Máa Fayọ̀ Sin Jèhófà
ṢÓ O rántí ọjọ́ tí inú ẹ dùn jù lọ? Ṣé ọjọ́ tó o ṣe ìgbéyàwó ni àbí ọjọ́ tó o bí àkọ́bí rẹ? Àbí ọjọ́ tó o ṣe ìrìbọmi? Bó bá jẹ́ ọjọ́ tó o ṣèrìbọmi, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọjọ́ yẹn ló ṣe pàtàkì jù sí ẹ, ọjọ́ yẹn ni inú ẹ sì dùn jù lọ. Wo bí inú àwọn ará ṣe dùn tó lọ́jọ́ yẹn nígbà tó o fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, èrò-inú rẹ àti gbogbo okun rẹ!—Máàkù 12:30.
Kò sí àní àní pé o ti ní ayọ̀ púpọ̀ láti ìgbà tó o ti ṣe ìrìbọmi. Àmọ́, àwọn akéde kan ti pàdánù ayọ̀ tí wọ́n ní nígbà kan rí. Kí ló fà á tí ìyẹn fi ṣẹlẹ̀? Àwọn ìdí wo la ní láti máa fi ayọ̀ sin Jèhófà nìṣó?
ÌDÍ TÍ ÀWỌN KAN FI PÀDÁNÙ AYỌ̀ TÍ WỌ́N NÍ
Ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run máa ń fún wa láyọ̀ gan-an. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jèhófà ti ṣèlérí pé Ìjọba náà máa tó fòpin sí ayé búburú yìí, á sì mú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí wá. Ìwé Sefanáyà 1:14 sọ pé: “Ọjọ́ ńlá Jèhófà sún mọ́lé. Ó sún mọ́lé, ìyára kánkán rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi.” Àmọ́, tá a bá wá ń rò pé àkókò tá a fi ń dúró de Ìjọba náà ti ń pẹ́ jù, a lè pàdánù ayọ̀ tá a ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Èyí sì lè mú kí ìtara tá a ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run dín kù.—Òwe 13:12.
Tá ò bá jìnnà sáwọn ará wa, àá máa ní ìdí tó pọ̀ láti máa fayọ̀ sin Jèhófà. Ó tiẹ̀ lè jẹ́ ìwà tó dáa tá a rí lára àwọn èèyàn Jèhófà ló mú kí ìjọsìn tòótọ́ wù wá, táwa náà sì wá bẹ̀rẹ̀ sí í fayọ̀ sin Ọlọ́run. (1 Pétérù 2:12) Àmọ́, kí ló lè ṣẹlẹ̀ tí wọ́n bá bá ọ̀kan lára àwọn arákùnrin tàbí arábìnrin wa wí torí pé kò pa àṣẹ Ọlọ́run mọ́? Èyí lè fa ìrẹ̀wẹ̀sì fún àwọn kan nínú ìjọ, wọ́n sì lè pàdánù ayọ̀ tí wọ́n ní.
Ìfẹ́ láti ní ohun ìní tara tún máa ń mú káwọn míì banú jẹ́. Báwo nìyẹn ṣe lè ṣẹlẹ̀? Ọ̀pọ̀ nǹkan tá ò nílò ló kúnnú ayé Sátánì, ó sì máa ń ṣe wá bíi ká rà wọ́n. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa rántí ohun tí Jésù sọ pé: “Kò sí ẹnì kan tí ó lè sìnrú fún ọ̀gá méjì; nítorí yálà òun yóò kórìíra ọ̀kan, kí ó sì nífẹ̀ẹ́ èkejì, tàbí òun yóò fà mọ́ ọ̀kan, kí ó sì tẹ́ńbẹ́lú èkejì. Ẹ kò lè sìnrú fún Ọlọ́run àti fún Ọrọ̀.” (Mátíù 6:24) Tá a bá ń gbìyànjú láti ní gbogbo ohun tó wù wá nínú ayé yìí, a ò lè láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.
AYỌ̀ TÓ WÀ NÍNÚ ÌJỌSÌN JÈHÓFÀ
Ìjọsìn Jèhófà kì í ṣe ẹrù ìnira fáwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (1 Jòhánù 5:3) Rántí ohun tí Jésù sọ pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi, ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín. Nítorí àjàgà mi jẹ́ ti inú rere, ẹrù mi sì fúyẹ́.” (Mátíù 11:28-30) Bá a ṣe jẹ́ Kristẹni tòótọ́ ń fọkàn wa balẹ̀, ó sì ń fún wa láyọ̀. A ní ìdí púpọ̀ láti máa fayọ̀ sin Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká jíròrò mẹ́ta lára àwọn ìdí náà.—Hábákúkù 3:18.
À ń jọ́sìn Olùfúnni-ní-Ìyè wa, Ọlọ́run aláyọ̀. (Ìṣe 17:28; 1 Tímótì 1:11) A mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá wa ló fún wa lẹ́bùn ìwàláàyè. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa fayọ̀ sin Jèhófà láìka iye ọdún tá a ti ń sìn ín bọ̀ sí.
Wo àpẹẹrẹ Héctor, ogójì [40] ọdún ló fi sin Jèhófà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alábòójútó arìnrìn-àjò. Kódà “nígbà orí ewú” pàápàá, ó ṣì ń gbádùn iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. (Sáàmù 92:12-14) Àìlera ìyàwó rẹ̀ ti dín ohun tó lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run kù, àmọ́ kò jẹ́ kíyẹn sorí òun kodò. Ó sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojoojúmọ́ ni ìlera ìyàwó mi ń burú sí i, kò sì rọrùn láti tọ́jú rẹ̀, mi ò jẹ́ kíyẹn gba ayọ̀ tí mo ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run lọ́wọ́ mi. Bí mo ṣe mọ̀ pé ó ní ìdí tí Jèhófà fi dá àwa èèyàn, òun ló sì fún mi ní ìwàláàyè, ìyẹn ti tó ìdí fún mi láti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ kí n sì máa sìn ín tọkàntọkàn. Mo máa ń sapá kí ìtara tí mo ní fún iṣẹ́ ìwàásù má bàa dín kù, mo sì máa ń fi ìrètí Ìjọba Ọlọ́run sọ́kàn ní gbogbo ìgbà kí n má bàa pàdánù ayọ̀ tí mo ní.”
Jèhófà ti fún wa lẹ́bùn ìràpadà tó ń mú ká máa láyọ̀. Lóòótọ́, “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Ọlọ́run á dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì, àá sì jèrè ìyè àìnípẹ̀kun tá a bá lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà tí Ọlọ́run fìfẹ́ pèsè. Ìdí pàtàkì kan tó fi yẹ ká máa dúpẹ́ nìyẹn. Bá a sì ṣe mọrírì ìràpadà náà á mú ká máa fayọ̀ sin Jèhófà.
Arákùnrin Jesús tó gbé lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò sọ pé: “Iṣẹ́ mi ló gbà mí lọ́kàn ju ohunkóhun mìíràn lọ, nígbà míì ìgbà márùn-ún ni mo máa ń ṣiṣẹ́ lóòjọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò pọn dandan kí n ṣe bẹ́ẹ̀. Torí owó ni mo ṣe ń ṣe é. Mo wá kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àti bó ṣe fi Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n ṣe ìràpadà fún wa. Bó ṣe di pé ó ń wù mí látọkànwá láti sin Jèhófà nìyẹn. Torí náà, mo ṣe ìyàsímímọ́, mo sì kọ̀wé fi iṣẹ́ sílẹ̀ lẹ́yìn ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n [28] tí mo ti ń ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ náà, mo wá pinnu láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alákòókò-kíkún ní pẹrẹu.” Bí Jesús ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í fayọ̀ sin Jèhófà nìyẹn o.
A jẹ́ oníwà mímọ́, èyí sì ń fún wa láyọ̀. Ṣó o rántí bí ìgbésí ayé rẹ ṣe rí kó o tó wá mọ Jèhófà? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rán àwọn Kristẹni tó wà nílùú Róòmù létí pé wọ́n “jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí,” àmọ́ wọ́n ti wá di “ẹrú fún òdodo.” Torí pé wọ́n jẹ́ oníwà mímọ́, wọ́n nírètí láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun. (Róòmù 6:17-22) Àwa náà ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà, torí náà a kì í banú jẹ́ bíi tàwọn tó ń ṣèṣekúṣe àtàwọn tó ń hùwà jàgídíjàgan. Ẹ ò rí i pé ìdí ayọ̀ wa pọ̀ gan-an ni!
Wo àpẹẹrẹ Jaime, nígbà kan, kò gbà pé Ọlọ́run wà, ó gbà pé ara àwọn ẹranko làwa èèyàn ti wá, ó sì tún jẹ́ akànṣẹ́. Jaime bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìfẹ́ tí wọ́n ní láàárín ara wọn wú u lórí gan-an ni. Kò rọrùn fún Jaime láti jáwọ́ nínú àwọn ìwà tó ń hù tẹ́lẹ̀, ńṣe ló ní láti bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kóun gbà á gbọ́. Jaime wá sọ pé, “ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, mo rí i pé Ọlọ́run kan wà tó jẹ́ aláàánú, Bàbá onífẹ̀ẹ́ sì tún ni. Ààbò ni àwọn ìlànà òdodo Jèhófà jẹ́ fún mi. Ká ní mi ò tíì yí pa dà ni, wọ́n lè ti pa mí bíi tàwọn ọ̀rẹ́ mi kan tá a jọ ń kànṣẹ́. Àwọn ọdún tí mo láyọ̀ jù lọ làwọn ọdún tí mo fi sin Jèhófà.”
MÁÀ JẸ́ KÓ SÚ Ẹ!
Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn bá a ṣe ń dúró de òpin ayé búburú yìí? Ó yẹ ká máa rántí pé ìfẹ́ Jèhófà là ń ṣe, a sì ń retí láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun. “Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí a juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorí ní àsìkò yíyẹ àwa yóò kárúgbìn bí a kò bá ṣàárẹ̀.” (Gálátíà 6:8, 9) Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, ẹ jẹ́ ká fara dà á, ká máa sapá láti ní àwọn ànímọ́ tó máa jẹ́ ká la “ìpọ́njú ńlá náà” já, ká sì máa fayọ̀ sin Jèhófà.—Ìṣípayá 7:9, 13, 14; Jákọ́bù 1:2-4.
Ó dá wa lójú pé Jèhófà máa san èrè fún wa torí ìfaradà wa, torí ó ń rí gbogbo ohun tá à ń ṣe àti bá a ṣe ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ orúkọ rẹ̀. Tá a bá ń fayọ̀ sin Jèhófà, àwa náà á dà bíi Dáfídì tó sọ pé: “Mo ti gbé Jèhófà sí iwájú mi nígbà gbogbo. Nítorí pé ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mú kí n ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n. Nítorí náà, ọkàn-àyà mi yọ̀, ògo mi sì fẹ́ láti kún fún ìdùnnú. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ẹran ara mi yóò máa gbé ní ààbò.”—Sáàmù 16:8, 9.