ORIN 99
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún Àwa Ará
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwa ará;
A wà kárí ayé.
Ẹlẹ́rìí òótọ́ ni wá,
À ń pàwà títọ́ mọ́.
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún niye wa;
Ṣe la túbọ̀ ń pọ̀ sí i.
Látibi gbogbo kárí ayé,
À ń fògo f’Ọ́lọ́run.
2. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwa ará;
À ń ṣiṣẹ́ ìwàásù.
Ìhìnrere aláyọ̀
Là ń kéde fáráyé.
Nígbà míì, ó lè rẹ̀ wá.
Ká má ṣe sorí kọ́.
Jésù ọ̀gá wa ń mára tù wá;
Ó ń fọkàn wa balẹ̀.
3. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwa ará;
Jáà ló ń dáàbò bò wá.
À ń jọ́sìn Ọlọ́run wa
Nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀.
Ojoojúmọ́ là ń pọ̀ sí i.
À ń ṣiṣẹ́ ìwàásù.
A sì ń bá Ọlọ́run wa ṣiṣẹ́;
À ń sìn ín tọ̀sántòru.
(Tún wo Àìsá. 52:7; Mát. 11:29; Ìfi. 7:15.)