Ẹ̀kọ́ Èké Kìíní: Ẹ̀mí Èèyàn Kì Í Kú
Báwo ni ẹ̀kọ́ èké yìí ṣe bẹ̀rẹ̀? Ìwé The New Encyclopædia Britannica (1988), ìdìpọ̀ 11 sọ lójú ìwé 25 pé, àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ onímọ̀ ọgbọ́n orí gbà pẹ̀lú àwọn ará Gíríìkì pé ẹ̀mí èèyàn kì í kú, wọ́n sì sọ pé Ọlọ́run ti fi ẹ̀mí yìí sí ara èèyàn láti ìpilẹ̀ṣẹ̀.
Kí ni Bíbélì sọ? ‘Ó pa dà sí erùpẹ̀ rẹ̀; ní ọjọ́ náà gan-an, ìrò inú rẹ̀ run.’—Orin Dáfídì 146:4, Bibeli Yoruba Atọ́ka.
Ṣé àwa èèyàn ní “ẹ̀mí” tó máa ń wà láàyè lẹ́yìn tí ara wa bá ti kú? Bíbélì kọ́ni pé Ọlọ́run fi ipá ìwàláàyè tàbí ẹ̀mí sínú èèyàn àti ẹranko, èémí ló sì ń jẹ́ kí ẹ̀mí lè máa ṣiṣẹ́. Ẹ̀mí yìí ló ń gbé ara ró. Àmọ́ tí ara èèyàn tàbí ti ẹranko kò bá mí mọ́, tí kò sì lè mú kí ẹ̀mí tí Ọlọ́run fi sínú rẹ̀ máa ṣiṣẹ́, èyí á yọrí sí ikú. Wọn kò sì ní mọ ohunkóhun mọ́.—Jẹ́nẹ́sísì 3:19; Oníwàásù 3:19-21; 9:5.
Látìgbà tí àwọn èèyàn ti gbà gbọ́ pé ẹ̀mí èèyàn kì í kú ni onírúurú ìbéèrè ti ń jẹ yọ, lára irú ìbéèré yìí ni: Ibo ni ẹ̀mí tó kúrò ní ara èèyàn máa ń lọ lẹ́yìn tí onítọ̀hún bá kú? Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn burúkú lẹ́yìn tí wọ́n bá ti kú? Nígbà tí àwọn tó ń pera wọn ní Kristẹni gba ẹ̀kọ́ èké yìí gbọ́ pé ẹ̀mí èèyàn kì í kú, èyí mú kí wọ́n gba ẹ̀kọ́ èké míì láyè, ìyẹn sì ni ẹ̀kọ́ nípa iná ọ̀run àpáàdì.
Fi àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí wéra: Oníwàásù 3:19; Mátíù 10:28; Ìṣe 3:23
ÒKODORO ÒTÍTỌ́:
Bí èèyàn bá ti kú, onítọ̀hún ti ṣaláìsí nìyẹn