Orin 125
Fífi Ìdúróṣinṣin Tẹrí Ba fún Ìṣàkóso Ọlọ́run
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Báwọn èèyàn Jáà ṣe ńkéde òtítọ́
Ìjọba iyebíye kárí ayé,
Wọ́n gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sétò Ọlọ́run,
Kí wọ́n dúró ṣinṣin pẹ̀lú ìṣọ̀kan.
(ÈGBÈ)
Jẹ́ kíṣòtítọ́ mú ọ tẹrí ba,
Èyí yẹ Ọlọ́run.
Ó ńdáàbò bò wá nínú ìfẹ́ rẹ̀,
Jẹ́ ká dúró ṣinṣin síi.
2. Ọlọ́run pèsè ìríjú àtẹ̀mí.
Wọ̀nyí yóò máa tọ́ wa lọ́nà òtítọ́.
Ǹjẹ́ ká dúró ṣinṣin, ká wu Ọlọ́run,
Ká fòótọ́ kéde òfin rẹ̀ ọlọ́gbọ́n!
(ÈGBÈ)
Jẹ́ kíṣòtítọ́ mú ọ tẹrí ba,
Èyí yẹ Ọlọ́run.
Ó ńdáàbò bò wá nínú ìfẹ́ rẹ̀,
Jẹ́ ká dúró ṣinṣin síi.
(Tún wo Lúùkù 12:42; Héb. 13:7, 17.)