ÌTÀN 2
Ọgbà Ẹlẹ́wà Kan
WO BÍ ilẹ̀ ayé ṣe rí nínú àwòrán yìí! Ó dára tàbí kò dára? Wo koríko àti igi, òdòdó àti gbogbo àwọn ẹranko. Ǹjẹ́ o lè tọ́ka sí èyí tó jẹ́ erin àti èyí tó jẹ́ kìnnìún nínú àwọn ẹranko yìí?
Báwo ni ọgbà ẹlẹ́wà yìí ṣe di èyí tó wà? Jẹ́ ká wo àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣe sílẹ̀ de àwa èèyàn ká lè gbádùn ilẹ̀ ayé.
Lákọ̀ọ́kọ́, Ọlọ́run mú kí koríko hù bo ojú ilẹ̀. Ó sì dá oríṣiríṣi àwọn igi kéékèèké àti àwọn igi ńlá-ńlá pẹ̀lú igbó ńlá-ńlá àti igbó kéékèèké. Àwọn nǹkan wọ̀nyí tó ń hù ló mú kí ilẹ̀ ayé lẹ́wà. Àmọ́ kì í ṣe pé wọ́n máa ń mú kí ilẹ̀ ayé lẹ́wà nìkan, a tún ń rí oúnjẹ aládùn lára ọ̀pọ̀ nínú wọn.
Lẹ́yìn èyí, Ọlọ́run wá dá àwọn ẹja pé kí wọ́n máa wẹ̀ nínú omi àti àwọn ẹyẹ pé kí wọ́n máa fò lójú ọ̀run. Ó dá ajá àti ológbò àti ẹṣin; àwọn ẹranko ńlá-ńlá àti ẹranko kéékèèké. Irú ẹranko wo ló wà nítòsí ilé yín? Ǹjẹ́ kò yẹ kí inú wa máa dùn pé Ọlọ́run dá àwọn nǹkan wọ̀nyí fún wa?
Níkẹyìn, Ọlọ́run ṣe apá ibì kan lórí ilẹ̀ ayé ní àrà ọ̀tọ̀. Ó pe ibẹ̀ ní ọgbà Édẹ́nì. Ibẹ̀ dára gan-an ni. Ohun gbogbo tó wà níbẹ̀ ló lẹ́wà. Ọlọ́run sì fẹ́ kí gbogbo orí ilẹ̀ ayé rí gẹ́gẹ́ bí ọgbà ẹlẹ́wà tó dá yìí.
Ṣùgbọ́n tún wo àwòrán ọgbà yìí dáadáa. Ǹjẹ́ o mọ ohun tí Ọlọ́run rí i pé kò sí níbẹ̀? Jẹ́ ká wò ó ná.