ORÍ KARÙN-ÚN
Ìràpadà Ni Ẹ̀bùn Tó Dáa Jù Lọ Tí Ọlọ́run Fún Wa
1, 2. (a) Kí ló máa fi hàn pé ẹ̀bùn kan ṣeyebíye lójú ẹ? (b) Kí nìdí tí ìràpadà fi jẹ́ ẹ̀bùn tó dáa jù lọ tí Ọlọ́run fún wa?
Ẹ̀BÙN wo ló ṣeyebíye jù lọ nínú gbogbo ẹ̀bùn tó o ti gbà rí? Kò dìgbà tí ẹ̀bùn kan bá jẹ́ olówó ńlá kó tó ṣeyebíye lójú ẹ. Tí ẹ̀bùn kan bá múnú ẹ dùn tàbí tó bá jẹ́ ohun tó o nílò, ó dájú pé wàá mọrírì ẹ̀ gan-an.
2 Nínú gbogbo ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún wa, ẹ̀bùn kan wà tá a nílò ju lọ. Òun ni ẹ̀bùn tó dáa jù lọ tí Ọlọ́run fún àwa èèyàn. Ní orí yìí, a máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jèhófà ṣe rán Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi, wá sáyé ká lè wà láàyè títí láé. (Ka Mátíù 20:28.) Bí Jèhófà ṣe rán Jésù wá sáyé láti rà wá pa dà fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an.
KÍ NI ÌRÀPADÀ?
3. Kí nìdí tí àwa èèyàn fi ń kú?
3 Ìràpadà ni Jèhófà fi gba àwa èèyàn lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Éfésù 1:7) Ká lè mọ ìdí tá a fi nílò ìràpadà, ó yẹ ká mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) ọdún sẹ́yìn nínú ọgbà Édẹ́nì. Àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀, wọ́n sì kú. Ìdí táwa náà sì fi ń kú ni pé a ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ Ádámù àti Éfà.—Wo Àlàyé Ìparí Ìwé 9.
4. Ta ni Ádámù, àwọn nǹkan wo sì ni Ọlọ́run fún un?
4 Nígbà tí Jèhófà dá Ádámù, ó fún un ní ohun kan tó ṣeyebíye gan-an. Ó dá Ádámù ní ẹni pípé. Ọpọlọ rẹ̀ pé, ó sì ní ìlera pípé. Ìyẹn túmọ̀ sí pé Ádámù kò ní ṣàìsàn, kò ní darúgbó, kò sì ní kú láé. Torí pé Jèhófà ló dá Ádámù, òun ni Baba rẹ̀. (Lúùkù 3:38) Jèhófà máa ń bá a sọ̀rọ̀ déédéé. Ó fún Ádámù ní ìtọ́sọ́nà tó ṣe kedere nípa ohun tó yẹ kó ṣe, ó sì fún un ní iṣẹ́ tó máa gbádùn mọ́ ọn.—Jẹ́nẹ́sísì 1:28-30; 2:16, 17.
5. Kí ló túmọ̀ sí nígbà tí Bíbélì sọ pé Ádámù jẹ́ “àwòrán Ọlọ́run”?
5 Ádámù jẹ́ “àwòrán Ọlọ́run.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Ìyẹn túmọ̀ sí pé Jèhófà jẹ́ kó ní ìwà àti ìṣe bíi tiẹ̀, lára wọn ni ìfẹ́, ọgbọ́n, ìdájọ́ òdodo àti agbára. Ó fún Ádámù ní òmìnira láti yan ohun tó bá wù ú. Ádámù kì í ṣe ẹ̀rọ rọ́bọ́ọ̀tì. Ọlọ́run dá a lọ́nà tó fi lè yan ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. Ká ní Ádámù yàn láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run ni, ì bá máa gbé títí láé nínú Párádísè.
6. Kí ni Ádámù pàdánù nígbà tó ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run? Báwo lèyí sì ṣe kàn wá?
6 Nígbà tí Ádámù ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run tó sì gba ìdájọ́ ikú, ohun ńlá gbáà ló pàdánù. Ó pàdánù àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ tó ní pẹ̀lú Jèhófà, ó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ pípé àti Párádísè tó jẹ́ ibùgbé rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 3:17-19) Ádámù àti Éfà yàn láti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, torí náà kò sí ìrètí kankan fún wọn mọ́. Ohun tí Ádámù ṣe yìí ló mú kí ‘ẹ̀ṣẹ̀ wọ ayé, tí ikú sì wá nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ikú ṣe tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn torí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.’ (Róòmù 5:12) Lẹ́yìn tí Ádámù dẹ́ṣẹ̀, ó ‘ta’ ara rẹ̀ àti àwa ọmọ rẹ̀ sí oko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Róòmù 7:14) Ṣé ìrètí kankan wà fún wa? Bẹ́ẹ̀ ni, ó wà.
7, 8. Kí ni ìràpadà?
7 Kí ni ìràpadà túmọ̀ sí? Àkọ́kọ́, ìràpadà lè jẹ́ iye tá a san láti dá ẹnì kan sílẹ̀ tàbí iye tá a fi ra ohun kan pa dà. Ìkejì, ìràpadà lè jẹ́ owó tá a san ká lè rí ohun kan gbà.
8 Kò sí ẹ̀dá èèyàn kankan tó lè rà wá pa dà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tí Ádámù mú wá sórí wa nígbà tó dẹ́ṣẹ̀. Àmọ́, Jèhófà pèsè ọ̀nà tá a máa gbà bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Ẹ jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Ọlọ́run ṣe pèsè ìràpadà náà àti bá a ṣe lè jàǹfààní ẹ̀.
BÍ JÈHÓFÀ ṢE PÈSÈ ÌRÀPADÀ
9. Ta ló yẹ kó san ìràpadà?
9 Kò sí ẹnì kankan nínú wa tó lè san ìràpadà fún ẹ̀mí tí Ádámù tó jẹ́ ẹni pípé sọ nù. Kí nìdí? Ìdí ni pé aláìpé ni gbogbo wa. (Sáàmù 49:7, 8) Torí náà, ẹ̀mí èèyàn pípé ló gbọ́dọ̀ san ìràpadà náà. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pè é ní “ìràpadà tó bá a mu rẹ́gí.” (1 Tímótì 2:6) Ìyẹn ni pé bí ìràpadà náà ṣe níye lórí tó gbọ́dọ̀ ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ohun tí Ádámù sọ nù.
10. Báwo ni Jèhófà ṣe pèsè ìràpadà náà?
10 Báwo ni Jèhófà ṣe pèsè ìràpadà náà? Ó rán Jésù ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n wá sáyé. Ọmọ yìí ni Ọlọ́run kọ́kọ́ dá. (1 Jòhánù 4:9,10) Tinútinú ni Jésù yọ̀ǹda láti fi Baba rẹ̀ sílẹ̀ lọ́run. (Fílípì 2:7) Jèhófà mú kí Jésù fi ọ̀run sílẹ̀ wá sí ayé, wọ́n sì bí Jésù sáyé ní ẹ̀dá èèyàn tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀.—Lúùkù 1:35.
11. Báwo ni ìràpadà tí ẹnì kan ṣoṣo san ṣe lè gba gbogbo èèyàn là?
11 Nígbà tí ọkùnrin àkọ́kọ́ náà Ádámù tó jẹ́ ẹni pípé ṣàìgbọràn sí Jèhófà, ó mú kí gbogbo èèyàn pàdánù ẹ̀mí pípé tó yẹ kí wọ́n ní. Ǹjẹ́ ẹnì kankan wà tó lè mú ikú kúrò lórí gbogbo àwọn ọmọ Ádámù? Bẹ́ẹ̀ ni. (Ka Róòmù 5:19.) Jésù tó jẹ́ ẹni pípé fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà. (1 Kọ́ríńtì 15:45) Torí náà, ẹ̀mí rẹ̀ pípé tó fi lélẹ̀ máa mú kó ṣeé ṣe fún àwọn ọmọ Ádámù láti bọ́ lọ́wọ́ ikú.—1 Kọ́ríńtì 15:21, 22.
12. Kí nìdí tí Jésù fi jìyà púpọ̀ kó tó kú?
12 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù jìyà púpọ̀ kó tó kú. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n nà án lẹ́gba lọ́nà tó burú jáì, wọ́n kàn án mọ́ òpó igi oró, wọ́n sì dá a lóró títí tó fi kú. (Jòhánù 19:1, 16-18, 30) Kí nìdí tí Jésù fi jìyà púpọ̀ kó tó kú? Ìdí ni pé Sátánì ti sọ pé kò sẹ́ni tó máa jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run tó bá dojú kọ àdánwò tó le gan-an. Jésù fi hàn pé ó ṣeé ṣe fún èèyàn pípé láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run, kódà tó bá ń jìyà tó pọ̀ gan-an. Ẹ ò rí i pé inú Jèhófà máa dùn sí Jésù gan-an!—Òwe 27:11; wo Àlàyé Ìparí Ìwé 15.
13. Báwo la ṣe san ìràpadà náà?
13 Báwo la ṣe san ìràpadà náà? Jèhófà fàyè gba àwọn ọ̀tá Jésù láti pa á ní Nísàn 14, ọdún 33, ti kàlẹ́ńdà àwọn Júù. (Hébérù 10:10) Ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà, Jèhófà jí ọmọ rẹ̀ dìde ní ẹni ẹ̀mí, kì í ṣe ní ẹ̀dá èèyàn. Lẹ́yìn náà, nígbà tí Jésù pa dà sọ́dọ̀ Baba rẹ̀ lọ́run, ó wá gbé ẹ̀tọ́ tó ní láti máa wà láàyè bí èèyàn pípé ní ayé fún Jèhófà kó lè fi ṣe ìràpadà. (Hébérù 9:24) Ní báyìí Jèhófà ti san ìràpadà náà, ìyẹn mú ká ní àǹfààní láti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.—Ka Róòmù 3:23, 24.
BÓ O ṢE LÈ JÀǸFÀÀNÍ NÍNÚ ÌRÀPADÀ NÁÀ
14, 15. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà?
14 Ní báyìí, à ń gbádùn ẹ̀bùn Ọlọ́run tó dáa jù lọ. Ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn nǹkan tá à ń gbádùn ní báyìí àti ohun tá a máa gbádùn lọ́jọ́ iwájú.
15 Ó ń jẹ́ ká rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. Kì í rọrùn láti ṣe ohun tó tọ́ ní gbogbo ìgbà. A máa ń ṣe àṣìṣe, a sì máa ń ṣe àwọn ohun tí kò dáa nígbà míì. (Kólósè 1:13, 14) Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà? A gbọ́dọ̀ ronú pìwà dà tọkàntọkàn, ká sì bẹ Jèhófà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé kó dárí jì wá. Ìyẹn ló máa mú kí Ọlọ́run dárí jì wá.—1 Jòhánù 1:8, 9.
16. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́?
16 Ó ń jẹ́ ká ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. Tá a bá ṣe ohun tí kò dáa, ẹ̀rí ọkàn wa máa dá wa lẹ́bi, ó tiẹ̀ lè jẹ́ ká rò pé ọ̀rọ̀ wa ti kọjá àtúnṣe àti pé a ò já mọ́ nǹkan kan. Àmọ́, a ò ní jẹ́ kó sú wa. Ó dá wa lójú pé tá a bá bẹ Jèhófà pé kó dárí jì wá, ó máa gbọ́ wa, á sì dárí jì wá. (Hébérù 9:13, 14) Jèhófà fẹ́ ká sọ àwọn ìṣòro èyíkéyìí tá a bá ní fún òun, títí kan àwọn ibi tá a kù sí. (Hébérù 4:14-16) Ìyẹn ló máa jẹ́ ká ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ níwájú Ọlọ́run.
17. Àǹfààní wo ni ikú Jésù ṣe wá?
17 Ó jẹ́ ká ní ìrètí láti wà láàyè títí láé. “Nítorí ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀, àmọ́ ìyè àìnípẹ̀kun ni ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fúnni nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.” (Róòmù 6:23) Ikú Jésù jẹ́ ká ní ìrètí láti wà láàyè títí láé, ká sì ní ìlera pípé. (Ìfihàn 21:3, 4) Àmọ́, kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká lè gbádùn àwọn ìbùkún yẹn?
ṢÉ O MỌYÌ Ẹ̀BÙN ÌRÀPADÀ NÁÀ?
18. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa?
18 Ó dájú pé inú rẹ máa ń dùn tẹ́nì kan bá fún ẹ lẹ́bùn tó dára. Ìràpadà ni ẹ̀bùn tó ju gbogbo ẹ̀bùn lọ, ó sì yẹ ká máa dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Jèhófà nítorí ẹ̀bùn iyebíye yìí. Jòhánù 3:16 sọ pé “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé gan-an débi pé ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni.” Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó fún wa ní Jésù Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n. Ó dájú pé Jésù náà nífẹ̀ẹ́ wa, torí ó gbà láti kú nítorí wa. (Jòhánù 15:13) Ó yẹ kí ẹ̀bùn ìràpadà náà jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà àti Jésù nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an.—Gálátíà 2:20.
19, 20. (a) Báwo lo ṣe lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà? (b) Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o mọyì ẹbọ ìràpadà Jésù?
19 Ní báyìí tó o ti mọ̀ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ tó jinlẹ̀ sí wa, báwo lo ṣe lè di ọ̀rẹ́ rẹ̀? Kò rọrùn láti nífẹ̀ẹ́ ẹnì kan tí o kò mọ̀. Jòhánù 17:3 sọ pé a lè wá mọ Jèhófà. Bó o ṣe ń ṣe èyí, ìfẹ́ tó o ní sí i á túbọ̀ jinlẹ̀, á máa wù ẹ́ láti mú inú rẹ̀ dùn, wàá sì di ọ̀rẹ́ rẹ̀. Torí náà, máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìṣó kó o lè túbọ̀ mọ Jèhófà.—1 Jòhánù 5:3.
20 Fi hàn pé o mọyì ẹbọ ìràpadà Jésù. Bíbélì sọ pé “Ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:36) Kí ló túmọ̀ sí láti ní ìgbàgbọ́? Ó túmọ̀ sí pé ká máa ṣe ohun tí Jésù kọ́ wa. (Jòhánù 13:15) A ò kàn lè fẹnu lásán sọ pé a gba Jésù gbọ́. Tá a bá fẹ́ fi hàn pé a mọyì ìràpadà náà, a gbọ́dọ̀ máa ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́. Jémíìsì 2:26 sọ pé: “Ìgbàgbọ́ láìsí àwọn iṣẹ́ jẹ́ òkú.”
21, 22. (a) Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ máa lọ síbi Ìrántí Ikú Kristi lọ́dọọdún? (b) Kí la máa kẹ́kọ̀ọ́ ní Orí 6 àti 7?
21 Máa lọ síbi Ìrántí Ikú Kristi. Lálẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ikú Jésù, ó kọ́ wa pé ká máa ṣe ìrántí ikú òun. A máa ń ṣe èyí lọ́dọọdún, a sì ń pè é ní Ìrántí Ikú Kristi tàbí “Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 11:20; Mátíù 26:26-28) Jésù fẹ́ ká máa rántí pé òun fi ẹ̀mí òun pípé lélẹ̀ láti rà wá pa dà. Ó sọ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (Ka Lúùkù 22:19.) Nígbà tó o bá lọ síbi Ìrántí Ikú Kristi, ó fi hàn pé ò ń rántí ìràpadà náà àti ìfẹ́ tó ga jù lọ tí Jèhófà àti Jésù ní fún wa.—Wo Àlàyé Ìparí Ìwé 16.
22 Ìràpadà náà ni ẹ̀bùn tó ga jù lọ tá a lè rí gbà. (2 Kọ́ríńtì 9:14, 15) Kódà, àìmọye èèyàn tó ti kú máa jàǹfààní ẹ̀bùn tó ṣeyebíye yẹn. A máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa èyí ní Orí 6 àti 7.