“Ọkàn Àyà Rẹ Ha Dúró Ṣánṣán Pẹ̀lú Mi Bí?”
“Bá mi ká lọ, kí o sì wo bí èmi kò ṣe fàyè gba bíbá Jèhófà díje.”—ÀWỌN ỌBA KEJÌ 10:16, NW.
1, 2. (a) Báwo ni ipò ìsìn Ísírẹ́lì ṣe bà jẹ́ bàlùmọ̀? (b) Ní ọdún 905 ṣááju Sànmánì Tiwa, àwọn ìyípadà amúnitagìrì wo ni ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣẹlẹ̀ ní Ísírẹ́lì?
ỌDÚN 905 ṣááju Sànmánì Tiwa jẹ́ àkókò ìyípadà ńláǹlà ní Ísírẹ́lì. Ní nǹkan bí 100 ọdún ṣáájú, Jèhófà mú kí a pín ìjọba àpapọ̀ Ísírẹ́lì nítorí ìpẹ̀yìndà Sólómọ́nì. (Àwọn Ọba Kìíní 11:9-13) Rèhóbóámù, ọmọkùnrin Sólómọ́nì, ni ó ń ṣàkóso Júdà, ìjọba gúúsù nígbà náà, nígbà tí Ọba Jèróbóámù, tí í ṣe ọmọ Éfúráímù, sì ń ṣàkóso Ísírẹ́lì, ìjọba àríwá. Ó bani nínú jẹ́ pé, ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba àríwá kún fún ìjábá. Jèróbóámù kò fẹ́ kí àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ lọ sí ìjọba gúúsù láti jọ́sìn ní tẹ́ńpìlì, ní bíbẹ̀rù pé wọn yóò máa ronú nípa pípadà sọ́dọ̀ agbo ilé Dáfídì. Nítorí náà, ó gbé ìjọsìn ọmọ màlúù kalẹ̀ ní Ísírẹ́lì, ó sì tipa báyìí gbé ọ̀nà ìbọ̀rìṣà kan kalẹ̀, ọ̀kan tí ó wà pẹ́ dé àyè kan jálẹ̀ ìtàn ìjọba àríwá.—Àwọn Ọba Kìíní 12:26-33.
2 Ipò nǹkan burú sí i nígbà tí Áhábù, ọmọkùnrin Ómírì, di ọba. Jésíbẹ́lì, àjèjì aya rẹ̀, gbé ìjọsìn Báálì lárugẹ, ó sì pa àwọn wòlíì Jèhófà. Láìka àwọn ìkìlọ̀ tí ń sọjú abẹ níkòó tí wòlíì Èlíjà ṣe sí, Áhábù kò ṣe ohunkóhun láti dá a lẹ́kun. Ṣùgbọ́n, ní ọdún 905 ṣááju Sànmánì Tiwa, Áhábù kú, Jèhórámù, ọmọkùnrin rẹ̀, sì ń ṣàkóso. Àkókò ti tó wàyí láti fọ ilẹ̀ náà mọ́. Èlíṣà, arọ́pò Èlíjà, fi tó Jéhù, ọ̀gágun, létí pé Jèhófà ń fi òróró yàn án gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ọba kàn ní Ísírẹ́lì. Iṣẹ́ wo ni yóò ṣe? Yóò pa ilé ẹlẹ́ṣẹ̀ ti Áhábù run, yóò sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì tí Jésíbẹ́lì ti ta sílẹ̀!—Àwọn Ọba Kejì 9:1-10.
3, 4. Báwo ni Jèhónádábù ṣe fi hàn pé ọkàn àyà òun ‘dúró ṣánṣán pẹ̀lú ọkàn àyà Jéhù’?
3 Ní ṣíṣègbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run, Jéhù mú kí a pa Jésíbẹ́lì olubi, lẹ́yìn náà, ó bẹ̀rẹ̀ fífọ Ísírẹ́lì mọ́ nípa pípa ilé Áhábù run. (Àwọn Ọba Kejì 9:15–10:14, 17) Nígbà náà ni ó pàdé olùrànlọ́wọ́ kan. “Ó ṣalábàápàdé Jèhónádábù ọmọkùnrin Rékábù tí ń bọ̀ wá pàdé rẹ̀. Nígbà tí ó súre fún un, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ó sọ fún un pé: ‘Ọkàn àyà rẹ ha dúró ṣánṣán pẹ̀lú mi bí, gan-an gẹ́gẹ́ bí ọkàn àyà tèmi ṣe jẹ́ pẹ̀lú ọkàn àyà rẹ?’ Jèhónádábù fèsì pé: ‘Bẹ́ẹ̀ ni.’ ‘Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, fún mi ní ọwọ́ rẹ.’ Nítorí náà, ó fún un ní ọwọ́ rẹ̀. Látàrí ìyẹn, ó mú kí ó gòkè wá sínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin pẹ̀lú rẹ̀. Nígbà náà ni ó sọ pé: ‘Bá mi ká lọ, kí o sì wo bí èmi kò ṣe fàyè gba bíbá Jèhófà díje.’ Wọ́n sì mú kí ó bá a gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun rẹ̀ lọ.”—Àwọn Ọba Kejì 10:15, 16, NW.
4 Jèhónádábù (tàbí, Jónádábù) kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì. Síbẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú orúkọ rẹ̀ (tí ó túmọ̀ sí “Jèhófà Ń Múra Tán,” “Jèhófà Ga Lọ́lá,” tàbí “Jèhófà Jẹ́ Ọ̀làwọ́”), ó jẹ́ olùjọsìn Jèhófà. (Jeremáyà 35:6) Dájúdájú, ó ní ọkàn ìfẹ́ tí ó ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú rírí bí Jéhù “kò ṣe fàyè gba bíbá Jèhófà díje.” Báwo ni a ṣe mọ̀? Tóò, kò ṣàdédé ṣalábàápàdé ọba Ísírẹ́lì tí a ti fòróró yàn. Jèhónádábù “ń bọ̀ wá pàdé rẹ̀,” èyí sì jẹ́ ní àkókò kan tí Jéhù ti pa Jésíbẹ́lì àti àwọn mìíràn nínú ilé Áhábù. Jèhónádábù mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí ó gba ìkésíni Jéhù láti gòkè sínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin pẹ̀lú rẹ̀. Kò sí àní-àní pé ìhà ọ̀dọ̀ Jéhù—àti Jèhófà—ni ó wà, nínú ìforígbárí yìí láàárín ìjọsìn èké àti ìjọsìn tòótọ́.
Jéhù Òde Òní àti Jèhónádábù Òde Òní
5. (a) Àwọn ìyípadà wo ni yóò ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ fún gbogbo aráyé? (b) Ta ni Jéhù Títóbijù, àwọn wo ni ó sì ń ṣojú fún un lórí ilẹ̀ ayé?
5 Lónìí, nǹkan yóò yí pa dà pátápátá láìpẹ́ fún gbogbo aráyé bí ó ṣe yí pa dà pátápátá fún Ísírẹ́lì lọ́jọ́sí ní ọdún 905 ṣááju Sànmánì Tiwa. Àkókò náà ti sún mọ́lé nísinsìnyí nígbà tí Jèhófà yóò fọ gbogbo àbájáde búburú ti ìdarí Sátánì, títí kan èyí tí ìsìn èké ní lórí ilẹ̀ ayé kúrò. Ta ni Jéhù òde òní? Kì í ṣe ẹlòmíràn bí kò ṣe Jésù Kristi, ẹni tí a sọ ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ náà nípa rẹ̀ pé: “Sán idà rẹ mọ́ ìdí rẹ, Alágbára jù lọ, àní ògo rẹ àti ọlá ńlá rẹ. Àti nínú ọlá ńlá rẹ máa gẹṣin lọ ní àlàáfíà, nítorí òtítọ́ àti ìwà tútù àti òdodo.” (Orin Dáfídì 45:3, 4) “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró “tí ń pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́ tí wọ́n sì ní iṣẹ́ jíjẹ́rìí Jésù,” ni ó ń ṣojú fún Jésù lórí ilẹ̀ ayé. (Gálátíà 6:16; Ìṣípayá 12:17) Láti ọdún 1922 àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Jésù wọ̀nyí ti ń kìlọ̀ nípa àwọn ìṣe ìdájọ́ Jèhófà tí ń bọ̀, láìṣojo.—Aísáyà 61:1, 2; Ìṣípayá 8:7–9:21; 16:2-21.
6. Àwọn wo ni ó ti inú àwọn orílẹ̀-èdè jáde láti kọ́wọ́ ti àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lẹ́yìn, báwo sì ni wọ́n ṣe wọnú kẹ̀kẹ́ Jéhù Títóbijù náà, kí a sọ ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀?
6 Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró kò dá ṣiṣẹ́ náà. Gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhónádábù ti jáde wá pàdé Jéhù, ọ̀pọ̀ láti inú àwọn orílẹ̀-èdè ti jáde wá láti ran Jésù, Jéhù Títóbijù náà, àti àwọn aṣojú rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, lọ́wọ́ nínú ìdúró wọn fún ìjọsìn tòótọ́. (Sekaráyà 8:23) Jésù pè wọ́n ní “àwọn àgùntàn míràn,” ní ọdún 1932, a mọ̀ wọ́n sí alábàádọ́gba Jèhónádábù ìgbàanì lóde òní, a sì ké sí wọn láti “gòkè wá sínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin” Jéhù òde òní. (Jòhánù 10:16) Lọ́nà wo? Nípa ‘pípa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́’ àti nípa bíbá àwọn ẹni àmì òróró lọ́wọ́ sí “iṣẹ́ jíjẹ́rìí Jésù.” Lóde òní, èyí ní wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tí a ti gbé kalẹ̀ lábẹ́ Jésù gẹ́gẹ́ bí Ọba nínú. (Máàkù 13:10) Ní ọdún 1935, a fi “àwọn Jónádábù” wọ̀nyí hàn gẹ́gẹ́ bí “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti Ìṣípayá 7:9-17.
7. Báwo ni àwọn Kristẹni lónìí ṣe fi hàn pé ‘ọkàn àyà wọn ṣì dúró ṣánṣán’ pẹ̀lú ọkàn àyà Jésù?
7 Láti àwọn ọdún 1930, ogunlọ́gọ̀ ńlá náà àti àwọn arákùnrin ẹni àmì òróró ti fìgboyà fi ìtìlẹyìn wọn hàn fún ìjọsìn tòótọ́. Ní àwọn ilẹ̀ kan ní Ìlà Oòrùn àti Ìwọ̀ Oòrùn Yúróòpù, Ìlà Oòrùn Jíjìnnà Réré, àti Áfíríkà, ọ̀pọ̀ nínú wọn ti kú nítorí ìgbàgbọ́ wọn. (Lúùkù 9:23, 24) Ní àwọn ilẹ̀ míràn, wọ́n fi wọ́n sẹ́wọ̀n, wọ́n kọ lù wọ́n, tàbí kí wọ́n ṣenúnibíni sí wọn lọ́nà míràn. (Tímótì Kejì 3:12) Ẹ wo irú àkọsílẹ̀ ìgbàgbọ́ tí wọ́n ti ní! Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn Ọdún 1997 sì fi hàn pé wọ́n ṣì pinnu láti sin Ọlọ́run, láìka ohunkóhun tí ó lè ṣẹlẹ̀ sí. ‘Ọkàn àyà wọn ṣì dúró ṣánṣán’ pẹ̀lú ọkàn àyà Jésù. A fi èyí hàn ní ọdún 1997, nígbà tí 5,599,931 akéde Ìjọba, tí gbogbo wọn fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ “àwọn Jónádábù,” lo àpapọ̀ 1,179,735,841 wákàtí nínú iṣẹ́ jíjẹ́rìí Jésù.
Wọ́n Ṣì Ń Fi Ìtara Wàásù
8. Báwo ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń fi ìtara wọn hàn fún ìjọsìn tòótọ́?
8 A mọ Jéhù fún fífi kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ sáré àsápajúdé—ẹ̀rí ìtara rẹ̀ láti ṣàṣeparí iṣẹ́ rẹ̀. (Àwọn Ọba Kejì 9:20) A ṣàpèjúwe Jésù, Jéhù Títóbijù náà, gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ìtara ‘ti jẹ tán.’ (Orin Dáfídì 69:9) Nítorí náà, kò yani lẹ́nu pé, a mọ àwọn Kristẹni tòótọ́ fún ìtara wọn lónìí. Nínú ìjọ àti ní gbangba, wọ́n ń “wàásù ọ̀rọ̀ náà, . . . ní kánjúkánjú ní àsìkò tí ó rọgbọ, ní àsìkò tí ó kún fún ìdààmú.” (Tímótì Kejì 4:2) Ní pàtàkì, ìtara wọn fara hàn ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1997 lẹ́yìn tí àpilẹ̀kọ kan nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa rọ ọ̀pọ̀ tí ó bá ṣeé ṣe tó láti nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Ní orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan, a gbé góńgó iye aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tí a ń retí kalẹ̀. Kí ni ìdáhùnpadà náà? Ó kàmàmà! Ọ̀pọ̀ ẹ̀ka rékọjá iye góńgó náà. Ecuador gbé góńgó 4,000 kalẹ̀ ṣùgbọ́n ní March ó ròyìn 6,936 aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Japan ròyìn àpapọ̀ 104,215 ní àwọn oṣù mẹ́ta wọ̀nyẹn. Ní Zambia, níbi tí wọ́n ti fi 6,000 ṣe góńgó wọn, 6,414 aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ròyìn ní March; 6,532 ní April; àti 7,695 ní May. Kárí ayé, góńgó aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ àti aṣáájú ọ̀nà déédéé lápapọ̀ jẹ́ 1,110,251, tí ó fi ìbísí 34.2 nínú ọgọ́rùn-ún ju ti 1996 lọ!
9. Ní àfikún sí iṣẹ́ ilé dé ilé, àwọn ọ̀nà míràn wo ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń wá àwọn ènìyàn rí láti sọ ìhìn rere náà fún wọn?
9 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn alàgbà láti Éfésù pé: “Èmi kò . . . fà sẹ́yìn kúrò nínú sísọ èyíkéyìí lára àwọn ohun tí ó lérè nínú fún yín tàbí kúrò nínú kíkọ́ yín ní gbangba àti láti ilé dé ilé.” (Ìṣe 20:20) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí ń fara wé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù, wọ́n sì ń fi ìtara wàásù ìhìn rere náà láti ilé dé ilé. Ṣùgbọ́n, ó lè máà rọrùn láti rí àwọn ènìyàn nínú ilé wọn. Nítorí náà, “olùṣòtítọ́ àti ọlọgbọ́n inú ẹrú” ń rọ àwọn akéde Ìjọba láti tọ àwọn ènìyàn lọ ni ibi iṣẹ́ ajé wọn, ní òpópónà, ní etíkun, ní ibi ìgbafẹ́ gbogbogbòò—ibikíbi tí wọ́n bá ti lè rí ènìyàn. (Mátíù 24:45-47) Ìyọrísí rẹ̀ ti dára púpọ̀.
10, 11. Báwo ni àwọn akéde ní àwọn orílẹ̀-èdè méjì ṣe fi ìdánúṣe àtàtà hàn ní ṣíṣàwárí àwọn olùfìfẹ́hàn tí ó lè ṣòro láti bá nílé?
10 Ní Copenhagen, Denmark, àwùjọ kéréje àwọn akéde ti ń jẹ́rìí ní òpópónà lẹ́yìn òde àwọn ibùdókọ̀ ojú irin. Láti January dé June, wọ́n fi 4,733 ìwé ìròyìn sóde, wọ́n rí ọ̀pọ̀ ènìyàn bá sọ̀rọ̀, wọ́n sì ṣe ọ̀pọ̀ ìpadàbẹ̀wò. Ọ̀pọ̀ akéde ní ilẹ̀ náà ti dá ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn sílẹ̀ ní àwọn ilé ìtajà. Ìlú kan ní ọjà ńlá tí a máa ń ná ní ọjọọjọ́ Friday, tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn sì ń ṣèbẹ̀wò síbẹ̀. Nítorí náà, ìjọ ṣètò fun jíjẹ́rìí déédéé nínú ọjà. Ní àgbègbè kan, a máa ń ṣèbẹ̀wò sí àwọn ilé ẹ̀kọ́ pẹ̀lú ìsọfúnni tí ó ní àwọn ìtẹ̀jáde tí ó bá àwọn olùkọ́ ilé ìwé mu ní pàtàkì.
11 Ni Hawaii pẹ̀lú, a ti sapá láti tọ àwọn tí a kò lè bá nílé lọ. Àwọn ibi tí gbogbogbòò ń lò sí (àwọn òpópónà, ọgbà ìtura, ibi ìgbọ́kọ̀sí, àti ibùdókọ̀), àgbègbè ìṣòwò ìlú, ilé ìtajà àti pápákọ̀ òfuurufú, ìjẹ́rìí orí tẹlifóònù, ètò ìrìnnà gbogbogbòò (wíwàásù nínú bọ́ọ̀sì), àti àwọn ọgbà ilé ẹ̀kọ́ gíga wà lára àwọn ìpínlẹ̀ àrà ọ̀tọ̀. A máa ń ṣọ́ra láti rí i dájú pé a yan iye Ẹlẹ́rìí tí ó tó sí ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan, a sì tún ń rí i dájú pé àwọn tí a yàn síbẹ̀ jẹ́ àwọn tí a dá lẹ́kọ̀ọ́ dáradára. A ròyìn ọ̀pọ̀ ìsapá báwọ̀nyí tí a ṣètò dáradára ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, a kàn sí àwọn olùfìfẹ́hàn tí ó ṣeé ṣe kí a máà rí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé.
Dídúró Ṣinṣin
12, 13. (a) Ọgbọ́n wo ni Sátánì ta fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ọdún 1997? (b) Ní ọ̀nà wo ni ìgbékèéyíde kò fi yọrí sí ohun tí wọ́n ń retí ní orílẹ̀-èdè kan?
12 Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ ní ọdún 1997, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nírìírí ìgbékèéyíde rírorò, tí a gbé lárugẹ nítorí ète ṣíṣe kedere ti gbígbé ìgbésẹ̀ òfin tí ó bá ṣeé ṣe lòdì sí wọn. Ṣùgbọ́n mìmì kan kò mì wọ́n! (Orin Dáfídì 112:7, 8) Wọ́n rántí àdúrà onísáàmù náà pé: “Àwọn agbéraga ti hùmọ̀ èké sí mi: ṣùgbọ́n èmi óò pa ẹ̀kọ́ rẹ mọ́ tinútinú mi gbogbo.” (Orin Dáfídì 119:69) Irú ìparọ́mọ́ni ní gbangba bẹ́ẹ̀ wulẹ̀ jẹ́ ẹ̀rí pé a kórìíra àwọn Kristẹni tòótọ́, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀. (Mátíù 24:9) Lọ́pọ̀ ìgbà sì rèé, ibi tí wọ́n fojú sí ọ̀nà kì í gbabẹ̀ rárá. Ọkùnrin kan ní Belgium ka àpilẹ̀kọ kan tí a fi ba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ nínú ìwé agbéròyìnjáde kan tí a mọ̀ bí ẹní mowó. Nítorí tí àwọn ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ tí a sọ náà ṣe é ní kàyéfì, ó lọ sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba kan ní Sunday tí ó tẹ̀ lé e. Ó ṣètò láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí, ó sì ń bá a nìṣó láti tẹ̀ síwájú lọ́nà yíyára kánkán. Tẹ́lẹ̀ rí, ọkùnrin yìí jẹ́ mẹ́ńbà ẹgbẹ́ jàǹdùkú kan. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀ ràn án lọ́wọ́ láti fọ ìgbésí ayé rẹ̀ mọ́, ohun kan tí àwọn tí ó wà láyìíká rẹ̀ kíyè sí. Dájúdájú, ẹni tí ó kọ àpilẹ̀kọ bíbanijẹ́ yìí kò mọ̀ pé báyìí ni ọ̀ràn náà yóò rí!
13 Àwọn kan tí wọ́n jẹ́ aláìlábòsí ọkàn ní Belgium ti sọ̀rọ̀ jáde nípa ìgbékèéyíde ẹlẹ́tàn náà. Olórí ìjọba kan tí ó sọ pé òun kan sáárá sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún ohun tí wọ́n ti ṣàṣeparí wà lára wọn. Ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin kan kọ̀wé pé: “Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ tí a ń sọ kiri nígbà míràn, lójú tèmí, [Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà] kò jọ ẹni tí ń wu Ìjọba léwu rárá. Àwọn aráàlú tí ó jẹ́ onífẹ̀ẹ́ àlàáfíà, tí ẹ̀rí ọkàn ń darí wọn, tí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún àwọn aláṣẹ ni wọ́n.” Ní tòótọ́, ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pétérù náà bọ́gbọ́n mu pé: “Ẹ tọ́jú ìwà yín kí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, pé, nínú ohun náà tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ lòdì sí yín gẹ́gẹ́ bí aṣebi, kí wọ́n lè tipa àwọn iṣẹ́ yín àtàtà èyí tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́rìí olùfojúrí rẹ̀ yin Ọlọ́run lógo ní ọjọ́ náà fún àbẹ̀wò rẹ̀.”—Pétérù Kíní 2:12.
Ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí Títayọlọ́lá
14. Àwọn ìròyìn amúnilóríyá wo ni a gbọ́ nípa iye àwọn tí ó wá sí Ìṣe Ìrántí ní ọdún 1997?
14 Ó yẹ kí àwọn tí ń jẹ́rìí Jésù wo Ìṣe Ìrántí ikú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì nínú ọdún wọn. Ní ọdún 1997, 14,322,226 ni ó pésẹ̀ ní March 23 láti ṣayẹyẹ ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ìyẹn fi iye tí ó lé ní 1,400,000 ju ti 1996 lọ. (Lúùkù 22:14-20) Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, àwọn tí ó wá sí Ìṣe Ìrántí ju iye àwọn akéde Ìjọba lọ fíìfíì, ó jẹ́ ìfojúsọ́nà tí ó ṣeé gbára lé fún ìbísí lọ́jọ́ ọ̀la. Fún àpẹẹrẹ, ní Haiti, ọdún 1997 rí góńgó 10,621 akéde, nígbà tí 67,259 wá sí Ìṣe Ìrántí. O lè yẹ ìròyìn ọdọọdún wò lójú ewé 18 sí 21, kí o sì ri bí àwọn orílẹ̀-èdè míràn tí wọ́n ní irú ìlọsókè bẹ́ẹ̀ nínú iye àwọn tí ó wà ti pọ̀ tó ní ìfiwéra pẹ̀lú iye àwọn akéde wọn.
15. Ní àwọn ilẹ̀ kan, báwo ni àwọn arákùnrin wa ṣe borí àwọn ìṣòro lílekoko láti lè ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí?
15 Fún àwọn kan, kò rọrùn láti wá sí Ìṣe Ìrántí. Ní Albania, kónílé-ó-gbélé wà lóde láti agogo 7 ìrọ̀lẹ́, nítorí rìgbòrìyẹ̀ aráàlú. Nínú 115 àwùjọ kéékèèké tí ó wà káàkiri orílẹ̀-èdè náà, Ìṣe Ìrántí náà bẹ̀rẹ̀ ní agogo 5:45 ìrọ̀lẹ́. Oòrùn wọ̀ ní agogo 6:08 ìrọ̀lẹ́, tí ó sàmì sí ìbẹ̀rẹ̀ Nísánì 14. A gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ káàkiri ní nǹkan bí agogo 6:15 ìrọ̀lẹ́. Níbi púpọ̀ jù lọ, a gbàdúrà ìparí ní agogo 6:30 ìrọ̀lẹ́, àwọn tí wọ́n wá sì tètè pa dà sílé kí kónílé-ó-gbélé tó bẹ̀rẹ̀. Síbẹ̀, iye àwọn tí ó wá sí Ìṣe Ìrántí náà jẹ́ 3,154, tí a bá fi wé góńgó 1,090 akéde. Ní orílẹ̀-èdè Áfíríkà kan, rìgbòrìyẹ̀ aráàlú mú kí a máà rọ́nà wọ inú Gbọ̀ngàn Ìjọba, nítorí náà àwọn alàgbà méjì pinnu láti pàdé nínú ilé alàgbà kẹta láti ṣètò ṣíṣe ayẹyẹ náà ní àwùjọ kéékèèké. Láti lè dé ilé náà, àwọn alàgbà méjì náà ní láti ré kòtò àgbàrá kan kọjá. Ṣùgbọ́n, ìjà ń lọ lọ́wọ́ ní àgbègbè náà, àwọn afarapamọ́yìnbọn sì ń yìnbọn lu ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ ré kòtò náà kọjá. Alàgbà kan kọjá láìsí jàǹbá kankan. Ẹnì kejì ń kọjá nígbà tí ó gbúròó ìbọn. Ó nà sílẹ̀ gbalaja, ó sì fàyà wọ́ kọjá bí ọta ìbọn ti ń sófòóòrò kọjá lórí rẹ̀. Ìpàdé àwọn alàgbà náà kẹ́sẹ járí, wọ́n sì bójú tó àìní ìjọ.
“Láti Inú Gbogbo Àwọn Orílẹ̀-Èdè àti Ẹ̀yà . . . àti Ahọ́n”
16. Báwo ni ẹgbẹ́ olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n inú ẹrú náà ṣe ṣètò fún títan ìhìn rere náà kálẹ̀ láàárín àwùjọ èdè kéékèèké?
16 Àpọ́sítélì Jòhánù wí pé ogunlọ́gọ̀ ńlá náà yóò jáde wá “láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n.” (Ìṣípayá 7:9) Nítorí náà, Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ṣètò fún mímú kí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní èdè púpọ̀ sí i—títí kan èyí tí àwọn ẹ̀yà tí ó wà níbi jíjìnnà réré àti àwọn àwùjọ kéékèèké ń sọ. Fún àpẹẹrẹ, ní Mòsáńbíìkì, a mú ìwé àṣàrò kúkúrú Igbesi-aye ninu Aye Titun alalaafia kan jáde ní èdè márùn-ún mìíràn. Ní Nicaragua, a mú ìwé pẹlẹbẹ Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae! jáde ní èdè Miskito—ìtẹ̀jáde àkọ́kọ́ ti Watch Tower Society ní èdè yẹn. Ọ̀pọ̀ àwọn Íńdíà tí ń sọ èdè Miskito fi tayọ̀tayọ̀ gba ìwé pẹlẹbẹ náà ní rírí ohun kan ní èdè wọn. Ní ọdún 1997, Society fọwọ́ sí títú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ jáde ní èdè 25 mìíràn, wọn sì tẹ ìwé ìròyìn tí ó lé ní bílíọ̀nù kan.
17. Àwùjọ tí ń sọ èdè wo ni a ràn lọ́wọ́ ní Korea, báwo sì ni fídíò ti ṣèrànwọ́ fún àwùjọ yìí?
17 Ní Korea, a ran àwùjọ tí ń sọ èdè míràn lọ́wọ́. Ní ọdún 1997, a ṣe àpéjọpọ̀ ní èdè àwọn adití lọ́nà ti Korea fún ìgbà àkọ́kọ́. Ìjọ 15 ni ó wà ní Korea tí ó ń sọ èdè àwọn adití, ó sì ní 543 akéde, ṣùgbọ́n 1,174 ni ó wá sí àpéjọpọ̀ náà, 21 sì ṣe batisí. Láti ran àwọn adití tí kò lè tètè lóye ọ̀rọ̀ tí a sọ tàbí tí a kọ sílẹ̀ lọ́wọ́, a ti ń ṣe àwọn ìtẹ̀jáde sínú fídíò ní èdè adití 13 ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Nípa báyìí, a ti ran àwọn adití lọ́wọ́ láti “ka” ìhìn rere náà àní láti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ pàápàá, ó sì ti yọrí sí rere. Ní United States, tẹ́lẹ̀ rí ó lè gbà tó ọdún márùn-ún kí adití kan tó lè tẹ̀ síwájú dórí ṣíṣe batisí. Nísinsìnyí, pẹ̀lú iye kásẹ́ẹ̀tì fídíò tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà, fún àwọn adití kan, ìyẹn ti dín kù sí nǹkan bí ọdún kan.
‘Dídúró Sínú Kẹ̀kẹ́ Ẹṣin Náà’
18. Lẹ́yìn pípàdé Jèhónádábù, kí ni Jéhù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe?
18 Nígbà yẹn lọ́hùn-ún ní ọdún 905 ṣááju Sànmánì Tiwa, lẹ́yìn tí Jèhónádábù ti dara pọ̀ mọ́ ọn, Jéhù bẹ̀rẹ̀ pípa ìjọsìn èké run. Ó ké sí gbogbo àwọn olùjọsìn Báálì pátá pé: “Ẹ ya àpéjọ sí mímọ́ fún Báálì.” Lẹ́yìn náà, ó ránṣẹ́ jákèjádò ilẹ̀ náà láti rí i dájú pé a kò yọ olùjọsìn Báálì kankan sílẹ̀. Bí ogunlọ́gọ̀ náà ti ń rọ́ wọ inú tẹ́ńpìlì ńlá ti ọlọ́run èké náà, ó rí i dájú pé olùjọsìn Jèhófà kankan kò sí níbẹ̀. Níkẹyìn, Jéhù àti ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ ké àwọn olùjọsìn Báálì lulẹ̀. “Báyìí ni Jéhù pa Báálì run kúrò ní Ísírẹ́lì.”—Àwọn Ọba Kejì 10:20-28.
19. Lójú ìwòye ohun tí ń bẹ níwájú fún aráyé, irú ẹ̀mí wo ni ó yẹ kí a fi hàn, iṣẹ́ wo sì ni ó yẹ kí a fi aápọn ṣe?
19 Lónìí, ìdájọ́ ìkẹyìn lórí gbogbo ìsìn èké wà gẹ́rẹ́ níwájú. Lábẹ́ ìdarí áńgẹ́lì, àwọn Kristẹni ń polongo ìhìn rere fún gbogbo aráyé, ní fífún wọn níṣìírí láti bẹ̀rù Ọlọ́run kí wọ́n sì ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú ìsìn èké. (Ìṣípayá 14:6-8; 18:2, 4) A fún àwọn ọlọ́kàn tútù níṣìírí láti jọ̀wọ́ ara wọn fún Ìjọba Ọlọ́run lábẹ́ Jésù Kristi, Ọba tí Jèhófà gbé gorí ìtẹ́. (Ìṣípayá 12:10) Ní àkókò arùmọ̀lárasókè yí, a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìtara wa dín kù bí a ti ń dúró tiiri fún ìjọsìn tòótọ́.
20. Kí ni ìwọ yóò pinnu láti ṣe ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 1998?
20 Nígbà kan, nígbà tí a fòòró ẹ̀mí Ọba Dáfídì, ó gbàdúrà pé: “Ọkàn àyà mi fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, Ọlọ́run, ọkàn àyà mi fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin. Ṣe ni èmi yóò máa kọrin, tí èmi yóò sì máa kọ orin atunilára. Èmi yóò máa gbé ọ lárugẹ láàárín àwọn ènìyàn, Jèhófà.” (Orin Dáfídì 57:7, 9, NW) Ǹjẹ́ kí àwa pẹ̀lú lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin. Ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 1997 tí ó kọjá, láìfi ọ̀pọ̀ àdánwò pè, igbe ìyìn ńlá gbé ògo Jèhófà Ọlọ́run ga. Ǹjẹ́ kí a lè gbọ́ irú igbe kan náà, àní èyí tí ó tilẹ̀ tún ròkè ju ti èṣí lọ nínú ọdún iṣẹ́ ìsìn tí a wà nínú rẹ̀ yí. Ǹjẹ́ kí èyí sì jẹ́ òtítọ́ láìka ohunkóhun tí Sátánì lè ṣe láti mú wa rẹ̀wẹ̀sì tàbí láti gbéjà kò wá sí. Nípa báyìí, a óò fi hàn pé ọkàn àyà wa dúró ṣánṣán pẹ̀lú ọkàn àyà Jéhù Títóbijù náà, Jésù Kristi, a óò sì fi gbogbo ọkàn wa dáhùn pa dà sí ọ̀rọ̀ ìyànjú tí a mí sí náà pé: “Ẹ máa yọ̀ nínú Jèhófà, kí ẹ sì kún fún ìdùnnú, ẹ̀yin olódodo; kí ẹ sì fi ìdùnnú ké jáde, gbogbo ẹ̀yin adúróṣánṣán ní ọkàn àyà.”—Orin Dáfídì 32:11, NW.
Ìwọ Ha Lè Ṣàlàyé Bí?
◻ Àwọn ìyípadà wo ni ó ṣẹlẹ̀ ní Ísírẹ́lì ní ọdún 905 ṣááju Sànmánì Tiwa?
◻ Ta ni Jéhù òde òní, báwo sì ni “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ṣe ń fi hàn pé ‘ọkàn àyà àwọn dúró ṣánṣán’ pẹ̀lú ọkàn àyà rẹ̀?
◻ Àkọsílẹ̀ oníṣirò wo láti inú ìròyìn ọdọọdún ni ó ṣàkàwé ìtara tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi hàn ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 1997?
◻ Ohun yòó wù tí Sátánì lè ṣe sí wa, irú ẹ̀mí wo ni a óò fi hàn ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 1998?
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 18-21]
ÌRÒYÌN ỌDÚN IṢẸ́ ÌSÌN 1997 TI ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JEHOFA KÁRÍ AYÉ
(Wo àdìpọ̀)
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Iye títayọlọ́lá ti àwọn tí ó wá sí Ìṣe Ìrántí fi hàn pé ìfojúsọ́nà tí ó ṣeé gbára lé ń bẹ fún ìbísí lọ́jọ́ ọ̀la
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Bí Jèhónádábù ṣe ti Jéhù lẹ́yìn, bẹ́ẹ̀ náà ni “ogunlọ́gọ̀ ńlá” lónìí ṣe ń ti Jésù Kristi, Jéhù Títóbijù náà, àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ẹni àmì òróró, lẹ́yìn