ÌTÀN 104
Jésù Padà Sọ́run
BÍ ỌJỌ́ ṣe ń gorí ọjọ́, Jésù fara han àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìgbà. Nígbà kan, nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ló rí i. Nígbà tí Jésù fara hàn wọ́n, ǹjẹ́ o mọ ohun tó bá wọn sọ? Ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run ni. Jèhófà rán Jésù wá sáyé kó bàa lè kọ́ àwọn èèyàn nípa Ìjọba Ọlọ́run. Lẹ́yìn tí Ọlọ́run jí i dìde pàápàá, kò dẹ́kun àtimáa kọ́ni nípa Ìjọba Ọlọ́run.
Ṣó o rántí ohun tí Ìjọba Ọlọ́run túmọ̀ sí? Bẹ́ẹ̀ ni, Ìjọba Ọlọ́run ni ìṣàkóso gidi tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ lókè ọ̀run, Jésù sì ni Ẹni tí Ọlọ́run yàn láti jẹ́ ọba Ìjọba rẹ̀ yìí. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, Jésù fi hàn pé òun máa jẹ́ ọba ìyanu nítorí pé ó bọ́ àwọn tí ebi ń pa ní àbọ́yó, ó wo àwọn aláìsàn sàn, kódà ó jí òkú dìde!
Nítorí náà, nígbà tí Jésù bá ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba ní ọ̀run fún ẹgbẹ̀rún ọdún, báwo ni ilẹ̀ ayé ṣe máa rí? Nǹkan á yàtọ̀, gbogbo ilẹ̀ ayé á di Párádísè ẹlẹ́wà. Kò ní sí ogun tàbí ìwà ọ̀daràn mọ́, àìsàn àti ikú pàápàá ò ní sí mọ́. A mọ̀ pé òótọ́ lèyí, nítorí pé Ọlọ́run dá ilẹ̀ ayé yìí gẹ́gẹ́ bíi Párádísè tí gbogbo èèyàn á ti máa gbádùn. Ìdí nìyẹn tó fi dá ọgbà Édẹ́nì ní ìbẹ̀rẹ̀. Jésù á sì rí sí i pé gbogbo nǹkan tí Ọlọ́run fẹ́ ló di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé.
Àkókò ti tó wàyí fún Jésù láti padà sọ́run. Fún ogójì ọjọ́ ló ti ń fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Nítorí náà, ó dá wọn lójú pé Jésù ti jíǹde. Ṣùgbọ́n kó tó fi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sílẹ̀ ó sọ fún wọn pé: ‘Ẹ dúró ní Jerúsálẹ́mù títí ẹ fi máa gba ẹ̀mí mímọ́.’ Ẹ̀mí mímọ́ ni agbára ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run, ó dà bí afẹ́fẹ́ tó ń fẹ́, òun ló máa ran àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù lọ́wọ́ láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Níkẹyìn, Jésù sọ pé: ‘Kẹ́ ẹ wàásù nípa mi títí dé òpin ilẹ̀ ayé.’
Lẹ́yìn tí Jésù sọ̀rọ̀ yìí tán, ohun ìyanu kan ṣẹlẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í gòkè lọ sí ọ̀run, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àwòrán yìí. Lẹ́yìn náà ni àwọ sánmà gbà á kúrò lójú wọn, wọn ò sì rí i mọ́. Jésù padà sọ́run látibẹ̀ ló sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lórí.