ORÍ 28
“Ìwọ Nìkan Ni Adúróṣinṣin”
1, 2. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìwà àìdúróṣinṣin kò jẹ́ tuntun sí Dáfídì Ọba?
ÌWÀ àìdúróṣinṣin kò jẹ́ tuntun sí Dáfídì Ọba. Ní àkókò kan, ńṣe ni ègbìnrìn ọ̀tẹ̀ ń rú lọ́tùn-ún lósì, táwọn ọmọ orílẹ̀-èdè tirẹ̀ pàápàá ń dìtẹ̀ mọ́ ọn nígbà ìjọba rẹ̀ tó kún fún rúkèrúdò. Kò mọ síbẹ̀ yẹn o, àwọn kan tá a lè pè ní kòríkòsùn Dáfídì tún dà á. Ọ̀ràn Míkálì, ìyàwó àkọ́fẹ́ Dáfídì, jẹ́ ọ̀kan. Obìnrin yìí kọ́kọ́ “nífẹ̀ẹ́ Dáfídì gidigidi,” ó sì dájú pé á ti máa ti ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba lẹ́yìn. Àmọ́ nígbà tó yá, ṣe ló “bẹ̀rẹ̀ sí tẹ́ńbẹ́lú rẹ̀ nínú ọkàn-àyà rẹ̀,” tó tiẹ̀ ka Dáfídì sí “ọ̀kan nínú àwọn akúrí.”—1 Sámúẹ́lì 18:20; 2 Sámúẹ́lì 6:16, 20.
2 Ẹlòmíràn tún ni Áhítófẹ́lì, tí í ṣe olùdámọ̀ràn Dáfídì. Bí ìgbà tí Jèhófà fúnra rẹ̀ gbani nímọ̀ràn ni ìmọ̀ràn rẹ̀ máa ń rí. (2 Sámúẹ́lì 16:23) Àmọ́ nígbà tó yá, ọ̀rẹ́-minú yìí dalẹ̀ ọ̀rẹ́, ó bá wọn dìtẹ̀ mọ́ Dáfídì. Ta sì ni ó wà nídìí tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun yìí? Ábúsálómù, ọmọ bíbí Dáfídì kúkú ni! Ọmọ tí ètekéte kún inú rẹ̀ yìí, “ń jí ọkàn-àyà àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì lọ,” ó sọ ara rẹ̀ di ọba nílùú tí ọba wà. Ọ̀tẹ̀ Ábúsálómù yìí le débi pé ńṣe ni Dáfídì Ọba sá bàràbàrà kúrò nílùú fún ẹ̀mí rẹ̀.—2 Sámúẹ́lì 15:1-6, 12-17.
3. Ìdánilójú wo ni Dáfídì ní?
3 Ṣé kò sí ẹni tó dúró ṣinṣin ti Dáfídì ni? Dáfídì mọ̀ pé ẹnì kan wà lẹ́yìn òun gbágbáágbá ní gbogbo ìgbà ìpọ́njú òun. Ta ni ẹni náà? Ta tún ni bí kò ṣe Jèhófà Ọlọ́run. Dáfídì sọ nípa Jèhófà pé: “Ìwọ yóò hùwà lọ́nà ìdúróṣinṣin sí ẹni ìdúróṣinṣin.” (2 Sámúẹ́lì 22:26) Kí ni ìdúróṣinṣin, báwo sì ni Jèhófà ṣe ń fi ànímọ́ yìí hàn lọ́nà àìláfiwé?
Kí Ni Ìdúróṣinṣin?
4, 5. (a) Kí ni “ìdúróṣinṣin”? (b) Báwo ni jíjẹ́ táwọn ohun aláìlẹ́mìí jẹ́ ohun tó ṣeé gbọ́kàn lé ṣe yàtọ̀ sí ìwà ìdúróṣinṣin tí ẹnì kan lè fi hàn?
4 Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà “ìdúróṣinṣin,” gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ṣe lò ó, ni inú rere tí ń fi tìfẹ́tìfẹ́ rọ̀ mọ́ ohun kan, tí kò sì ní dẹ̀yìn títí ó fi máa mú ìdí tó fi rọ̀ mọ́ ohun náà ṣẹ. Adúróṣinṣin máa ń fìfẹ́ hàn.a Ó yẹ fún àfiyèsí pé onísáàmù náà pe òṣùpá ní “ẹlẹ́rìí aṣeégbíyèlé ní sánmà” nítorí bó ṣe ń yọ lálaalẹ́. (Sáàmù 89:37) Ìyẹn ni pé, òṣùpá jẹ́ ohun tó ṣeé gbọ́kàn lé, tí kò ní ṣàìyọ nígbà tí àkókò rẹ̀ bá tó. Àmọ́ òṣùpá kò lè jẹ́ adúróṣinṣin gẹ́gẹ́ bí èèyàn ṣe lè jẹ́ adúróṣinṣin. Kí nìdí? Nítorí pé ìfẹ́ ló ń súnni jẹ́ adúróṣinṣin, a sì mọ̀ pé ohun aláìlẹ́mìí kò lè fi ìfẹ́ hàn.
A pe òṣùpá ní ẹlẹ́rìí aṣeégbíyèlé, àmọ́ àwọn ẹ̀dá onílàákàyè nìkan ló lè gbé ìdúróṣinṣin Jèhófà yọ ní ti gidi
5 Gẹ́gẹ́ bá a ṣe lo ọ̀rọ̀ náà ìdúróṣinṣin nínú Ìwé Mímọ́, ó jẹ́ ànímọ́ ọlọ́yàyà. Ẹ̀rí sábà máa ń wà pé àjọṣe wà láàárín ẹni tó fi ànímọ́ yìí hàn àti ẹni tá a fi í hàn sí. Irú ìdúróṣinṣin bẹ́ẹ̀ kì í yẹ̀. Kò rí bí ìgbì òkun tí ẹ̀fúùfù ń bì síwá bì sẹ́yìn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìdúróṣinṣin, tàbí ìfẹ́ dídúróṣinṣin, máa ń dúró gbọn-in láìyẹsẹ̀, kódà lójú òkè ìṣòro.
6. (a) Báwo ni ìdúróṣinṣin ṣe ṣọ̀wọ́n tó láàárín aráyé, báwo sì ni Bíbélì ṣe fi èyí hàn? (b) Kí ni ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí ìdúróṣinṣin jẹ́, èé sì ti ṣe?
6 Ká sòótọ́, irú ìdúróṣinṣin bẹ́ẹ̀ ṣọ̀wọ́n lóde òní. Mélòó la fẹ́ kà lára àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tí wọ́n sábà máa ń fẹ́ “fọ́ ara wọn sí wẹ́wẹ́ lẹ́nì kìíní-kejì.” Àìmọye ìgbà là ń gbọ́ nípa àwọn tọkọtaya tí wọ́n ń já ara wọn jù sílẹ̀. (Òwe 18:24; Málákì 2:14-16) Ìwà àdàkàdekè wọ́pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí àwa náà fi lè máa sọ bíi ti wòlíì Míkà pé: “Ẹni ìdúróṣinṣin ti ṣègbé kúrò lórí ilẹ̀ ayé.” (Míkà 7:2) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èèyàn kì í sábàá fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn, gbogbo ọ̀nà ni Jèhófà ti ń fi ìdúróṣinṣin hàn lọ́nà títayọ. Ohun tó tiẹ̀ ṣẹlẹ̀ ni pé, ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà mọ ohun tí ìdúróṣinṣin jẹ́ gan-an ni pé kéèyàn ṣàyẹ̀wò bí Jèhófà ṣe ń fi apá títayọlọ́lá lára ìfẹ́ rẹ̀ yìí hàn.
Ìdúróṣinṣin Jèhófà Jẹ́ Aláìláfiwé
7, 8. Èé ṣe tí Bíbélì fi sọ pé Jèhófà nìkan ni adúróṣinṣin?
7 Bíbélì sọ nípa Jèhófà pé: “Ìwọ nìkan ni adúróṣinṣin.” (Ìṣípayá 15:4) Báwo ló ṣe lè jẹ́ bẹ́ẹ̀? Àwọn èèyàn àtàwọn áńgẹ́lì kò ha ti fi ìdúróṣinṣin tó kàmàmà hàn rí bí? (Jóòbù 1:1; Ìṣípayá 4:8) Jésù Kristi náà ńkọ́? Òun ha kọ́ ni olórí lára àwọn “ẹni ìdúróṣinṣin” Ọlọ́run? (Sáàmù 16:10) Báwo wá ni Bíbélì ṣe lè sọ pé Jèhófà nìkan ni adúróṣinṣin?
8 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, rántí pé ìdúróṣinṣin jẹ́ apá kan lára ìfẹ́. A sì mọ̀ pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́,” tó túmọ̀ sí pé òun ni àpẹẹrẹ gíga jù lọ ní ti ká ní ànímọ́ yìí. Nítorí náà, ta ni ìdúróṣinṣin tirẹ̀ wá lè tó ti Jèhófà? (1 Jòhánù 4:8) Òótọ́ ni pé àwọn áńgẹ́lì àti èèyàn lè gbé àwọn ànímọ́ Ọlọ́run yọ, ṣùgbọ́n Jèhófà nìkan ló jẹ́ adúróṣinṣin lọ́nà tí kò lẹ́gbẹ́. Níwọ̀n bí òun ti jẹ́ “Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé,” ìgbà tó ti ń fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn bọ̀ pẹ́ ju ti ẹ̀dá èyíkéyìí lọ, láyé lọ́run. (Dáníẹ́lì 7:9) Fún ìdí yìí, ìdúróṣinṣin ti Jèhófà kò láfiwé o. Ó ń fi ànímọ́ yìí hàn lọ́nà tó ta ti ẹ̀dá èyíkéyìí yọ. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ mélòó kan yẹ̀ wò.
9. Báwo ni Jèhófà ṣe “jẹ́ adúróṣinṣin nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀”?
9 Jèhófà “jẹ́ adúróṣinṣin nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.” (Sáàmù 145:17) Lọ́nà wo? A lè rí ìdáhùn nínú Sáàmù 136. Ibẹ̀ mẹ́nu kan díẹ̀ lára àwọn iṣẹ́ ìgbàlà tí Jèhófà ṣe, títí kan bó ṣe mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì la Òkun Pupa kọjá lọ́nà ìyanu. Ó yẹ fún àfiyèsí pé gbogbo ẹsẹ tó wà nínú sáàmù yìí ló ní gbólóhùn kan tó sọ pé: “Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ [tàbí, ìdúróṣinṣin rẹ̀] wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Sáàmù yìí wà lára ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tò sábẹ́ Ìbéèrè Tí A Ó Fi Ṣàṣàrò lójú ewé 289. Bó o ṣe ń ka ẹsẹ wọ̀nyẹn, ọ̀pọ̀ ọ̀nà tí Jèhófà gbà fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn sáwọn èèyàn rẹ̀ kò ní ṣàì wú ọ lórí. Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà ń dúró ṣinṣin ti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ nípa gbígbọ́ igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́ àti nípa gbígbé ìgbésẹ̀ ní àkókò yíyẹ. (Sáàmù 34:6) Ìfẹ́ dídúróṣinṣin tí Jèhófà ní sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kì í yẹ̀, ìyẹn bí wọ́n bá jẹ́ adúróṣinṣin sí i.
10. Báwo ni Jèhófà ṣe ń fi hàn pé òun dúró ṣinṣin ti àwọn ìlànà òun?
10 Láfikún sí i, Jèhófà ń fi ìdúróṣinṣin hàn sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nípa rírọ̀mọ́ àwọn ìlànà rẹ̀. Láìdàbí ẹ̀dá èèyàn tó lè pahùn dà lọ́sàn-án kan òru kan, tàbí tó lè fi èrò tó ṣàdédé sọ sí wọn lọ́kàn kù gìrì ṣe ìpinnu, Jèhófà kì í ṣe aláìdúrósójúkan nínú èrò rẹ̀ nípa ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. Jálẹ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún tó ti kọjá, èrò rẹ̀ nípa àwọn nǹkan bí ìbẹ́mìílò, ìbọ̀rìṣà àti ìpànìyàn kò yí padà. Ó gbẹnu wòlíì rẹ̀ Aísáyà sọ pé: “Àní títí di ọjọ́ ogbó ènìyàn, Ẹnì kan náà ni mí.” (Aísáyà 46:4) Fún ìdí yìí, a ní ìdánilójú pé títẹ̀lé òfin ìwà rere tá a là sílẹ̀ kedere nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò ṣe wá láǹfààní.—Aísáyà 48:17-19.
11. Tọ́ka sí àwọn àpẹẹrẹ tó fi hàn pé Jèhófà ń fi ìdúróṣinṣin pa ìlérí rẹ̀ mọ́.
11 Jèhófà tún ń fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin nípa pípa ìlérí rẹ̀ mọ́. Gbogbo ohun tó bá sọ tẹ́lẹ̀ ló ń ṣẹ. Ìdí nìyí tí Jèhófà fi sọ pé: “Ọ̀rọ̀ mi tí ó ti ẹnu mi jáde . . . kì yóò padà sọ́dọ̀ mi láìní ìyọrísí, ṣùgbọ́n ó dájú pé yóò ṣe èyí tí mo ní inú dídùn sí, yóò sì ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú nínú èyí tí mo tìtorí rẹ̀ rán an.” (Aísáyà 55:11) Bí Jèhófà ṣe ń pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́, ó ń fi ìdúróṣinṣin hàn sí àwọn èèyàn rẹ̀ nìyẹn. Kì í jẹ́ kí wọ́n máa fi ìháragàgà retí ohun tó mọ̀ pé òun kò ní ṣe. Jèhófà ti ṣe orúkọ rere fún ara rẹ̀ nínú ọ̀ràn yìí dépò pé Jóṣúà ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ pé: “Kò sí ìlérí kan tí ó kùnà nínú gbogbo ìlérí dáradára tí Jèhófà ti ṣe fún ilé Ísírẹ́lì; gbogbo rẹ̀ ni ó ṣẹ.” (Jóṣúà 21:45) Nítorí náà, a ní ìdánilójú pé kò lè sí ìjákulẹ̀ láé látọ̀dọ̀ Jèhófà, kò sí pé ó lè kùnà láti mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ.—Aísáyà 49:23; Róòmù 5:5.
12, 13. Àwọn ọ̀nà wo ni inú rere onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà ní fi “wà fún àkókò tí ó lọ kánrin”?
12 Gẹ́gẹ́ bá a ṣe ṣàlàyé tẹ́lẹ̀, Bíbélì sọ fún wa pé inú-rere-onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà ní “wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Sáàmù 136:1) Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Lọ́nà kan, tí Jèhófà bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini, ó dárí rẹ̀ jini pátápátá nìyẹn. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe ṣàlàyé ní Orí 26, Jèhófà kì í padà fìyà jẹ èèyàn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àtẹ̀yìnwá tó ti dárí rẹ̀ jini. Níwọ̀n bí “gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, [tí] wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run,” ó yẹ kí kálukú wa máa dúpẹ́ pé inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Jèhófà wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.—Róòmù 3:23.
13 Àmọ́ inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Jèhófà tún wà fún àkókò tí ó lọ kánrin lọ́nà mìíràn. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé olódodo “yóò dà bí igi tí a gbìn sẹ́bàá àwọn ìṣàn omi, tí ń pèsè èso tirẹ̀ ní àsìkò rẹ̀ èyí tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé kì í sì í rọ, gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe ni yóò sì máa kẹ́sẹ járí.” (Sáàmù 1:3) Igi gbígbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ tí ewé rẹ̀ kì í rọ máa ń fani mọ́ra gan-an ni! Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, bí ìfẹ́ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bá jinlẹ̀ lọ́kàn wa, a óò ní ẹ̀mí gígùn, ayé wa á tòrò, a ó sì jẹ́ aláṣeyọrí. Àwọn ìbùkún tí Jèhófà ń fi ìdúróṣinṣin pèsè fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ jẹ́ ìbùkún ayérayé. Ní ti tòótọ́, nínú ayé tuntun òdodo tí Jèhófà yóò mú wá, ìran ènìyàn onígbọràn yóò máa gbádùn inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ fún àkókò tí ó lọ kánrin.—Ìṣípayá 21:3, 4.
Jèhófà ‘Kì Yóò Fi Àwọn Ẹni Ìdúróṣinṣin Rẹ̀ Sílẹ̀’
14. Báwo ni Jèhófà ṣe ń fi hàn pé òun mọrírì ìdúróṣinṣin àwọn ìránṣẹ́ òun?
14 Léraléra ni Jèhófà ti fi hàn pé adúróṣinṣin lòun. Níwọ̀n bí Jèhófà ti jẹ́ awíbẹ́ẹ̀-ṣe-bẹ́ẹ̀, ìdúróṣinṣin tó ń fi hàn sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ kì í yẹ̀. Onísáàmù náà kọ̀wé pé: “Èmi ti jẹ́ ọ̀dọ́ rí, mo sì ti darúgbó, síbẹ̀síbẹ̀, èmi kò tíì rí i kí a fi olódodo sílẹ̀ pátápátá, tàbí kí ọmọ rẹ̀ máa wá oúnjẹ kiri. Nítorí pé olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo ni Jèhófà, òun kì yóò sì fi àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ sílẹ̀.” (Sáàmù 37:25, 28) Lóòótọ́, Jèhófà yẹ ní ẹni tí à ń sìn, torí pé òun ni Ẹlẹ́dàá. (Ìṣípayá 4:11) Síbẹ̀, nítorí pé Jèhófà jẹ́ adúróṣinṣin, ó mọrírì ìṣòtítọ́ wa gidigidi.—Málákì 3:16, 17.
15. Ṣàlàyé bí ọ̀nà tí Jèhófà gbà bá Ísírẹ́lì lò ṣe fi ìdúróṣinṣin Rẹ̀ hàn.
15 Nínú inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́, léraléra ni Jèhófà ń ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ nígbà tí ìpọ́njú bá dé bá wọn. Onísáàmù náà sọ fún wa pé: “Ó ń ṣọ́ ọkàn àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀; ó ń dá wọn nídè kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹni burúkú.” (Sáàmù 97:10) Kíyè sí bó ṣe bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lò. Lẹ́yìn tí Jèhófà mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì la Òkun Pupa kọjá lọ́nà ìyanu, wọ́n kọrin sí Jèhófà pé: “Nínú inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ [tàbí, “ìfẹ́ dídúróṣinṣin,” àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé NW], ìwọ ti ṣamọ̀nà àwọn ènìyàn tí ìwọ gbà sílẹ̀.” (Ẹ́kísódù 15:13) Láìsí àní-àní, ìfẹ́ dídúróṣinṣin tí Jèhófà ní ló jẹ́ kó mú wọn la Òkun Pupa kọjá. Ìdí nìyẹn tí Mósè fi sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Kì í ṣe nítorí pé ẹ jẹ́ àwọn tí ó pọ̀ jù lọ nínú gbogbo ènìyàn ni Jèhófà ṣe fi ìfẹ́ni hàn sí yín, tí ó fi yàn yín, nítorí ẹ̀yin ni ẹ kéré jù lọ nínú gbogbo ènìyàn. Ṣùgbọ́n ó jẹ́ nítorí níní tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ yín, àti nítorí pípa tí ó pa gbólóhùn ìbúra tí ó búra fún àwọn baba ńlá yín mọ́, ni Jèhófà fi fi ọwọ́ líle mú yín jáde, kí ó bàa lè tún ọ rà padà kúrò ní ilé àwọn ẹrú, kúrò ní ọwọ́ Fáráò ọba Íjíbítì.”—Diutarónómì 7:7, 8.
16, 17. (a) Ìwà àìmoore bíburú jáì wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì hù, síbẹ̀ báwo ni Jèhófà ṣe fi ìyọ́nú hàn sí wọn? (b) Báwo ni ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe fi hàn pé ‘kò sí ìmúláradá’ mọ́ nínú ọ̀ràn tiwọn, ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n wo sì ni èyí jẹ́ fún wa?
16 A mọ̀ pé, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan, kò mọrírì inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Jèhófà, torí pé lẹ́yìn ìdáǹdè náà ńṣe ni wọ́n “tún ń bá a nìṣó ní títúbọ̀ dẹ́ṣẹ̀ sí [Jèhófà], nípa ṣíṣọ̀tẹ̀ sí Ẹni Gíga Jù Lọ.” (Sáàmù 78:17) Ní àwọn ọ̀rúndún tó tẹ̀ lé e, léraléra ni wọ́n ṣọ̀tẹ̀, tí wọ́n fi Jèhófà sílẹ̀, tí wọ́n lọ ń bọ̀rìṣà, tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé àṣà àwọn kèfèrí, èyí tó sọ wọ́n di eléèérí kanlẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, Jèhófà kò da májẹ̀mú rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà gbẹnu wòlíì Jeremáyà pàrọwà fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé: “Padà, ìwọ Ísírẹ́lì ọ̀dàlẹ̀ . . . Èmi kì yóò jẹ́ kí ojú mi sọ̀ kalẹ̀ tìbínú-tìbínú sórí yín, nítorí adúróṣinṣin ni mí.” (Jeremáyà 3:12) Àmọ́, bá a ṣe ṣàlàyé ní Orí 25, etí ikún ni ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ sí àrọwà yìí. Àní sẹ́, ṣe ni “wọ́n ń bá a lọ ní fífi àwọn ońṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ ṣẹ̀fẹ̀, wọ́n sì ń tẹ́ńbẹ́lú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ń fi àwọn wòlíì rẹ̀ ṣe ẹlẹ́yà.” Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Níkẹyìn, “ìhónú Jèhófà . . . jáde wá sórí àwọn ènìyàn rẹ̀, títí kò fi sí ìmúláradá.”—2 Kíróníkà 36:15, 16.
17 Ẹ̀kọ́ wo ni èyí kọ́ wa? Pé ìdúróṣinṣin Jèhófà kò gbàgbàkugbà, ẹ̀tàn ò sì ràn án rárá. Lóòótọ́, Jèhófà “pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́,” ó sì máa ń dùn mọ́ ọn láti fi àánú hàn nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n kí ló máa ṣẹlẹ̀ bí ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ti jingíri sínú ìwà ẹ̀ṣẹ̀? Bó bá ti dà bẹ́ẹ̀, ṣe ni Jèhófà yóò rọ̀ mọ́ ìlànà òdodo tirẹ̀, yóò sì dá onítọ̀hún lẹ́jọ́. Ó sọ fún Mósè pé “lọ́nàkọnà, [Jèhófà] kì í dáni sí láìjẹni-níyà.”—Ẹ́kísódù 34:6, 7.
18, 19. (a) Báwo ni ìdájọ́ Jèhófà lórí àwọn olubi ṣe tún jẹ́ ìwà ìdúróṣinṣin pẹ̀lú? (b) Báwo ni Jèhófà yóò ṣe fi ìdúróṣinṣin rẹ̀ hàn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n kú lójú inúnibíni?
18 Ìdájọ́ Ọlọ́run lórí àwọn olubi tún jẹ́ ìwà ìdúróṣinṣin pẹ̀lú. Lọ́nà wo? Ẹ̀rí kan nípa èyí ń bẹ nínú ìwé Ìṣípayá, nínú àṣẹ tí Jèhófà pa fún àwọn áńgẹ́lì méje náà, pé: “Ẹ lọ da àwokòtò méje ìbínú Ọlọ́run jáde sí ilẹ̀ ayé.” Nígbà tí áńgẹ́lì kẹta da àwokòtò tirẹ̀ “sínú àwọn odò àti àwọn ìsun omi,” wọ́n di ẹ̀jẹ̀. Áńgẹ́lì náà wá sọ fún Jèhófà pé: “Ìwọ, Ẹni tí ń bẹ, tí ó sì ti wà, Ẹni ìdúróṣinṣin, jẹ́ olódodo, nítorí pé ìwọ ti ṣe ìpinnu wọ̀nyí, nítorí pé wọ́n tú ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹni mímọ́ àti ti àwọn wòlíì jáde, ìwọ sì ti fún wọn ní ẹ̀jẹ̀ mu. Ó tọ́ sí wọn.”—Ìṣípayá 16:1-6.
Jèhófà máa rántí gbogbo àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ sí i títí dójú ikú, ó sì máa jí wọn dìde
19 Ṣàkíyèsí pé bí áńgẹ́lì náà ṣe ń jẹ́ iṣẹ́ ìdájọ́ yẹn, ó pe Jèhófà ní “Ẹni ìdúróṣinṣin.” Èé ṣe? Nítorí pé nípa pípa àwọn ẹni ibi run, ṣe ni Jèhófà ń fi ìdúróṣinṣin hàn sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, tí ọ̀pọ̀ nínú wọ́n ti kú lójú inúnibíni. Gẹ́gẹ́ bí adúróṣinṣin, Jèhófà kò jẹ́ gbàgbé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Ó ń fẹ́ láti tún padà rí àwọn olóòótọ́ tó ti kú wọ̀nyí, Bíbélì sì mú un dá wa lójú pé ète rẹ̀ ni láti fi àjíǹde san wọ́n lẹ́san. (Jóòbù 14:14, 15) Jèhófà kì í tìtorí pé àwọn ìránṣẹ́ òun adúróṣinṣin kò sí láàyè mọ́, kí ó wá gbàgbé wọn. Rárá o, kàkà bẹ́ẹ̀, “gbogbo wọn wà láàyè lójú rẹ̀.” (Lúùkù 20:37, 38) Ète Jèhófà láti jí àwọn tó wà nínú ìrántí rẹ̀ dìde jẹ́ ẹ̀rí tó dájú pé ó jẹ́ adúróṣinṣin.
Ìfẹ́ Dídúróṣinṣin Tí Jèhófà Ní Ṣí Ọ̀nà Ìgbàlà Sílẹ̀
20. Àwọn wo ni “ohun èlò àánú,” báwo sì ni Jèhófà ṣe fi ìdúróṣinṣin hàn sí wọn?
20 Jálẹ̀ ìtàn aráyé ni Jèhófà ti fi ìdúróṣinṣin tó kàmàmà hàn sáwọn olóòótọ́ ènìyàn. Àní sẹ́, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ni Jèhófà ti “fi ọ̀pọ̀ ìpamọ́ra fàyè gba àwọn ohun èlò ìrunú tí a mú yẹ fún ìparun.” Kí nìdí rẹ̀? Ìdí rẹ̀ ní pé: “Kí ó bàa lè sọ àwọn ọrọ̀ ògo rẹ̀ di mímọ̀ lórí àwọn ohun èlò àánú, èyí tí ó pèsè sílẹ̀ tẹ́lẹ̀ fún ògo.” (Róòmù 9:22, 23) “Ohun èlò àánú” wọ̀nyí ni àwọn ọlọ́kàn títọ́ tá a fi ẹ̀mí mímọ́ yàn láti jẹ́ ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi nínú Ìjọba rẹ̀. (Mátíù 19:28) Nípa ṣíṣí tí Jèhófà ṣí ọ̀nà ìgbàlà sílẹ̀ fáwọn ohun èlò àánú wọ̀nyí, ńṣe ló dúró ṣinṣin ti Ábúráhámù, tó bá dá májẹ̀mú pé: “Nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ . . . ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé yóò bù kún ara wọn nítorí òtítọ́ náà pé ìwọ ti fetí sí ohùn mi.”—Jẹ́nẹ́sísì 22:18.
21. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe fi ìdúróṣinṣin hàn sí “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tó ń retí láti la “ìpọ́njú ńlá” já? (b) Kí ni ìdúróṣinṣin Jèhófà sún ọ láti ṣe?
21 Jèhófà ń fi irú ìdúróṣinṣin bẹ́ẹ̀ hàn sí “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tó ń retí láti la “ìpọ́njú ńlá” já, kí wọ́n sì wà láàyè títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 7:9, 10, 14) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ aláìpé, Jèhófà ti fi ìdúróṣinṣin nawọ́ àǹfààní wíwàláàyè títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé sí wọn. Lọ́nà wo? Nípasẹ̀ ìràpadà ni, tí í ṣe ẹ̀rí gíga jù lọ tó fi hàn pé adúróṣinṣin ni Jèhófà. (Jòhánù 3:16; Róòmù 5:8) Ìdúróṣinṣin Jèhófà ń mú kí àwọn tí ọkàn wọn ń yán hànhàn fún òdodo fà mọ́ Jèhófà. (Jeremáyà 31:3) Ǹjẹ́ ọkàn rẹ kò túbọ̀ fà mọ́ Jèhófà nítorí ìdúróṣinṣin gíga lọ́lá tó ti fi hàn, àti èyí tí yóò sì tún fi hàn bí? Níwọ̀n bí ó ti wù wá pé ká sún mọ́ Ọlọ́run, ǹjẹ́ kí á dáhùn sí ìfẹ́ rẹ̀, nípa títúbọ̀ máa fi ìdúróṣinṣin sìn ín.
a Ó yẹ fún àfiyèsí pé ọ̀rọ̀ kan náà tá a túmọ̀ sí “ìdúróṣinṣin” nínú 2 Sámúẹ́lì 22:26 la túmọ̀ sí “inú-rere-onífẹ̀ẹ́” tàbí “ìfẹ́ dídúróṣinṣin” níbòmíràn.