ORIN 143
Tẹpá Mọ́ṣẹ́, Wà Lójúfò, Kó O sì Máa Retí
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Àmì tá à ń rí jẹ́ ká mọ̀ pé
Jèhófà Olódùmarè
Máa sorúkọ rẹ̀ di mímọ́;
Àkókò náà kò ní yẹ̀.
(ÈGBÈ)
Tẹpá mọ́ṣẹ́, kó o sì wà lójúfò;
Máa fayọ̀ retí àkókò
Tá ó wà láàyè títí láé.
2. Ọmọ Ọlọ́run ti ṣe tán;
Àkókò tó láti ṣígun
Bo àwọn ọ̀tá tó ń gbógun,
Ìṣẹ́gun sì ti dájú.
(ÈGBÈ)
Tẹpá mọ́ṣẹ́, kó o sì wà lójúfò;
Máa fayọ̀ retí àkókò
Tá ó wà láàyè títí láé.
3. Ìrora ti pọ̀ jù láyé,
A mọ̀ pé ìtura dé tán.
Ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé;
A máa fìgbàgbọ́ dúró.
(ÈGBÈ)
Tẹpá mọ́ṣẹ́, kó o sì wà lójúfò;
Máa fayọ̀ retí àkókò
Tá ó wà láàyè títí láé.
(Tún wo Mát. 25:13; Lúùkù 12:36.)