ORIN 39
Ní Orúkọ Rere Lọ́dọ̀ Ọlọ́run
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Gbogbo ayé wa ló yẹ kí á fi ṣe
Orúkọ rere, ká sì pòfin Jáà mọ́.
Tí Jèhófà bá rí bí a ṣe ń sapá tó
Láti ṣèfẹ́ rẹ̀, ó máa láyọ̀.
2. Ayé yìí lè fẹ́ ká wá orúkọ ńlá;
Ká wá òkìkí àt’ojúure èèyàn.
Tá a bá dọ̀rẹ́ ayé, asán ni gbogbo rẹ̀.
A ò ní rí ojúure Jèhófà.
3. A fẹ́ k’Ọ́lọ́run rántí wa sí rere;
Ká ní orúkọ rere títí ayé.
A ó gbèjà òtítọ́, a gbọ́kàn wa lé Ọ.
A ó pa orúkọ rere wa mọ́.
(Tún wo Jẹ́n. 11:4; Òwe 22:1; Mál. 3:16; Ìfi. 20:15.)