Ẹ Yọ̀ Nítorí Ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn!
“Ẹ jẹ́ kí a yọ̀, kí a sì láyọ̀ púpọ̀ . . . nítorí ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn ti dé.”—ÌṢÍ. 19:7.
1, 2. (a) Ìgbéyàwó ta ló máa mú káwọn tó wà lọ́run yọ̀ ayọ̀ ńlá? (b) Àwọn ìbéèrè wo lèyí mú wá?
Ó SÁBÀ máa ń gba àkókò láti múra sílẹ̀ fún ìgbéyàwó. A máa sọ̀rọ̀ nípa ìgbéyàwó kan tó ṣe pàtàkì gan-an. Ìdílé ọba làwọn tó ń ṣègbéyàwó náà ti wá. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbàá [2,000] ọdún sẹ́yìn tí wọ́n ti ń múra sílẹ̀ fún ìgbéyàwó náà. Àkókò ìgbéyàwó náà ti wá dé tán báyìí. Láìpẹ́, orin ayọ̀ máa gba ààfin Ọba kan, ogunlọ́gọ̀ àwọn áńgẹ́lì tí ń bẹ lọ́run á sì máa kọrin pé: “Ẹ yin Jáà, nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run wa, Olódùmarè, ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba. Ẹ jẹ́ kí a yọ̀, kí a sì láyọ̀ púpọ̀, ẹ sì jẹ́ kí a fi ògo fún un, nítorí ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn ti dé, aya rẹ̀ sì ti múra sílẹ̀.”—Ìṣí. 19:6, 7.
2 Jésù Kristi ni “Ọ̀dọ́ Àgùntàn” tí ìgbéyàwó rẹ̀ máa mú káwọn tó wà lọ́run yọ̀. (Jòh. 1:29) Aṣọ wo ló wọ̀ nígbà ìgbéyàwó náà? Ta ni ìyàwó rẹ̀? Báwo la ṣe múra obìnrin náà sílẹ̀ fún ìgbéyàwó? Ìgbà wo ni ìgbéyàwó náà wáyé? Ìgbéyàwó yìí máa mú káwọn tó wà lọ́run yọ̀, àmọ́ ṣé àwọn tó nírètí láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé máa bá wọn yọ ayọ̀ ìgbéyàwó náà? Ó dájú pé àá fẹ́ mọ ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa bá ìjíròrò wa lọ nínú Sáàmù 45 ká lè rí ìdáhùn sí wọn.
‘Ẹ̀WÙ RẸ̀ KÚN FÚN ÒÓRÙN DÍDÙN’
3, 4. (a) Kí ni Bíbélì sọ nípa aṣọ tí Ọkọ Ìyàwó wọ̀, kí ló sì pa kún ayọ̀ rẹ̀? (b) Àwọn wo ni “àwọn ọmọbìnrin àwọn ọba” àti “olorì” tí wọ́n bá Ọkọ Ìyàwó yọ̀?
3 Ka Sáàmù 45:8, 9. Jésù Kristi tó jẹ́ Ọkọ Ìyàwó gbé ẹ̀wù oyè rírẹwà tó fẹ́ fi ṣe ìgbéyàwó wọ̀. Abájọ, òórùn atunilára tó ń jáde lára aṣọ rẹ̀ jọ ti “lọ́fínńdà tí ó jẹ́ ààyò jù lọ,” irú bí òjíá àti kasíà, tí wọ́n wà lára àwọn èròjà tí wọ́n fi ń ṣe òróró mímọ́ àfiyanni tí wọ́n máa ń lò nílẹ̀ Ísírẹ́lì.—Ẹ́kís. 30:23-25.
4 Orin tó gba inú ààfin náà kan ní ọ̀run mú kí inú Ọkọ Ìyàwó yìí túbọ̀ dùn bí àkókò ìgbéyàwó rẹ̀ ti ń sún mọ́. Lára àwọn tó ń bá Ọkọ Ìyàwó yìí yọ̀ ni “Olorì.” Ta ni Olorì yìí? Òun ni apá ti òkè ọ̀run lára ètò Jèhófà, tó ní nínú “àwọn ọmọbìnrin àwọn ọba,” ìyẹn, àwọn áńgẹ́lì mímọ́. Ẹ sì wo bó ṣe máa dùn mọ́ni tó láti gbọ́ tí wọ́n ń polongo lọ́run pé: “Ẹ jẹ́ kí a yọ̀, kí a sì láyọ̀ púpọ̀ . . . nítorí ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn ti dé”!
ÌYÀWÓ TI WÀ NÍ SẸPẸ́ LÁTI TẸ̀ LÉ ỌKỌ RẸ̀
5. Ta ni “aya Ọ̀dọ́ Àgùntàn” náà?
5 Ka Sáàmù 45:10, 11. A ti mọ Ọkọ Ìyàwó náà, àmọ́ ta ni ìyàwó rẹ̀? Ìyàwó rẹ̀ ni àpapọ̀ àwọn tó wà nínú ìjọ, èyí tí Jésù Kristi jẹ́ orí fún. (Ka Éfésù 5:23, 24.) Wọ́n máa bá Kristi ṣàkóso nínú Ìjọba Mèsáyà. (Lúùkù 12:32) Àwọn Kristẹni tá a fẹ̀mí yàn tí iye wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] yìí “ń tọ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà lẹ́yìn ṣáá níbikíbi tí ó bá ń lọ.” (Ìṣí. 14:1-4) Wọ́n di “aya Ọ̀dọ́ Àgùntàn,” wọ́n sì ń bá a gbé ní ọ̀run tó jẹ́ ibùgbé rẹ̀.—Ìṣí. 21:9; Jòh. 14:2, 3.
6. Kí nìdí tí Bíbélì fi pe àwọn ẹni àmì òróró ní “ọmọbìnrin ọba”? Kí nìdí tá a fi sọ fún wọn pé kí wọ́n ‘gbàgbé àwọn èèyàn wọn’?
6 Yàtọ̀ sí pé Bíbélì pe ìyàwó lọ́la náà ní “ìwọ ọmọbìnrin,” ó tún pè é ní “ọmọbìnrin ọba.” (Sm. 45:13) “Ọba” wo nìyẹn? Ẹ rántí pé Jèhófà gba àwọn Kristẹni tá a fẹ̀mí yàn ṣe “ọmọ” rẹ̀. (Róòmù 8:15-17) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn ẹni àmì òróró á di ìyàwó lọ́run, a sọ fún wọn pé: “Gbàgbé àwọn ènìyàn rẹ àti ilé baba rẹ [nípa tara].” Wọ́n ní láti “gbé èrò inú [wọn] ka àwọn nǹkan ti òkè, kì í ṣe àwọn nǹkan tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé.”—Kól. 3:1-4.
7. (a) Báwo ni Kristi ṣe ń múra ìyàwó rẹ̀ ọjọ́ iwájú sílẹ̀? (b) Ojú wo ni ìyàwó náà fi ń wo ẹni tó máa jẹ́ Ọkọ rẹ̀?
7 Ọ̀pọ̀ ọdún ti kọjá báyìí tí Kristi ti ń múra ìyàwó rẹ̀ ọjọ́ iwájú sílẹ̀ fún ìgbéyàwó wọn lọ́run. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé Kristi “nífẹ̀ẹ́ ìjọ . . . ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún un, kí ó lè sọ ọ́ di mímọ́, ní wíwẹ̀ ẹ́ mọ́ pẹ̀lú ìwẹ̀ omi nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ náà, kí ó lè mú ìjọ wá síwájú ara rẹ̀ nínú ìdángbinrin rẹ̀, láìní èérí kan tàbí ìhunjọ kan tàbí èyíkéyìí nínú irúfẹ́ nǹkan bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n pé kí ó lè jẹ́ mímọ́ àti láìsí àbààwọ́n.” (Éfé. 5:25-27) Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà nílùú Kọ́ríńtì ìgbàanì pé: “Èmi ń jowú lórí yín pẹ̀lú owú lọ́nà ti Ọlọ́run, nítorí èmi fúnra mi ti fẹ́ yín sọ́nà fún ọkọ kan, kí èmi lè mú yín wá fún Kristi gẹ́gẹ́ bí wúńdíá oníwà mímọ́.” (2 Kọ́r. 11:2) Jésù Kristi Ọba tó jẹ́ Ọkọ Ìyàwó yìí mọrírì “ẹwà” tẹ̀mí tí ìyàwó rẹ̀ lọ́la ní. Ìyàwó rẹ̀ náà sì gbà pé ó jẹ́ “olúwa” òun, ó sì ń “tẹrí ba fún un,” gẹ́gẹ́ bí ọkọ rẹ̀ lọ́la.
WỌ́N “MÚ” ÌYÀWÓ “TỌ ỌBA WÁ”
8. Kí nìdí tó fi bá a mu pé Bíbélì ṣàlàyé pé ìyàwó náà “kún fún ògo látòkè délẹ̀”?
8 Ka Sáàmù 45:13, 14a. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí fi hàn pé a ti múra ìyàwó tó “kún fún ògo látòkè délẹ̀” náà sílẹ̀ fún ìgbéyàwó tó wáyé ní ìdílé ọba yìí. Nínú Ìṣípayá 21:2, a fi ìyàwó náà wé ìlú kan, ìyẹn Jerúsálẹ́mù Tuntun, a sì ṣe é “lọ́ṣọ̀ọ́ fún ọkọ rẹ̀.” Ìlú tó wà lọ́run yìí “ní ògo Ọlọ́run,” ó sì ń tàn yinrin “bí òkúta ṣíṣeyebíye jù lọ, bí òkúta jásípérì tí ń dán bí kírísítálì tí ó mọ́ kedere.” (Ìṣí. 21:10, 11) Ìwé Ìṣípayá ṣàlàyé bí Jerúsálẹ́mù Tuntun yìí ṣe ń dán gbinrin ní ọ̀nà kan tó fani mọ́ra. (Ìṣí. 21:18-21) Abájọ tí onísáàmù náà fi sọ pé ìyàwó náà “kún fún ògo látòkè délẹ̀”! Ó ṣe tán, ọ̀run ni wọ́n ti máa ṣe ìgbéyàwó tó jẹ́ ti ìdílé ọba yìí.
9. Ta ni “ọba” tí wọ́n mú ìyàwó náà wá bá, irú aṣọ wo ní ìyàwó náà sì wọ̀?
9 Ẹni tí wọ́n mú ìyàwó náà wá bá ni Ọkọ Ìyàwó, ìyẹn Mèsáyà Ọba. Ó ti ń múra ìyàwó rẹ̀ yìí sílẹ̀ nípa “wíwẹ̀ ẹ́ mọ́ pẹ̀lú ìwẹ̀ omi nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ náà.” Ó wà ní “mímọ́ àti láìsí àbààwọ́n.” (Éfé. 5:26, 27) Ìyàwó náà alára gbọ́dọ̀ múra lọ́nà tó bá ayẹyẹ ìgbéyàwó wọn mu. Bó sì ṣe rí gan-an nìyẹn! Kódà, “aṣọ rẹ̀ ní àwọn ibi tí [wọ́n] lẹ wúrà mọ́,” wọ́n á sì ‘mú un tọ ọba wá nínú aṣọ ọ̀ṣọ́ híhun.’ Nígbà ìgbéyàwó rẹ̀ pẹ̀lú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, Bíbélì sọ pé, “a ti yọ̀ǹda fún un kí a fi aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà, títànyòyò, tí ó mọ́ ṣe é ní ọ̀ṣọ́, nítorí pé aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà náà dúró fún àwọn ìṣe òdodo àwọn ẹni mímọ́.”—Ìṣí. 19:8.
ÀKÓKÒ ÌGBÉYÀWÓ NÁÀ TI TÓ
10. Ìgbà wo ló yẹ kí ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà wáyé?
10 Ka Ìṣípayá 19:7. Ìgbà wo ló yẹ kí ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà wáyé? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ‘aya Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ti múra sílẹ̀’ fún ìgbéyàwó, àlàyé nípa bí ìgbéyàwó náà ṣe wáyé kọ́ ló wà nínú àwọn ẹsẹ tó tẹ̀ lé e. Kàkà bẹ́ẹ̀, àlàyé tó ṣe kedere nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn ìpọ́njú ńlá ló wà nínú àwọn ẹsẹ náà. (Ìṣí 19:11-21) Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé ìgbéyàwó yìí wáyé kó tó di pé Ọba tó jẹ́ Ọkọ Ìyàwó náà parí ìṣẹ́gun rẹ̀ ni? Rárá o. Bíbélì ò to àwọn ìran tó wà nínú ìwé Ìṣípayá tẹ̀ léra bí wọ́n ṣe wáyé. Ìwé Sáàmù 45 sọ pé ìgbéyàwó tó jẹ́ ti ìdílé ọba náà wáyé lẹ́yìn tí Jésù Kristi Ọba sán idà rẹ̀ tó sì “tẹ̀ síwájú dé àṣeyọrí sí rere” nínú ogun tó bá àwọn ọ̀tá rẹ̀ jà.—Sm. 45:3, 4.
11. Tá a bá ní ká tò ó ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, ìgbà wo ni Kristi máa parí ìṣẹ́gun rẹ̀?
11 A lè wá parí èrò sí pé bí àwọn nǹkan ṣe máa wáyé tẹ̀ léra rèé: Lákọ̀ọ́kọ́, a óò mú ìdájọ́ ṣẹ sórí “aṣẹ́wó ńlá” náà, ìyẹn Bábílónì Ńlá, tí í ṣe ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé. (Ìṣí. 17:1, 5, 16, 17; 19:1, 2) Lẹ́yìn náà, Kristi máa jáde lọ kó lè mú ìdájọ́ Ọlọ́run ṣẹ sórí ìyókù ètò búburú Sátánì nígbà tó bá pa á run ní Amágẹ́dọ́nì, ìyẹn “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.” (Ìṣí. 16:14-16; 19:19-21) Níkẹyìn, Ọba Ajagun náà máa parí ìṣẹ́gun rẹ̀ nípa jíju Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, wọ́n á wá dà bí òkú tí kò lè ṣe ohunkóhun.—Ìṣí 20:1-3.
12, 13. (a) Ìgbà wo ni ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn máa wáyé? (b) Àwọn wo ló máa yọ̀ lọ́run nígbà ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà?
12 Bí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró bá ti ń parí iṣẹ́ wọn lórí ilẹ̀ ayé nígbà wíwàníhìn-ín Kristi la ó máa jí wọn dìde sí ọ̀run. Lákòókò kan lẹ́yìn ìparun Bábílónì Ńlá, Jésù máa kó gbogbo àwọn tó ṣẹ́ kù lára ẹgbẹ́ ìyàwó náà jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀. (1 Tẹs. 4:16, 17) Torí náà, kí ogun Amágẹ́dọ́nì tó bẹ̀rẹ̀, gbogbo àwọn tó wà lára “ìyàwó” náà yóò ti wà ní ọ̀run. Lẹ́yìn ogun yẹn, ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà lè wá wáyé. Ẹ sì wo bí ìgbéyàwó yẹn ṣe máa lárinrin tó! Ìwé Ìṣípayá 19:9 sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí a ké sí wá síbi oúnjẹ alẹ́ ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” Kò sí àní-àní pé àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ́ ìyàwó náà máa láyọ̀. Bákan náà, inú Ọba tó jẹ́ Ọkọ Ìyàwó yìí máa dùn gan-an tí gbogbo àwọn amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ bá ‘ń jẹ, tí wọ́n sì ń mu’ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ‘nídìí tábìlì rẹ̀ nínú ìjọba rẹ̀.’ (Lúùkù 22:18, 28-30) Àmọ́ o, kì í ṣe Ọkọ Ìyàwó àti ìyàwó rẹ̀ nìkan ni wọ́n máa láyọ̀ nígbà tí ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà bá wáyé.
13 Bá a ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ogunlọ́gọ̀ àwọn áńgẹ́lì tí ń bẹ lọ́run jùmọ̀ kọrin pé: “Ẹ jẹ́ kí a yọ̀, kí a sì láyọ̀ púpọ̀, ẹ sì jẹ́ kí a fi ògo fún [Jèhófà], nítorí ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn ti dé, aya rẹ̀ sì ti múra sílẹ̀.” (Ìṣí. 19:6, 7) Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé ńkọ́? Ṣé àwọn náà máa bá wọn yọ ayọ̀ ìgbéyàwó náà?
‘A ÓÒ MÚ WỌN WÁ PẸ̀LÚ AYỌ̀ YÍYỌ̀’
14. Gẹ́gẹ́ bí Sáàmù 45 ṣe sọ, àwọn wo ni ‘wúńdíá alábàákẹ́gbẹ́’ ìyàwó náà?
14 Ka Sáàmù 45:12, 14b, 15. Wòlíì Sekaráyà sọ tẹ́lẹ̀ pé ní àkókò òpin, inú àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè á dùn láti máa sìn Jèhófà pẹ̀lú àwọn àṣẹ́kù Ísírẹ́lì tẹ̀mí. Ó sọ pé: “Ní ọjọ́ wọnnì . . . ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè yóò dì í mú, bẹ́ẹ̀ ni, ní ti tòótọ́, wọn yóò di ibi gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ ọkùnrin kan tí ó jẹ́ Júù mú, pé: ‘Àwa yóò bá yín lọ, nítorí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.’” (Sek. 8:23) Àwọn “ọkùnrin mẹ́wàá” ìṣàpẹẹrẹ yìí ni Sáàmù 45:12 pè ní “ọmọbìnrin Tírè” àti “àwọn ọlọ́rọ̀ lára àwọn ènìyàn.” Wọ́n wá fún àṣẹ́kù ẹni àmì òróró ní ẹ̀bùn ‘kí wọ́n lè rí ojú rere wọn’ kí wọ́n sì gba ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí. Láti ọdún 1935, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ti jẹ́ kí àṣẹ́kù náà ‘mú wọn wá sí òdodo.’ (Dán. 12:3) Àwọn alábàákẹ́gbẹ́ tí wọ́n dúró ṣinṣin ti àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró yìí ti ṣe àtúnṣe tó yẹ nígbèésí ayé wọn, wọ́n sì ti di wúńdíá nípa tẹ̀mí. ‘Àwọn wúńdíá alábàákẹ́gbẹ́’ ìyàwó yìí ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, wọ́n sì ti fi hàn pé àwọn jẹ́ adúróṣinṣin lábẹ́ Ọba tó jẹ́ Ọkọ Ìyàwó náà.
15. Báwo ni ‘àwọn wúńdíá alábàákẹ́gbẹ́’ yìí ṣe ń bá àwọn tó ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé lára ẹgbẹ́ ìyàwó náà ṣiṣẹ́ pọ̀?
15 Àṣẹ́kù ẹgbẹ́ ìyàwó yìí mọrírì rẹ̀ gan-an pé ‘àwọn wúńdíá alábàákẹ́gbẹ́’ yìí ń fi ìtara ràn wọ́n lọ́wọ́ lẹ́nu wíwàásù “ìhìn rere ìjọba” Ọlọ́run jákèjádò ilẹ̀ ayé. (Mát. 24:14) Kì í wulẹ̀ ṣe pé “ẹ̀mí àti ìyàwó ń bá a nìṣó ní sísọ pé, ‘Máa bọ̀!’” nìkan ni, ṣùgbọ́n àwọn tó ń gbọ́ náà ń sọ pé, “Máa bọ̀!” (Ìṣí. 22:17) “Àwọn àgùntàn mìíràn” gbọ́ tí ẹgbẹ́ ìyàwó tá a fòróró yàn ń sọ pé “Máa bọ̀!” àwọn náà sì ti dara pọ̀ mọ́ ìyàwó náà láti máa ké sí àwọn tó ń gbé lórí ilẹ̀ ayé pé “Máa bọ̀!”—Jòh. 10:16.
16. Àǹfààní wo ni Jèhófà ti fi jíǹkí àwọn àgùntàn mìíràn?
16 Àṣẹ́kù ẹni àmì òróró fẹ́ràn àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn, inú wọn sì dùn bí wọ́n ṣe mọ̀ pé Jèhófà tó jẹ́ Bàbá Ọkọ Ìyàwó ti fún àwọn àgùntàn mìíràn tó wà lórí ilẹ̀ ayé yìí ní àǹfààní láti bá wọn yọ ayọ̀ ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn tó máa wáyé lókè ọ̀run. Bíbélì ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ‘àwọn wúńdíá alábàákẹ́gbẹ́’ yìí ni “a óò mú . . . wá pẹ̀lú ayọ̀ yíyọ̀ àti ìdùnnú.” Nígbà tí ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà bá wáyé lọ́run, ó dájú pé àwọn àgùntàn mìíràn tí wọ́n nírètí láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé, máa bá wọn yọ ayọ̀ ìgbéyàwó náà. Ó bá a mu nígbà náà pé ìwé Ìṣípayá ṣàpèjúwe “ogunlọ́gọ̀ ńlá” náà pé “wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” Wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì tẹ̀mí rẹ̀.—Ìṣí. 7:9, 15.
‘ÀWỌN ỌMỌKÙNRIN RẸ YÓÒ WÀ NÍPÒ ÀWỌN BABA ŃLÁ RẸ’
17, 18. Báwo ni ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ṣe máa méso jáde? Àwọn wo ni Kristi máa di baba fún nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso rẹ̀?
17 Ka Sáàmù 45:16. Àwọn ‘wúńdíá tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́’ ìyàwó Kristi máa rí ohun táá tún mú kí wọ́n máa yọ̀ nígbà tí ìgbéyàwó náà bá méso jáde nínú ayé tuntun. Ọba tó jẹ́ Ọkọ Ìyàwó náà máa darí àfiyèsí rẹ̀ sí ilẹ̀ ayé, ó máa jí àwọn tó jẹ́ “baba ńlá” rẹ̀ nígbà tó wà láyé dìde, wọ́n á sì wá di “ọmọkùnrin” rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. (Jòh. 5:25-29; Héb. 11:35) Lára wọn ló máa yàn ṣe “olórí” tàbí àwọn ọmọ aládé, “ní gbogbo ilẹ̀ ayé.” Kò sí iyè méjì pé Kristi máa yan àwọn kan nínú àwọn alàgbà tó jẹ́ adúróṣinṣin lóde òní kí wọ́n lè máa múpò iwájú nínú ayé tuntun.—Aísá. 32:1.
18 Kristi tún máa di baba fún àwọn mìíràn nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso rẹ̀. Ká sòótọ́, ohun tó máa jẹ́ kí gbogbo àwọn tó ń gbé láyé nígbà yẹn jogún ìyè àìnípẹ̀kun ni pé kí wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù. (Jòh. 3:16) Jésù á wa tipa bẹ́ẹ̀ di “Baba Ayérayé” fún wọn.—Aísá. 9:6, 7.
WỌ́N Ń ‘MẸ́NU KAN ORÚKỌ RẸ̀’
19, 20. Báwo ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ amóríyá tí Sáàmù 45 sọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe kan gbogbo Kristẹni tòótọ́ lónìí?
19 Ka Sáàmù 45:1, 17. Ó ṣe kedere pé gbogbo àwa Kristẹni pátá ni àwọn ohun tó wà nínú Sáàmù 45 kàn. Inú àwọn ẹni àmì òróró tó ṣẹ́ kù lórí ilẹ̀ ayé ń dùn gan-an bí wọ́n ṣe ń retí pé wọ́n máa dara pọ̀ mọ́ àwọn arákùnrin wọn àti Ọkọ wọn láìpẹ́. Àwọn àgùntàn mìíràn náà wá túbọ̀ ń fi ara wọn sábẹ́ Ọba wọn ológo, wọ́n sì mọrírì àǹfààní tí wọ́n ní láti máa bá ìyókù lára ìyàwó Ọba náà kẹ́gbẹ́ ní báyìí tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé. Lẹ́yìn ìgbéyàwó wọn, Kristi àtàwọn tó ń bá a ṣèjọba máa bù kún àwọn olùgbé ayé lọ́pọ̀ yanturu.—Ìṣí. 7:17; 21:1-4.
20 Bá a ṣe ń fojú sọ́nà fún ìmúṣẹ “ọ̀ràn kan tí ó jọjú” nípa Mèsáyà Ọba yìí, ǹjẹ́ kò wù wá pé ká máa bá a nìṣó láti ‘mẹ́nu kan orúkọ rẹ̀’? Àdúrà wa ni pé ká wà lára àwọn tí yóò máa ‘gbé Ọba náà lárugẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.’