ORIN 121
A Nílò Ìkóra-Ẹni-Níjàánu
Bíi Ti Orí Ìwé
1. A nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tọkàntọkàn.
Àmọ́ ọkàn wa lè máa fà sí ẹ̀ṣẹ̀.
A gbọ́dọ̀ kóra wa níjàánu,
Ká lè níyè àti àlàáfíà.
2. Ojoojúmọ́ ni Èṣù ń dán wa wò,
Àìpé ara wa sì lè mú wa ṣìnà.
Ẹ̀kọ́ òtítọ́ ń jẹ́ ká borí,
Jèhófà sì tún wà lẹ́yìn wa.
3. Ká máa fọ̀rọ̀ àtìṣe wa yin Jáà,
Ká má ṣe tàbùkù sí orúkọ rẹ̀.
Ká wà láìlẹ́bi lójoojúmọ́,
Ká sì máa kóra wa níjàánu.
(Tún wo 1 Kọ́r. 9:25; Gál. 5:23; 2 Pét. 1:6.)