Ẹ̀KỌ́ 5
Kàwé Lọ́nà Tó Tọ́
BÓ O ṢE LÈ ṢE É:
Múra sílẹ̀ dáadáa. Ronú nípa ìdí tí ọ̀rọ̀ yẹn fi wà lákọsílẹ̀. Fi kọ́ra láti máa ka àwọn ọ̀rọ̀ bíi mélòó kan pa pọ̀, kó má ṣe jẹ́ ẹyọ ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan ni wàá kàn máa kà. Má ṣe fi ọ̀rọ̀ kún un, má ṣe fo ọ̀rọ̀, má sì ṣe fi ọ̀rọ̀ kan pe òmíì. Máa kíyè sí àwọn àmì tá a fi ń pín gbólóhùn.
Pe ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan bó ṣe tọ́. Tí o kò bá mọ bó o ṣe máa pe ọ̀rọ̀ kan, o lè wo inú ìwé atúmọ̀ èdè, o lè tẹ́tí sí ìtẹ̀jáde náà tá a ti gba ohùn rẹ̀ sílẹ̀, tàbí kó o sọ pé kí ẹnì kan tó mọ̀wé kà dáadáa ràn ẹ́ lọ́wọ́.
Sọ̀rọ̀ ketekete. Fara balẹ̀ pe ọ̀rọ̀, gbé orí sókè, kó o sì la ẹnu rẹ dáadáa. Rí i pé ò ń pè ọ̀rọ̀ lọ́nà tó ṣe kedere.