Sún Mọ́ Ọlọ́run
Ó Fún Wa Lómìnira Láti Ṣe Ohun Tó Wù Wá
Ó YẸ kí àwọn òbí fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún àwọn ọmọ wọn. Ìwà rere òbí lè jẹ́ kí ọmọ ní àwọn ànímọ́ tó dára, tí á sì lè máa ṣe àwọn ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu nígbèésí ayé rẹ̀. Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ òbí ni kò fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún àwọn ọmọ wọn. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ kò lè ṣàṣeyọrí? Òtítọ́ kan tó dájú ni pé, Jèhófà Ọlọ́run ti fún wa lómìnira láti ṣe ohun tó wù wá, èyí sì jẹ́ ká lè dáhùn ìbéèrè yìí. Jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀rọ̀ Hesekáyà nínú ìwé 2 Àwọn Ọba 18:1-7.
“Áhásì ọba Júdà” ló bí Hesekáyà. (Ẹsẹ 1) Áhásì kó àwọn tó ń ṣàkóso lé lórí ṣìnà kúrò nínú ìjọsìn Jèhófà. Ọba búburú yìí wá ń jọ́sìn Báálì, ó sì ń fi èèyàn rúbọ sí Báálì. Ó pa ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn arákùnrin Hesekáyà. Áhásì ti ilẹ̀kùn tẹ́ńpìlì pa, ó sì “ṣe àwọn pẹpẹ fún ara rẹ̀ ní gbogbo igun ọ̀nà ní Jerúsálẹ́mù.” Ó “mú Jèhófà . . . bínú.” (2 Kíróníkà 28:3, 24, 25) Kò sí iyèméjì pé bàbá burúkú ló bí Hesekáyà. Ṣé Hesekáyà máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ bàbá rẹ̀?
Nígbà tí Hesekáyà gorí ìtẹ́ lẹ́yìn Áhásì bàbá rẹ̀, kò pẹ́ tó fi hàn pé òun kò ní tẹ̀ lé àpẹẹrẹ búburú bàbá òun. Hesekáyà “ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà.” (Ẹsẹ 3) Hesekáyà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, “kò tún wá sí ẹnì kankan tí ó dà bí rẹ̀ nínú gbogbo ọba Júdà.” (Ẹsẹ 5) Ní ọdún àkọ́kọ́ ìgbà ìṣàkóso rẹ̀, ọ̀dọ́mọdé ọba yìí bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àtúnṣe nínú ìjọsìn, èyí sì yọrí sí mímú àwọn ibi gíga tí wọ́n ti ń ṣe ìjọsìn èké kúrò. Wọ́n ṣí tẹ́ńpìlì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìsìn tòótọ́ pa dà. (Ẹsẹ 4; 2 Kíróníkà 29:1-3, 27-31) Hesekáyà “ń bá a nìṣó ní fífà mọ́ Jèhófà . . . , Jèhófà sì wà pẹ̀lú rẹ̀.”—Ẹsẹ 6, 7.
Kí ló mú kí Hesekáyà yàgò fún àpẹẹrẹ búburú bàbá rẹ̀? Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí Ábíjà ìyá rẹ̀ tí a kò fi bẹ́ẹ̀ mọ ohun púpọ̀ nípa rẹ̀ ní ipa rere lórí ọmọkùnrin rẹ̀ yìí? Àbí àpẹẹrẹ rere Aísáyà tó ti ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó bí Hesekáyà ní ipa rere lórí ọ̀dọ́mọdé ọba yìí?a Bíbélì kò sọ. Èyí tó wù kó jẹ́, ohun kan dájú, ohun náà ni pé, Hesekáyà yàn láti ṣe ohun tó yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí bàbá rẹ̀ ṣe.
Ìṣírí ni àpẹẹrẹ Hesekáyà jẹ́ fún ẹnikẹ́ni tí nǹkan kò rọgbọ fún nígbà tó wà ní kékeré nítorí àpẹẹrẹ búburú àwọn òbí rẹ̀. Kò sí ohun tí a lè ṣe sí ohun tó ti kọjá, àpá kò lè jọ àwọ̀ ara. Àmọ́ àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ kò túmọ̀ sí pé a kò lè ṣàṣeyọrí. Ìpinnu tá a bá ṣe lè jẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la wa dùn bí oyin. Bíi ti Hesekáyà, a lè yàn láti nífẹ̀ẹ́ àti láti jọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́. Irú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀ máa jẹ́ ká ní ìtẹ́lọ́rùn nísinsìnyí, ó sì lè yọrí sí ìyè ayérayé fún wa nínú ayé tuntun Ọlọ́run. (2 Pétérù 3:13; Ìṣípayá 21:3, 4) A mà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ tó fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa láǹfààní tó ṣeyebíye jù lọ, ìyẹn òmìnira láti ṣe ohun tó wù wá!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ láti nǹkan bí ọdún 778 ṣáájú Sànmánì Kristẹni títí di ẹ̀yìn nǹkan bí ọdún 732 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Hesekáyà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lọ́dún 745 ṣáájú Sànmánì Kristẹni nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25].