Kí Nìdí Tá A Fi Nílò Ìrètí?
KÁ NÍ ìrètí Daniel, ọmọkùnrin tó lárùn jẹjẹrẹ tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí ò ṣákìí ni, kí ni ì bá ṣẹlẹ̀? Ǹjẹ́ ì bá ru àrùn jẹjẹrẹ náà là? Ṣé á ṣì wà láàyè dòní? Kódà àwọn tó ń fìgbà gbogbo sọ pé ìrètí lè mú ìwòsàn wá gan-an ò lè fọwọ́ rẹ̀ sọ̀yà. Kókó pàtàkì kan sì nìyẹn jẹ́. Kò yẹ ká pọ́n ìrètí gẹ̀gẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ. Kì í ṣe awogba-àrùn, kì í ṣe gbogboǹṣe.
Nígbà tí ilé iṣẹ́ ìròyìn CBS fọ̀rọ̀ wá Dókítà Nathan Cherney lẹ́nu wò, ó kìlọ̀ pé ó léwu láti máa pọ́n ìrètí gẹ̀gẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ nígbà tá a bá ń tọ́jú àwọn tí àìsàn wọn le gan-an. Ó sọ pé: “A ti rí àwọn ọkọ tí wọ́n ń bá ìyàwó wọn wí pé wọn kì í ṣe àṣàrò dáadáa àti pé wọn ò lérò tó dáa tó. Ohun tí èrò òdì yìí túmọ̀ sí ni pé ọwọ́ aláìsàn ló wà yálà ó máa tètè gbádùn tàbí kò ní tètè gbádùn, tó bá sì wá di pé ohun tó ń ṣe aláìsàn náà burú sí i, irú bí ìgbà tí jẹjẹrẹ tó wú sára ẹ̀ bá tóbi sí i a jẹ́ pé kò tọ́jú ara rẹ̀ dáadáa nìyẹn. Irú èrò bẹ́ẹ̀ ò sì dára.”
Ká sòótọ́, ojú àwọn tó ń ṣàìsàn tó la ikú lọ ti rí màbo lọ́wọ́ àìsàn náà. Kò sí ẹbí tàbí ọ̀rẹ́ tá tún fẹ́ pa kún ohun tí wọ́n ń forí rọ́ nípa dídá wọn lẹ́bi. Ṣé a wá lè torí bẹ́ẹ̀ sọ pé ìrètí ò wúlò fún nǹkan kan?
A ò lè sọ bẹ́ẹ̀ rárá. Iṣẹ́ dókítà kan náà yìí ni láti ran àwọn aláìsàn lọ́wọ́ láti dín ìrora wọn kù—kì í ṣe nípasẹ̀ ìtọ́jú tó lè mú àìsàn náà kúrò tàbí èyí tó lè mú kí ẹ̀mí aláìsàn náà gùn sí i, àmọ́ kó tọ́jú aláìsàn náà káyé lè dẹrùn fún un, kó sì gbádùn ìwọ̀nba tó kù tá lò láyé. Irú àwọn dókítà bẹ́ẹ̀ gbà pé ó ṣeé ṣe láti tọ́jú aláìsàn kí inú rẹ̀ túbọ̀ máa dùn, àní àwọn tí àìsàn wọn le koko pàápàá. Ẹ̀rí jaburata wà pé ìrètí lè ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì lè ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ.
Bí Ìrètí Ṣe Wúlò Tó
Oníròyìn kan tó máa ń kọ̀ròyìn nípa ìṣègùn, tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Dókítà W. Gifford-Jones sọ pé: “Ìtọ́jú tó lágbára ni ìrètí.” Ó yẹ oríṣiríṣi ìwádìí tí wọ́n ti ṣe wò láti mọ bó ṣe ṣe pàtàkì tó láti máa ṣaájò àwọn tí àìsàn tó la ikú lọ ń ṣe. Èrò wọn ni pé ṣíṣaájò àwọn èèyàn lọ́nà yìí á ràn wọ́n lọ́wọ́ láti má sọ̀rètí nù, á sì jẹ́ kí wọ́n lérò tó dáa. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lọ́dún 1989 fi hàn pé ó máa ń pẹ́ kí àwọn aláìsàn tí wọ́n bá rí irú aájò bẹ́ẹ̀ gbà tó kú, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò rí nǹkan pàtó tó jọ bẹ́ẹ̀ tá a lè rí gbá mú láti inú ìwádìí tí wọ́n ń ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Àmọ́ ṣá, ìwádìí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn aláìsàn táwọn èèyàn ṣaájò wọn kì í sábà ní ìdààmú ọkàn àti ìrora bí àwọn táwọn èèyàn pa tì.
Tún wo ìwádìí mìíràn tí wọ́n ṣe, èyí tó dá lórí ipa tí ẹ̀mí pé nǹkan yóò dára àti ẹ̀mí pé nǹkan ò ní dára ń ní lórí àrùn tó ń ṣe iṣan tó ń gbẹ́jẹ̀ wọnú ọkàn. Ó lé ní ẹ̀ẹ́dégbèje [1,300] àwọn ọkùnrin tí wọ́n yẹ̀ wò láti mọ̀ bóyá èrò tí wọ́n ní nípa ìgbésí ayé ni ẹ̀mí pé nǹkan yóò dára tàbí pé nǹkan kò ní dáa. Nígbà tí wọ́n tún ìwádìí yẹn ṣe lọ́dún mẹ́wàá lẹ́yìn náà, wọ́n rí i pé ìdá méjìlá nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ọkùnrin náà ló ti ní àrùn tó ń ṣe iṣan tó ń gbẹ́jẹ̀ wọnú ọkàn rí. Lára gbogbo àwọn ọkùnrin tí wọ́n yẹ̀ wò yìí, àwọn tó gbà pé ara àwọn kò ní yá nínú wọn tó ìlọ́po méjì àwọn tó gbà pé ara àwọn máa yá. Laura Kubzansky, tó jẹ́ igbákejì ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ nípa ìlera àti ìhùwà ẹ̀dá ní Ilé Ẹ̀kọ́ Nípa Ìlera Gbogbo Gbòò ti Harvard, sọ pé: “Àgbọ́sọ lásán ni èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ẹ̀rí tó wà pé ‘ríronú lọ́nà rere’ ṣe pàtàkì fún ìlera rẹ—ìwádìí tí wọ́n ṣe yìí ló jẹ́ ẹ̀rí àkọ́kọ́ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ lè fọwọ́ rẹ̀ sọ̀yà nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ pé ó ṣe pàtàkì, pàápàá lórí àrùn ọkàn.”
Àwọn ìwádìí kan fi hàn pé àwọn tó gbà pé olókùnrùn làwọn kì í tètè gbádùn lẹ́yìn tí wọ́n bá ṣe iṣẹ́ abẹ fún wọn bí àwọn tó gbà pé ara àwọn le dáadáa. Kódà, wọ́n tiẹ̀ sọ pé béèyàn bá lẹ́mìí pé nǹkan yóò dáa, ó lè pẹ́ láyé. Wọ́n ṣe ìwádìí lórí ipa tí ojú táwọn èèyàn fi ń wo ọjọ́ ogbó ń ní lórí àwọn arúgbó. Nígbà tí wọ́n jẹ́ káwọn arúgbó gbọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan táwọn èèyàn ń sọ nípa bí ọgbọ́n àti ìrírí ṣe máa ń pọ̀ béèyàn ṣe ń darúgbó, àwọn arúgbó yìí lókun àti agbára láti rìn kánmọ́kánmọ́ sí i. Àní, ńṣe ló dà bíi pé wọ́n fi ọ̀sẹ̀ méjìlá ṣe eré ìmárale tó fún wọn lágbára!
Kí ló dé tó fi dà bí i pé ìrètí, ẹ̀mí pé nǹkan yóò dáa àti èrò rere ṣàǹfààní fún ìlera? Bóyá làwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ àtàwọn dókítà lóye èrò inú àti ara èèyàn débi tí wọ́n á fi lè dáhùn irú ìbéèrè yìí ṣàkó. Síbẹ̀, àwọn ògbógi tí wọ́n kọ́ nípa ìrònú àti ara èèyàn lè máa méfò látàrí ohun tí wọ́n kọ́ àti ìrírí wọn. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀jọ̀gbọ́n kan nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ètò iṣan ara sọ pé: “Inú dídùn máa ń mórí yá, àgbẹ́kẹ̀lé kì í sì í pani lébi. Báyọ̀ bá gbọkàn èèyàn ìdààmú ò ní sí lọ́kàn olúwarẹ̀ bẹ́ẹ̀ sì lara èèyàn máa ń balẹ̀. Ara nǹkan téèyàn lè ṣe láti jẹ́ kára òun máa jí pépé ni kó máa wá bí inú òun yóò ṣe máa dùn.”
Ohun tá à ń sọ yìí lè dà bí àrà tuntun lójú àwọn dókítà, afìṣemọ̀rònú ẹ̀dá àtàwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀, ṣùgbọ́n lójú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àgbọ̀nrín èṣí ni. Ó ti tó ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] ọdún báyìí tí Ọlọ́run ti mí sí ọlọgbọ́n Ọba Sólómọ́nì láti kọ èrò yìí sílẹ̀ pé: “Ọkàn-àyà tí ó kún fún ìdùnnú ń ṣe rere gẹ́gẹ́ bí awonisàn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí tí ìdààmú bá ń mú kí àwọn egungun gbẹ.” (Òwe 17:22) Kíyè si pé ọ̀rọ̀ tó wà níbí yìí ò lábùmọ́ o. Ẹsẹ yìí ò sọ pé ọkàn tó kún fún ìdùnnú yóò wo àìsàn kankan o, ṣùgbọ́n ó sọ pé ó “ń ṣe rere gẹ́gẹ́ bí awonisàn.”
Kò burú tẹ́nìkan bá béèrè pé, Bó bá jẹ́ pé oògùn ni ìrètí, oníṣègùn wo ni kò ní máa júwe ẹ̀ fáwọn èèyàn? Ìrètí tún láwọn àǹfààní mìíràn tó ń ṣe ju mímúniláradá lọ.
Ipa Tí Irú Ẹ̀mí Tó O Ní Lè Ní Lórí Rẹ
Àwọn olùwádìí ti rí i pé àwọn tó máa ń lérò pé nǹkan yóò dáa máa ń jàǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà látinú èrò wọn. Ó dà bíi pé wọ́n máa ń fakọyọ nílé ìwé, lẹ́nu iṣẹ́, àti nínú eré ìdárayá pàápàá. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìwádìí kan, wọ́n ní káwọn obìnrin tí wọ́n wà nínú ẹgbẹ́ eléré ìdárayá kan wá ṣe oríṣiríṣi ìdíje. Àwọn olùkọ́ ẹgbẹ́ eléré ìdárayá náà sọ ibi tí agbára àwọn obìnrin yẹn mọ láti díje nínú eré ìdárayá. Lọ́wọ́ kan náà, wọ́n yẹ àwọn obìnrin náà wò dáadáa wọ́n sì fẹ́ mọ bí ìrètí wọn láti pegedé ṣe lágbára tó. Ẹ jẹ́ mọ̀ pé ìrètí táwọn obìnrin wọ̀nyẹn ní pé àwọn lè pegedé ràn wọ́n lọ́wọ́ ju báwọn olùkọ́ wọn ṣe sọ pé agbára wọn láti díje mọ. Kí nìdí tí ìrètí fi nípa tó lágbára bẹ́ẹ̀ lórí àwọn èèyàn?
Ọ̀pọ̀ nǹkan laráyé ti kọ́ nípa ìdàkejì ẹ̀mí pé nǹkan yóò dára, ìyẹn ẹ̀mí pé nǹkan ò ní dáa. Láàárín ọdún 1960 sí 1970, wọ́n rí ọ̀pọ̀ nǹkan tí wọn ò rò tẹ́lẹ̀ nínú ìwádìí tí wọ́n ṣe nípa báwọn ẹranko ṣe ń hùwà, èyí ló sì sún àwọn olùṣèwádìí láti ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ náà “kíkọ́ àìnírètí.” Wọ́n rí i pé irú àmódi bẹ́ẹ̀ lè kọlu èèyàn pẹ̀lú. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n fi àwọn èèyàn kan ṣe ìwádìí, wọ́n kó àwọn wọ̀nyí síbi tí ariwo tó ń han wọ́n létí wà, wọ́n sì sọ fún wọn pé wọ́n lè kọ́ bí wọ́n á ṣe dá ariwo yẹn dúró nípa títẹ àwọn nǹkan kan lára ẹ̀rọ tó ń pariwo náà. Wọ́n rí ariwo yẹn dá dúró.
Wọ́n kó àwọn mìíràn jọ, wọ́n ní káwọn náà ṣe ohun kan náà, ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ ariwo yẹn ò mà dúró o. Kò lè ṣòro fún ọ láti rí i pé ọ̀pọ̀ lára àwọn kejì yẹn á máa wo ara wọn bí ẹni tí kò ní ìrètí. Nígbà tí wọ́n tún dán wọn wò láìpẹ́ sígbà yẹn, wọn ò tiẹ̀ fẹ́ láti dá ariwo náà dúró. Ìgbàgbọ́ wọn ni pé kò sí nǹkan táwọn lè ṣe tó lè dá ariwo náà dúró. Síbẹ̀, àwọn tó lẹ́mìí pé nǹkan yóò dáa lára wọn pàpà gbà pé ariwo yẹn lè dúró, wọn ò gbà pé àwọn ò ní ìrètí.
Ọ̀mọ̀wé Martin Seligman, tó bá wọn ṣètò ìwádìí yẹn kúkú torí bẹ́ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀mí pé nǹkan yóò dáa àti ẹ̀mí pé nǹkan ò ní dáa. Ó wá fìn-ín ìdí kókò nípa báwọn tó gbà pé àwọn ò nírètí ṣe máa ń ronú. Ó sọ pé irú èrò pé nǹkan kò ní dára bẹ́ẹ̀ máa ń ṣèdíwọ́ fáwọn tó bá ní in bí wọ́n bá fẹ́ gbé nǹkan ṣe nínú ìgbésí ayé, kódà ó lè sọ wọ́n di aláìlè dá nǹkan kan ṣe. Seligman wá fi gbólóhùn kan kó gbogbo ipa tí ẹ̀mí pé nǹkan ò ní dáa máa ń ní pọ̀, ó ní: “Láàárín ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tí mo fi kẹ́kọ̀ọ́, ó ti dá mi lójú pé tá a bá sábà ń ní irú èrò táwọn tó ní ẹ̀mí pé nǹkan ò ní dáa máa ń ní, ìyẹn èrò pé ẹ̀bi wa ni ìṣòro tó bá dé bá wa, àti pé kò ní lọ, tá sì máa dabarú gbogbo nǹkan tá a bá dáwọ́ lé, bẹ́ẹ̀ náà ni ìṣòro á máa ṣẹlẹ̀ sí wa tó.”
Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ ṣáájú, ó lè jọ àwọn kan lójú pé ìrètí lágbára tó bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe ọ̀rọ̀ tuntun létí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Òwe yìí wà nínú Bíbélì pé: “Ìwọ ha ti jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ ní ọjọ́ wàhálà bí? Agbára rẹ yóò kéré jọjọ.” (Òwe 24:10) Òdodo ọ̀rọ̀, Bíbélì ṣàlàyé kedere pé ìrẹ̀wẹ̀sì pẹ̀lú èrò òdì tó máa ń bá a rìn lè gba agbára lọ́wọ́ rẹ tó ò sì ní lè dá nǹkan ṣe mọ́. Ṣùgbọ́n kí lo lè ṣe láti kòòré ẹ̀mí pé nǹkan ò ní dáa, tí wà á wá dẹni tó lérò pé nǹkan yóò dára, tí wà á sì nírètí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14, 15]
Ìrètí lè ṣe ọ́ láǹfààní tó kọ yọyọ