ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 2A
Bá A Ṣe Lè Lóye Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì
KÍ NI ÀSỌTẸ́LẸ̀?
Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ ìṣe inú èdè Hébérù tí wọ́n ń pè ní na·vaʼʹ, túmọ̀ sí “sọ tẹ́lẹ̀.” Ní pàtàkì, ó ń tọ́ka sí ìkéde ọ̀rọ̀ tá a mí sí, ìdájọ́, ẹ̀kọ́ nípa ìwà híhù tàbí àṣẹ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ó tún lè túmọ̀ sí ìkéde ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe lọ́jọ́ iwájú. Gbogbo ohun tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá yìí ló wà nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì.—Ìsík. 3:10, 11; 11:4-8; 14:6, 7; 37:9, 10; 38:1-4.
ÀWỌN Ọ̀NÀ TÓ GBÀ JÍṢẸ́
ÌRAN
ÀPÈJÚWE
ÀṢEFIHÀN
Àwọn ohun tó wà nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì ni ìran, àpèjúwe, àkàwé àti àṣefihàn àwọn àsọtẹ́lẹ̀.
BÍ WỌ́N ṢE ṢẸ
Nígbà míì, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Ìsíkíẹ́lì sọ máa ń ṣẹ ju ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo lọ. Bí àpẹẹrẹ, díẹ̀ lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí nǹkan ṣe máa pa dà bọ̀ sípò ló ṣẹ nígbà tí àwọn èèyàn Ọlọ́run pa dà sí Ilẹ̀ Ìlérí. Àmọ́ bá a ṣe sọ ní Orí 9 ìwé yìí, ọ̀pọ̀ lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí nǹkan ṣe máa pa dà bọ̀ sípò ló ṣẹ lóde òní, tí wọ́n sì tún máa ṣẹ lọ́jọ́ iwájú.
Tẹ́lẹ̀, a máa ń ronú pé àwọn apá kan nínú àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì dúró fún nǹkan míì tó máa ṣẹlẹ̀. Àmọ́ nínú ìwé yìí, a ò sọ pé ẹnì kan, ohun kan, ibì kan tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ kan dúró fún nǹkan míì lóde òní, àfi tí Ìwé Mímọ́ bá jẹ́ kó ṣe kedere pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí.a Dípò bẹ́ẹ̀, ìwé yìí máa sọ bí ọ̀pọ̀ nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì ṣe ṣẹ lọ́nà tó gbòòrò. Ó tún máa sọ àwọn ohun tá a lè rí kọ́ látinú iṣẹ́ tí Ìsíkíẹ́lì jẹ́, títí kan àwọn èèyàn tó jíṣẹ́ ọ̀hún fún, àwọn ibi tó ti jíṣẹ́ náà àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó mẹ́nu bà.
a Tó o bá fẹ́ àlàyé lórí àwọn ohun kan tó dúró fún ohun míì tó máa ṣẹlẹ̀, wo Ilé Ìṣọ́, March 15, 2015, ojú ìwé 9 sí 11, ìpínrọ̀ 7 sí 12; àti “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé,” ojú ìwé 17 àti 18, inú ẹ̀dà kan náà ni méjèèjì wà.