ORIN 13
Kristi, Àwòkọ́ṣe Wa
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa,
Ó ṣoore ńlá fún wa.
Ó fọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n r’aráyé pa dà.
Nígbà tó wá sáyé,
Àpẹẹrẹ rere ni.
Ìwà rẹ̀ gbórúkọ Ọlọ́run ga.
2. Ọ̀rọ̀ Jèhófà yè;
Ó fún Jésù nímọ̀,
Ó sì fún un lóye, ó gbé ẹ̀mí rẹ̀ ró.
Bó ṣe j’ónírẹ̀lẹ̀
Jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa.
Ó máa ń wù ú láti ṣèfẹ́ Jèhófà.
3. Bíi ti Jésù Kristi,
Kígbèésí ayé wa
Máa mú ìyìn bá Jèhófà Bàbá wa.
Ká fìwà jọ Jésù
Lójoojúmọ́ ayé,
Ká lè máa rójú rere Jèhófà.
(Tún wo Jòh. 8:29; Éfé. 5:2; Fílí. 2:5-7.)