Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé Jèhófà kò ní “jẹ́ kí a dẹ yín wò ré kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra.” (1 Kọ́r. 10:13) Ṣé èyí túmọ̀ sí pé Jèhófà ti kọ́kọ́ máa ń díwọ̀n ohun tá a lè mú mọ́ra kó tó wá pinnu irú àdánwò táá jẹ́ kó dé bá wa?
Tó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, ẹ jẹ́ ká wo ohun tó lè mú kéèyàn rò. Arákùnrin kan tí ọmọ rẹ̀ ṣekú para rẹ̀ béèrè pé: ‘Ṣé Jèhófà ti kọ́kọ́ díwọ̀n bóyá èmi àtìyàwó mi á lè mú ikú ọmọ wa mọ́ra kó tó wá gbà kọ́mọ náà ṣekú para rẹ̀ ni? Ṣé torí pé Jèhófà ti pinnu pé àá lè fara dà á ló fi jẹ́ kó ṣẹlẹ̀?’ Ǹjẹ́ ẹ̀rí wà pé Jèhófà máa ń darí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa lọ́nà bẹ́ẹ̀?
Nígbà tá a túbọ̀ ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú 1 Kọ́ríńtì 10:13, ohun tá a rí ni pé: Kò sí ẹ̀rí èyíkéyìí nínú Ìwé Mímọ́ tó fi hàn pé Jèhófà kọ́kọ́ máa ń díwọ̀n ìṣòro tàbí àdánwò tá a lè fara dà kó tó wá pinnu irú ìṣòro tàbí àdánwò tó máa jẹ́ kó dé bá wa. Ẹ jẹ́ ká jíròrò ìdí mẹ́rin tá a fi sọ bẹ́ẹ̀.
Àkọ́kọ́, Jèhófà fún àwa èèyàn ní òmìnira. Ó fún wa láǹfààní láti yan ohun tá a máa fayé wa ṣe. (Diu. 30:19, 20; Jóṣ. 24:15) Tá a bá yàn láti ṣe ohun tó tọ́, a lè bẹ Jèhófà pé kó tọ́ wa sọ́nà. (Òwe 16:9) Àmọ́ tá a bá yàn láti ṣe ohun tí kò tọ́, àwa náà la máa jìyà ohun tó bá tẹ̀yìn ẹ̀ yọ. (Gál. 6:7) Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni Jèhófà ń pinnu àdánwò tó máa dé bá wa, ṣé a lè sọ pé ó fún wa lómìnira láti ṣe ohun tó wù wá lóòótọ́?
Èkejì, Jèhófà máa ń fàyè gba “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀.” (Oníw. 9:11) Ìjàǹbá lè ṣẹlẹ̀ sẹ́nikẹ́ni torí pé onítọ̀hún rin àrìnfẹsẹ̀sí tàbí pé ó ṣe kòńgẹ́ aburú. Bí àpẹẹrẹ, Jésù mẹ́nu ba ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kan níbi tí ilé gogoro ti wó pa àwọn èèyàn méjìdínlógún [18], ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé kì í ṣe Ọlọ́run ló fà á. (Lúùkù 13:1-5) Ṣó wá bọ́gbọ́n mu láti gbà pé kí àjálù kan tó ṣẹlẹ̀ ni Ọlọ́run ti máa ń pinnu ẹni tó máa bá àjálù náà lọ àtẹni tó máa yè é?
Ẹ̀kẹta, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló máa fi hàn bóyá òun á jẹ́ olóòótọ́ tàbí òun ò ní jólóòótọ́. A ò ní gbàgbé pé Sátánì fẹ̀sùn kan gbogbo àwa tá à ń sin Jèhófà pé a ò ní jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà tí ìṣòro tàbí àdánwò bá dé bá wa. (Jóòbù 1:9-11; 2:4; Ìṣí. 12:10) Tí Jèhófà kò bá jẹ́ káwọn àdánwò kan dé bá wa torí pé ó ti díwọ̀n pé a ò ní lè fara dà á, ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ Sátánì kò ní já sóòótọ́ pé ohun tá à ń rí gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run ló jẹ́ ká máa sìn ín?
Ẹ̀kẹrin, kò di dandan kí Jèhófà mọ gbogbo nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ sí wa. Tá a bá sọ pé Jèhófà ti kọ́kọ́ máa ń pinnu àwọn àdánwò tó máa dé bá wa, ohun tá à ń sọ ni pé ó mọ gbogbo ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wa lọ́jọ́ iwájú. Àmọ́, èrò yìí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Kò sí àní-àní pé Ọ̇lọ́run lè mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. (Aísá. 46:10) Àmọ́ Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà máa ń yan ohun tó bá fẹ́ mọ̀ nípa ọjọ́ iwájú. (Jẹ́n. 18:20, 21; 22:12) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà lè mọ ọjọ́ ọ̀la wa, síbẹ̀ kì í dí wa lọ́wọ́ àtilo òmìnira tá a ní. Ǹjẹ́ kì í ṣe ohun tá a retí pé kí Ọlọ́run ṣe nìyẹn? Ó ṣe tán, kì í ṣe amúnisìn, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣi agbára tó ní lò.—Diu. 32:4; 2 Kọ́r. 3:17.
Kí wá ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: ‘Ọlọ́run kì yóò jẹ́ kí a dẹ yín wò ré kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra’? Kì í ṣe ohun tí Jèhófà ń ṣe fún wa ṣáájú àdánwò lohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ bíkòṣe ohun tó máa ń ṣe fún wa lásìkò tá à ń kojú àdánwò.a Ńṣe ni Pọ́ọ̀lù ń fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé kò sí àdánwò tó lè dé bá wa tí Jèhófà máa fi wá sílẹ̀ tá a bá ṣáà ti gbẹ́kẹ̀ lé e. (Sm. 55:22) Ẹ jẹ́ ká wo ìdí méjì tí Pọ́ọ̀lù fi sọ bẹ́ẹ̀.
Ìdí àkọ́kọ́ ni pé àwọn àdánwò tá à ń kojú jẹ́ èyí tó “wọ́pọ̀ fún àwọn ènìyàn.” Ìyẹn ni pé, àdánwò tó ń dé bá ọ̀pọ̀ èèyàn làwa náà ń kojú. Irú àwọn àdánwò tó wọ́pọ̀ yìí kì í ṣe èyí tá ò lè borí, àmọ́ a gbọ́dọ̀ gbára lé Ọlọ́run. (1 Pét. 5:8, 9) Kí Pọ́ọ̀lù tó sọ ohun tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 10:13, ó ti kọ́kọ́ mẹ́nu kan àwọn ìdẹwò tó bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nínú aginjù. (1 Kọ́r. 10:6-11) Ìdẹwò tó wọ́pọ̀ fáwa èèyàn làwọn ọmọ Ísírẹ́lì náà kojú nínú aginjù, kò sì ṣòro fáwọn olóòótọ́ lára wọn láti borí àwọn ìdẹwò náà. Àmọ́, ó yani lẹ́nu pé ẹ̀ẹ̀mẹrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Pọ́ọ̀lù sọ pé “àwọn kan nínú wọn” ṣàìgbọràn. Ó mà ṣe o, àwọn kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gba ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ láyè torí pé wọn ò gbára lé Ọlọ́run.
Ìdí kejì ni pé “Ọlọ́run jẹ́ olùṣòtítọ́.” Àkọsílẹ̀ bí Jèhófà ṣe ń bójú tó àwọn èèyàn rẹ̀ látọdúnmọ́dún jẹ́ ká mọ̀ pé ó máa ń fìfẹ́ dúró ti “àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti àwọn tí ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.” (Diu. 7:9) Àkọsílẹ̀ yẹn tún fi hàn pé ìgbà gbogbo ni Ọlọ́run máa ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. (Jóṣ. 23:14) Torí pé Jèhófà jẹ́ olóòótọ́, àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ rẹ̀ lè fọkàn tán ìlérí tó ṣe. Ohun méjì ni Jèhófà ṣèlérí pé òun máa ṣe fún wa tí àdánwò bá dé bá wa: (1) Kò ní jẹ́ kí àdánwò náà le débi pé a ò ní lè fara dà á, àti pé (2) “yóò . . . ṣe ọ̀nà àbájáde” fún wa.
Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń ṣe ọ̀nà àbájáde fún àwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé e nígbà ìṣòro? Ohun kan ni pé ó lè mú ìṣòro tàbí àdánwò kúrò tó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ká rántí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ pé, Jèhófà “yóò tún ṣe ọ̀nà àbájáde kí ẹ lè fara dà á.” Lọ́pọ̀ ìgbà, Jèhófà máa ń ṣe “ọ̀nà àbájáde” ní ti pé ó máa ń pèsè ohun tá a nílò ká lè fara da àdánwò náà láìbọ́hùn. Ẹ jẹ́ ká jíròrò mélòó kan lára àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀:
Ó máa “ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.” (2 Kọ́r. 1:3, 4) Jèhófà máa ń lo Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àtàwọn ìtẹ̀jáde tí ẹrú olóòótọ́ ń pèsè láti mú kí ọkàn wa balẹ̀, kára sì tù wá.—Mát. 24:45; Jòh. 14:16; Róòmù 15:4.
Ó lè fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ darí wa. (Jòh. 14:26) Nígbà ìṣòro, ẹ̀mí Ọlọ́run lè mú ká rántí àwọn àkọsílẹ̀ kan nínú Bíbélì tàbí àwọn ìlànà kan táá jẹ́ ká lè ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu.
Ó lè lo àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́.—Héb. 1:14.
Ó lè lo àwọn ará wa láti ràn wá lọ́wọ́. Wọ́n lè sọ̀rọ̀ ìtùnú fún wa tàbí kí wọ́n ṣe ohun táá fún wa lókun.—Kól. 4:11.
Níbi tá a bọ́rọ̀ dé yìí, kí wá lohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ nínú 1 Kọ́ríńtì 10:13? Jèhófà kì í yan àwọn àdánwò tó máa dé bá wa. Àmọ́ tí ìṣòro tàbí àdánwò bá dé bá wa, ohun tó dájú ni pé: Tá a bá gbára lé Jèhófà pátápátá, kò ní jẹ́ kí àdánwò náà kọjá agbára wa. Yàtọ̀ síyẹn, yóò ṣe ọ̀nà àbájáde fún wa ká lè fara dà á. Ẹ ò rí i pé èyí fini lọ́kàn balẹ̀!
a A tún lè lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “ìdẹwò” nínú ẹsẹ yìí fún àdánwò tàbí ìṣòro.