ÌBÉÈRÈ TÁ A MÁA Ń BI ÀWỌN TÓ FẸ́ ṢÈRÌBỌMI
Apá Kejì: Ìgbé Ayé Kristẹni
Àwọn ohun tó o kọ́ nínú Bíbélì ti jẹ́ kó o mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kó o máa ṣe àti bó o ṣe lè jẹ́ kí ìlànà òdodo Jèhófà máa darí ìgbésí ayé rẹ. Àwọn ohun tó o kọ́ ti lè mú kó o ṣe àwọn àtúnṣe kan nínú ìwà rẹ àti bó o ṣe ń ronú. Ní báyìí tó o sì ti pinnu láti jẹ́ kí ìlànà òdodo Jèhófà máa darí ìgbé ayé rẹ, o ti ń sin Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́ gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ tó ń wàásù ìhìn rere.
Àwọn ìbéèrè tá a fẹ́ fi ṣàtúnyẹ̀wò yìí á jẹ́ káwọn ìlànà òdodo Jèhófà túbọ̀ wọ̀ ẹ́ lọ́kàn, á sì tún rán ẹ létí díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó o lè máa ṣe kó o lè di ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó tẹ́wọ́ gbà. Àlàyé yìí máa jẹ́ kó o túbọ̀ mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kó o máa fi ẹ̀rí ọkàn tó dáa ṣe gbogbo nǹkan lọ́nà tó máa fi ìyìn fún Jèhófà.—2 Kọ́r. 1:12; 1 Tím. 1:19; 1 Pét. 3:16, 21.
Níbi tó o kẹ́kọ̀ọ́ dé yìí, ó dájú pé ó wù ẹ́ pé kí Jèhófà máa darí rẹ, kó o sì wà nínú ètò rẹ̀. Àwọn ìbéèrè àtàwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀ á jẹ́ kó o mọ̀ bóyá lóòótọ́ lo mọ ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ kí Jèhófà máa darí rẹ nínú ìjọ, nínú ìdílé àti nínú àwọn ọ̀rọ̀ tó kan àwọn ìjọba ayé yìí. Ó dájú pé wàá túbọ̀ mọyì ètò tí Jèhófà ṣe kó lè máa kọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́, kó sì mú kí ìgbàgbọ́ wọn túbọ̀ lágbára. Lára àwọn ètò náà ni àwọn ìpàdé ìjọ, ó sì dájú pé wàá máa wá, wàá sì máa kópa níbẹ̀ déédéé tó bá ṣe lè ṣeé ṣe tó.
Yàtọ̀ síyẹn, nínú apá yìí, a máa jíròrò ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o máa wàásù Ìjọba Ọlọ́run déédéé, kó o sì ran àwọn míì lọ́wọ́ láti wá mọ Jèhófà àti ohun tó ń ṣe fún aráyé. (Mát. 24:14; 28:19, 20) Ju gbogbo ẹ̀ lọ, á jẹ́ kó o túbọ̀ rí i pé ìyàsímímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run àti ìrìbọmi kì í ṣe ọ̀rọ̀ ṣeréṣeré. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé inú Jèhófà dùn gan-an sí ẹ pé o mọyì inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tó fi hàn sí ẹ.
1. Ìlànà wo làwa Kristẹni gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé lórí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó? Kí ni ìdí kan ṣoṣo tó bá Ìwé Mímọ́ mu tó lè mú kí tọkọtaya kọra wọn sílẹ̀?
• “Ṣé ẹ ò kà á pé ẹni tó dá wọn ní ìbẹ̀rẹ̀ dá wọn ní akọ àti abo, ó sì sọ pé, ‘Torí èyí, ọkùnrin á fi bàbá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, á sì fà mọ́ ìyàwó rẹ̀, àwọn méjèèjì á sì di ara kan’? Tó fi jẹ́ pé wọn kì í ṣe méjì mọ́, àmọ́ wọ́n jẹ́ ara kan. Torí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí èèyàn kankan má ṣe yà á. . . . Ẹnikẹ́ni tó bá kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀, àfi tó bá jẹ́ torí ìṣekúṣe, tó sì fẹ́ ẹlòmíì ti ṣe àgbèrè.”—Mát. 19:4-6, 9.
2. Kí nìdí táwọn tó ń gbé bíi tọkọtaya fi gbọ́dọ̀ ṣègbéyàwó lọ́nà tó bá òfin mu? Tó o bá ti ṣègbéyàwó, ṣé ó dá ẹ lójú pé ìgbéyàwó rẹ bófin mu, ṣé ìjọba sì fọwọ́ sí i?
• “Máa rán wọn létí pé kí wọ́n máa tẹrí ba fún ìjọba àti àwọn aláṣẹ, kí wọ́n máa ṣègbọràn sí wọn.”—Títù 3:1.
• “Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo èèyàn, kí ibùsùn ìgbéyàwó má sì ní ẹ̀gbin, torí Ọlọ́run máa dá àwọn oníṣekúṣe àti àwọn alágbèrè lẹ́jọ́.”—Héb. 13:4.
3. Kí ni ojúṣe rẹ nínú ìdílé?
• “Ọmọ mi, fetí sí ìbáwí bàbá rẹ, má sì pa ẹ̀kọ́ ìyá rẹ tì.”—Òwe 1:8.
• “Ọkọ ni orí aya rẹ̀ bí Kristi ṣe jẹ́ orí ìjọ . . . Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, bí Kristi ṣe nífẹ̀ẹ́ ìjọ.”—Éfé. 5:23, 25.
• “Ẹ̀yin bàbá, ẹ má ṣe máa mú àwọn ọmọ yín bínú, kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa tọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìmọ̀ràn Jèhófà.”—Éfé. 6:4.
• “Ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn òbí yín lẹ́nu nínú ohun gbogbo, nítorí èyí dára gidigidi lójú Olúwa.”—Kól. 3:20.
• “Kí ẹ̀yin aya máa tẹrí ba fún àwọn ọkọ yín.”—1 Pét. 3:1.
4. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀mí?
• “[Ọlọ́run] ló ń fún gbogbo èèyàn ní ìyè àti èémí àti ohun gbogbo. . . . Ipasẹ̀ rẹ̀ ni a fi ní ìyè, tí à ń rìn, tí a sì wà.”—Ìṣe 17:25, 28.
5. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká pa ẹnikẹ́ni, títí kan ọmọ tó ṣì wà nínú oyún?
• “Tí àwọn èèyàn bá ń jà, tí wọ́n sì ṣe obìnrin tó lóyún léṣe, . . . tó bá la ẹ̀mí lọ, kí o fi ẹ̀mí dípò ẹ̀mí.”—Ẹ́kís. 21:22, 23.
• “Ojú rẹ rí mi nígbà tí mo ṣì wà nínú ikùn; gbogbo àwọn ẹ̀yà rẹ̀ wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé rẹ ní ti àwọn ọjọ́ tí o ṣẹ̀dá wọn, kí ìkankan lára wọn tó wà.”—Sm. 139:16.
• “Jèhófà kórìíra . . . ọwọ́ tó ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.”—Òwe 6:16, 17.
6. Àṣẹ wo ni Ọlọ́run pa nípa ẹ̀jẹ̀?
• “Máa ta kété sí . . . ẹ̀jẹ̀ [àti] sí ohun tí wọ́n fún lọ́rùn pa.”—Ìṣe 15:29.
7. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa?
• “Mò ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín; bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ yín, kí ẹ̀yin náà nífẹ̀ẹ́ ara yín. Èyí ni gbogbo èèyàn máa fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, tí ìfẹ́ bá wà láàárín yín.”—Jòh. 13:34, 35.
8. Kí ẹni tó ní àìsàn tó burú tó lè ranni má bàa ṣàkóbá fún àwọn míì, (a) Kí nìdí tí kò fi yẹ kó máa gbá àwọn èèyàn mọ́ra tàbí kó máa fẹnu kò wọ́n lẹ́nu? (b) Kí nìdí tí kò fi yẹ kó bínú táwọn kan ò bá fẹ́ kó wá sílé àwọn? (d) Tó bá ṣẹlẹ̀ pé ó ṣeé ṣe kẹ́nì kan ti kó àrùn tó lè ran ẹlòmíì, kí nìdí tó fi yẹ kí onítọ̀hún fúnra rẹ̀ lọ ṣe àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kó tó bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ ẹnì kan sọ́nà? (e) Kí nìdí tí ẹni tó ní àìsàn tó lè ran ẹlòmíì fi gbọ́dọ̀ sọ fún olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà kó tó ṣèrìbọmi?
• “Ẹ má jẹ ẹnikẹ́ni ní gbèsè ohunkóhun, àmọ́ kí ẹ máa nífẹ̀ẹ́ ara yín. . . . ‘Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.’ Ìfẹ́ kì í ṣiṣẹ́ ibi sí ọmọnìkejì ẹni.”—Róòmù 13:8-10.
• “Bí ẹ ṣe ń wá ire àwọn ẹlòmíì, kì í ṣe tiyín nìkan.”—Fílí. 2:4.
9. Kí nìdí tí Jèhófà fi retí pé ká máa dárí ji àwọn ẹlòmíì?
• “Ẹ máa fara dà á fún ara yín, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà, kódà tí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí láti fẹ̀sùn kan ẹlòmíì. Bí Jèhófà ṣe dárí jì yín ní fàlàlà, ẹ̀yin náà gbọ́dọ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀.”—Kól. 3:13.
10. Kí ló yẹ kó o ṣe tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá bà ẹ́ lórúkọ jẹ́ tàbí tó lù ẹ́ ní jìbìtì?
• “Tí arákùnrin rẹ bá ṣẹ̀, lọ sọ ẹ̀bi rẹ̀ fún un láàárín ìwọ àti òun nìkan. Tó bá fetí sí ọ, o ti jèrè arákùnrin rẹ. Àmọ́ tí kò bá fetí sí ọ, mú ẹnì kan tàbí méjì dání, kó lè jẹ́ pé nípa ẹ̀rí ẹni méjì tàbí mẹ́ta, a ó fìdí gbogbo ọ̀rọ̀ múlẹ̀. Tí kò bá fetí sí wọn, sọ fún ìjọ. Tí kò bá fetí sí ìjọ pàápàá, bí èèyàn àwọn orílẹ̀-èdè àti agbowó orí ni kó rí sí ọ gẹ́lẹ́.”—Mát. 18:15-17.
11. Irú ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yìí?
▪ Ìṣekúṣe
▪ Lílo ère nínú ìjọsìn
▪ Kí ọkùnrin máa bá ọkùnrin lò pọ̀ tàbí kí obìnrin máa bá obìnrin lò pọ̀
▪ Olè jíjà
▪ Tẹ́tẹ́ títa
▪ Ìmutíyó
• “Ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n ṣì yín lọ́nà. Àwọn oníṣekúṣe, àwọn abọ̀rìṣà, àwọn alágbèrè, àwọn ọkùnrin tó ń jẹ́ kí ọkùnrin bá wọn lò pọ̀, àwọn abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀, àwọn olè, àwọn olójúkòkòrò, àwọn ọ̀mùtípara, àwọn pẹ̀gànpẹ̀gàn àti àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run.”—1 Kọ́r. 6:9, 10.
12. Kí lo pinnu láti ṣe nípa ìṣekúṣe, èyí tó ní nínú ohunkóhun tó jẹ mọ́ ìbálòpọ̀ láàárín àwọn tí kì í ṣe tọkọtaya?
• “Ẹ máa sá fún ìṣekúṣe!”—1 Kọ́r. 6:18.
13. Kí nìdí tó fi yẹ ká sá fún àwọn oògùn tó lè di bárakú tàbí èyí tó lè pani lọ́bọlọ̀, tí dókítà kò sọ pé ká lò?
• “Ẹ fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, tó jẹ́ mímọ́, tó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà, kí ẹ lè ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ pẹ̀lú agbára ìrònú yín. Ẹ má sì jẹ́ kí ètò àwọn nǹkan yìí máa darí yín, àmọ́ ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín pa dà, kí ẹ lè fúnra yín ṣàwárí ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.”—Róòmù 12:1, 2.
14. Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ẹ̀mí èṣù tí Ọlọ́run kórìíra?
• “Ẹnì kankan láàárín yín . . . kò gbọ́dọ̀ woṣẹ́, kò gbọ́dọ̀ pidán, kò gbọ́dọ̀ wá àmì ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀, kò gbọ́dọ̀ di oṣó, kò gbọ́dọ̀ fi èèdì di àwọn ẹlòmíì, kò gbọ́dọ̀ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ abẹ́mìílò tàbí woṣẹ́woṣẹ́, kò sì gbọ́dọ̀ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ òkú.”—Diu. 18:10, 11.
15. Tí ẹnì kan bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì, tó sì fẹ́ pa dà rí ojú rere Jèhófà, kí ló yẹ kí onítọ̀hún ṣe lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀?
• “Mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún ọ; Mi ò bo àṣìṣe mi mọ́lẹ̀. Mo sọ pé: ‘Màá jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Jèhófà.’ ”—Sm. 32:5.
• “Ṣé ẹnikẹ́ni ń ṣàìsàn láàárín yín? Kó pe àwọn alàgbà ìjọ, kí wọ́n gbàdúrà lé e lórí, kí wọ́n fi òróró pa á ní orúkọ Jèhófà. Àdúrà ìgbàgbọ́ sì máa mú aláìsàn náà lára dá, Jèhófà máa gbé e dìde. Tó bá sì ti dẹ́ṣẹ̀, a máa dárí jì í.”—Jém. 5:14, 15.
16. Tó o bá mọ̀ pé arákùnrin tàbí arábìnrin kan ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú, kí ló yẹ kó o ṣe?
• “Tí ẹnì kan bá gbọ́ tí wọ́n ń kéde ní gbangba pé kí ẹni tó bá mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ kan wá jẹ́rìí sí i, tí ẹni náà sì jẹ́ ẹlẹ́rìí ọ̀rọ̀ náà tàbí tó ṣojú rẹ̀ tàbí tó mọ̀ nípa rẹ̀, àmọ́ tí kò sọ, ó ti ṣẹ̀, yóò sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.”—Léf. 5:1.
17. Tí wọ́n bá ṣèfilọ̀ pé ẹnì kan kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́, báwo ló ṣe yẹ ká máa ṣe sí ẹni náà?
• “Ẹ jáwọ́ nínú kíkẹ́gbẹ́ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí a pè ní arákùnrin, àmọ́ tó jẹ́ oníṣekúṣe tàbí olójúkòkòrò tàbí abọ̀rìṣà tàbí pẹ̀gànpẹ̀gàn tàbí ọ̀mùtípara tàbí alọ́nilọ́wọ́gbà, kí ẹ má tiẹ̀ bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹun.”—1 Kọ́r. 5:11.
• “Bí ẹnikẹ́ni bá wá sọ́dọ̀ yín, tí kò sì mú ẹ̀kọ́ yìí wá, ẹ má gbà á sílé, ẹ má sì kí i.”—2 Jòh. 10.
18. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ló yẹ kó o yàn lọ́rẹ̀ẹ́?
• “Ẹni tó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, àmọ́ ẹni tó ń bá òmùgọ̀ da nǹkan pọ̀ yóò rí láburú.”—Òwe 13:20.
• “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ. Ẹgbẹ́ búburú ń ba ìwà rere jẹ́.”—1 Kọ́r. 15:33.
19. Kí nìdí tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í dá sọ́rọ̀ òṣèlú?
• “Wọn kì í ṣe apá kan ayé, bí èmi [Jésù] ò ṣe jẹ́ apá kan ayé.”—Jòh. 17:16.
20. Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa ṣègbọràn sí ìjọba?
• “Kí gbogbo èèyàn máa tẹrí ba fún àwọn aláṣẹ onípò gíga, nítorí kò sí àṣẹ kankan àfi èyí tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run; àwọn aláṣẹ tó wà ni a gbé sí àwọn ipò wọn tó ní ààlà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”—Róòmù 13:1.
21. Tí èèyàn bá sọ pé kó o ṣe nǹkan, àmọ́ tí òfin Ọlọ́run sọ pé o ò gbọ́dọ̀ ṣe é, kí lo máa ṣe?
• “A gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí alákòóso dípò èèyàn.”—Ìṣe 5:29.
22. Tó o bá fẹ́ yan iṣẹ́ tó o máa ṣe, ẹsẹ Bíbélì wo ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o má bàa di apá kan ayé?
• “Àwọn orílẹ̀-èdè kò ní yọ idà sí ara wọn mọ́.”—Míkà 4:3.
• “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀ [Bábílónì Ńlá], ẹ̀yin èèyàn mi, tí ẹ kò bá fẹ́ pín nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, tí ẹ kò bá sì fẹ́ gbà lára àwọn ìyọnu rẹ̀.”—Ìfi. 18:4.
23. Irú eré ìdárayá àti eré ìnàjú wo lo máa yàn, irú èwo lo sì máa yẹra fún?
• “Jèhófà . . . kórìíra ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.”—Sm. 11:5.
• “Ẹ kórìíra ohun búburú; ẹ rọ̀ mọ́ ohun rere.”—Róòmù 12:9.
• “Ohunkóhun tó jẹ́ òótọ́, ohunkóhun tó ṣe pàtàkì, ohunkóhun tó jẹ́ òdodo, ohunkóhun tó jẹ́ mímọ́, ohunkóhun tó yẹ ní fífẹ́, ohunkóhun tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, ohunkóhun tó bá dára, ohunkóhun tó bá yẹ fún ìyìn, ẹ máa ronú lórí àwọn nǹkan yìí.”—Fílí. 4:8.
24. Kí nìdí tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í jọ́sìn pẹ̀lú àwọn ìsìn míì?
• “Ẹ ò lè máa jẹun lórí ‘tábìlì Jèhófà’ àti tábìlì àwọn ẹ̀mí èṣù.”—1 Kọ́r. 10:21.
• “ ‘Ẹ . . . ya ara yín sọ́tọ̀,’ ni Jèhófà wí, ‘ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ mọ́’; ‘màá sì gbà yín wọlé.’ ”—2 Kọ́r. 6:17.
25. Àwọn ìlànà wo ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti pinnu bóyá o máa lọ́wọ́ nínú ayẹyẹ kan tàbí o ò ní lọ́wọ́ sí i?
• “Wọ́n ń bá àwọn orílẹ̀-èdè náà ṣe wọlé wọ̀de, wọ́n sì ń hùwà bíi tiwọn. Wọ́n ń sin àwọn òrìṣà wọn, àwọn òrìṣà náà sì di ìdẹkùn fún wọn.”—Sm. 106:35, 36.
• “Àwọn òkú kò mọ nǹkan kan rárá.”—Oníw. 9:5.
• “Wọn kì í ṣe apá kan ayé, bí èmi ò ṣe jẹ́ apá kan ayé.”—Jòh. 17:16.
• “Àkókò tó ti kọjá tí ẹ fi ṣe ìfẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè ti tó yín, nígbà tí ẹ̀ ń hu ìwà àìnítìjú, tí ẹ̀ ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, tí ẹ̀ ń mu ọtí àmujù, ṣe àríyá aláriwo, ṣe ìdíje ọtí mímu àti àwọn ìbọ̀rìṣà tó jẹ́ ohun ìríra.”—1 Pét. 4:3.
26. Báwo làwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣèpinnu lórí ọ̀rọ̀ ayẹyẹ ọjọ́ ìbí?
• “Ọjọ́ kẹta wá jẹ́ ọjọ́ ìbí Fáráò, ó sì se àsè fún gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀, ó wá mú olórí agbọ́tí àti olórí alásè jáde níṣojú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Ó dá olórí agbọ́tí pa dà sí ipò tó wà tẹ́lẹ̀ . . . Àmọ́, ó gbé olórí alásè kọ́.”—Jẹ́n. 40:20-22.
• “Nígbà tí wọ́n ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí Hẹ́rọ́dù, ọmọbìnrin Hẹrodíà jó níbi ayẹyẹ náà, ó sì múnú Hẹ́rọ́dù dùn gan-an débi pé ó ṣèlérí, ó sì búra pé òun máa fún un ní ohunkóhun tó bá béèrè. Ìyá ọmọbìnrin náà kọ́ ọ ní ohun tó máa sọ, ó sì sọ pé: ‘Fún mi ní orí Jòhánù Arinibọmi níbí yìí nínú àwo pẹrẹsẹ.’ Ó wá ránṣẹ́ pé kí wọ́n lọ bẹ́ orí Jòhánù nínú ẹ̀wọ̀n.”—Mát. 14:6-8, 10.
27. Kí nìdí tó o fi fẹ́ máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà àwọn alàgbà?
• “Ẹ máa ṣègbọràn sí àwọn tó ń mú ipò iwájú láàárín yín, kí ẹ sì máa tẹrí ba, torí wọ́n ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí yín bí àwọn tó máa jíhìn, kí wọ́n lè ṣe é tayọ̀tayọ̀, kì í ṣe pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn, torí èyí máa pa yín lára.”—Héb. 13:17.
28. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí ìwọ àti ìdílé rẹ ya àkókò kan sọ́tọ̀ láti máa ka Bíbélì déédéé, kẹ́ ẹ sì máa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀?
• “Òfin Jèhófà máa ń mú inú rẹ̀ dùn, ó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin Rẹ̀ tọ̀sántòru. Ó máa dà bí igi tí a gbìn sétí odò, tó ń so èso ní àsìkò rẹ̀, tí ewé rẹ̀ kì í sì í rọ. Gbogbo ohun tó bá ń ṣe yóò máa yọrí sí rere.”—Sm. 1:2, 3.
29. Kí nìdí tó o fi fẹ́ràn láti máa lọ sípàdé kó o sì máa kópa níbẹ̀?
• “Màá sọ orúkọ rẹ fún àwọn arákùnrin mi; màá sì yìn ọ́ láàárín ìjọ.”—Sm. 22:22.
• “Ẹ sì jẹ́ ká gba ti ara wa rò ká lè máa fún ara wa níṣìírí láti ní ìfẹ́ àti láti ṣe àwọn iṣẹ́ rere, ká má ṣe máa kọ ìpàdé wa sílẹ̀, bí àṣà àwọn kan, àmọ́ ká máa gba ara wa níyànjú, ní pàtàkì jù lọ bí ẹ ṣe ń rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.”—Héb. 10:24, 25.
30. Iṣẹ́ wo ni iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ tí Jésù gbé fún wa?
• “Torí náà, ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn . . . , ẹ máa kọ́ wọn pé kí wọ́n máa pa gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún yín mọ́.”—Mát. 28:19, 20.
31. Tá a bá fẹ́ múnú Jèhófà dùn nígbà tá à ń ṣètọrẹ fún iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run tàbí tá a fẹ́ ṣèrànwọ́ fáwọn ará wa, báwo ló ṣe yẹ ká ṣe é?
• “Fi àwọn ohun ìní rẹ tó níye lórí bọlá fún Jèhófà.”—Òwe 3:9.
• “Kí kálukú ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú lílọ́ra tàbí lábẹ́ àfipáṣe, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ẹni tó ń fúnni pẹ̀lú ìdùnnú.”—2 Kọ́r. 9:7.
32. Àwọn ìṣòro wo làwa Kristẹni retí pé a máa dojú kọ?
• “Aláyọ̀ ni àwọn tí wọ́n ṣe inúnibíni sí nítorí òdodo, torí Ìjọba ọ̀run jẹ́ tiwọn. Aláyọ̀ ni yín tí àwọn èèyàn bá pẹ̀gàn yín, tí wọ́n ṣe inúnibíni sí yín, tí wọ́n sì parọ́ oríṣiríṣi ohun burúkú mọ́ yín nítorí mi. Ẹ máa yọ̀, kí inú yín sì dùn gidigidi, torí èrè yín pọ̀ ní ọ̀run, torí bí wọ́n ṣe ṣe inúnibíni sí àwọn wòlíì tó wà ṣáájú yín nìyẹn.”—Mát. 5:10-12.
33. Kí nìdí tó fi jẹ́ àǹfààní tó ṣàrà ọ̀tọ̀ pé kéèyàn ṣèrìbọmi, kó sì di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
• “Ọ̀rọ̀ rẹ sì di ayọ̀ fún mi àti ìdùnnú ọkàn mi, nítorí wọ́n ti fi orúkọ rẹ pè mí, Jèhófà Ọlọ́run.”—Jer. 15:16.