-
Títọ́ Àwọn Ọmọlúwàbí Dàgbà Ó Ha Ṣì Ṣeé Ṣe Bí?Ilé Ìṣọ́—1997 | October 15
-
-
Títọ́ Àwọn Ọmọlúwàbí Dàgbà Ó Ha Ṣì Ṣeé Ṣe Bí?
ROBERT Glossop ti Àjọ Tí Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Ìdílé ti Vanier ní Ottawa, Kánádà, sọ pé: “A ń gbé nínú àwùjọ kan tí ó díjú gidigidi, àwùjọ kan tí ó yàtọ̀ pátápátá, níbi ti ìlànà ìwà híhù kò ti ṣọ̀kan.” Kí ni ó yọrí sí? Ìròyìn kan nínú ìwé agbéròyìnjáde The Toronto Star sọ pé: “Oyún àwọn ọmọ tí kò tí ì pé ogún ọdún, ìwà ipá àwọn màjèṣín àti ìṣekúpara-ẹni ti àwọn ọmọ tí kò tí ì pé ogun ọdún ń peléke sí i.”
Ìṣòro náà kò mọ sí Àríwá Amẹ́ríkà nìkan. Bill Damon, olùdarí Ibùdó fún Ìdàgbàsókè Ẹ̀dá Ènìyàn ní Yunifásítì Brown ní Erékùṣù Rhode, U.S.A., ti ṣèwádìí lórí àwọn ọ̀ràn yí ní Britain àti ní àwọn orílẹ̀-èdè míràn ní Europe, àti ní Australia, Ísírẹ́lì, àti Japan. Ó tọ́ka sí bí ìtọ́sọ́nà tí ṣọ́ọ̀ṣì, ilé ẹ̀kọ́, àti àwọn àjọ mìíràn ń pèsè fún àwọn èwe ṣe ń jó rẹ̀yìn. Ó gbà gbọ́ pé àwùjọ wa “kò mọ ohun tí àwọn ọmọ nílò láti ní ìwà ọmọlúwàbí, kí wọ́n sì dáńgájíá.” Ní títọ́ka sí àwọn ògbóǹkangí nínú títọ́ ọmọ, tí wọ́n ń fi kọ́ni pé “ìbáwí léwu fún ìlera àti ire àwọn ọmọ,” Damon tẹnu mọ́ ọn pé èyí jẹ́ “ìlànà fún títọ́ àwọn alágídí àti aláìgbọràn ọmọ dàgbà.”
Kí ni ohun tí àwọn èwe òde òní nílò? Wọ́n nílò ẹ̀kọ́ onífẹ̀ẹ́ tí ń tún èrò inú àti ọkàn àyà ṣe nígbà gbogbo. Èwe ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nílò ìbáwí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Nígbà ti ìfẹ́ bá sún wa, a lè báni wí nípa bíbáni sọ̀rọ̀. Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí a fi sọ fún wa nínú Òwe 8:33 (NW) láti “fetí sí ìbáwí.” Ṣùgbọ́n, àwọn kan ń bẹ tí ‘kìkìdá ọ̀rọ̀ kò lè tọ́ sọ́nà láti mú kí wọ́n ṣàtúnṣe.’ Fún wọn, ó lè jẹ́ ìyà tí a fi jẹ wọ́n ní ìwọ̀n tí ó yẹ, tí ó tọ́ sí ìwà àìgbọràn wọn, ni ohun tí wọ́n ń fẹ́. (Òwe 17:10; 23:13, 14; 29:19, NW) Ní dídábàá yìí, kì í ṣe fífi ìbínú nani lẹ́gba tàbí líluni lálùbolẹ̀, tí ó lè dégbò sí ọmọ lára tàbí kí ó ṣe é léṣe, ni Bíbélì ń sọ. (Òwe 16:32) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ọmọ kan mọ ìdí tí a fi ń tọ́ ọ sọ́nà, kí ó sì mọ̀ pé ó jẹ́ nítorí pé òbí náà nífẹ̀ẹ́ òun.—Fi wé Hébérù 12:6, 11.
A tẹnu mọ́ irú ìmọ̀ràn Bíbélì, tí ó gbéṣẹ́, tí ó sì múná dóko bẹ́ẹ̀ nínú ìwé náà Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé.
-
-
Ìwọ Yóò Ha Fẹ́ Kí A Bẹ̀ Ọ́ Wò Bí?Ilé Ìṣọ́—1997 | October 15
-
-
Ìwọ Yóò Ha Fẹ́ Kí A Bẹ̀ Ọ́ Wò Bí?
Àní nínú ayé onídààmú yìí, ìwọ lè jèrè ayọ̀ láti inú ìmọ̀ pípéye Bíbélì nípa Ọlọ́run, Ìjọba rẹ̀, àti ète àgbàyanu rẹ̀ fún aráyé. Bí ìwọ yóò bá fẹ́ láti gba ìsọfúnni síwájú sí i tàbí kí ẹnì kan kàn sí ọ nílé láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú rẹ lọ́fẹ̀ẹ́, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó ṣe wẹ́kú nínú èyí tí a tò sí ojú ìwé 2.
-