Ṣé Nítorí Àtiṣoge Nìkan Ni?
LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ SÍPÉÈNÌ
ǸJẸ́ o ti kíyè si rí pé ìṣẹ́jú-ìṣẹ́jú làwọn ẹyẹ máa ń fi àgógó tún ìyẹ́ wọn ṣe? Ọ̀pọ̀ wákàtí ni wọ́n máa ń lò lójúmọ́ lórí rírú ìyẹ́ wọn sókè àti gbígbọ̀n ọ́n lásán. Gbogbo ẹyẹ pátá ló máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ lójoojúmọ́, ì báà ṣe ayékòótọ́ tàbí òfú, ológoṣẹ́ tàbí ẹyẹdò. Kí ló dé tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀? Ṣé nítorí kí ẹwà wọn kàn ṣáà lè yọ ni?
Ìdí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì jùyẹn lọ. Ó yẹ káwọn ẹyẹ máa fi àgógó tún ìyẹ́ wọn ṣe bó ṣe yẹ ká máa tún ẹ̀yà ara ọkọ̀ òfuurufú ṣe. Ọ̀rọ̀ ikú rèé, ìyè rèé ni fáwọn ẹyẹ láti mú kí ìyẹ́ wọn máa gún régé. Jíjù táwọn ẹyẹ máa ń ju apá wọn máa ń jẹ́ kí ìyẹ́ wọn tètè gbó, ó sì máa ń tu dànù, àmọ́, bí wọ́n ṣe ń fi àgógó rú u sókè, ńṣe lá máa mọ́ tónítóní, kò sì ní jẹ́ káwọn kòkòrò àfòmọ́ ráyè dúró níbẹ̀, ìyẹn nìkan kọ́, ó tún ń jẹ́ kí ìyẹ́ yẹn ṣeé fò dáadáa.
Lára nǹkan tí wọ́n máa ń ṣe bí wọ́n ṣe ń túnra ṣe lójoojúmọ́ yìí ni pé wọ́n máa ń tún àwọn fọ́nrán ìyẹ́ tó bá ti dàrú “to.” Nígbà táwọn fọ́nrán ìyẹ́ bá ṣù pọ̀ dáadáa ni ìyẹ́ máa
ń lè gbé ẹyẹ fò lọ sókè lálá. Ìwé Book of British Birds ṣàlàyé pé: “Oríṣi ìyẹ́ méjì ló yẹ ká kíyè sí dáadáa, àwọn ni ìyẹ́ tí ẹyẹ fi ń fò àtèyí tó fi ‘ń yí po’ tó wà níbi ìrù.”
Àwọn ẹyẹ ò sì tún gbọ́dọ̀ ṣíwọ́ jíjá àwọn kòkòrò àfòmọ́ kúrò lára. Yàtọ̀ sí pé àwọn kòkòrò kéékèèké yìí lè wu ẹ̀mí àwọn ẹyẹ léwu, wọ́n tún máa ń jẹ àwọn ìyẹ́ wọn. Àwọn tó mọ̀ nípa àwọn ohun abẹ̀mí inú igbó sọ pé àwọn ẹyẹ tí àgógó wọn bá ti ṣẹ́ kò ní lè tún ìyẹ́ wọn ṣe dáadáa, látàrí èyí, kòkòrò á pọ̀ nínú ìyẹ́ wọn ju ti ẹyẹ tára rẹ̀ dá lọ. Àwọn ẹyẹ kan wà tó máa ń jẹ́ kí èèrà bò wọ́n nítorí pé èròjà formic tó wà lára àwọn èèrà yìí dà bí oògùn apakòkòrò, ìyẹn sì máa ń lé àwọn kòkòrò jìnnà sí ìyẹ́ ẹyẹ.
Ní paríparì, ìyẹ́ ń fẹ́ kí wọ́n máa fi ohun tó dà bí epo pá a. Ohun tó dà bí epo tó máa ń wà lára ìyẹ́ àwọn ẹyẹ etí odò ni kì í jẹ́ kí omi lè wọnú ìyẹ́ náà, gbogbo ẹyẹ sì ni pípọ̀ tí ohun tó dà bí epo yìí pọ̀ lára ìyẹ́ wọn máa ń jẹ́ kí wọ́n lè wà lálàáfíà tòjò tẹ̀ẹ̀rùn. Níbo ni wọ́n ti máa ń rí ohun tó dà bí epo yìí? Ẹṣẹ́ kan wà lápá ibì kan lórí ìrù tó máa ń sun ohun tó jọ epo àti ìda jáde. Ohun tó ń sun jáde yìí ni ẹyẹ yóò rọra máa fi àgógó gbé lọ sára ìyẹ́ rẹ̀. Bó ṣe ń ṣé bẹ́ẹ̀, ńṣe lá máa da ìyẹ́ tó fi ń fò rú tá sì máa tún un tò.
Nítorí náà kò yẹ ká máa rò pé ńṣe làwọn ẹyẹ kàn ń fàkókò ṣòfò bí wọ́n bá ń fi àgógó to ìyẹ́ wọn. Lóòótọ́, gbogbo nǹkan tí ẹyẹ ń ṣe yìí máa ń jẹ́ kí ẹwà rẹ̀ yọ o, àmọ́ ó tún ń jẹ́ kára ẹyẹ le. Káwọn ẹyẹ má bàa kú, wọ́n gbọ́dọ̀ máa túnra ṣe.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Igi ìyẹ́
Ibi tí ìyẹ́ ti ń kọ́ra
Ìhùùhu ìyẹ́
Fọ́nrán ìyẹ́
[Àwòrán]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Báwọn ẹyẹ ṣe ń fi àgógó túnra ṣe, àwọn èròjà tín-tìn-tín tó wà nínú ìyẹ́ á túbọ̀ ṣù pọ̀ dáadáa, ìyẹn á sì jẹ́ káwọn fọ́nrán ìyẹ́ ṣù mọ́ra
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 23]
Cortesía del Zoo de la Casa de Campo, Madrid
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 24]
Ẹyẹ òfú: Foto: Loro Parque, Puerto de la Cruz, Tenerife; ayékòótọ́: Cortesía del Zoo de la Casa de Campo, Madrid