níyà ṣàpẹẹrẹ ẹran ara Jésù. (Hébérù 10:19, 20) Òun ni ìdènà tí kò jẹ́ kí Jésù lọ sí iwájú Bàbá rẹ̀ nígbà tí ó wà níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ènìyàn. (Korinti Kìíní 15:50) Nígbà ikú Jésù, “aṣọ ìkélé ibùjọsìn ya sí méjì, láti òkè dé ìsàlẹ̀.” (Mátíù 27:51) Lọ́nà tí ó wọni lọ́kàn, èyí fi hàn pé, a ti mú ìdènà tí kò jẹ́ kí Jésù lè lọ sí ọ̀run kúrò. Ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà, Jèhófà Ọlọ́run ṣe ìṣẹ ìyanu tí ó gọntiọ. Ó jí Jésù dìde kúrò nínú ikú, kì í ṣe bí ẹni kíkú, tí ó jẹ́ ẹlẹ́ran ara àti ẹ̀jẹ̀, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí ológo ‘tí yóò máa bá a lọ ní wíwà láàyè títí láé.’ (Hébérù 7:24) Ogójì ọjọ́ lẹ́yìn náà, Jésù gòkè lọ sí ọ̀run, ó sì wọ “Ibi Mímọ́ Jù Lọ” tí ó jẹ́ gidi lọ, “láti fara hàn níwájú Ọlọ́run fúnra rẹ̀ fún wa.”—Hébérù 9:24.
10. (a) Kí ni ó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Jésù gbé ìtóye ẹbọ rẹ̀ kalẹ̀ fún Bàbá rẹ̀ ọ̀run? (b) Kí ni fífi ẹ̀mí mímọ́ yanni túmọ̀ sí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi?
10 Ọlọ́run ha tẹ́wọ́ gba ìtóye ẹ̀jẹ̀ Jésù tí a ta sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aráyé bí? Ní tòótọ́, ó tẹ́wọ́ gbà á. Ẹ̀rí èyí wáyé ní 50 ọjọ́ géérégé lẹ́yìn tí a jí Jésù dìde, ní ọjọ́ àjọ̀dún Pẹ́ńtíkọ́sì. A tú ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run sórí 120 ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí wọ́n pàdé pọ̀ ní Jerúsálẹ́mù. (Ìṣe 2:1, 4, 33) Gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà wọn, Jésù Kristi, a ti fi òróró yàn wọ́n nísinsìnyí láti ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí “àlùfáà mímọ́, láti máa rú àwọn ẹbọ ti ẹ̀mí” lábẹ́ ìṣètò tẹ́ḿpìlì ńlá Ọlọ́run nípa tẹ̀mí. (Pétérù Kìíní 2:5) Síwájú sí i, àwọn ẹni-àmì-òróró wọ̀nyí para pọ̀ jẹ́ orílẹ̀-èdè tuntun, “orílẹ̀-èdè mímọ́” ti Ọlọ́run, tí í ṣe Ísírẹ́lì nípa tẹ̀mí. Láti ìgbà náà lọ, gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ ohun rere nípa Ísírẹ́lì, irú bí ìlérí “májẹ̀mú tuntun” tí a kọ sílẹ̀ nínú Jeremáyà 31:31, yóò ní ìmúṣẹ sí ìjọ Kristẹni ẹni-àmì-òróró lára, ojúlówó “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.”—Pétérù Kìíní 2:9; Gálátíà 6:16.
Àwọn Apá Mìíràn tí Tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run Nípa Tẹ̀mí Ní
11, 12. (a) Nínú ọ̀ràn ti Jésù, kí ni àgbàlá tí ó wà fún àwọn àlùfáà ṣàpẹẹrẹ, kí sì ni ó jẹ́ nínú ọ̀ràn ti àwọn ẹni-àmì-òróró ọmọlẹ́yìn rẹ̀? (b) Kí ni agbada omi náà ń ṣàpẹẹrẹ, báwo sì ni a ṣe ń lò ó?
11 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ibi Mímọ́ Jù Lọ ṣàpẹẹrẹ “ọ̀run fúnra rẹ̀,” níbi tí Ọlọ́run gúnwà sí, gbogbo àwọn apá mìíràn tí tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run nípa tẹ̀mí ní, ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé. (Hébérù 9:24) Nínú tẹ́ḿpìlì tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù, àgbàlá ti inú lọ́hùn-ún kan wà fún àwọn àlùfáà, tí ó ní pẹpẹ fún ìrúbọ àti agbada ńlá kan fún omi, tí àwọn àlùfáà ń lò láti wẹ ara wọn mọ́ tónítóní kí wọ́n tó ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀. Kí ni àwọn nǹkan wọ̀nyí ń ṣàpẹẹrẹ nínú ìṣètò tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run nípa tẹ̀mí?
12 Nínú ọ̀ràn ti Jésù Kristi, àgbàlá inú lọ́hùn-ún tí ó wà fún àwọn àlùfáà, ṣàpẹẹrẹ ipò aláìlẹ́ṣẹ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn pípé Ọmọkùnrin Ọlọ́run. Nípa lílo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ Jésù, a fi òdodo jíǹkí àwọn ẹni-àmì-òróró ọmọlẹ́yìn Kristi. Nípa báyìí, Ọlọ́run lè fi ẹ̀tọ́ bá wọn lò bí ẹni pé wọ́n jẹ́ aláìlẹ́ṣẹ̀. (Róòmù 5:1; 8:1, 33) Nítorí náà, àgbàlá yìí tún ń ṣàpẹẹrẹ ipò òdodo àfijíǹkì ẹ̀dá ènìyàn tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn mẹ́ḿbà ẹgbẹ́ àlùfáà mímọ́ náà ń gbádùn níwájú Ọlọ́run. Lọ́wọ́ kan náà, àwọn Kristẹni ẹni-àmì-òróró ṣì jẹ́ aláìpé, wọ́n sì lè dẹ́ṣẹ̀. Agbada omi tí ó wà ní àgbàlá náà ń ṣàpẹẹrẹ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tí Àlùfáà Àgbà náà ń lò láti wẹ ẹgbẹ́ àlùfáà mímọ́ náà mọ́ tónítóní ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. Nípa jíjuwọ́ sílẹ̀ fún ọ̀nà ìwẹ̀mọ́ tónítóní yìí, wọ́n ti ní ìrísí àrímáleèlọ, tí ń bọlá fún Ọlọ́run, tí ó sì ń fa àwọn ará ìta mọ́ra sí ìjọsìn rẹ̀ mímọ́ gaara.—Éfésù 5:25, 26; fi wé Málákì 3:1-3.
Ibi Mímọ́
13, 14. (a) Kí ni Ibi Mímọ́ inú tẹ́ḿpìlì ṣàpẹẹrẹ nínú ọ̀ràn Jésù àti ti àwọn ẹni-àmì-òróró ọmọlẹ́yìn rẹ̀? (b) Kí ni ọ̀pá fìtílà oníwúrà náà ń ṣàpẹẹrẹ?
13 Iyàrá ìkélé àkọ́kọ́ nínú tẹ́ḿpìlì náà ń ṣàpẹẹrẹ ipò gíga lọ́lá ju ti àgbàlá lọ. Nínú ọ̀ràn ti ẹ̀dá ènìyàn pípé náà Jésù Kristi, ó ṣàpẹẹrẹ títún un bí gẹ́gẹ́ bí Ọmọkùnrin Ọlọ́run nípa tẹ̀mí, tí a ti kádàrá láti padà sí ìyè ti ọ̀run. Lẹ́yìn tí a ti polongo wọn ní olódodo, lórí ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ wọn nínú ẹ̀jẹ̀ Kristi tí a ta sílẹ̀, àwọn ẹni-àmì-òróró ọmọlẹ́yìn wọ̀nyí tún nírìírí ìṣiṣẹ́ ẹ̀mí Ọlọ́run lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. (Róòmù 8:14-17) Nípasẹ̀ “omi [ìyẹn ni, ìbatisí wọn] àti ẹ̀mí,” a ti ‘tún wọn bí’ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Ọlọ́run nípa tẹ̀mí. Nípa báyìí, wọ́n ní ìrètí dídi ẹni tí a óò jí dìde sí ìyè ti ọ̀run gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Ọlọ́run nípa tẹ̀mí, kìkì bí wọ́n bá dúró gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́ títí dé ojú ikú.—Jòhánù 3:5, 7; Ìṣípayá 2:10.
14 Àwọn olùjọsìn tí wọ́n wà lẹ́yìn òde tẹ́ḿpìlì orí ilẹ̀ ayé náà, kì í rí àwọn àlùfáà tí wọ́n ṣiṣẹ́ sìn nínú Ibi Mímọ́ ti tẹ́ḿpìlì náà. Bákan náà, àwọn Kristẹni ẹni-àmì-òróró ń nírìírí ipò tẹ̀mí tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn olùjọsìn Ọlọ́run, tí wọ́n ní ìrètí ìyè títí láé nínú párádísè kan lórí ilẹ̀ ayé kò ṣàjọpín, tàbí ti wọn kò lóye lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Ọ̀pá fìtílà oníwúrà ti àgọ́ àjọ náà ń ṣàpẹẹrẹ ipò ìlàlóye tí àwọn Kristẹni ẹni-àmì-òróró wà. Ìṣiṣẹ́ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, bí òróró tí ń bẹ nínú fìtílà, ń tan ìmọ́lẹ̀ sórí Bíbélì. Òye tí àwọn Kristẹni ń rí gbà gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, ni wọn kò fi mọ sọ́dọ̀ ara wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ṣègbọràn sí Jésù, tí ó wí pé: “Ẹ̀yin ni ìmọ́lẹ̀ ayé. . . . Kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ àtàtà yín kí wọ́n sì lè fi ògo fún Bàbá yín tí ń bẹ ní àwọn ọ̀run.”—Mátíù 5:14, 16.
15. Kí ni àkàrà tí ó wà lórí tábìlì àkàrà ìfihàn ṣàpẹẹrẹ?
15 Láti lè dúró sínú ipò ìlàlóye yìí, àwọn Kristẹni ẹni-àmì-òróró gbọ́dọ̀ máa jẹ ohun tí àkàrà tí ó wà lórí tábìlì àkàrà ìfihàn ń ṣàpẹẹrẹ déédéé. Orísun pàtàkì fún oúnjẹ tẹ̀mí wọn ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n ń sakun láti kà, tí wọ́n sì ń ṣàṣàrò lé lórí lójoojúmọ́. Jésù tún ṣèlérí láti pèsè “oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́mu” nípasẹ̀ “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n inú ẹrú.” (Mátíù 24:45) “Ẹrú” yìí ni ẹgbẹ́ àwọn Kristẹni ẹni-àmì-òróró lódindi lórí ilẹ̀ ayé ní àkókò pàtó èyíkéyìí. Kristi ti lo ẹgbẹ́ tí a fi òróró yàn yìí láti tẹ ìsọfúnni jáde lórí ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, kí ó sì fúnni ní ìtọ́sọ́nà tí ó bọ́ sákòókò lórí bí a ṣe ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nínú ìgbésí ayé ojoojúmọ́ lóde òní. Nítorí náà, àwọn Kristẹni ẹni-àmì-òróró ń fi ìmọrírì jẹ gbogbo irú ìpèsè nípa tẹ̀mí bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n, gbígbé ìwàláàyè wọn nípa tẹ̀mí ró sinmi lórí ohun tí ó ju gbígba ìmọ̀ Ọlọ́run sínú èrò inú àti ọkàn-àyà wọn. Jésù wí pé: “Oúnjẹ mi ni fún mi láti ṣe ìfẹ́-inú ẹni tí ó rán mi àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀.” (Jòhánù 4:34) Bákan náà, àwọn Kristẹni ẹni-àmì-òróró ń ní ìtẹ́lọ́rùn nípa lílàkàkà lójoojúmọ́ láti ṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run èyí tí a ṣí payá.
16. Kí ni iṣẹ́ ìsìn níbi pẹpẹ tùràrí ṣàpẹẹrẹ?
16 Ní òwúrọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́, àlùfáà kan máa ń sun tùràrí sí Ọlọ́run lórí pẹpẹ tùràrí nínú Ibi Mímọ́. Lọ́wọ́ kan náà, àwọn olùjọsìn tí wọn kì í ṣe àlùfáà máa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run nígbà tí wọ́n bá dúró sí àgbàlá tí ó wà ní ìta tẹ́ḿpìlì náà. (Lúùkù 1:8-10) Bíbélì ṣàlàyé pé: “Tùràrí náà . . . túmọ̀ sí àdúrà àwọn ẹni mímọ́.” (Ìṣípayá 5:8) Onísáàmù náà, Dáfídì, kọ̀wé pé: “Jẹ́ kí àdúrà mi kí ó wá sí iwájú rẹ bí ẹbọ tùràrí.” (Sáàmù 141:2) Àwọn Kristẹni ẹni-àmì-òróró tún ń ṣìkẹ́ àǹfààní tí wọ́n ní láti tọ Jèhófà lọ nínú àdúrà nípasẹ̀ Jésù Kristi. Àdúrà àtọkànwá tí ń jáde láti inú ọkàn-àyà dà bíi tùràrí olóòórùn dídùn. Àwọn Kristẹni ẹni-àmì-òróró tún ń yin Ọlọ́run ní àwọn ọ̀nà míràn, nípa lílo ètè wọn láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn lẹ́kọ̀ọ́. Ní pàtàkì, ìfaradà wọn lójú ìṣòro àti ìwà títọ́ wọn lábẹ́ àdánwò ń mú inú Ọlọ́run dùn.—Pétérù Kìíní 2:20, 21.
17. Kí ni ó wé mọ́ ìmúṣẹ àpẹẹrẹ alásọtẹ́lẹ̀, tí a pèsè nípasẹ̀ wíwọ̀ tí àlùfáà àgbà kọ́kọ́ wọnú Ibi Mímọ́ Jù Lọ ní Ọjọ́ Ètùtù?
17 Ní Ọjọ́ Ètùtù, àlùfáà àgbà Ísírẹ́lì ní láti wọ Ibi Mímọ́ Jù Lọ, kí ó sì sun tùràrí lórí àwo oníwúrà tí a fi ń sun tùràrí, tí ó kún fún ẹ̀yin iná. Ó ní láti ṣe èyí kí ó tó mú ẹ̀jẹ̀ ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wá. Ní ìmúṣẹ àpẹẹrẹ alásọtẹ́lẹ̀ yìí, ọkùnrin náà, Jésù, pa ìwà títọ́ pátápátá mọ́ sí Jèhófà Ọlọ́run kí ó tó fi ìwàláàyè rẹ̀ rúbọ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ kan títí láé fún ẹ̀ṣẹ̀ wa. Nípa báyìí, ó fi hàn pé ènìyàn pípé lè pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́ sí Ọlọ́run láìka pákáǹleke tí Sátánì bá mú bá a sí. (Òwe 27:11) Nígbà tí a dán an wò, Jésù lo àdúrà “pẹ̀lú igbe ẹkún kíkankíkan àti omijé, a sì gbọ́ ọ pẹ̀lú ojú rere nítorí ìbẹ̀rù rẹ̀ fún Ọlọ́run.” (Hébérù 5:7) Ní ọ̀nà yìí, ó fi ògo fun Jèhófà gẹ́gẹ́ bí olódodo àti ẹni tí ó lẹ́tọ̀ọ́ sí Ipò Ọba Aláṣẹ àgbáyé. Ọlọ́run san èrè fún Jésù nípa jíjí i dìde kúrò nínú ikú sí ìyè àìlèkú ní òkè ọ̀run. Ní ipò gíga yìí, Jésù pe àfiyèsí sí ìdí kejì tí òun fi wá sí ilẹ̀ ayé, èyíinì ni láti mú ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n ronú pìwà dà, padà bá Ọlọ́run rẹ́.—Hébérù 4:14-16.
Ògo Títóbi Lọ́lá ti Tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run Nípa Tẹ̀mí
18. Báwo ni Jèhófà ṣe mú ògo títayọ wá sínú tẹ́ḿpìlì rẹ̀ nípa tẹ̀mí?
18 Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ògo ilé ìkẹyìn yìí yóò pọ̀ ju ti ìṣáájú lọ.” (Hágáì 2:9) Nípa jíjí Jésù dìde gẹ́gẹ́ bí Ọba àti Àlùfáà Àgbà tí kò lè kú mọ́, Jèhófà mú ògo títayọ lọ́lá wá sínú tẹ́ḿpìlì rẹ̀ nípa tẹ̀mí. Nísinsìnyí, Jésù ti wà ní ipò láti mú “ìgbàlà àìnípẹ̀kun wá fún gbogbo àwọn wọnnì tí ń ṣègbọràn sí i.” (Hébérù 5:9) Àwọn tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe irú ìgbọràn bẹ́ẹ̀ ni 120 ọmọ ẹ̀yìn tí wọ́n gba ẹ̀mí mímọ́ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Ìwé Ìṣípayá sọ tẹ́lẹ̀ pé, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa tẹ̀mí wọ̀nyí yóò jẹ́ 144,000 nígbẹ̀yìn gbẹ́yín. (Ìṣípayá 7:4) Lẹ́yìn tí wọ́n bá kú, ọ̀pọ̀ nínú wọn ní láti wà láìmọ ohunkóhun nínú sàréè gbogbo aráyé, ní dídúró de àkókò wíwà níhìn-ín Jésù nínú agbára ọba. Àsọtẹ́lẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ nínú Dáníẹ́lì 4:10-17, 20-27 tọ́ka sí ọdún 1914 pé ó jẹ́ àkókò fún Jésù láti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso láàárín àwọn ọ̀tá rẹ̀. (Sáàmù 110:2) Fún àwọn ẹ̀wádún tí ó ṣáájú, àwọn Kristẹni ẹni-àmì-òróró ń fi tọkàntọkàn dúró de ọdún yẹn. Ogun Àgbáyé Kìíní àti àwọn ègbé tí ó bá a rìn, tí ó dé sórí aráyé jẹ́rìí sí i pé, ní tòótọ́ ni Jésù gun orí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba ní 1914. (Mátíù 24:3, 7, 8) Kété lẹ́yìn náà, nígbà tí àkókò náà tó fún “ìdájọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ní ilé Ọlọ́run,” Jésù yóò mú ìlérí rẹ̀ fún àwọn ẹni-àmì-òróró ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tí wọ́n ti sùn nínú ikú ṣẹ pé: “Èmí tún ń bọ̀ wá èmi yóò sì gbà yín sí ilé sọ́dọ̀ ara mi dájúdájú.”—Pétérù Kìíní 4:17; Jòhánù 14:3.
19. Báwo ni àṣẹ́kù 144,000 yóò ṣe ráyè wọnú Ibi Mímọ́ Jù Lọ ní òkè ọ̀run?
19 A kò tí ì fi èdìdì dí gbogbo 144,000 mẹ́ḿbà ẹgbẹ́ àlùfáà mímọ́ náà pátápátá, a kò sì tí ì kó gbogbo wọn jọ sí ilé wọn ní òkè ọ̀run. Àṣẹ́kù wọn ṣì wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé nínú ipò tẹ̀mí tí Ibi Mímọ́ náà ń ṣàpẹẹrẹ, tí ẹran ara wọn, “aṣọ ìkélé” náà, tàbí ohun ìdènà, pín níyà sí ibi mímọ́ tí Ọlọ́run wà. Bí àwọn wọ̀nyí ṣe ń kú sínú ìṣòtítọ́, lọ́gán ni a ń jí wọn dìde gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí tí kò lè kú mọ́, láti dara pọ̀ mọ́ àwọn tí wọ́n jẹ́ ara 144,000 tí wọ́n ti wà ní ọ̀run.—Kọ́ríńtì Kìíní 15:51-53.
20. Iṣẹ́ pàtàkì wo ni àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú ẹgbẹ́ àlùfáà mímọ́ náà ń ṣe lónìí, pẹ̀lú ìyọrísí wo sì ni?
20 Pẹ̀lú àwọn àlùfáà tí ó pọ̀ tó yìí, tí ń ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú Àlùfáà Àgbà títóbi lọ́lá náà ní ọ̀run, tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run nípa tẹ̀mí ti gba àlékún ògo. Ní báyìí ná, àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú ẹgbẹ́ àlùfáà mímọ́ náà ń ṣe iṣẹ́ tí ó níye lórí ní ilẹ̀ ayé. Nípa ìwàásù wọn, Ọlọ́run ń fi àwọn ọ̀rọ̀ ìdájọ́ rẹ̀ “mi gbogbo orílẹ̀-èdè jìgìjìgì,” gẹ́gẹ́ bí a ti sọ tẹ́lẹ̀ nínú Hágáì 2:7 (NW). Lọ́wọ́ kan náà, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ olùjọsìn tí a ṣàpèjúwe bí “ohun fífani lọ́kàn mọ́ra ti gbogbo orílẹ̀-èdè” ń rọ́ wá sí àgbàlá orí ilẹ̀ ayé ti tẹ́ḿpìlì Jèhófà. Báwo ni àwọn wọ̀nyí ṣe wọnú ìṣètò Ọlọ́run fún ìjọsìn, kí sì ni ògo ọjọ́ ọ̀la tí a lè retí fún tẹ́ḿpìlì ńlá rẹ̀ nípa tẹ̀mí? Ìbéèrè wọ̀nyí ni a óò gbé yẹ̀ wò nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e.
Àwọn Ìbéèrè fún Àtúnyẹ̀wò
◻ Àpẹẹrẹ títayọ wo ni Jésù fi lélẹ̀ ní ọdún 29 Sànmánì Tiwa?
◻ Ìṣètò wo ni ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ọdún 29 Sànmánì Tiwa?
◻ Kí ni Ibi Mímọ́ àti Ibi Mímọ́ Jù Lọ ṣàpẹẹrẹ?
◻ Báwo ni a ṣe ṣe tẹ́ḿpìlì ńlá náà nípa tẹ̀mí lógo?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Nígbà tí a fi ẹ̀mí mímọ́ yan Jésù ní ọdún 29 Sànmánì Tiwa, tẹ́ḿpìlì ńlá Ọlọ́run nípa tẹ̀mí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́