ORÍ 20
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tá A Fi Ń Ṣe Ìrànwọ́
1, 2. (a) Ìṣòro wo ni àwọn Kristẹni tó ń gbé ní Jùdíà ní? (b) Kí ni ìfẹ́ sún àwọn ará ní Áńtíókù láti ṣe fún àwọn tí ìṣòro bá yìí?
NÍ NǸKAN bí ọdún 46 Sànmánì Kristẹni, ìyàn mú gan-an nílẹ̀ Jùdíà. Oúnjẹ ò tó nǹkan, ìwọ̀nba tó sì wà gbówó lórí débi pé àwọn Júù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi pàápàá ò fi bẹ́ẹ̀ rówó rà á. Ebi fẹ́rẹ̀ẹ́ lè yọ ojú wọn! Àṣé wọ́n máa tó rọ́wọ́ Jèhófà lára wọn ní irú ọ̀nà tí kò ṣẹlẹ̀ sí èyíkéyìí lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi rí. Kí ló wá ṣẹlẹ̀?
2 Nígbà tí àwọn Júù àtàwọn Kèfèrí tó di Kristẹni, tó wà nílùú Áńtíókù nílẹ̀ Síríà gbọ́ bí ìyà ṣe ń jẹ àwọn Júù tó di Kristẹni ní Jerúsálẹ́mù àti Jùdíà, ni wọ́n bá dá oríṣiríṣi nǹkan jọ tí wọ́n fẹ́ fi ràn wọ́n lọ́wọ́. Lẹ́yìn náà, wọ́n yan àwọn àgbà ọkùnrin méjì, ìyẹn Bánábà àti Sọ́ọ̀lù pé kí wọ́n gbé àwọn nǹkan wọ̀nyí lọ sọ́dọ̀ àwọn alàgbà ìjọ tó wà ní Jerúsálẹ́mù. (Ka Ìṣe 11:27-30; 12:25.) Ẹ wo bí inú àwọn ará tó wà ní Jùdíà yẹn ṣe máa dùn tó nígbà táwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn ní Áńtíókù dìde ìrànwọ́! Bóyá ni wọ́n tíì rí irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ rí!
3. (a) Báwo ni àwọn èèyàn Ọlọ́run lóde òní ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn ará Áńtíókù ìgbàanì? Sọ àpẹẹrẹ kan. (Tún wo àpótí náà, “Ètò Ìrànwọ́ Àkọ́kọ́ Tó Kárí Ayé Lóde Òní.”) (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò nínú orí yìí?
3 Ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni yìí ni àkọ́kọ́ irú rẹ̀ tí àwọn ará máa fi nǹkan ìrànwọ́ ránṣẹ́ sí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn tí wọ́n nílò ìrànwọ́ lórílẹ̀-èdè míì. Àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni tó wà ní Áńtíókù ìgbàanì la ṣì ń tẹ̀ lé títí di òní. Nígbàkigbà tá a bá gbọ́ pé àjálù tàbí àdánwò bá àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa, ńṣe la máa ń dìde ìrànwọ́.a Ká lè mọyì bí ṣíṣe irú ìrànwọ́ bẹ́ẹ̀ ṣe tan mọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ìbéèrè mẹ́ta yẹ̀ wò nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí a fi ń ṣe ìrànwọ́: Kí nìdí tí a fi ka ṣíṣe ìrànwọ́ fún àwọn tí àjálù bá sí ara iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa? Kí nìdí tá a fi ń ṣe irú iṣẹ́ ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀? Àǹfààní wo là ń rí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ tá a fi ń ṣe ìrànwọ́?
Ìdí Tí Ṣíṣe Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù Fi Jẹ́ “Iṣẹ́ Ìsìn Ọlọ́wọ̀”
4. Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará Kọ́ríńtì nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni?
4 Nínú ìwé kejì tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì, ó ṣàlàyé fún wọn pé ọ̀nà méjì ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ àwa Kristẹni pín sí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹni àmì òróró ló darí ìwé náà sí, ọ̀rọ̀ tó sọ kan “àwọn àgùntàn mìíràn” tí Kristi sọ̀rọ̀ nípa wọn. (Jòh. 10:16) Apá àkọ́kọ́ tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa pín sí ni “iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìpadàrẹ́,” ìyẹn iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni. (2 Kọ́r. 5:18-20; 1 Tím. 2:3-6) Apá kejì jẹ mọ́ ‘iṣẹ́ òjíṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́’ tí Pọ́ọ̀lù sọ, ìyẹn iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí a fi ń ṣe ìrànwọ́ fáwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa nígbà ìṣòro. (2 Kọ́r. 8:4) Ní ti gbólóhùn méjèèjì náà “iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìpadàrẹ́” àti ‘iṣẹ́ òjíṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́,’ ọ̀rọ̀ tá a túmọ̀ sí “iṣẹ́ òjíṣẹ́” lédè Yorùbá wá látinú ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan náà, ìyẹn di·a·ko·niʹa. Kí nìdí tí ìyẹn fi ṣe pàtàkì?
5. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé Pọ́ọ̀lù pé iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù ní iṣẹ́ òjíṣẹ́?
5 Bí Pọ́ọ̀lù ṣe lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan náà yìí, ńṣe ló fi iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù wé irú àwọn iṣẹ́ òjíṣẹ́ míì tá à ń ṣe nínú ìjọ Kristẹni. Ó ti kọ́kọ́ sọ fún wọn pé: “Onírúurú iṣẹ́ òjíṣẹ́ sì ní ń bẹ, síbẹ̀ Olúwa kan náà ni ó wà; onírúurú ọ̀nà ìṣiṣẹ́ sì ní ń bẹ, . . . Ṣùgbọ́n gbogbo ọ̀nà ìṣiṣẹ́ wọ̀nyí ni ẹ̀mí kan ṣoṣo náà ń mú ṣe.” (1 Kọ́r. 12:4-6, 11) Kódà, Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ̀ pé oríṣiríṣi iṣẹ́ òjíṣẹ́ tá à ń ṣe nínú ìjọ Ọlọ́run jẹ́ “iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀.”b (Róòmù 12:1, 6-8) Abájọ tó fi kà á sí ohun pàtàkì láti yọ̀ǹda àkókò rẹ̀ kó lè fi “ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́”!—Róòmù 15:25, 26.
6. (a) Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù jẹ́ apá kan ìjọsìn wa? (b) Ṣàlàyé bí a ṣe ń ṣe iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù kárí ayé lónìí. (Wo àpótí náà, “Nígbà Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀!” lójú ìwé 214.)
6 Pọ́ọ̀lù jẹ́ kó yé àwọn ará tó wà ní Kọ́ríńtì pé iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ fáwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn nígbà ìṣòro jẹ́ ara iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti ìjọsìn wọn sí Jèhófà. Pọ́ọ̀lù gbà pé Kristẹni tó bá ń ṣèrànwọ́ fún onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ń fi hàn pé òun ní “ẹ̀mí ìtẹríba fún ìhìn rere nípa Kristi.” (2 Kọ́r. 9:13) Nítorí náà, Kristẹni tó bá ń fi ẹ̀kọ́ Kristi sílò kò ní ṣàì ṣèrànwọ́ fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Pọ́ọ̀lù tún sọ pé ohun tí àwọn ará ń ṣe yìí jẹ́ “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run títayọ ré kọjá.” (2 Kọ́r. 9:14; 1 Pét. 4:10) Tó bá di ọ̀rọ̀ ṣíṣe ìrànwọ́ fáwọn ará wa tó wà nínú ìṣòro, tó fi mọ́ iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù, Ile-Iṣọ Na June 1, 1976 sọ pé: “Àwa kò gbọ́dọ̀ ṣiyè méjì pé Jèhófà àti Jésù ka irú iṣẹ́ báyìí sí nǹkan pàtàkì.” Ó dá wa lójú ní tòótọ́ pé irú iṣẹ́ ìsìn mímọ́ kan tó ṣeyebíye ni iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù jẹ́.—Róòmù 12:1, 7; 2 Kọ́r. 8:7; Héb. 13:16.
Ìdí Tá A Fi Ń Ṣe Iṣẹ́ Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù
7, 8. Kí nìdí àkọ́kọ́ tá a fi ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí a fi ń ṣe ìrànwọ́ nígbà ìṣòro? Ṣàlàyé.
7 Kí nìdí tá a fi ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ tá a fi ń ṣe ìrànwọ́ fáwọn tí àjálù bá? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dáhùn ìbéèrè yìí nínú ìwé kejì tó kọ sí àwọn ará ní Kọ́ríńtì. (Ka 2 Kọ́ríńtì 9:11-15.) Nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn, Pọ́ọ̀lù sọ ìdí pàtàkì mẹ́ta tá a fi ń ṣe “iṣẹ́ òjíṣẹ́ iṣẹ́ ìsìn fún gbogbo ènìyàn yìí,” ìyẹn, iṣẹ́ ìrànwọ́ nígbà àjálù. Ní báyìí, a fẹ́ gbé ìdí mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yẹ̀ wò lọ́kọ̀ọ̀kan.
8 Àkọ́kọ́, iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí a fi ń ṣe ìrànwọ́ nígbà ìṣòro ń yin Jèhófà lógo. Ẹ kíyè sí pé nínú ẹsẹ Bíbélì márààrún tá a kà yẹn, ọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run ni Pọ́ọ̀lù darí àfiyèsí àwọn ará sí. Ó rán wọn létí nípa ‘ìfọpẹ́hàn fún Ọlọ́run’ àti “ọ̀pọ̀ ìfọpẹ́hàn fún Ọlọ́run.” (Ẹsẹ 11 àti 12) Ó tún sọ bí iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù yìí ṣe máa ń sún àwọn Kristẹni láti “yin Ọlọ́run lógo” kí wọ́n sì tún yìn ín nítorí “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí” rẹ̀ “títayọ ré kọjá.” (Ẹsẹ 13 àti 14) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ lórí iṣẹ́ òjíṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́ náà, ìyẹn iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí a fi ń ṣe ìrànwọ́ fáwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa nígbà ìṣòro, ó sọ pé: “Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run.”—Ẹsẹ 15; 1 Pét. 4:11.
9. Irú àyípadà wo ni iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù tá à ń ṣe lè mú bá èrò àwọn èèyàn? Sọ àpẹẹrẹ kan.
9 Bíi ti Pọ́ọ̀lù, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí ka ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù sí àǹfààní láti yin Jèhófà lógo àti ọ̀nà kan láti fi hàn pé àwọn ń fi ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò. (1 Kọ́r. 10:31; Títù 2:10) Kódà, iṣẹ́ ìrànwọ́ yìí máa ń jẹ́ kí àwọn tó ti ní èrò òdì nípa Jèhófà àti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, yí èrò wọn pa dà. Bí àpẹẹrẹ: Obìnrin kan tó ń gbé níbì tí ìjì líle ti jà so àkọlé kan mọ́ ẹnu ọ̀nà rẹ̀ pé: “Mí Ò Fẹ́ Rí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Níbí.” Nígbà tó yá, ó rí àwọn ará wa tó ń ṣèrànwọ́ fáwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn tí àjálù ba ilé wọn jẹ́. Obìnrin náà kíyè sí pé tẹ̀rín-tọ̀yàyà ni wọ́n fi ń ṣe iṣẹ́ náà. Ló bá tọ̀ wọ́n lọ, kó lè mọ bí wọ́n ṣe jẹ́. Ó yà á lẹ́nu nígbà tó rí i pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n, ó wá sọ pé “ọ̀tọ̀ ni ohun tí mo máa ń rò nípa yín tẹ́lẹ̀.” Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Ńṣe ló gbé àkọlé tó wà lára ìlẹ̀kùn rẹ̀ kúrò.
10, 11. (a) Kí ni ìdí kejì tá a fi ń ṣe iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù, àwọn àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé à ń ṣe bẹ́ẹ̀? (b) Ìwé wo ni a ti pèsè láti ran àwọn tó ń ṣèrànwọ́ nígbà àjálù lọ́wọ́? (Wo àpótí náà, “Ìwé Kan Tó Wà Fáwọn Tó Ń Ṣe Iṣẹ́ Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù.”)
10 Ìkejì, a ń “pèsè lọ́pọ̀ yanturu” fún àìní àwọn ará wa. (2 Kọ́r. 9:12a) Tí àwọn ará wa bá wà nínú ìṣòro, ńṣe ni a máa ń múra tán láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Ìdí ni pé “ara kan ṣoṣo” ni gbogbo wá jẹ́ nínú ìjọ Ọlọ́run, “bí ẹ̀yà ara kan bá sì ń jìyà, gbogbo ẹ̀yà ara yòókù a bá a jìyà.” (1 Kọ́r. 12:20, 26) Torí náà, ìfẹ́ni ará àti àánú ló ń sún àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin wa láti fi ohun tí wọ́n ń ṣe sílẹ̀, tí wọ́n á sì kọrí síbi tí àjálù ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn kí wọ́n lè lọ ràn wọ́n lọ́wọ́ níbẹ̀. (Ják. 2:15, 16) Àpẹẹrẹ kan ni ti àkúnya omi tí wọ́n ń pè ní sùnámì tó wáyé ní Japan lọ́dún 2011. Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kọ lẹ́tà sí àwọn Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn tó wà ní Amẹ́ríkà pé àwọn fẹ́ kí “àwọn arákùnrin díẹ̀ tó mọṣẹ́” yọ̀ǹda láti bá wọn tún àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba kọ́ níbi tí àjálù náà ti wáyé. Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Láàárín ọ̀sẹ̀ mélòó kan, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [600] èèyàn ló ti yọ̀ǹda ara wọn, wọ́n sì múra tán láti wọkọ̀ òfuurufú lọ sí Japan kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ níbẹ̀. Èyí tó yani lẹ́nu ni pé owó ara wọn ni wọ́n fi wọkọ̀ lọ. Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Ohun tí àwọn ará ṣe yìí wú wa lórí gan-an.” Nígbà tí arákùnrin kan ní Japan tiẹ̀ bi ọ̀kan lára àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti ilẹ̀ òkèèrè yẹn pé kí nìdí tó fi wá ṣèrànwọ́. Ó sọ pé: “‘Ara wa’ ni àwọn ará Japan jẹ́. Ohun tó bá sì dé bá ojú ti dé bá imú náà nìyẹn.” Irú ẹ̀mí ìfara-ẹni-jìn yìí ló mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ará fi ẹ̀mí wọn wewu kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn tí àjálù bá.c—1 Jòh. 3:16.
11 Kì í ṣe àwa nìkan ni orí wa máa ń wú tá a bá rí nǹkan bẹ́ẹ̀, àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí pàápàá ti fi ìmọrírì hàn fún iṣẹ́ ìrànwọ́ tá à ń ṣe. Àpẹẹrẹ kan ni ti àjálù tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 2013, ní ìpínlẹ̀ Arkansas, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ìwé ìròyìn kan níbẹ̀ gbóríyìn fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún bí wọ́n ṣe tètè gbé ìgbésẹ̀, ó ní: “Ètò tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe láti ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù bá wúni lórí gan-an.” Abájọ tí ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi bá a mu wẹ́kú pé, à ń “pèsè lọ́pọ̀ yanturu” fún àìní àwọn ará wa.
12-14. (a) Kí ni ìdí kẹta tó fi ṣe pàtàkì láti máa pèsè ìrànwọ́ fún àwọn tí àjálù bá? (b) Kí ni àwọn kan ti sọ tó fi hàn pé ó ṣe pàtàkì kí a máa bá àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí wa nìṣó?
12 Ìkẹta, iṣẹ́ ìrànwọ́ tá à ń ṣe ń jẹ́ kí àwọn tí àjálù bá lè tètè pa dà sẹ́nu ìjọsìn wọn. Kí nìdí tí èyí fi ṣe pàtàkì? Ṣé ẹ rántí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ pé tí a bá ṣèrànwọ́ fáwọn èèyàn, ó máa ń mú kí wọ́n “fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run lọ́pọ̀lọpọ̀.” (2 Kọ́r. 9:12b) Torí náà, ọ̀nà kan tó dara jù tí àwọn tí àjálù bá lè gbà fi ọpẹ́ hàn fún ìrànwọ́ tí wọ́n rí gbà ni pé kí wọ́n tètè pa dà sẹ́nu ìjọsìn wọn sí Jèhófà. (Fílí. 1:10) Lọ́dún 1945, Ilé Ìṣọ́ kan sọ pé: ‘Pọ́ọ̀lù fọwọ́ sí i . . . pé kí wọ́n gba àwọn nǹkan tí wọ́n fẹ́ fi ṣèrànwọ́ jọ torí pé ó wúlò . . . fún àwọn Kristẹni tó ṣe aláìní kí wọ́n lè túbọ̀ ráyè láti lo gbogbo agbára wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù nípa Jèhófà.’ Ohun tí àwa náà ń ṣe lónìí nìyẹn. Kété tá a bá ti pa dà sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù báyìí, àtàwa àtàwọn tí àjálù bá la jọ ń gbé ara wa ró.—Ka 2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.
13 Lẹ́yìn tí àwọn tí àjálù bá rí ìrànwọ́ gbà, wọ́n pa dà sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Wọn sọ díẹ̀ lára àǹfààní tí wọ́n rí nínú wíwàásù lákòókò náà. Arákùnrin kan sọ pé: “Ìbùkún ńlá ló jẹ́ fún ìdílé wa pé a lè máa bá iṣẹ́ ìwàásù wa nìṣó. Bá a ṣe ń tu àwọn ẹlòmíì nínú kì í jẹ́ ká ronú nípa àwọn àníyàn tiwa.” Arábìnrin kan ní tiẹ̀ sọ pé: “Bí mo ṣe gbájú mọ́ ìgbòkègbodò tẹ̀mí kò jẹ́ kí n bọkàn jẹ́ jù lórí àwọn nǹkan tí àjálù náà bà jẹ́. Ó fi mí lọ́kàn balẹ̀ pẹ̀sẹ̀.” Arábìnrin míì tún sọ pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan tó ṣẹlẹ̀ ju agbára wa lọ, àmọ́ iṣẹ́ ìwàásù jẹ́ kí ìdílé wa rí ìtọ́sọ́nà tí a nílò. Bá a ṣe ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa ayé tuntun tá à ń retí bẹ́ẹ̀ ni àwa náà túbọ̀ ń ní ìgbọ́kànlé pé Ọlọ́run máa sọ ohun gbogbo dọ̀tun.”
14 Ohun míì tí àwọn tó rí ìrànwọ́ gbà nígbà àjálù tún gbọ́dọ̀ ṣe ni pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kó pẹ́ tí wọ́n á tún fi bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé ìjọ. Ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Kiyoko tó ti sún mọ́ ẹni ọgọ́ta ọdún [60]. Nígbà tí sùnámì wáyé níbi tó ń gbé, gbogbo ohun tó ní pátá ló pàdánù. Kìkì aṣọ àti bàtà tó wọ̀ ló kù lára rẹ̀, kò tiẹ̀ mọ nǹkan tó lè ṣe mọ́. Alàgbà kan wá sọ fún un pé inú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ òun làwọn á ti máa ṣe ìpàdé táwọn máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Arábìnrin Kiyoko sọ pé: “Alàgbà kan àti ìyàwó rẹ̀ àti àwa arábìnrin méjì la wà nínú mọ́tò náà, ibẹ̀ sì la ti ń ṣe ìpàdé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìpàdé yẹn kì í pẹ́ púpọ̀, ọkàn mi balẹ̀, ó sì yà mí lẹ́nu pé kò pẹ́ tí ìrònú àjálù náà fi kúrò lọ́kàn mi. Ìpàdé yẹn jẹ́ kí n rí bí ìpéjọpọ̀ Kristẹni ṣe lágbára tó.” Nígbà tí arábìnrin míì ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìpàdé tó lọ lẹ́yìn tí àjálù náà ṣẹlẹ̀, ó ní: “Àwọn ìpàdé náà gbé ìgbàgbọ́ mi ró.”—Róòmù 1:11, 12; 12:12.
Àǹfààní Pípẹ́ Títí Wà Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tí A Fi Ń Ṣe Ìrànwọ́
15, 16. (a) Àǹfààní wo ni àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì àti ibòmíì máa rí tí wọ́n bá tẹra mọ́ ṣíṣe ìrànwọ́ fún àwọn tí àjálù bá? (b) Báwo làwa náà ṣe ń jàǹfààní nínú iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù lónìí?
15 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ‘iṣẹ́ òjíṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́,’ ìyẹn iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí a fi ń ṣe ìrànwọ́ fáwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa nígbà ìṣòro, ó sọ àǹfààní tí àwọn ará Kọ́ríńtì àti àwọn Kristẹni mìíràn máa rí gbà bí wọ́n bá ń kópa nínú rẹ̀. Ó ní: “Pẹ̀lú ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ fún yín, aáyun yín ń yun wọ́n [ìyẹn àwọn Júù tó di Kristẹni ní Jerúsálẹ́mù, tí wọ́n rí ìrànwọ́ gbà], nítorí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run títayọ . . . wà lórí yín.” (2 Kọ́r. 9:14) Òótọ́ ni Pọ́ọ̀lù sọ torí pé ìwà ọ̀làwọ́ tí àwọn ará Kọ́ríńtì hù máa mú kí àwọn Júù tó di Kristẹni náà máa gbàdúrà fún àwọn ará wọn tó wà ní Kọ́ríńtì títí kan àwọn Kèfèrí, á sì tún mú kí ìfẹ́ tí wọ́n ní sí wọn túbọ̀ jinlẹ̀.
16 Nígbà tí Ilé Ìṣọ́ December 1, 1945 ń fi ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ ṣàlàyé àǹfààní tó wà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí a fi ń ṣe ìrànwọ́ fáwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa nígbà ìṣòro lóde òní, ó ní: ‘Nígbà táwọn tí Ọlọ́run sọ di mímọ́ bá ń ran àwọn arákùnrin wọn tó wà nínú àìní lọ́wọ́, ẹ wo bí ìrẹ́pọ̀ tó wà láàárín wọn á ṣe dùn tó!’ Bọ́rọ̀ àwọn tó ń kópa nínú iṣẹ́ ìrànwọ́ ṣe máa ń rí gan-an nìyẹn. Alàgbà kan tó lọ ṣèrànwọ́ níbi ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé sọ pé: “Bí mo ṣe ń kópa nínú iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù yìí ti jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ mi ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.” Arábìnrin kan tó ń ṣọpẹ́ torí ìrànwọ́ tó rí gbà sọ pé: “Ńṣe ni ẹgbẹ́ ará wa yìí dà bí Párádísè.”—Ka Òwe 17:17.
17. (a) Báwo ni ọ̀rọ̀ tó wà nínú Aísáyà 41:13 ṣe kan iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù? (b) Sọ àwọn ìrírí tó jẹ́ ká mọ̀ pé iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù ń gbé Jèhófà ga àti pé ó ń jẹ́ kí ìfẹ́ tó so wá pọ̀ lágbára sí i. (Tún wo àpótí náà, “Àwọn Olùyọ̀ǹda Ara Ẹni Ń Pèsè Ìrànwọ́ Jákèjádò Ayé.”)
17 Nígbà tí àwọn ará bá gbéra láti lọ ṣèrànwọ́ fáwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn tí àjálù bá, àwọn èèyàn náà máa ń rí ọwọ́ Ọlọ́run lára wọn. Ó kúkú ti ṣèlérí pé: “Èmi, Jèhófà Ọlọ́run rẹ, yóò di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, Ẹni tí ń wí fún ọ pé, ‘Má fòyà. Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.’” (Aísá. 41:13) Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí arábìnrin kan la àjálù burúkú kan já, ó sọ pé: “Nígbà tí mo rí adúrú ohun tí àjálù náà bà jẹ́, ìdààmú ọkàn bá mi, mo rò pé gbogbo rẹ̀ ti parí fún mi, àmọ́ mo rí ọwọ́ Jèhófà lára mi torí pé ìrànlọ́wọ́ táwọn ará ṣe fún mi gadabú.” Lẹ́yìn tí ìmìtìtì ilẹ̀ ba agbègbè tí ìjọ kan wà jẹ́, àwọn alàgbà méjì tó ṣojú fún ìjọ náà sọ pé: “Àdánù ńlá gbáà ni ìmìtìtì ilẹ̀ náà fà ṣùgbọ́n Jèhófà gbé ìrànlọ́wọ́ dìde nípasẹ̀ àwọn arákùnrin wa. A ti máa ń ka ìtàn nípa bí àwọn ará ṣe ń ran àwọn tí àjálù bá lọ́wọ́, àmọ́ ní báyìí, ojú wa kòró ló ṣe.”
Ìwọ Náà Lè Kópa
18. Tó o bá fẹ́ kópa nínú iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù, kí ló yẹ kó o ṣe? (Tún wo àpótí náà, “Ó Jẹ́ Kó Fi Ìgbésí Ayé Rẹ̀ Ṣe Ohun Tó Dára.”)
18 Ṣé wàá fẹ́ rí ayọ̀ tó wà nínú iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù? Tó o bá fẹ bẹ́ẹ̀, jọ̀wọ́ fi sọ́kàn pé àwọn tí wọ́n sábà máa ń yàn láti ṣe ìrànwọ́ ni àwọn tó ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Torí náà, sọ fún àwọn alàgbà ìjọ rẹ pé o fẹ́ di ara àwọn tó ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kí wọ́n lè fún ẹ ní fọ́ọ̀mù tí wàá fi bẹ̀rẹ̀. Alàgbà kan tó ti pẹ́ nínú iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù yìí sọ ohun kan tó yẹ ká fi sọ́kàn, ó ní: “Tí Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù bá ké sí ọ láti wá ni kó o tó lọ sí agbègbè náà.” Nípa bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ náà á lè lọ létòletò.
19. Báwo ni àwọn tó ń kópa nínú iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù ṣe ń fi hàn pé ọmọ ẹ̀yìn Kristi làwọn jẹ́ lóòótọ́?
19 Iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù jẹ́ ọ̀nà pàtàkì tá à ń gbà tẹ̀ lé àṣẹ Jésù pé kí a ‘nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.’ Bí a ṣe ń fìfẹ́ hàn lọ́nà yìí fi hàn pé ọmọ ẹ̀yìn Kristi la jẹ́ lóòótọ́. (Jòh. 13:34, 35) Ẹ ò rí i pé ìbùkún ló jẹ́ fún wa lónìí pé a ní àwọn tó ń fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ tó ń pèsè ìrànwọ́ fáwọn tó ń ti Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn. Èyí sì ń gbé Jèhófà Ọlọ́run ga!
a Ohun tí orí yìí dá lé ni iṣẹ́ ìrànwọ́ tá à ń ṣe fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa tí àjálù bá. Àmọ́, lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàápàá máa ń jàǹfààní nínú rẹ̀.—Gál. 6:10.
b Ọ̀rọ̀ ẹlẹ́ni púpọ̀ náà di·aʹko·nos (òjíṣẹ́), ni Pọ́ọ̀lù lò nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa “àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.”—1 Tímótì 3:12.
c Ka àpilẹ̀kọ tá a pe àkòrí rẹ̀ ní “Ṣíṣèrànwọ́ Fún Àwọn Ìdílé Onígbàgbọ́ Wa Ní Bosnia,” tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ November 1, 1994, ojú ìwé 23 sí 27.