Orin 138
Jèhófà Ni Orúkọ Rẹ
Bíi Ti Orí Ìwé
Ọlọ́run alààyè—
Ọlọ́run ohun gbogbo
Láti ìran dé ìran—
Jèhófà loókọ rẹ.
O dá wa lọ́lá gan-an
A ń yọ̀ p’a jẹ́ èèyàn rẹ.
À ń kéde ògo rẹ fún,
Ẹ̀yà orílẹ̀èdè.
(ÈGBÈ)
Jèhófà, Jèhófà,
Kò s’Ọlọ́run bí ‘rẹ.
Kò sẹ́lòmíì lọ́run bí ‘rẹ
Tàbí láyé níbí.
Ìwọ ni Olódùmarè,
Aráyé gbọ́dọ̀ mọ̀.
Jèhófà, Jèhófà,
Ìwọ nìkan l’Ọlọ́run wa.
Ìwọ mú kí a di
Ohunkóhun tí o fẹ́,
Ka lè ṣohun tí o fẹ́—
Jèhófà loókọ rẹ.
Nítorí àánú rẹ
O pè wá l’Ẹ́lẹ́rìí rẹ.
O dá wa lọ́lá torí—
À ń jẹ́ orúkọ rẹ.
(ÈGBÈ)
Jèhófà, Jèhófà,
Kò s’Ọlọ́run bí ‘rẹ.
Kò sẹ́lòmíì lọ́run bí ‘rẹ
Tàbí láyé níbí.
Ìwọ ni Olódùmarè,
Aráyé gbọ́dọ̀ mọ̀.
Jèhófà, Jèhófà,
Ìwọ nìkan l’Ọlọ́run wa.
(Tún wo 2 Kíró. 6:14; Sm. 72:19; Aísá. 42:8.)