Bó o Ṣe Lè Máa Ṣe Ohun Tí Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ Ń sọ
“Ohun gbogbo ni ó mọ́ fún àwọn tí ó mọ́. Ṣùgbọ́n fún àwọn tí ó jẹ́ ẹlẹ́gbin àti aláìnígbàgbọ́, kò sí ohun tí ó mọ́.” —TÍTÙ 1:15.
1. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe dá sí ọ̀rọ̀ àwọn ìjọ tó wà ní Kírétè?
LẸ́YÌN tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti parí ìrìn àjò rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kẹta lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì, wọ́n fàṣẹ ọba mú un, wọ́n fi í ránṣẹ́ sí Róòmù, wọ́n sì tì í mọ́lé fọ́dún méjì níbẹ̀. Nígbà tí wọ́n fi sílẹ̀, kí ló wá ṣe? Kò pẹ́ sígbà yẹn lòun àti Títù lọ sí erékùṣù Kírétè, ẹ̀yìn ìgbà yẹn ló wá kọ lẹ́tà sí Títù pé: “Mo . . . fi ọ́ sílẹ̀ ní Kírétè, kí o lè ṣe àtúnṣe àwọn ohun tí ó ní àbùkù, kí o sì lè yan àwọn àgbà ọkùnrin sípò.” (Títù 1:5) Iṣẹ́ tí Pọ́ọ̀lù ní kí Títù ṣe yẹn á mú kó dá sí ọ̀rọ̀ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò ṣiṣẹ́ dáadáa.
2. Ìṣòro wo ni Títù ní láti bójú tó ní erékùṣù Kírétè?
2 Pọ́ọ̀lù sọ àwọn ohun tó yẹ ká rí lára ọkùnrin èyíkéyìí kó tó lè di alàgbà nínú ìjọ fún Títù, lẹ́yìn náà ló wá ṣàlàyé fún un pé “ọ̀pọ̀ ewèlè ènìyàn” àti “àwọn asọ̀rọ̀ tí kò lérè, àti àwọn tí ń tan èrò inú jẹ” ló wà. Àwọn èèyàn yìí ń dojú “gbogbo àwọn agbo ilé pátá dé nípa kíkọ́ni ní àwọn ohun tí kò yẹ kí wọ́n fi kọ́ni.” Pọ́ọ̀lù ní kí Títù máa fi “ìbáwí tọ́ wọn sọ́nà.” (Títù 1:10-14; 1 Tímótì 4:7) Pọ́ọ̀lù sọ pé ọkàn àti ẹ̀rí ọkàn wọn jẹ́ “ẹlẹ́gbin,” bí ìgbà tí aró bá dà sí aṣọ. (Títù 1:15) Àwọn kan lára àwọn ọkùnrin yẹn lè jẹ́ Júù, torí pé wọ́n “rọ̀ mọ́ ìdádọ̀dọ́.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sáwọn ọkùnrin tó ń fi ọ̀ràn ìdádọ̀dọ́ dá ìṣòro sílẹ̀ nínú ìjọ lónìí bíi tàwọn wọ̀nyí; síbẹ̀, a lè róhun tó pọ̀ kọ́ nípa ọ̀ràn ẹ̀rí ọkàn nínú ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún Títù.
Àwọn Tí Ẹ̀rí Ọkàn Wọn Jẹ́ Eléèrí
3. Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ fún Títù nípa ẹ̀rí ọkàn?
3 Kíyè sí ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù bá débi tó fi mẹ́nu ba ẹ̀rí ọkàn. “Ohun gbogbo ni ó mọ́ fún àwọn tí ó mọ́. Ṣùgbọ́n fún àwọn tí ó jẹ́ ẹlẹ́gbin àti aláìnígbàgbọ́, kò sí ohun tí ó mọ́, ṣùgbọ́n èrò inú wọn àti ẹ̀rí-ọkàn wọn jẹ́ ẹlẹ́gbin. Wọ́n polongo ní gbangba pé àwọn mọ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n wọ́n sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nípa àwọn iṣẹ́ wọn.” Ó dájú pé lákòókò yẹn, ó yẹ káwọn kan yí èrò wọn padà kí wọ́n bàa lè “jẹ́ onílera nínú ìgbàgbọ́.” (Títù 1:13, 15, 16) Ìṣòro wọn ni pé wọn ò mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó mọ́ àtohun tí kò mọ́, ẹ̀rí ọkàn wọn tí kò sì ṣiṣẹ́ dáadáa ló fà á.
4, 5. Ìṣòro wo làwọn kan láwọn ìjọ tó wà ní Kírétè ní, kí nìyẹn sì ń jẹ́ kí wọ́n ṣe?
4 Lákòókò yẹn, ó ti ju ọdún mẹ́wàá lọ tí ìgbìmọ̀ olùdarí ti pinnu pé ìdádọ̀dọ́ ò pọn dandan mọ́ fẹ́ni tó bá fẹ́ sin Jèhófà ní tòótọ́, wọ́n sì ti fi ìpinnu yẹn tó àwọn ìjọ létí. (Ìṣe 15:1, 2, 19-29) Síbẹ̀, àwọn kan ní Kírétè ṣì ń “rọ̀ mọ́ ìdádọ̀dọ́.” Wọ́n ń sọ gbangba gbàǹgbà páwọn ò fara mọ́ ohun tí ìgbìmọ̀ olùdarí sọ, ‘wọ́n wá ń kọ́ni ní àwọn ohun tí kò yẹ kí wọ́n fi kọ́ni.’ (Títù 1:10, 11) Níwọ̀n bí ìrònú wọn ò ti já gaara, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn apá ibi tó sọ̀rọ̀ nípa oúnjẹ àti ìwẹ̀nùmọ́ nínú Òfin Mósè ni wọ́n ń tẹnu mọ́. Kódà, ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti máa fi kún ohun tí Òfin sọ, bíi tàwọn kan nígbà ayé Jésù, tàbí kí wọ́n ti máa polongo àlọ́ àwọn Júù àtàṣẹ àwọn èèyàn.—Máàkù 7:2, 3, 5, 15; 1 Tímótì 4:3.
5 Bí wọ́n ṣe ń ronú yẹn ti ṣàkóbá fún làákàyè wọn àti òye wọn lórí ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́, ìyẹn ẹ̀rí ọkàn wọn. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Fún àwọn tí ó jẹ́ ẹlẹ́gbin àti aláìnígbàgbọ́, kò sí ohun tí ó mọ́.” Ẹ̀rí ọkàn wọn ò wá ṣiṣẹ́ dáadáa mọ́ débi tí wọ́n á fi lè máa tẹ̀ lé e láti mọ̀ bóyá ohun tí wọ́n ṣe tọ́ tàbí kò tọ́. Síwájú sí i, wọ́n ń ṣèdájọ́ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni lórí ọ̀ràn tí kò kàn wọ́n, ìyẹn àwọn ọ̀ràn tí Kristẹni kọ̀ọ̀kan lè pinnu ohun tó yàtọ̀ sí tẹlòmíì lé lórí. Nípa báyìí, àwọn ará Kírétè yẹn ń pe ohun tí kì í ṣe ẹlẹ́gbin ní ẹlẹ́gbin. (Róòmù 14:17; Kólósè 2:16) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n sọ pé àwọn mọ Ọlọ́run, iṣẹ́ ọwọ́ wọn ò fi hàn pé wọ́n mọ̀ ọ́n.—Títù 1:16.
“Ó Mọ́ fún Àwọn Tí Ó Mọ́”
6. Irú oríṣi èèyàn méjì wo ni Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa wọn?
6 Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ fún Títù? Ó dáa ná, wo bó ṣe fìyàtọ̀ sáàárín oríṣi èèyàn méjì nínú gbólóhùn yìí: “Ohun gbogbo ni ó mọ́ fún àwọn tí ó mọ́. Ṣùgbọ́n fún àwọn tí ó jẹ́ ẹlẹ́gbin àti aláìnígbàgbọ́, kò sí ohun tí ó mọ́, ṣùgbọ́n èrò inú wọn àti ẹ̀rí-ọkàn wọn jẹ́ ẹlẹ́gbin.” (Títù 1:15) Ó dájú pé kì í ṣohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni pé, fún Kristẹ́ni tíwà ẹ̀ mọ́, gbogbo nǹkan pátá ló mọ́, kò sì sóhun tó burú lójú ẹ̀. Ohun tó mú kíyẹn dá wa lójú ni pé Pọ́ọ̀lù ti kọ́kọ́ sọ ọ́ kedere nínú lẹ́tà míì pé àwọn àgbèrè, àwọn abọ̀rìṣà, àwọn abẹ́mìílò àtirú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ “kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.” (Gálátíà 5:19-21) A wá lè tipa bẹ́ẹ̀ rí i dájú pé ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni òótọ́ pọ́ńbélé kan nípa irú àwọn èèyàn méjì tó wà, ìyẹn àwọn tí ìwà wọn dáa tí wọ́n sì ní àjọṣe rere pẹ̀lú Ọlọ́run àtàwọn tíwà wọn ò dáa tí wọn ò sì ní àjọṣe rere pẹ̀lú Ọlọ́run.
7. Kí ni Hébérù 13:4 kà léèwọ̀, àmọ́ ìbéèrè wo ló lè jẹyọ?
7 Kì í ṣe ohun tí Bíbélì bá ti sọ pàtó pé kò dáa nìkan ló yẹ kẹ́ni tó jẹ́ Kristẹni tọkàntọkàn yẹra fún o. Bí àpẹẹrẹ, gbólóhùn kan rèé tí Bíbélì sọ láìfọ̀rọ̀ bopobọyọ̀, ó ní: “Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo ènìyàn, kí ibùsùn ìgbéyàwó sì wà láìní ẹ̀gbin, nítorí Ọlọ́run yóò dá àwọn àgbèrè àti àwọn panṣágà lẹ́jọ́.” (Hébérù 13:4) Kódà àwọn tí kì í ṣe Kristẹni àtàwọn tí kò mọ nǹkan kan nínú Bíbélì gan-an mọ̀ pé gbólóhùn yìí ka panṣágà léèwọ̀. Ó ṣe kedere nínú ẹsẹ Bíbélì yìí àtàwọn míì pé Ọlọ́run ò fara mọ́ kí ọkùnrin kan tó níyàwó tàbí obìnrin kan tó ti lọ́kọ máa ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹlòmíì tó yàtọ̀ sẹ́ni tí wọ́n jọ fẹ́ra lọ́nà tó tọ́. Àmọ́ tọ́rọ̀ bá dọ̀rọ̀ ẹni méjì tí wọn kì í ṣe tọkọtaya tí wọ́n wá ń ní ìbálòpọ̀ aláfẹnuṣe ńkọ́? Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ò ka ìwà yìí sóhun tó léwu nítorí kì í ṣe pé ẹni méjì ń bára wọn sùn. Ṣé ẹni yòówù tó bá jẹ́ Kristẹni lè ka ìbálòpọ̀ aláfẹnuṣe sóhun tó mọ́?
8. Lórí ọ̀ràn ìbálòpọ̀ aláfẹnuṣe, báwo làwọn Kristẹni ṣe yàtọ̀ sí ọ̀pọ̀ èèyàn nínú ayé?
8 Hébérù 13:4 àti 1 Kọ́ríńtì 6:9 là á kalẹ̀ pé Ọlọ́run ò fọwọ́ sí panṣágà àti àgbèrè, ìyẹn por·neiʹa lédè Gíríìkì. Kí ló ń jẹ́ por·neiʹa gan-an? Ohun tí ọ̀rọ̀ tó wá látinú èdè Gíríìkì yẹn túmọ̀ sí fífi ẹ̀yà ìbímọ ẹni ṣèṣekúṣe, yálà nípa níní ìbálòpọ̀ ní tààràtà tàbí lọ́nà èyíkéyìí mìíràn tí kò bójú mu. Ó tan mọ́ gbogbo ìbálòpọ̀ takọtabo tí kò tọ́ láàárín àwọn méjì tí kò ṣe ìgbéyàwó tó bá Ìwé Mímọ́ mu. Torí náà, ó kan ìbálòpọ̀ aláfẹnuṣe, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ jákèjádò ayé ló gbà pé kò sóhun tó burú nínú ìbálòpọ̀ aláfẹnuṣé, tàbí kó jẹ́ pé ohun tí wọ́n sọ fún wọn nìyẹn. Àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í jẹ́ kí “àwọn asọ̀rọ̀ tí kò lérè, àti àwọn tí ń tan èrò inú jẹ” máa darí èrò àti ìṣe àwọn. (Títù 1:10) Ìlànà Ìwé Mímọ́ tí kò fàyè gbàgbàkugbà ni wọ́n rọ̀ mọ́. Dípò tí wọ́n á fi máa wí àwíjàre pé kò sóhun tó burú nínú ìbálòpọ̀ aláfẹnuṣe, wọ́n mọ̀ pé por·neiʹa, ìyẹn àgbèrè, ni Ìwé Mímọ́ kà á sí, wọ́n sì ti kọ́ ẹ̀rí ọkàn wọn kó má ṣe fàyè gbà á.a—Ìṣe 21:25; 1 Kọ́ríńtì 6:18; Éfésù 5:3.
Ẹ̀rí Ọkan Yàtọ̀, Torí Náà Ìpinnu Lè Yàtọ̀
9. Bó bá jẹ́ pé “ohun gbogbo ni ó mọ́,” kí wá niṣẹ́ ẹ̀rí ọkàn?
9 Ṣùgbọ́n kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé “ohun gbogbo ni ó mọ́ fún àwọn tí ó mọ́”? Àwọn tí Pọ́ọ̀lù ń sọ pé wọ́n mọ́ làwọn Kristẹni tó ti jẹ́ kí àwọn ìlànà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa darí ìrònú wọn àti ojú tí wọ́n fi ń wo ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́. Àwọn Kristẹni yẹn mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kí ìpinnu àwọn táwọn jọ jẹ́ onígbàgbọ́ yàtọ̀ síra lórí ọ̀pọ̀ nǹkan tí Ọlọ́run ò kà sí ohun tó burú. Dípò tí wọ́n á fi máa dá ara wọn lẹ́jọ́ lórí ohun tí Ọlọ́run ò bá ti sọ pé ká má ṣe, wọ́n gbà pé irú ohun bẹ́ẹ̀ “mọ́.” Wọn ò retí pé kí gbogbo èèyàn máa ronú gẹ́lẹ́ bíi tiwọn lórí àwọn ọ̀ràn ìgbésí ayé tí Bíbélì ò bá ti fún wa ní ìtọ́ni tó ṣe pàtó. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ tá a lè fi ṣàlàyé ohun tá à ń sọ yìí.
10. Báwo ni ọ̀ràn ìgbéyàwó (tàbí ti ìsìnkú) ṣe lè dá ìṣòro sílẹ̀?
10 Ọ̀pọ̀ tọkọtaya ló wà tó jẹ́ pé ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì ló tíì di Kristẹni, tí ẹnì kejì kò sì tíì dì í. (1 Pétérù 3:1; 4:3) Èyí lè fa onírúurú ìṣòro, bí irú ìgbà tí wọ́n bá fẹ́ ṣe ìgbéyàwó tàbí ìsìnkú aráalé wọn kan. Bí àpẹẹrẹ, wo ọ̀ràn arábìnrin kan tí ọkọ rẹ̀ kò tíì di Kristẹni. Ká wá ní aráalé ọkọ yẹn ń ṣègbéyàwó, tó sì jẹ́ pé ṣọ́ọ̀ṣì ni wọ́n ti máa ṣe é. (Tàbí kó jẹ́ pé aráalé ọkọ, ó tiẹ̀ lé jẹ́ òbí ẹ̀, ló kú tí wọ́n sì fẹ́ ṣètò ìsìnkú ní ṣọ́ọ̀ṣì.) Ọkùnrin yìí sì fẹ́ kíyàwó òun bá òun lọ. Ǹjẹ́ ẹ̀rí ọkàn ẹ̀ á gbà pé kó lọ? Kí ló máa ṣe? Wo ohun méjì tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀.
11. Ṣàlàyé ohun tí arábìrin kan tó jẹ́ abilékọ lè rò tọ́ràn bá dọ̀ràn kó lọ síbi ìgbéyàwó ní ṣọ́ọ̀ṣì, ìpinnu wo sì nìyẹn lè mú kó ṣe?
11 Fúnmi ronú síwá sẹ́yìn lórí àṣẹ tí Bíbélì pa, pé ‘Jáde kúrò nínú Bábílónì Ńlá,’ ìyẹn àgbáríjọ ìsìn èké àgbáyé. (Ìṣípaya 18:2, 4) Ó ti fìgbà kan rí wà nínú ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n ti fẹ́ ṣe ìgbèyáwò yẹn, ó sì mọ̀ pé nígbà tí ayẹyẹ yẹn bá ń lọ lọ́wọ́, wọ́n á ní kí gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ jọ máa ṣe ààtò ìsìn bí àdúrà, orin, àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n máa ń ṣe nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìsìn. Ó ti pinnu pé òun ò ní bá wọn lọ́wọ́ sí gbogbo ohun tó jọ báyẹn kò sì fẹ́ sí níbẹ̀ kó máa lọ dí pé á wà níbi tó ti máa ṣòro fún un láti ṣe ohun tó bá Ìwé Mímọ́ mu. Fúnmi máa ń bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀, ó sì fẹ́ máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ọkọ tí Ìwé Mímọ́ pè ní orí rẹ̀; síbẹ̀ kò fẹ́ pa àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ tó ń tẹ̀ lé tì. (Ìṣe 5:29) Torí náà, ó fọgbọ́n ṣàlàyé fún ọkọ ẹ̀ pé bó bá fẹ́ lọ, òun ò ní lè bá a lọ. Ó ṣeé ṣe kó ṣàlàyé fún un pé bóun bá tiẹ̀ lọ tóun ò wá bá wọn lọ́wọ́ sáwọn kan lára ohun tí wọ́n ń ṣe, ó lè dójú ti ọkọ òun lọ́hùn-ún, torí náà, á dáa kóun má lọ. Ìpinnu tó ṣe yẹn mú kí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ mọ́.
12. Kí lẹnì kan lè rò nípa lílọ síbi ìgbéyàwó kan tí wọ́n pè é sí ní ṣọ́ọ̀ṣì?
12 Ohun kan náà tó ṣẹlẹ̀ sí Fúnmi ṣẹlẹ̀ sí Ṣadé. Òun náà máa ń bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀, ó pinnu láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run, ó sì ní láti ṣèpinnu tó bá ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ tó ti fi Bíbélì kọ́ mu. Lẹ́yìn tí Ṣadé ti ronú lórí àwọn kókó tí Fúnmi gbé yẹ̀ wò, ó fara balẹ̀ ka “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ May 15, 2002, ó sì gbàdúrà nípa rẹ̀. Ó rántí pé àwọn Hébérù mẹ́tà yẹn tẹ̀ lé àṣẹ ọba pé kí wọ́n wà níbi tí ayẹyẹ ìbọ̀rìṣà ti máa wáyé, síbẹ̀ wọn ò pa ìgbàgbọ́ wọn tì, torí pé wọn ò lọ́wọ́ nínú àṣà ìbọ̀rìṣà. (Dáníẹ́lì 3:15-18) Ó pinnu pé òun á bá ọkọ òun lọ àmọ́ òun ò ní bá wọn lọ́wọ́ nínú ààtò ìsìn, ohun tó ṣe yẹn sì bá ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ mu. Ó fọgbọ́n ṣàlàyé kedere fún ọkọ rẹ̀ nípa ohun tó máa lè ṣe àtohun tí kò ní lè ṣe. Ṣadé rò pé èyí lè jẹ́ kí ọkọ òun rí ìyàtọ̀ láàárín ìsìn tòótọ́ àti ìsìn èké.—Ìṣe 24:16.
13. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká kà á sí nǹkan bàbàrà táwọn Kristẹni méjì bá ṣe ìpinnu tó yàtọ̀ síra lórí ọ̀ràn kan náà?
13 Ṣé torí pé ìpinnu àwọn Kristẹni méjì kan lè yàtọ̀ wá túmọ̀ sí pé ohun tó bá wu kálukú ló lè ṣe tàbí pé kì í ṣe àwọn méjèèjì ni ẹ̀rí ọkàn wọn ń ṣiṣẹ́ dáadáa? Rárá o. Nítorí ohun tí Fúnmi ti rí nínú orin àti afẹfẹyẹ̀yẹ̀ inú ayẹyẹ ṣọ́ọ̀ṣì, ó lè rí i pé ó máa léwu fún oun tóun bá lọ síbẹ̀. Àwọn ohun tó ti wáyé rí láàárín òun àtọkọ ẹ̀ lórí ọ̀ràn ìjọsìn lè mú kí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ sọ fún un pé kó ṣerú ìpinnu tó ṣe yẹn. Torí náà, ó dá a lójú pé ìpinnu tóun ṣe yẹn ló dára jù lọ fún òun.
14. Kí ló yẹ káwọn Kristẹni fi sọ́kàn lórí ọ̀ràn tó bá yẹ kẹ́nì kan fúnra rẹ̀ pinnu lé lórí?
14 Àmọ́, ṣé ìpinnu tí Ṣadé ṣe yẹn burú ni? Kò sẹ́ni tó lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ bẹ́ẹ̀. A ò gbọ́dọ̀ dá a lẹ́jọ́ tàbí ká ta kò ó torí pé ó lọ síbi ayẹyẹ ìsìn kan tí kò sì bá wọn dá sí ìsìn. Ẹ rántí ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù lórí ọ̀ràn ìpinnu tó yẹ kéèyàn fúnra rẹ̀ ṣe nípa bóyá kó jẹ àwọn oúnjẹ kan tàbí kó má jẹ ẹ́. Ó sọ pé: “Kí ẹni tí ń jẹ má fojú tẹ́ńbẹ́lú ẹni tí kò jẹ, kí ẹni tí kò sì jẹ má ṣèdájọ́ ẹni tí ń jẹ . . . Lọ́dọ̀ ọ̀gá òun fúnra rẹ̀ ni ó dúró tàbí ṣubú. Ní tòótọ́, a óò mú un dúró, nítorí Jèhófà lè mú un dúró.” (Róòmù 14:3, 4) Ó dájú pé kò sí Kristẹni tòótọ́ kan tó máa fẹ́ rọ ẹnì kan pé kó má tẹ̀ lé ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ tó kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, torí ẹní bá ṣe bẹ́ẹ̀ ń pa nǹkan tó ń fọhùn nínú ẹ̀ lẹ́nu mọ́ nìyẹn, ó sì lè jẹ́ pé ọ̀rọ̀ yẹn ló máa gbẹ̀mí onítọ̀hún là.
15. Kí nìdí tó fi yẹ ká ro ti ẹ̀rí ọkàn àwọn ẹlòmíì àti ojú tí wọ́n fi máa wo ìpinnu wa?
15 Ká tún padà sórí ọ̀ràn lílọ sí ṣọ́ọ̀ṣì yìí kan náà, àwọn arábìnrin méjèèjì ní láti gbé ọ̀ràn míì yẹ̀ wò, ọ̀kan lára rẹ̀ ni ojú táwọn ẹlòmíì á fi wò ó. Pọ́ọ̀lù gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ fi èyí ṣe ìpinnu yín, láti má ṣe fi ohun ìkọ̀sẹ̀ tàbí okùnfà fún ìgbéniṣubú sí iwájú arákùnrin.” (Róòmù 14:13) Fúnmi lè mọ̀ pé ọ̀ràn tó jọ irú ìyẹn ti dá họ́wùhọ́wù sílẹ̀ nínú ìjọ tàbí nínú ìdílé rẹ̀ rí, tó sì mọ̀ pé nǹkan tóun bá ṣe á ní ipa tó lágbára lórí àwọn ọmọ òun. Àmọ́ Ṣadé ní tiẹ̀ lè mọ̀ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò tíì fa ìṣòro kankan rí nínú ìjọ tàbí ládùúgbò. Àwọn arábìnrin méjèèjì, tó fi mọ́ gbogbo wa pàápàá, gbọ́dọ̀ mọ̀ pé tá a bá kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa dáadáa, ó yẹ ká máa ro ojú táwọn ẹlòmíì á fi wo ìpinnu wa. Jésù sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá mú ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré wọ̀nyí tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú mi kọsẹ̀, ó ṣàǹfààní púpọ̀ fún un kí a so ọlọ kọ́ ọrùn rẹ̀, irúfẹ́ èyí tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ máa ń yí, kí a sì rì í sínú òkun gbalasa, tí ó lọ salalu.” (Mátíù 18:6) Tẹ́nì kan bá fojú tẹ́ńbẹ́lú ọ̀rọ̀ tó lè ṣokùnfà ìkọ̀sẹ̀ fáwọn ẹlòmíì, ẹ̀rí ọkàn onítọ̀hún lè di ẹlẹ́gbin bíi tàwọn Kristẹni kan ní Kírétè.
16. Àwọn ìtẹ̀síwájú wo la lè retí pé kó bá Kristẹni kan bó ṣe ń pẹ́ sí i nínú òtítọ́?
16 Ṣe ló yẹ kẹ́ni tó bá jẹ́ Kristẹni túbọ̀ máa sún mọ́ Ọlọ́run sí i, bákan náà ló sì yẹ kó máa gbọ́ ohun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bá ń sọ kó sì máa tẹ̀ lé e. Ẹ jẹ́ ká ronú nípa ti Wálé tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi. Ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ sọ fún un pé kó jáwọ́ nínú àwọn àṣà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu tó ti máa ń lọ́wọ́ nínú ẹ̀ tẹ́lẹ̀, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀ràn ìbọ̀rìṣà tàbí ẹ̀jẹ̀. (Iṣe 21:25) Kódà ní báyìí, kì í sún mọ́ àwọn ohun tó bá ṣe bí ẹní jọ ohun tí Ọlọ́run kà léèwọ̀. Àmọ́ ṣá, ó jọ ọ́ lójú bó ṣe ráwọn kan tí wọ́n ò fara mọ́ àwọn nǹkan kan tóun gbà pó dáa, irú bí àwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n kan.
17. Ṣàlàyé bí ẹ̀rí ọkàn àti ìpinnu arákùnrin kan ṣe lè yí padà torí bó ṣe ń pẹ́ sí i nínú òtítọ́ àti bó ṣe ń sún mọ́ Ọlọ́run sí i.
17 Nígbà tó yá, ìmọ̀ Wálé pọ̀ sí i, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sún mọ́ Ọlọ́run sí i. (Kólósè 1:9, 10) Kí wá nìyẹn ti yọrí sí? Ó ti kọ́ ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ní ẹ̀kọ́ tó pọ̀ sí i. Ní báyìí, Wálé ti túbọ̀ wá ń gbọ́ ohun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ń sọ, ó sì ń lè yiiri àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ wò dáadáa. Kódà, ó ti wá rí i pé àwọn kan lára ‘ohun tó fẹ́ ṣe bí ẹní jọ’ ohun tí Ọlọ́run kà léèwọ̀ tóun ti ń lòdì sí kò burú lójú Ọlọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, ní báyìí tí Wálé ti wá túbọ̀ ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì tó sì fẹ́ láti máa tẹ̀ lé ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ tó ti kọ́ dáadáa, ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ti ń mú kó yẹra fáwọn ètò orí tẹlifísọ̀n tó rò pé ó dáa tẹ́lẹ̀. Ìyẹn ni pé ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ti ń ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ.—Sáàmù 37:31.
18. Kí ló ń mú ká máa láyọ̀?
18 Nínú ọ̀pọ̀ ìjọ, a máa ń rí oríṣiríṣi èèyàn tí òye òtítọ́ yé wọn jura wọn lọ. Àwọn kan nínú wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ donígbàgbọ́ ni. Ó lè jẹ́ pé ẹ̀rí ọkàn wọn kì í rí nǹkan tó burú nínú àwọn ọ̀ràn kan nígbà tó sì jẹ́ pé ó máa ń bá wọn sọ̀rọ̀ tí wọ́n á fi lè pinnu ohun tí wọ́n á ṣe lórí àwọn ọ̀ràn míì. Ó lè ṣe díẹ̀ kírú àwọn bẹ́ẹ̀ tó lè dẹni tó ń tẹ̀ lé ìtọ́ni Jèhófà dáadáa kí wọ́n sì máa gbọ́ ohun tí ẹ̀rí ọkàn wọn tí wọ́n ti kọ́ bá sọ, irú wọn sì nílò ìrànlọ́wọ́. (Éfésù 4:14, 15) Ó dùn mọ́ wa nínú pé láwọn ìjọ kan náà yìí, ó ṣeé ṣe ká ráwọn tó ní ìmọ̀ jíjinlẹ̀ nínú Bíbélì, tí wọ́n mọ àwọn ìlànà rẹ̀ lò dáadáa, tí ẹ̀rí ọkàn wọn sì ń mú kí wọ́n ṣe ohun tó bá èrò Ọlọ́run mu rẹ́gí. Inú wa mà dùn o, pé irú “àwọn tí ó mọ́” lọ́nà yẹn ló yí wa ká, àwọn tí wọ́n gbà pé àwọn ohun tó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lójú Olúwa jẹ́ ohun tó “mọ́” lójú ọmọlúwàbí, kò sì ba ẹ̀sìn wa jẹ́! (Éfésù 5:10) Ǹjẹ́ kí gbogbo wa máa fi ṣe àfojúsùn wa pé a fẹ́ dàgbà dé ipò yẹn ká sì máa jẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn wa máa ṣiṣẹ́ níbàámu pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́ àti ìfọkànsìn Ọlọ́run.—Títù 1:1.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ile-Iṣọ Naa ti September 15, 1983, ojú ìwé 30 àti 31 ṣe àlàyé tó kan ọkọ àtaya, èyí tó yẹ ká gbé yẹ̀ wò.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí nìdí táwọn Kristẹni kan ní Kírétè fi ní ẹ̀rí ọkàn tó jẹ́ ẹlẹ́gbin?
• Kí nìdí tó fi jẹ́ pé àwọn Kristẹni méjì tí ẹ̀rí ọkàn wọn ń ṣiṣẹ́ dáadáa lè ṣèpinnu tó yàtọ̀?
• Bá a ṣe ń pẹ́ sí i nínú òtítọ́, kí ló yẹ kó ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀rí ọkàn wa?
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 26]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Sísílì
GÍRÍÌSÌ
Kírétè
ÉṢÍÀ KÉKERÉ
Kípírọ́sì
OKUN MẸDITARÉNÍÀ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Báwọn Kristẹni méjì bá bára wọn nípò kan náà, ó ṣeé ṣe kí wọ́n ṣèpinnu ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀