ORIN 125
“Aláyọ̀ Ni Àwọn Aláàánú”
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Aláàánú ni Ọlọ́run wa,
Ó ń yọ́nú síni látọkàn,
Ó nífẹ̀ẹ́ láti máa ṣoore;
Kì í fi ohun tá a fẹ́ dù wá.
Ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá yí pa dà
Mọ̀ pé Ó máa yọ́nú sáwọn.
Tor’ó mọ̀ páláìpé ni wá,
Olóore ni, olóòótọ́ ni.
2. Bàbá, gbọ́ igbe ẹ̀bẹ̀ wa;
Ẹ̀ṣẹ̀ mú ọkàn wa gbọgbẹ́.
K’Ọ́lọ́run lè dárí jì wá,
Kristi kọ́ wa lóhun tá ó ṣe:
Pé ká bẹ̀bẹ̀ fún àánú rẹ̀,
Ká sì lẹ́mìí ìdáríjì.
Tá a kò bá dira wa sínú,
A ó máa ní ìbàlẹ̀ ọkàn.
3. Ká jẹ́ ẹlẹ́mìí ọ̀làwọ́,
Kí àánú jẹ́ ká máa fúnni,
Kì í ṣe lọ́nà ṣekárími;
Ìyẹn máa jẹ́ ká lè láyọ̀.
Ọlọ́run ń rí wa kedere,
Yóò san wá lẹ́san ní gbangba.
Aláyọ̀ làwọn aláàánú;
Wọ́n lẹ́wà lójú Ọlọ́run.
(Tún wo Mát. 6:2-4, 12-14.)