‘Àwọn Àwòrán Yìí Nítumọ̀ Gan-an Ni’
NÍBI táwọn orílẹ̀-èdè ti máa ń ṣe àfihàn àwòrán nílùú Kassel, lórílẹ̀ èdè Jámánì, lẹnì kan ti sọ̀rọ̀ yìí nípa onírúurú àwòrán tó máa ń wà nínú ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Katja, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún, ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tóun àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lọ síbi àfihàn náà, tí wọ́n sì ń wo àwọn àwòrán tí wọ́n yà lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, ó sọ pé:
“Afinimọ̀nà wa béèrè lọ́wọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà bóyá wọ́n ti yẹ èyíkéyìí wò rí nínú ìwé ìròyìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tí gbogbo wọ́n sọ pé àwọn ò tíì yẹ̀ wọ́n wò, ó wá ki ẹnu bọ ìròyìn nípa báwọn àwòrán tó wà nínú àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ṣe rẹwà tó. Ó sọ pé àwọn àwòrán yẹn jojú ní gbèsè àti pé wọ́n bá ohun tí wọ́n ń sọ níbi tí wọ́n yà wọ́n sí mu, ó tún fi kún un pé ‘àwọn àwòrán yẹn nítumọ̀ gan-an ni.’
“Ó sọ fún wa pé ó yẹ ká fẹ̀lẹ̀ wo àwọn àwòrán tó fani mọ́ra wọ̀nyẹn dáadáa,” ó ní yíyà tí wọ́n ń ya àwòrán nípa àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá nínú Bíbélì ń mú ká tètè rí ẹ̀kọ́ tá a lè rí kọ́ nínú wọn. Ó wá rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pé kí wọ́n máa gba àwọn ìwé ìròyìn náà nígbàkigbà tí wọ́n bá fi lọ̀ wọ́n, kí wọ́n má sì fi mọ sórí wíwo àwọn àwòrán inú wọn nìkan àmọ́ kí wọ́n máa ka àwọn àpilẹ̀kọ tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ tó sì dùn-ún kà tó wà níbẹ̀.