ORIN 117
Ìwà Rere
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Jèhófà, Ẹniire ni ọ́;
Adúróṣinṣin ni ọ́.
Ìgbà gbogbo lò ń bù kún wa;
Gbogbo ọ̀nà rẹ ló dáa.
O máa ń fojúure hàn sí wa
Bí a tiẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀.
Ìwọ nìkan lògo tọ́ sí;
Aó máa fayọ̀ jọ́sìn rẹ.
2. Àwa tá a jẹ́ ènìyàn rẹ
Ńfara wé inúure rẹ.
Ó máa ń hàn nínú ìwà wa
Àtiṣẹ́ ‘wàásù tá à ńṣe.
Ẹ̀kọ́ rẹ ń ṣe wá láǹfààní,
Ó ń sèso kárí ayé.
Jọ̀ọ́, fún wa lẹ́mìí mímọ́ rẹ
Ká lè máa hùwà rere.
3. Jọ̀wọ́, bù kún wa Jèhófà
Bí a ṣe ń hùwà rere
Sáwọn ará níbi gbogbo,
Lọ́kùnrin àtobìnrin.
Fi ẹ̀mí rẹ ràn wá lọ́wọ́
Ká lè máa hùwà rere
Nínú ilé, nínú ìjọ,
Ládùúgbò, níbi gbogbo.
(Tún wo Sm. 103:10; Máàkù 10:18; Gál. 5:22; Éfé. 5:9.)