ORIN 19
Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa
1. Jèhófà, Bàbá wa ní ọ̀run,
Alẹ́ mímọ́ jù lọ nìyí,
Tó o pinnu láti fagbára àtìfẹ́ hàn
Pẹ̀lú ìdájọ́ òdodo.
Ẹ̀jẹ̀ àgùntàn Ìrékọjá
Lo fi gbàwọn èèyàn rẹ là.
Alẹ́ yìí kan náà ni Kristi kú torí wa
Kó lè mú àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ.
2. Búrẹ́dì tó wà níwájú wa
Àti wáìnì ń rán wa létí
Pé Jésù jólóòótọ́
títí dójú ikú;
Ohun ńlá lo san, Jèhófà.
A ó máa ṣèrántí ikú Jésù.
Alẹ́ yìí ń rán wa létí pé
Ikú Ọmọ rẹ yìí
lo fi rà wá pa dà.
A moore ńlá tó o ṣe fún wa yìí.
3. O pè wá, a sì dá ọ lóhùn.
A pé jọ ká lè jọ́sìn rẹ.
O fìfẹ́ yọ̀ǹda Kristi
Láti kú fún wa;
A yìn ọ́, a yin Ọmọ rẹ.
Ìrántí tá à ńṣe ńfògo fún ọ,
Ó ń fún àwa náà nígbàgbọ́.
A ó máa tẹ̀ lápẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀
Ká lè rí ìyè àìnípẹ̀kun.
(Tún wo Lúùkù 22:14-20; 1 Kọ́r. 11:23-26.)