Sún Mọ́ Ọlọ́run
Bàbá Àwọn Ọmọ Aláìníbaba
“BABA àwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba . . . ni Ọlọ́run nínú ibùgbé rẹ̀ mímọ́.” (Sáàmù 68:5) Àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí yẹn kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ kan nípa Jèhófà Ọlọ́run pé ó ṣe tán láti pèsè fáwọn tí ìyà ń jẹ. Òfin tó fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ tí òbí wọn ti kú jẹ́ ẹ lógún gan-an ni. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ibi tí Bíbélì ti kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa “ọmọdékùnrin aláìníbaba,”a ìyẹn nínú ìwé Ẹ́kísódù 22:22-24.
Ọlọ́run kìlọ̀ pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣẹ́ . . . ọmọdékùnrin aláìníbaba níṣẹ̀ẹ́.” (Ẹsẹ 22) Ọ̀rọ̀ yìí kì í ṣe ẹ̀bẹ̀ pé kí wọ́n ṣàánú ọmọ aláìníbaba, àṣẹ Ọlọ́run ni. Ọmọ kan tí bàbá ẹ̀ ti kú ò lẹ́ni táá máa dáàbò bò ó àtẹni táá máa fún un láwọn nǹkan tó bá nílò, èyí sì lè jẹ́ káwọn kan máa fìlọ̀kulọ̀ lọ̀ ọ́. Kò sẹ́ni tó gbọ́dọ̀ “ṣẹ́” irú ọmọ bẹ́ẹ̀ “níṣẹ̀ẹ́.” Ọ̀rọ̀ tá a tú sí “ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́” nínú ẹsẹ yìí làwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì pè ní “lò nílòkulò,” “fìyà jẹ” àti “fìlọ̀kulọ̀ lọni.” Ọ̀ràn ńlá lẹni tó bá hùwà ìkà sọ́mọ aláìníbaba dá lójú Ọlọ́run. Àmọ́, báwo gan-an lọ̀ràn yìí ṣe le tó?
Òfin yẹn tún sọ pé: “Bí o bá ṣẹ́ ẹ níṣẹ̀ẹ́ pẹ́nrẹ́n, tí ó sì ké jáde sí mi pẹ́nrẹ́n, èmi yóò gbọ́ igbe ẹkún rẹ̀ láìkùnà.” (Ẹsẹ 23) Nínú òfin yẹn “ẹ” ni Jèhófà lò ní ẹsẹ 22, ìyẹn sì fi hàn pé gbogbo wọn ló ń bá wí, àmọ́ “o” ló wà ní ẹsẹ 23 tó fi hàn pé ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ni Jèhófà darí ọ̀rọ̀ náà sí. Ohun téyìí túmọ̀ sí ni pé ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn àti gbogbo wọn lápapọ̀ ló gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn sófin tí Ọlọ́run ṣe yẹn. Jèhófà ń wò wọ́n, ó máa ń tẹ́tí gbọ́ àwọn ọmọ aláìníbaba, ó sì ṣe tán láti dá wọn lóhun nígbàkúùgbà tí wọ́n bá sunkún pé àwọn nílò ìrànlọ́wọ́ rẹ̀.—Sáàmù 10:14; Òwe 23:10, 11.
Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ tẹ́nì kan bá hùwà àìdáa sọ́mọ aláìníbaba kan débi pé ọmọ náà sunkún pé kí Ọlọ́run ran òun lọ́wọ́? Jèhófà sọ pé: “Ìbínú mi yóò sì ru ní ti gidi, èmi yóò sì fi idà pa yín dájúdájú.” (Ẹsẹ 24) Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú ẹ̀ sọ pé ohun tí gbólóhùn yìí “ń sọ gan-an ni pé ‘orí mi máa gbóná sí yín,’ àkànlò èdè tó túmọ̀ sí ìbínú tó gbóná sì nìyẹn.” Kíyè sí i pé kì í ṣe àwọn onídàájọ́ ní Ísírẹ́lì ni Jèhófà lò láti fìyà jẹ ẹni tó bá rú òfin yìí. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló máa ṣèdájọ́ ẹnikẹ́ni tó bá rẹ́ ọmọ tí ò lólùgbèjà jẹ.—Diutarónómì 10:17, 18.
Jèhófà ò tíì yí pa dà. (Málákì 3:6) Àánú àwọn ọmọ òrukàn àtàwọn tí ò ní ìyá tàbí tí ò ní bàbá máa ń ṣe gan-an ni. (Jákọ́bù 1:27) Ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé o, pé Bàbá àwọn ọmọ aláìníbaba máa ń bínú lọ́nà òdodo tẹ́nì kan bá dún mọ̀huru-mọ̀huru mọ́ àwọn ọmọ tí ò ní ìyá àtèyí tí ò ní bàbá. Ẹnikẹ́ni tó bá fìyà jẹ ọmọ tí ò lólùrànlọ́wọ́ ò ní bọ́ lọ́wọ́ “ìbínú jíjófòfò Jèhófà.” (Sefanáyà 2:2) Irú àwọn èèyàn burúkú bẹ́ẹ̀ máa wá mọ̀ pé “ó jẹ́ ohun akúnfẹ́rù láti ṣubú sí ọwọ́ Ọlọ́run alààyè.”—Hébérù 10:31.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nǹkan bí ogójì [40] ìgbà ni gbólóhùn náà “ọmọdékùnrin aláìníbaba” fara hàn nínú Bíbélì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọdékùnrin ni èdè Hébérù yẹn túmọ̀ sí lédè Yorùbá, àmọ́ ká má lọ rò pé ìlànà yẹn ò kan àwọn ọmọdébìnrin tí bàbá wọn ti kú o. Òfin Mósè jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ọmọdébìnrin aláìníbaba lẹ́tọ̀ọ́ tiwọn náà.—Númérì 27:1-8.