ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 2
Máa Yin Jèhófà Nínú Ìjọ
“Èmi yóò máa yìn ọ́ ní àárín ìjọ.”—SM. 22:22.
ORIN 59 Jẹ́ Ká Yin Jáà
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Kí ni Dáfídì sọ nípa Jèhófà, kí nìyẹn sì mú kó ṣe?
ỌBA DÁFÍDÌ sọ pé: “Jèhófà tóbi, ó sì yẹ fún ìyìn gidigidi.” (Sm. 145:3) Dáfídì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ìyẹn sì mú kó máa yin Ọlọ́run “ní àárín ìjọ.” (Sm. 22:22; 40:5) Ó dájú pé ìwọ náà nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, o sì fara mọ́ ohun tí Dáfídì sọ pé: “Ìbùkún ni fún ọ, Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì baba wa, láti àkókò tí ó lọ kánrin àní dé àkókò tí ó lọ kánrin.”—1 Kíró. 29:10-13.
2. (a) Ọ̀nà wo là ń gbà yin Jèhófà lónìí? (b) Ìṣòro wo làwọn kan ní, kí la sì máa jíròrò?
2 Ọ̀nà pàtàkì kan tá à ń gbà yin Jèhófà lónìí ni bá a ṣe ń dáhùn nípàdé. Àmọ́ ó máa ń ṣòro fún àwọn kan láti dáhùn. Ó máa ń wù wọ́n pé káwọn náà lóhùn sípàdé, àmọ́ ẹ̀rù máa ń bà wọ́n. Kí ló máa jẹ́ kí wọ́n borí ẹ̀rù tó ń bà wọ́n? Àwọn nǹkan wo la lè ṣe táá jẹ́ ká lè máa dáhùn lọ́nà tó ń gbéni ró? Ká tó dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ìdí pàtàkì mẹ́rin tá a fi ń dáhùn nípàdé.
KÍ NÌDÍ TÁ A FI Ń DÁHÙN NÍPÀDÉ?
3-5. (a) Bí Hébérù 13:15 ṣe sọ, kí nìdí tá a fi ń dáhùn nípàdé? (b) Ṣé ọ̀nà kan náà ni Jèhófà ń retí pé ká máa gbà dáhùn? Ṣàlàyé.
3 Jèhófà fún wa láǹfààní láti yin òun. (Sm. 119:108) Ìdáhùn wa wà lára “ẹbọ ìyìn” tá à ń rú sí Jèhófà, kò sì sẹ́ni tó lè bá wa rú u. (Ka Hébérù 13:15.) Ṣé irú ẹbọ kan náà ni Jèhófà ń retí látọ̀dọ̀ wa tàbí lédè míì, ṣé ọ̀nà kan náà ló retí pé ká máa gbà dáhùn nípàdé? Rárá, kò rí bẹ́ẹ̀!
4 Jèhófà mọ̀ pé ipò wa yàtọ̀ síra, ẹ̀bùn wa ò sì rí bákan náà. Síbẹ̀, ó mọyì gbogbo ohun tágbára wa gbé. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa fi rúbọ sí òun. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan máa ń fi àgùntàn tàbí ewúrẹ́ rúbọ. Àmọ́, àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ lówó lè fi “oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì” rúbọ. Kódà, tí ọmọ Ísírẹ́lì kan ò bá lágbára ẹyẹ méjì, Jèhófà gbà pé kó fi “ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà ìyẹ̀fun kíkúnná” rúbọ. (Léf. 5:7, 11) Ìyẹ̀fun ò wọ́n púpọ̀, àmọ́ Jèhófà mọyì ẹ̀ gan-an tó bá ṣáà ti jẹ́ “ìyẹ̀fun kíkúnná.”
5 Onínúure ni Jèhófà, ó sì ń gba tiwa náà rò. Kò retí pé nígbà tá a bá ń dáhùn, kí ọ̀rọ̀ wa dùn bíi ti Àpólò tàbí ká mọ̀rọ̀ sọ bíi ti Pọ́ọ̀lù. (Ìṣe 18:24; 26:28) Gbogbo ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa dáhùn nípàdé. Ẹ rántí opó tó fi ẹyọ owó kéékèèké méjì sínú àpótí ọrẹ. Ohun tó fi sílẹ̀ kéré, àmọ́ Jèhófà mọyì rẹ̀ gan-an torí gbogbo ohun tágbára rẹ̀ gbé ló ṣe.—Lúùkù 21:1-4.
6. (a) Bó ṣe wà nínú Hébérù 10:24, 25, báwo ni ìdáhùn àwọn ará ṣe máa ń rí lára wa? (b) Kí la lè ṣe táá jẹ́ káwọn ará mọ̀ pé a mọrírì ìdáhùn wọn?
6 À ń gbé ara wa ró bá a ṣe ń dáhùn nípàdé. (Ka Hébérù 10:24, 25.) Inú wa máa ń dùn bá a ṣe ń gbọ́ onírúurú ìdáhùn nípàdé. Bí àpẹẹrẹ, tí ọmọdé kan bá dáhùn látọkàn wá, orí wa máa ń wú. Tí ẹnì kan bá ń sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i tàbí ohun kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀, ó máa ń wọ̀ wá lọ́kàn gan-an. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń wú wa lórí tí àwọn tó ń kọ́ èdè wa tàbí àwọn tó ń tijú bá dáhùn nípàdé. (1 Tẹs. 2:2) Kí la lè ṣe táá jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a mọrírì ìsapá wọn? Ó yẹ ká máa gbóríyìn fún wọn lẹ́yìn tí ìpàdé bá parí. Ohun míì tá a lè ṣe ni pé kí àwa fúnra wa máa dáhùn. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, bá a ṣe ń fún àwọn míì níṣìírí làwa náà á máa rí ìṣírí gbà.—Róòmù 1:11, 12.
7. Báwo ni ìdáhùn wa ṣe ń ṣe wá láǹfààní?
7 A máa ń jàǹfààní bá a ṣe ń dáhùn nípàdé. (Aísá. 48:17) Lọ́nà wo? Àkọ́kọ́, tá a bá ní in lọ́kàn láti dáhùn nípàdé, a máa múra ìpàdé sílẹ̀ dáadáa. Tá a bá múra sílẹ̀ dáadáa, àá túbọ̀ lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bí òye wa bá ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ lá túbọ̀ máa rọrùn fún wa láti fi ohun tá à ń kọ́ sílò. Ìkejì, bá a bá ṣe ń lóhùn sí ìpàdé bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa gbádùn ìpàdé. Ìkẹta, torí pé ó máa ń gba ìsapá láti dáhùn, a ò ní tètè gbàgbé ohun tá a sọ nípàdé.
8-9. (a) Bí Málákì 3:16 ṣe sọ, báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà tá a bá dáhùn nípàdé? (b) Ìṣòro wo làwọn kan ní?
8 Inú Jèhófà máa ń dùn tá a bá ń lóhùn sípàdé. Ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà ń tẹ́tí sí wa, ó sì mọyì gbogbo bá a ṣe ń sapá láti dáhùn nípàdé. (Ka Málákì 3:16.) Jèhófà máa ń fi hàn pé òun mọyì wa bó ṣe ń bù kún wa torí pé à ń sapá láti ṣe ohun tó fẹ́.—Mál. 3:10.
9 A ti wá rí ìdí tó fi yẹ ká máa dáhùn nípàdé, síbẹ̀ ẹ̀rù ṣì lè máa ba àwọn kan láti nawọ́. Tó bá jẹ́ pé bó ṣe ń ṣe ẹ́ nìyẹn, má rẹ̀wẹ̀sì. Láti borí ìṣòro yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìlànà Bíbélì kan tó máa ràn wá lọ́wọ́, a sì máa jíròrò àwọn àpẹẹrẹ àtàwọn àbá mélòó kan táá jẹ́ kí gbogbo wa lè túbọ̀ máa dáhùn nípàdé.
BÁ A ṢE LÈ BORÍ ÌBẸ̀RÙ
10. (a) Kí ló máa ń jẹ́ kẹ́rù bà wá tá a bá fẹ́ dáhùn? (b) Kí ni ẹ̀rù tó ń bà ẹ́ lè fi hàn?
10 Ṣé àyà ẹ máa ń lù kìkì tó o bá fẹ́ nawọ́ nípàdé? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ ni irú ẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀ sí. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé ọ̀pọ̀ wa lẹ̀rù máa ń bà déwọ̀n àyè kan tá a bá fẹ́ dáhùn. Kó o tó lè borí ìbẹ̀rù yìí, o gbọ́dọ̀ mọ ohun tó ń fà á. Ṣé ẹ̀rù máa ń bà ẹ́ pé wàá gbàgbé ohun tó o fẹ́ sọ àbí pé o ò ní gba ìdáhùn náà? Ṣé ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé ìdáhùn rẹ ò ní dáa tó tàwọn míì? Ká sòótọ́, ẹ̀rù tó ń bà ẹ́ fi hàn pé o lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Ó fi hàn pé o gbà pé àwọn míì sàn jù ẹ́ lọ, Jèhófà sì fẹ́ràn àwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. (Sm. 138:6; Fílí. 2:3) Àmọ́, Jèhófà fẹ́ kó o máa yin òun kó o sì máa gbé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin rẹ ró nípàdé. (1 Tẹs. 5:11) Ó nífẹ̀ẹ́ rẹ, ó sì máa fún ẹ nígboyà láti máa dáhùn.
11. Ìlànà Bíbélì wo ló lè ràn wá lọ́wọ́?
11 Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ìlànà Bíbélì kan. Bíbélì sọ pé gbogbo wa la máa ń ṣàṣìṣe nínú ọ̀rọ̀ tá à ń sọ àti nínú bá a ṣe ń sọ ọ́. (Ják. 3:2) Torí náà, Jèhófà ò retí pé ká jẹ́ ẹni pípé, àwọn ará wa náà ò sì retí pé a máa jẹ́ bẹ́ẹ̀. (Sm. 103:12-14) Ìdílé kan náà ni gbogbo wa, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. (Máàkù 10:29, 30; Jòh. 13:35) Wọ́n mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni ìdáhùn wa máa bọ́ sójú ẹ̀ tán.
12-13. Kí la rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Nehemáyà àti Jónà?
12 Àwọn àpẹẹrẹ kan wà nínú Bíbélì tó lè jẹ́ kó o borí ìbẹ̀rù rẹ. Ọ̀kan lára wọn ni Nehemáyà. Ààfin ọba alágbára kan ló ti ń ṣiṣẹ́, àmọ́ inú ẹ̀ ò dùn nígbà tó gbọ́ pé ògiri Jerúsálẹ́mù ti wó lulẹ̀ wọ́n sì ti dáná sun àwọn ẹnubodè rẹ̀. (Neh. 1:1-4) Ẹ wo bí àyà ẹ̀ á ṣe máa lù kìkì nígbà tí ọba bi í pé kí nìdí tí ojú rẹ̀ fi kọ́rẹ́ lọ́wọ́. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Nehemáyà gbàdúrà, ó sì dá ọba lóhùn. Jèhófà gbọ́ àdúrà rẹ̀ torí pé ọba náà ran àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́wọ́. (Neh. 2:1-8) Àpẹẹrẹ míì ni ti Jónà. Nígbà tí Jèhófà ní kó lọ bá àwọn ará ìlú Nínéfè sọ̀rọ̀, àyà ẹ̀ já débi pé ṣe ló sá lọ síbòmíì. (Jónà 1:1-3) Àmọ́, Jèhófà ràn án lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ náà láṣeyọrí, àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ sì mú káwọn ará ìlú Nínéfè yí pa dà. (Jónà 3:5-10) Àpẹẹrẹ Nehemáyà kọ́ wa pé ká máa gbàdúrà ká tó dáhùn. Àpẹẹrẹ Jónà ní tiẹ̀ sì jẹ́ ká rí i pé Jèhófà lè ràn wá lọ́wọ́ láìka ẹ̀rù tó ń bà wá sí. Ká sòótọ́, ṣé a lè fi ìjọ àwa èèyàn Jèhófà èyíkéyìí wé àwọn ará ìlú Nínéfè?
13 Àwọn nǹkan wo ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa dáhùn lọ́nà táá gbé àwọn ará ró nípàdé? Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn àbá mélòó kan yẹ̀ wò.
14. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa múra ìpàdé sílẹ̀ dáadáa, àwọn ìgbà wo la sì lè ṣe bẹ́ẹ̀?
14 Máa múra gbogbo ìpàdé sílẹ̀. Tó o bá ṣètò àkókò tí wàá fi máa múra ìpàdé sílẹ̀, tó o sì ń múra sílẹ̀ dáadáa, ọkàn rẹ á balẹ̀ láti dáhùn. (Òwe 21:5) Àmọ́, ọ̀nà tá à ń gbà múra sílẹ̀ yàtọ̀ síra, àkókò wa ò sì bára mu. Bí àpẹẹrẹ, opó ni Arábìnrin Eloise, ó sì ti lé lẹ́ni ọgọ́rin (80) ọdún. Ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sẹ̀ ló máa ń múra ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ sílẹ̀. Ó sọ pé, “Mo túbọ̀ máa ń gbádùn ìpàdé tí mo bá ti múra ẹ̀ sílẹ̀ láwọn ọjọ́ mélòó kan ṣáájú.” Iṣẹ́ bó-o-jí-o-jí-mi ni Arábìnrin Joy ń ṣe ní tiẹ̀, àmọ́ ọjọ́ Sátidé ló máa ń múra ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ rẹ̀ sílẹ̀. Ó sọ pé: “Mo máa ń fẹ́ kí nǹkan tí mo múra sílẹ̀ wà lọ́kàn mi nígbà tá a bá fi máa lọ sípàdé.” Alàgbà àti aṣáájú-ọ̀nà ni Ike, ọwọ́ rẹ̀ sì máa ń dí gan-an, ó sọ pé, “Mo ti rí i pé ohun tó dáa jù fún mi ni pé kí n máa múra sílẹ̀ díẹ̀díẹ̀ jálẹ̀ ọ̀sẹ̀ dípò kí n múra gbogbo rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan náà.”
15. Báwo lo ṣe lè múra ìpàdé sílẹ̀?
15 Kí ló yẹ kó o ṣe tó o bá fẹ́ múra ìpàdé sílẹ̀? Ó yẹ kó o kọ́kọ́ gbàdúrà pé kí Jèhófà fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (Lúùkù 11:13; 1 Jòh. 5:14) Lẹ́yìn náà, wo àkòrí àpilẹ̀kọ náà, àwọn ìsọ̀rí tó wà níbẹ̀, àwọn àwòrán, ìbéèrè tó wà fún àtúnyẹ̀wò àtàwọn àpótí míì. Ẹ̀yìn ìyẹn ni kó o wá bẹ̀rẹ̀ sí í ka ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan, kó o sì rí i pé o ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a tọ́ka sí. Ronú nípa ohun tó ò ń kà, kó o sì kíyè sí àwọn kókó tó o fẹ́ sọ nípàdé. Bó o bá ṣe múra sílẹ̀ tó ni wàá ṣe jàǹfààní tó nípàdé, ìyẹn á sì mú kó rọrùn fún ẹ láti dáhùn.—2 Kọ́r. 9:6.
16. Àwọn nǹkan wo la lè fi múra ìpàdé sílẹ̀, báwo la ṣe lè lò wọ́n?
16 Lo àwọn ètò ìṣiṣẹ́ tó wà lédè rẹ láti múra ìpàdé sílẹ̀. Ètò Ọlọ́run ti ṣe onírúurú nǹkan tá a lè fi múra ìpàdé sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ètò ìṣiṣẹ́ JW Library® máa ń jẹ ká lè wa àwọn ìwé tá à ń lò nípàdé sórí fóònù tàbí ẹ̀rọ míì. Ìyẹn á jẹ́ ká lè ka àwọn ìwé náà tàbí ká tẹ́tí sí wọn nígbàkigbà tàbí níbikíbi tá a bá wà. Àwọn kan máa ń lo ètò ìṣiṣẹ́ yìí láti múra ìpàdé sílẹ̀ nígbà tí wọ́n bá gba ìsinmi ọ̀sán níbi iṣẹ́ tàbí níléèwé. Àwọn míì sì máa ń lò ó tí wọ́n bá ń rìnrìn àjò. Yàtọ̀ síyẹn, a tún ní Watchtower Library àti ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ® (ti Watchtower) tá a lè fi ṣe ìwádìí nípa àwọn nǹkan tá a fẹ́ jíròrò nípàdé.
17. (a) Kí nìdí tó fi yẹ kó o múra ju ìdáhùn kan lọ? (b) Kí lo rí kọ́ nínú fídíò Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà—Múra Ohun Tó O Máa Sọ ní Ìpàdé Sílẹ̀?
17 Múra ju ìdáhùn kan lọ tó bá ṣeé ṣe. Kí nìdí? Ìdí ni pé kì í ṣe gbogbo ìgbà tó o bá nawọ́ ni wọ́n máa pè ẹ́. Àwọn míì náà máa nawọ́, ó sì lè jẹ́ ẹlòmíì ni ẹni tó ń darí ìpàdé máa pè. Ìwọ̀nba èèyàn lẹni tó ń darí ìpàdé máa lè pè lórí kókó kan torí àkókò. Torí náà, má jẹ́ kínú bí ẹ tí wọn ò bá tètè pè ẹ́, má sì tìtorí ẹ̀ pinnu pé o ò ní nawọ́ mọ́. Tó o bá múra ìdáhùn tó pọ̀ díẹ̀, wàá lè dáhùn láwọn ibòmíì. Kódà, ó tiẹ̀ lè jẹ́ pé Bíbélì lo máa kà. Àmọ́, tó bá ṣeé ṣe, gbìyànjú láti dáhùn ìbéèrè lọ́rọ̀ ara rẹ.b
18. Kí nìdí tó fi yẹ kí ìdáhùn wa máa ṣe ṣókí?
18 Jẹ́ kí ìdáhùn rẹ ṣe ṣókí. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ìdáhùn tó máa ń gbéni ró kì í lọ́jú pọ̀, ó sì máa ń ṣe ṣókí. Torí náà, jẹ́ kí ìdáhùn rẹ máa ṣe ṣókí. Gbìyànjú kí ìdáhùn rẹ má ju ààbọ̀ ìṣẹ́jú lọ. (Òwe 10:19; 15:23) Tó o bá ti pẹ́ nínú ètò, tó o sì máa ń dáhùn nípàdé, o ní iṣẹ́ ńlá kan láti ṣe. Ìyẹn sì ni pé kó o jẹ́ kí ìdáhùn rẹ máa ṣe ṣókí, wàá tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fáwọn míì. Tí ìdáhùn rẹ bá gùn jù, tó ò ń ti orí kókó kan bọ́ sí òmíì, àyà àwọn míì lè máa já pé àwọn ò ní lè dáhùn bíi tìẹ. Àmọ́, tí ìdáhùn rẹ bá ṣe ṣókí, ẹni tó ń darí ìpàdé á lè pe àwọn tó pọ̀. Tó bá jẹ́ ìwọ ni wọ́n kọ́kọ́ pè, sọ ìdáhùn náà ní tààràtà, kó sì ṣe ṣókí. Má ṣe sọ gbogbo kókó tó wà nínú ìpínrọ̀ náà tán káwọn míì lè láǹfààní láti sọ̀rọ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti sọ kókó tó wà nínú ìpínrọ̀ kan tán, o lè wá sọ àwọn nǹkan míì tó so mọ́ kókó náà.—Wo àpótí náà “Báwo Ni Mo Ṣe Lè Dáhùn Nípàdé?”
19. Báwo ni ẹni tó ń darí ìpàdé ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́, kí nìyẹn máa gba pé kó o ṣe?
19 Jẹ́ kí ẹni tó ń darí ìpàdé mọ ìpínrọ̀ tó wù ẹ́ láti dáhùn. Tó o bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, ó yẹ kó o ti sọ fún ẹni tó ń darí ìpàdé kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀. Tí ẹ bá ti dé ìpínrọ̀ náà, tètè nawọ́ sókè, kó o sì nà án sókè dáadáa kí ẹni náà lè rí i.
20. Báwo làwọn ìpàdé wa ṣe dà bí ìgbà táwọn ọ̀rẹ́ bá kóra jọ?
20 Àwọn ìpàdé wa dà bí ìgbà tí àwọn ọ̀rẹ́ kóra jọ, tí wọ́n sì jọ ń jẹun. Jẹ́ ká sọ pe àwọn ará mélòó kan ṣètò àpèjẹ ráńpẹ́ kan níjọ yín, wọ́n sì ní kíwọ náà gbé nǹkan dání, kí lo máa ṣe? Ó ṣeé ṣe kó o ṣàníyàn nípa ohun tó o máa gbé wá, àmọ́ ó dájú pé wàá ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kí gbogbo èèyàn lè gbádùn ẹ̀. Bí àwọn ìpàdé wa náà ṣe rí nìyẹn. Jèhófà ló pè wá, ó sì ti tẹ́ tábìlì oúnjẹ tó dọ́ṣọ̀ síwájú wa. (Sm. 23:5; Mát. 24:45) Inú rẹ̀ máa dùn tá a bá mú ẹ̀bùn tó dáa jù wá bó ti wù kó kéré tó. Torí náà, máa múra ìpàdé sílẹ̀ dáadáa, kó o sì dáhùn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, kì í ṣe pé wàá máa jẹun lórí tábìlì Jèhófà nìkan ni, wàá tún máa mú ẹ̀bùn wá fún àwọn ará ìjọ.
ORIN 2 Jèhófà Ni Orúkọ Rẹ
a Bíi ti Dáfídì, gbogbo wa la nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a sì máa ń láyọ̀ bá a ṣe ń yìn ín. A ní àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tá a bá pé jọ nípàdé. Àmọ́, ó máa ń ṣòro fún àwọn kan lára wa láti dáhùn nípàdé. Tó bá jẹ́ pé ìwọ náà máa ń bẹ̀rù láti dáhùn, àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ kó o mọ ohun tó ṣeé ṣe kó fà á àti ohun tó o lè ṣe láti borí ẹ̀.
b Wo fídíò náà Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà—Múra Ohun Tó O Máa Sọ ní Ìpàdé Sílẹ̀. Wo abẹ́ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > ÀWỌN ỌMỌDÉ lórí ìkànnì jw.org/yo.
c ÀWÒRÁN: Àwọn ará ìjọ kan ń gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́.
d ÀWÒRÁN: Díẹ̀ rèé lára àwọn ará tó ń dáhùn nínú ìjọ tá a rí lẹ́ẹ̀kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò wọn yàtọ̀ síra, kálukú wọn ló wáyè láti múra ohun tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ nípàdé sílẹ̀.