Bó Ò Ṣe Ní Yẹsẹ̀ Tí Ọmọ Rẹ Bá Kẹ̀yìn sí Ìlànà Jèhófà
OBÌNRIN kan tá a máa pe orúkọ rẹ̀ ní Joy nínú àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ Kristẹni tó tọ́ ọmọ rẹ̀ lọ́nà táá fi nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run. Àmọ́ nígbà tó kù díẹ̀ kí ọmọkùnrin náà pé ogún ọdún, ó yàyàkuyà ó sì filé sílẹ̀. Joy sọ pé: “Ohun tí ọmọ mi ṣe yìí ló tíì dùn mí jù. Ọkàn mi gbọgbẹ́, ìjákulẹ̀ bá mi, ìbànújẹ́ sì sorí mi kodò. Mo máa ń rò ó pé ọmọ yìí mà lè ṣe báyìí lọ pátápátá kó má padà wá mọ́.”
Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà ti fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ àwọn ọmọ rẹ kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ kí wọ́n sì máa sìn ín, àmọ́ tí ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára wọn wá kẹ̀yìn sí Ọlọ́run nígbà tí wọ́n dàgbà. Kí lo lè ṣe tí ìrònú ìjákulẹ̀ ńláǹlà yẹn ò fi ní borí rẹ? Kí ló máa ràn ọ́ lọ́wọ́ tí o kò fi ní yẹsẹ̀ nínú ìjọsìn Jèhófà?
Nígbà Tí Àwọn Ọmọ Jèhófà Ṣọ̀tẹ̀
Ohun tó yẹ kó o kọ́kọ́ mọ̀ ni pé Jèhófà mọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ gan-an. Nínú Aísáyà 49:15, Jèhófà sọ pé: “Aya ha lè gbàgbé ọmọ ẹnu ọmú rẹ̀ tí kì yóò fi ṣe ojú àánú sí ọmọ ikùn rẹ̀? Àní àwọn obìnrin wọ̀nyí lè gbàgbé, síbẹ̀, èmi kì yóò gbàgbé.” Èyí fi hàn pé bí nǹkan ṣe máa ń rí lára bàbá àti ìyá jọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára Jèhófà. Kò sí àní-àní pé inú Jèhófà dùn gan-an nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ áńgẹ́lì ń yìn ín tí wọ́n sì ń sìn ín. Nígbà tí Jèhófà ń bá Jóòbù baba ńlá sọ̀rọ̀ “láti inú ìjì ẹlẹ́fùúùfù,” ó rántí àkókò aláyọ̀ tóun àti ìdílé rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí tí gbogbo wọn wà níṣọ̀kan fi jọ wà pa pọ̀. Ó bi Jóòbù pé: “Ibo ni ìwọ wà nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀? . . . Nígbà tí àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ jùmọ̀ ń fi ìdùnnú ké jáde, tí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí hó yèè nínú ìyìn?”—Jóòbù 38:1, 4, 7.
Àmọ́ nígbà tó yá, ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run tòótọ́ wọ̀nyí tí wọ́n jẹ́ ọmọ rẹ̀ pípé ṣọ̀tẹ̀ sí i, ó sì di Sátánì, èyí tó túmọ̀ sí “Alátakò.” Ádámù tí í ṣe ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́ tó jẹ́ ọmọ Jèhófà àti Éfà aya rẹ̀ pípé pẹ̀lú gbè sẹ́yìn Sátánì, wọ́n sì di ọlọ̀tẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6; Ìṣípayá 12:9) Nígbà tó ṣe, àwọn míì lára àwọn ọmọ Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ áńgẹ́lì “ṣá ibi gbígbé tiwọn tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu tì” wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run.—Júúdà 6.
Bíbélì ò sọ bó ṣe rí lára Jèhófà nígbà táwọn kan lára àwọn ọmọ rẹ̀ pípé ṣọ̀tẹ̀ sí i. Àmọ́ Bíbélì sọ ọ́ kedere pé: “Jèhófà rí i pé ìwà búburú ènìyàn pọ̀ yanturu ní ilẹ̀ ayé, gbogbo ìtẹ̀sí ìrònú ọkàn-àyà rẹ̀ sì jẹ́ kìkì búburú ní gbogbo ìgbà. Jèhófà sì kẹ́dùn pé òun dá àwọn ènìyàn sórí ilẹ̀ ayé, ó sì dùn ún ní ọkàn-àyà rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:5, 6) Bákan náà, nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ èèyàn tí Jèhófà yàn láàyò ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, “inú rẹ̀ bà jẹ́” ó sì ‘dùn ún.’—Sáàmù 78:40, 41.
Ó dájú pé Jèhófà máa ń gba ọ̀rọ̀ àwọn tí inú wọn bà jẹ́ nítorí ìwàkiwà ọmọ wọn rò. Nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó fún wọn ní ìmọ̀ràn gidi kí wọ́n lè mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe, ó sì tún gbà wọ́n níyànjú. Ó ní kí wọ́n kó àníyàn wọn lé òun, kí wọ́n ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, kí wọ́n má sì gba Sátánì Èṣù láyè. Jẹ́ ká wo bí títẹ̀lé ìmọ̀ràn yìí ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ tí wàá fi dúró ṣinṣin nínú ìjọsìn Ọlọ́run nígbà tí ọmọ rẹ bá kẹ́yìn sí ìlànà Jèhófà.
Kó Àníyàn Rẹ Lé Jèhófà
Jèhófà mọ̀ pé àwọn òbí máa ń dààmú gan-an nígbà tí wọ́n bá mọ̀ pé ọmọ àwọn ń ṣe ohun tó lè fa ìpalára fún un tàbí tí wọ́n mọ̀ pé àwọn míì lè ṣèpalára fún un. Àpọ́sítélì Pétérù sọ ohun kan táwọn òbí lè ṣe tí èyí tàbí àwọn ohun míì bá ń kó ìdààmú bá wọn. Ó kọ̀wé pé: “Ẹ . . . kó gbogbo àníyàn yín lé [Jèhófà], nítorí ó bìkítà fún yín.” (1 Pétérù 5:7) Báwo ni ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí rọni láti ṣe àti ọ̀rọ̀ ìfinilọ́kànbalẹ̀ tó sọ ṣe lè ran àwọn òbí tí ọmọ wọn yàyàkuyà lọ́wọ́?
Nígbà tí ọmọ rẹ ṣì kéré lọ́jọ́ orí, o máa ń dáàbò bò ó nígbà gbogbo nípa títọ́ ọ sọ́nà tìfẹ́tìfẹ́ kéwu má bàa wu ú, ó sì ṣeé ṣe kó máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ. Àmọ́ bó ṣe ń dàgbà, o lè má lágbára lórí rẹ̀ bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, síbẹ̀ ìfẹ́ tó o ní láti máa dáàbò bò ó nínú ewu kò dín kù. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni ìfẹ́ náà ń pọ̀ sí i.
Nípa bẹ́ẹ̀, o lè máa rò ó pé ẹ̀bi rẹ ni tí ọmọ rẹ bá yàyàkuyà tí èyí sì mú kí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run bà jẹ́, tó kó ìbànújẹ́ bá a tó sì ṣèpalára fún un. Bọ́rọ̀ ṣe rí lára Joy tá a mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí nìyẹn. Ó sọ pé: “Ojoojúmọ́ ni ìrònú máa ń bá mi pé mo ṣàṣetì. Mo máa ń ro àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn bóyá ibì kan wà tí mi ò ti ṣe dáadáa.” Ṣó o rí i, irú ìgbà yẹn gan-an ni Jèhófà fẹ́ kó o ‘kó gbogbo àníyàn rẹ lé òun.’ Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, á ràn ọ́ lọ́wọ́. Onísáàmù kan sọ pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró. Kì yóò jẹ́ kí olódodo ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n láé.” (Sáàmù 55:22) Joy rí irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ gbà. Ó ní: “Mo sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn mi fún Jèhófà. Nígbà tí mo sì sọ gbogbo bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára mi fún un tán, ara tù mí.”
Níwọ̀n bó o ti jẹ́ aláìpé, ó ṣeé ṣe kó o ti ṣàṣìṣe nígbà tó ò ń tọ́ ọmọ rẹ. Àmọ́ kò yẹ kó jẹ́ pé àṣìṣe rẹ nìkan ni wàá máa rò. Ẹ̀rí fi hàn pé Jèhófà kì í wo àṣìṣe nìkan, nítorí onísáàmù kọ ọ́ lórin pé: “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ìṣìnà ni ìwọ ń ṣọ́, Jáà, Jèhófà, ta ni ì bá dúró?” (Sáàmù 130:3) Kódà kó jẹ́ pé ẹni pípé ni ọ́, ọmọ rẹ ṣì lè yàyàkuyà. Nítorí náà, gbàdúrà sí Jèhófà, kó o sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára rẹ fún un, yóò sì ràn ọ́ lọ́wọ́ kí ìrònú má bàa borí rẹ. Àmọ́ nǹkan míì tún wà tó o gbọ́dọ̀ ṣe bí ìwọ alára ò bá fẹ́ yẹsẹ̀ nínú ìjọsìn Jèhófà tí o kò sì fẹ́ kọ́wọ́ Sátánì tẹ̀ ọ́.
Ní Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀
Pétérù kọ̀wé pé: “Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára ńlá Ọlọ́run, kí ó lè gbé yín ga ní àkókò yíyẹ.” (1 Pétérù 5:6) Kí nìdí tí ìwọ òbí fi gbọ́dọ̀ lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tí ọmọ rẹ bá kẹ̀yìn sí ìlànà Jèhófà? Ìdí ni pé tí ọmọ rẹ bá kẹ̀yìn sí ìlànà Jèhófà, ìyẹn lè mú kó o máa dá ara rẹ lẹ́bi, ó sì tún lè kó ìtìjú bá ọ. Ìrònú lè bá ọ pé ìwà ọmọ náà ti ba orúkọ ìdílé rẹ jẹ́, àgàgà tó bá jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n yọ ọ́ lẹ́gbẹ́ nínú ìjọ Kristẹni. Tó o bá lọ ń ronú pé ẹ̀bi rẹ lohun tó ṣẹlẹ̀ tó o sì rò pé o ti dẹni ẹ̀tẹ́, ìyẹn lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ tí o kò fi ní fẹ́ lọ sípàdé mọ́.
Tó o bá wà nírú ipò yẹn, ńṣe ni kó o hùwà ọlọgbọ́n. Òwe 18:1 kìlọ̀ pé: “Ẹni tí ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ yóò máa wá ìyánhànhàn onímọtara-ẹni-nìkan; gbogbo ọgbọ́n gbígbéṣẹ́ ni yóò ta kété sí.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú rẹ bà jẹ́, tó o bá ń lọ sípàdé déédéé, wàá lè máa gbọ́ ọ̀rọ̀ ìyànjú àti ìmọ̀ràn tó ṣe kókó. Joy sọ pé: “Nígbà tọ́mọ mi fòtítọ́ sílẹ̀ tó sì kó jáde nílé, mi ò kọ́kọ́ fẹ́ sún mọ́ ẹnikẹ́ni. Àmọ́ mo rán ara mi létí pé lílọ́wọ́ nínú àwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn Ọlọ́run ṣe pàtàkì gan-an. Yàtọ̀ síyẹn, ká ní ńṣe ni mo kàn ń jókòó sílé ti mi ò lọ sípàdé ni, ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ì bá gbà mí lọ́kàn. Ìpàdé tí mò ń lọ jẹ́ kí n gbájú mọ́ àwọn ohun tó ń gbéni ró tá à ń ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Mo dúpẹ́ o, ká ní mo ya ara mi láṣo ni, ì bá má ṣeé ṣe fún mi láti rí ìrànlọ́wọ́ àwọn ará.”—Hébérù 10:24, 25.
Tún máa rántí pé olúkúlùkù ẹni tó jẹ́ Kristẹni nínú ìdílé kan ni yóò “ru ẹrù ti ara rẹ̀.” (Gálátíà 6:5) Jèhófà fẹ́ káwọn òbí nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n sì máa tọ́ wọn sọ́nà. Ó tún fẹ́ káwọn ọmọ náà máa gbọ́rọ̀ sáwọn òbí wọn lẹ́nu kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn. Tí òbí kan bá sa gbogbo ipá rẹ̀ láti tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ dàgbà “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà,” òbí náà yóò ní orúkọ rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run. (Éfésù 6:1-4) Tọ́mọ kan bá wá mọ̀ọ́mọ̀ fi ọ̀nà rere táwọn òbí rẹ̀ fìfẹ́ kọ́ ọ sílẹ̀, òun lorúkọ rẹ̀ máa bà jẹ́. Òwe 20:11 sọ pé: “Àní nípa àwọn ìṣe rẹ̀, ọmọdékùnrin kan ń mú kí a dá òun mọ̀, ní ti bóyá ìgbòkègbodò rẹ̀ mọ́ gaara tí ó sì dúró ṣánṣán.” Dájúdájú, àwọn tó mọ bí àríyànjiyàn tí Sátánì dá sílẹ̀ ṣe jẹ́ gan-an mọ̀ pé ìwà ọ̀tẹ̀ Sátánì ò ba Jèhófà lórúkọ jẹ́.
Má Gba Èṣù Láyè
Pétérù kìlọ̀ pé: “Ẹ pa agbára ìmòye yín mọ́, ẹ máa kíyè sára. Elénìní yín, Èṣù, ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.” (1 Pétérù 5:8) Ńṣe ni Èṣù ń ṣe bíi kìnnìún, àwọn ọmọdé tí ò tíì nírìírí ló sábà máa ń dájú sọ. Láyé ọjọ́un, àwọn kìnnìún máa ń rìn kiri lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì wọ́n sì máa ń pa àwọn ẹran ọ̀sìn jẹ. Tí ọ̀dọ́ àgùntàn kan bá lọ jẹ̀ kúrò láàárín agbo àgùntàn, ó máa túbọ̀ rọrùn fún kìnnìún láti pa á jẹ. Àgùntàn kan lè fẹ̀mí ara rẹ̀ wewu láti dáàbò bo ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n tí Ọlọ́run dá mọ́ ọn. Síbẹ̀, àgùntàn tó ti dàgbà dáadáa pàápàá ò lè bá kìnnìún figẹ̀ wọngẹ̀. Ìdí nìyẹn táwọn olùṣọ́ àgùntàn tó lè máa dáàbò bo agbo àgùntàn fi gbọ́dọ̀ wà.—1 Sámúẹ́lì 17:34, 35.
Kí Jèhófà lè dáàbò bo àwọn àgùntàn rẹ̀ nípa tẹ̀mí kúrò lọ́wọ́ “kìnnìún tí ń ké ramúramù,” ó ṣètò pé káwọn olùṣọ́ àgùntàn tẹ̀mí máa bójú tó agbo rẹ̀ lábẹ́ Jésù Kristi tí í ṣe “olorí olùṣọ́ àgùntàn.” (1 Pétérù 5:4) Pétérù gba irú àwọn ọkùnrin bẹ́ẹ̀ tí Ọlọ́run yàn níyànjú pé: “Ẹ máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run tí ń bẹ lábẹ́ àbójútó yín, kì í ṣe lábẹ́ àfipáṣe, bí kò ṣe tinútinú; bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nítorí ìfẹ́ fún èrè àbòsí, bí kò ṣe pẹ̀lú ìháragàgà.” (1 Pétérù 5:1, 2) Bí ìwọ òbí bá bá àwọn olùṣọ́ àgùntàn wọ̀nyí fọwọ́ sowọ́ pọ̀, ó lè ṣeé ṣe fún wọn láti ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ kó lè ṣàtúnṣe.
Tó bá di dandan pé káwọn olùṣọ́ àgùntàn Ọlọ́run bá ọmọ rẹ tó ṣẹ̀ wí, ó lè ṣe ọ́ bíi pé kó o má gbà fún wọn. Àmọ́, tó o bá lọ ṣe bẹ́ẹ̀, àṣìṣe ńlá lo ṣe o. Ohun tí Pétérù sọ ni pé ‘ko o mú ìdúró rẹ lòdì sí Èṣù,’ kò sọ pé kó o mú ìdúró rẹ lòdì sí àwọn olùṣọ́ àgùntàn tẹ̀mí.—1 Pétérù 5:9.
Tí Ìbáwí Bá Le
Tọ́mọ rẹ ò bá ronú pìwà dà tó sì jẹ́ pé ó ti ṣèrìbọmi, ó ṣeé ṣe kó gba ìbáwí tó le jù lọ, ìyẹn ni pé wọ́n lè yọ ọ́ kúrò nínú ìjọ. Tí wọ́n bá yọ ọ́ lẹ́gbẹ́, ọjọ́ orí rẹ̀ àtàwọn ohun míì ló máa pinnu bí àjọṣe ìwọ àtọmọ náà ṣe máa rí.
Tó bá ṣì kéré lọ́jọ́ orí tó sì jẹ́ pé ńṣe lẹ jọ ń gbé, wàá ṣì máa pèsè àwọn ohun tó nílò fún un. Ojúṣe rẹ sì tún ni láti máa kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ ìwà rere kó o sì máa bá a wí nítorí pé ó nílò rẹ̀. (Òwe 1:8-18; 6:20-22; 29:17) O lè máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú rẹ̀ kó sì máa dáhùn nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. O lè ní kó ronú lórí onírúurú ẹsẹ Ìwé Mímọ́, àtàwọn ohun tó wà nínú ìwé àti nínú àwọn nǹkan míì tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” pèsè. (Mátíù 24:45) O tún lè máa mú un lọ sí ìpàdé ìjọ kó sì máa jókòó pẹ̀lú rẹ. O lè ṣe gbogbo èyí ní ìrètí pé á tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó bá rí gbà látinú Ìwé Mímọ́.
Àmọ́ má ṣe ṣe àwọn ohun wọ̀nyẹn tó bá jẹ́ pé ọmọ rẹ tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ náà ti dàgbà tí ẹ ò sì jọ gbé mọ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn Kristẹni ní ìlú Kọ́ríńtì ayé ọjọ́un pé: “Ẹ jáwọ́ dídarapọ̀ nínú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí a pè ní arákùnrin, tí ó jẹ́ àgbèrè tàbí oníwọra tàbí abọ̀rìṣà tàbí olùkẹ́gàn tàbí ọ̀mùtípara tàbí alọ́nilọ́wọ́gbà, kí ẹ má tilẹ̀ bá irúfẹ́ ènìyàn bẹ́ẹ̀ jẹun.” (1 Kọ́ríńtì 5:11) Lóòótọ́, tẹ́ ẹ bá fẹ́ bójú tó àwọn ọ̀ràn kan tó pọn dandan nínú ìdílé, nígbà míì ó lè gba pé kí ọmọ tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ wà níbẹ̀. Tó bá ti yẹ̀ lórí ìyẹn, kò yẹ kẹ́yin òbí máa bá ọmọ náà ṣe wọléwọ̀de rárá.
Nígbà táwọn olùṣọ́ àgùntàn Ọlọ́run bá bá ọmọ rẹ tó ṣẹ̀ wí, kò ní bọ́gbọ́n mu pé kó o ta ko irú ìbáwí bẹ́ẹ̀ tàbí kó o fojú kéré ìbáwí tí wọ́n fún un látinú Bíbélì. Tó o bá lọ ń gbè sẹ́yìn ọmọ rẹ, mọ̀ pé o kò dáàbò bò ó kúrò lọ́wọ́ Èṣù o. Kódà ìyẹn lè mú kí ìwọ alára ba àjọṣe tó o ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Àmọ́ tó o bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn olùṣọ́ àgùntàn, wàá lè ‘dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́’ wàá sì lè ṣe ìrànlọ́wọ́ gidi fún ọmọ rẹ.—1 Pétérù 5:9.
Jèhófà Yóò Mú Ọ Dúró
Tọ́mọ rẹ bá kẹ̀yìn sí ìlànà Jèhófà, mọ̀ pé ìwọ kọ́ ni irú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ sí. Ó ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn òbí míì tẹ́ ẹ jọ jẹ́ Kristẹni pẹ̀lú. Ìṣòro yòówù ká ní, Jèhófà lè mú wa dúró.—Sáàmù 68:19.
Gbójú lé Jèhófà, kó o máa gbàdúrà sí i. Máa lọ sí ìpàdé ìjọ déédéé. Má ta ko ìbáwí táwọn olùṣọ́ àgùntàn tí Ọlọ́run yàn bá fún ọmọ rẹ. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá lè dúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́. Àpẹẹrẹ rere rẹ sì lè ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti gbọ́ ohun tí Jèhófà ń fìfẹ́ sọ fún un pé kó padà sọ́dọ̀ òun.—Málákì 3:6, 7.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Máa gbàdúrà kó o sì máa lọ sí ìpàdé ìjọ kó o lè lókun nípa tẹ̀mí