Kí Ló Ti Jẹ́ Àbájáde Ẹ̀kọ́ Ìsìn Calvin Láti Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta Ọdún?
ỌDÚN 1509 ni wọ́n bí Jean Cauvin (ìyẹn John Calvin) nílùú Noyon, lórílẹ̀-èdè Faransé. Ó dá ìsìn kan sílẹ̀ tó kó ipa pàtàkì nínú ìgbésí ayé àwọn èèyàn ilẹ̀ Yúróòpù, àwọn ilẹ̀ Amẹ́ríkà, Gúúsù Áfíríkà àtàwọn ilẹ̀ mìíràn. Wọ́n kà á sí ọ̀kan pàtàkì lára àwọn Alátùn-únṣe ṣọ́ọ̀ṣì nínú ìtàn Ìwọ̀ Oòrùn ayé.
Lónìí, ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ọdún lẹ́yìn tí wọ́n bí Calvin, ẹ̀kọ́ ìsìn Calvin ṣì wà ní oríṣiríṣi ọ̀nà nínú ẹ̀ka ṣọ́ọ̀ṣì àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì, ìyẹn àwọn tó ń ṣàtúnṣe ìsìn bíi ṣọ́ọ̀ṣì Reformed, Presbyterian, Congregational, Puritan àtàwọn míì. Ní September ọdún 2009, Àgbájọ àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Alátùn-únṣe kárí ayé ní àwọn ọmọ ìjọ tí wọ́n jẹ́ mílíọ̀nù márùn-ún dín lọ́gọ́rin ní orílẹ̀-èdè tó jẹ́ ọgọ́rùn-ún lé méje [107].
Ó Gbéjà Ko Ìsìn Kátólíìkì
Bàbá John jẹ́ agbẹjọ́rò àti akọ̀wé fún ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì nílùú Noyon. Ó ṣeé ṣe kí iṣẹ́ rẹ̀ mú kó mọ púpọ̀ nípa bí ìwàkiwà táwọn àlùfáà ń hù ti gbilẹ̀ tó nígbà yẹn. Kò dá wa lójú bóyá èyí yọrí sí ìwọ́de lòdì sí ṣọ́ọ̀ṣì tàbí àìbọ̀wọ̀ fún ṣọ́ọ̀ṣì, àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n yọ bàbá John àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin kúrò ní ṣọ́ọ̀ṣì. Nígbà tí bàbá John kú, ó dojú kọ ìṣòro torí pé wọn kò gbà láti sin ín gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí túbọ̀ mú kí ìgbẹ́kẹ̀lé tí John ní nínú ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì dín kù.
Ọ̀pọ̀ ìwé tó sọ nípa Calvin kò sọ ohun tó pọ̀ nípa ìgbà èwe rẹ̀ yàtọ̀ sí pé ó jẹ́ ẹni tí kì í fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀. Kódà nígbà tó ń kàwé ní Paris, Orléans àti Bourges, ó jọ pé ọ̀rẹ́ díẹ̀ ló ní. Àmọ́ Calvin ní ẹ̀bùn títètè lóye nǹkan, ó sì máa ń rántí nǹkan gan-an. Ẹ̀bùn tó ní yìí àti agbára àrà ọ̀tọ̀ tó ní láti ṣiṣẹ́ mú kó máa kẹ́kọ̀ọ́ láti aago márùn-ún òwúrọ̀ títí di aago méjìlá òru. Èyí mú kó di ọ̀mọ̀wé nípa òfin kó tó di ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún. Ó tún kọ́ èdè Hébérù, Gíríìkì àti Látìn kó bàa lè mọ̀ nípa Bíbélì. Àmọ́, èyí tó gba iwájú jù lọ nínú ìwà Calvin ni pé kì í fi iṣẹ́ ṣeré, ìwà yìí lọ̀pọ̀ èèyàn lónìí sì gbà pé ó jẹ́ ara ẹ̀kọ́ Calvin.
Ní àkókò yẹn, ní àgbègbè ẹnubodè ní orílẹ̀-èdè Jámánì, ọ̀gbẹ́ni Martin Luther ń ṣàríwísí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ní gbangba nítorí ìwà ìbàjẹ́ àti àwọn ẹ̀kọ́ tí kò bá Bíbélì mu tó wà nínú ṣọ́ọ̀ṣì náà. ọ̀pọ̀ èèyàn sọ nípa rẹ̀ pé lọ́dún 1517, ó lẹ àwọn ọ̀rọ̀ márùn-ún dín lọ́gọ́rùn-ún mọ́ ilẹ̀kùn Ṣọ́ọ̀ṣì kan nílùú Wittenberg, tó fi ń ta kò wọ́n pé kí ṣọ́ọ̀ṣì ṣe àtúnṣe ẹ̀kọ́ rẹ̀. Ọ̀pọ̀ ló gba ohun tí Luther sọ, Àtúnṣe Ìsìn sì tàn ká gbogbo ilẹ̀ Yúróòpù. Lóòótọ́, ó dá àtakò tó gbóná janjan sílẹ̀ níbi tó pọ̀, àwọn tó ń fẹ́ àtúnṣe ìsìn fẹ̀mí ara wọn wewu bí wọ́n ti ń sọ èrò wọn káàkiri. Lọ́dún 1533 nílùú Paris, ọ̀rẹ́ Calvin tó ń jẹ́ Nicholas Cop sọ àsọyé kan tó fi ti Luther lẹ́yìn, nígbà tó sì jẹ́ pé Calvin ló bá a kọ ọ̀rọ̀ tó sọ náà, àwọn méjèèjì ní láti sá àsálà fún ẹ̀mí wọn. Calvin kò tún pa dà wá gbé ilẹ̀ Faransé mọ́.
Lọ́dún 1536, Calvin tẹ ìwé kan jáde nípa ohun tí àwọn Alátùn-únṣe Ìsìn gbà gbọ́, ìyẹn ìwé Institutes of the Christian Religion. Ó fi ránṣẹ́ sí Ọba Francis Kìíní láti fi gbèjà àwọn Alátùn-únṣe Ìsìn tó wà nílẹ̀ Faransé, ìyẹn àwọn tá a wá mọ̀ sí Huguenots nígbà tó yá. Calvin gbéjà ko àwọn ẹ̀kọ́ Kátólíìkì, ó sì di òpó ìgbàgbọ́ tirẹ̀ mú, pé Ọlọ́run ni ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. Yàtọ̀ sí ipa tí ìwé Institutes tí Calvin kọ ní lórí ọ̀ràn ìsìn, ó tún nípa lórí èdè Faransé àti ọ̀nà ìgbàkọ̀wé wọn. Wọ́n kókìkí Calvin pé ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Alátùn-únṣe Ìsìn tó gba iwájú jù lọ. Níkẹyìn, ó fìdí kalẹ̀ sí ìlú Geneva, lórílẹ̀-èdè Switzerland, ó sì gbájú mọ́ iṣẹ́ àtúnṣe ìsìn tó ń ṣe láti ìlú náà, láti ọdún 1541 síwájú.
Ó Ń Ṣe Àtúnṣe Ìsìn Nílùú Geneva
Ipa tí Calvin ní lórí ìlú Geneva lágbára gan-an ni. Nítorí ìwà rere àti òdodo tó wà lọ́kàn Calvin, ó yí Geneva pa dà, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ nípa ìsìn, ìyẹn Encyclopedia of Religion sọ pé, ó yí “ìlú oníwà ìbàjẹ́ náà pa dà di ìlú tí ìlànà rere ń darí ìwà gbogbo olùgbé ibẹ̀.” Àwọn ìyípadà tún ṣẹlẹ̀ láwọn ọ̀nà míì. Ọ̀mọ̀wé Sabine Witt, tó ń bójú tó àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé ilẹ̀ Jámánì ní Ilé Ìkóhun-Ìṣẹ̀ǹbáyé sí tó wà nílùú Berlin, ṣàlàyé pé: “Nítorí àwọn ogun ìsìn tó ń lọ lọ́wọ́ nílẹ̀ Faransé, iye èèyàn ìlú Geneva di ìlọ́po méjì láàárín ọdún díẹ̀ nítorí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Alátùn-únṣe Ìsìn tó ń sá wá sí ibi ìsádi.” Àwọn Huguenots tí wọ́n dà bíi Calvin tí kì í fiṣẹ́ ṣeré, mú kí ọrọ̀ ajé ìlú Geneva bú rẹ́kẹ́, wọ́n sì sọ ọ́ di ibi tí wọ́n ti ń tẹ̀wé àti ibi tí wọ́n ti ń ṣe aago.
Àwọn tó ń wá ibi ìsádi láti orílẹ̀-èdè míì náà tún wá sí ìlú Geneva títí kan ọ̀pọ̀ láti ilẹ̀ England, níbi tí Ọbabìnrin Mary Kìíní ti gbógun ti àwọn Alátùn-únṣe Ìsìn. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Calvin tí ọ̀pọ̀ jù lọ wọn jẹ́ àwọn tí wọ́n lé kúrò nílùú tipa báyìí gbé ẹ̀kọ́ ìsìn kan kalẹ̀, tí ìwé ìròyìn ìsìn náà, Christ in der Gegenwart pè ní “ẹ̀kọ́ ìsìn àwọn tí wọ́n ṣe inúnibíni sí.” Lọ́dún 1560 àwọn olùwá ibi ìsádi tẹ Bíbélì Geneva Bible, ìyẹn Bíbélì àkọ́kọ́ lédè Gẹ̀ẹ́sì tó ní àwọn ẹsẹ tí wọ́n fi nọ́ńbà sí. Nítorí pé Bíbélì yìí kò tóbi púpọ̀, ó mú kí ìdákẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run túbọ̀ rọrùn. Ó lè jẹ́ pé ẹ̀dà Bíbélì yìí làwọn Puritans mú dání nígbà tí wọ́n ṣí lọ sí Amẹ́ríkà Àríwá lọ́dún 1620.
Àmọ́ kì í ṣe gbogbo èèyàn ló rí ààbò nílùú Geneva. Ọdún 1511 ni wọ́n bí Michael Servetus, lórílẹ̀-èdè Sípéènì, ó kọ́ èdè Gíríìkì, Látìn, Hébérù àti ẹ̀kọ́ nípa ìṣègùn, ó sì ṣeé ṣe kó ti pàdé Calvin nígbà táwọn méjèèjì wà nílé ẹ̀kọ́ nílùú Paris. Ẹ̀kọ́ tí Servetus kọ́ nínú Bíbélì mú kó gbà pé ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Ó sapá láti kọ̀wé sí Calvin lórí ọ̀ràn yìí, àmọ́ ọ̀tá ni Calvin ka Servetus sí. Àwọn Kátólíìkì tó wà nílẹ̀ Faransé ṣe inúnibíni sí Servetus, ó sá lọ sí ìlú Geneva níbi tí Calvin wà. Dípò kí wọ́n tẹ́wọ́ gbà á, ńṣe ni wọ́n mú un, wọ́n bá a ṣẹjọ́ pé ó ta ko ẹ̀kọ́ tí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́, wọ́n sì dáná sun ún lórí òpó igi lọ́dún 1553. Òpìtàn Friedrich Oehninger sọ pé, “Pípa tí wọ́n pa Servetus kó ẹ̀gàn bá Calvin táwọn èèyàn kà sí Alátùn-únṣe Ìsìn tó gbayì, ó sì tún kó ẹ̀gàn bá iṣẹ́ rẹ̀.”
Calvin kọ ọ̀pọ̀ ìwé nígbà tó wà lẹ́nu ṣíṣe àtúnṣe ìsìn. Wọ́n sọ pé ó kọ ìwé tó lé lọ́gọ́rùn-ún [100] téèyàn lè fi ṣèwádìí àti àwọn lẹ́tà tó lé lẹ́gbẹ̀rún [1000], ó tún wàásù ní gbangba ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [4000] ìgbà ní Geneva. Yàtọ̀ sí pé Calvin sọ èrò rẹ̀ nípa ohun tó yẹ kí ẹ̀sìn Kristẹni jẹ́, ó tún fipá mú káwọn èèyàn tọ ọ̀nà tó rò pé ó yẹ káwọn Kristẹni máa gbà gbé ìgbé ayé wọn, pàápàá ní Geneva, èyí tó pè ní ìlú Ọlọ́run.a
Kí ni àbájáde ìsapá tí Calvin ṣe láti ṣàtúnṣe ìsìn ní Geneva? Gẹ́gẹ́ bí ọ́fíìsì ìfìṣirò-ṣèwádìí ti Ìjọba Àpapọ̀ Swiss ti wí, lọ́dún 2000, èèyàn mẹ́rìndínlógún nínu ọ̀gọ́rùn-ún àwọn ará Geneva ló ń lọ sí Ṣọ́ọ̀ṣì Alátùn-únṣe (ti Calvin), àwọn Kátólíìkì ibẹ̀ sì pọ̀ jù wọ́n lọ.
Ìsìn Túbọ̀ Ń Pín Yẹ́lẹyẹ̀lẹ
Ohun tó jẹ́ àbájáde Àtúnṣe Ìsìn ni pé, ìlú kọ̀ọ̀kan àti ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan pinnu pé ẹ̀sìn Kátólíìkì, ẹ̀sìn Luther tàbí ẹ̀sìn Calvin, làwọn fẹ́ máa ṣe, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ sọ ilẹ̀ Yúróòpù di ibi tí ẹ̀sìn ti pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Alátùn-únṣe Ìsìn ṣọ̀kan nínú àríwísí wọn nípa ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì, àmọ́, kò sí ìṣọ̀kan láàárín wọn. Ọ̀mọ̀wé Witt, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ sọ pé: “Àárín àwọn Alátùn-únṣe Ìsìn gan-an ni àìsí ìṣọ̀kan nínú ẹ̀kọ́ ìsìn ti bẹ̀rẹ̀.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo wọn gbà pé Bíbélì ló yẹ kó jẹ́ ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ Kristẹni, àmọ́ tó bá dọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ ìsìn, èdèkòyédè tó wà láàárín wọn kì í ṣe kékeré. Èyí tó ń jà ràn-ìn láàárín wọn nísinsìnyí ni ohun tí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa àti wíwàníhìn-ín Kristi túmọ̀ sí. Nígbà tó yá, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Calvin gbé ọ̀kan lára ẹ̀kọ́ wọn tó ń fa àríyànjiyàn jù lọ jáde, ìyẹn àyànmọ́.
Àríyànjiyàn tó pọ̀ gan-an ló wà nípa ìtumọ̀ àyànmọ́. Àwùjọ kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Calvin sọ pé kí èèyàn tó dẹ́ṣẹ̀, Ọlọ́run ti pinnu pé àwọn èèyàn kan ló máa rí ìgbàlà nípasẹ̀ Kristi, nígbà tí àwọn yòókù kò ní rí ìgbàlà. Àwùjọ yìí gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ti pinnu láti fún ìwọ̀nba àwọn èèyàn kan ní ìgbàlà àti pé àwọn èèyàn kò dọ́gba. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Calvin yòókù sọ pé gbogbo èèyàn ló lè rí ìgbàlà àti pé ọwọ́ olúkúlùkù ló kù sí bóyá ó fẹ́ tàbí kò fẹ́. Èyí túmọ̀ sí pé ohun tí ẹnì kan bá ṣe ló máa pinnu bóyá ó máa rí ìgbàlà. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí Calvin ti kú, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kò tíì lóye ẹ̀kọ́ nípa ìpinnu Ọlọ́run, òmìnira láti ṣe ohun téèyàn fẹ́ àti ẹ̀tọ́ ọgbọọgba láàárín ọmọ èèyàn.
Ohun Tí Ìgbàgbọ́ Calvin Dá Sílẹ̀
Ní ọgọ́rùn-ún ọdún lọ́nà ogún, ẹ̀kọ́ àyànmọ́ dá ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè South Africa. Ṣọ́ọ̀ṣì Alátùn-únṣe Dutch ti àwọn ọmọ ẹ̀yìn Calvin ló sì ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ náà. Ọ̀gbẹ́ni Nelson Mandela tó jẹ́ ààrẹ aláwọ̀ dúdú àkọ́kọ́ fun ilẹ̀ South Africa sọ nípa ìlànà aláwọ̀ funfun lọ́gàá ti ìjọba ṣe pé: “Ṣọ́ọ̀ṣì Alátùn-únṣe Dutch fọwọ́ sí ìlànà yìí, èyí sì mú kí àwọn èèyàn ṣe kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà nítorí pé ìsìn fọwọ́ sí i pé àwọn ẹ̀yà Afrikaners ni Ọlọ́run yàn àti pé ẹrú làwọn adúláwọ̀. Èrò àwọn Afrikaners ni pé ṣọ́ọ̀ṣì ti kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà lẹ́yìn.”
Láwọn ọdún 1990 sí 1999, Ṣọ́ọ̀ṣì Alátùn-únṣe ti Dutch tọrọ àforíjì ní gbangba fún bó ṣe ṣètìlẹ́yìn fún kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà. Nínú ọ̀rọ̀ kan táwọn aláṣẹ ìjọba fọwọ́ sí, èyí tí wọ́n pè ní Ìkéde Rustenburg, àwọn olórí ṣọ́ọ̀ṣì sọ pé: “Àwọn kan lára wa lo Bíbélì lọ́nà òdì pé ó dá kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà láre, èyí tó mú kí ọ̀pọ̀ gbà gbọ́ pé Ọlọ́run fọwọ́ sí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà.” Yàtọ̀ sí pé ìtìlẹ́yìn tí ṣọ́ọ̀ṣì ṣe fún ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà dá ẹ̀tanú sílẹ̀ láàárín àwọn ẹ̀yà, ó tún sọ pé Ọlọ́run ló yẹ ká dá lẹ́bi!
Ọ̀gbẹ́ni John Calvin kú ní ìlú Geneva lọ́dún 1564. Kó tó kú, wọ́n sọ pé ó dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ará ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ “fún dídá ẹnì kan lọ́lá tó pọ̀ gan-an bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò yẹ kí wọ́n dá a lọ́lá,” ó sì tọrọ àforíjì nítorí àìnísùúrù àti ìbínú tó ti mọ́ òun lára. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè ní àwọn kùdìẹ̀kudiẹ yẹn, kò sí iyèméjì pé iṣẹ́ Alátùn-únṣe Ìsìn tí John Calvin ṣe fi hàn pé ó jẹ́ alákitiyan, aláìgbagbẹ̀rẹ́ àti ẹni tó máa ń fi gbogbo ara ṣiṣẹ́.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka ìwé Mankind’s Search for God, ojú ìwé 321 sí 325. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí tó wà ní ojú ìwé 21]
Ohun tó jẹ́ àbájáde Àtúnṣe Ìsìn ni pé, ìlú kọ̀ọ̀kan àti ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kàn pinnu pé ẹ̀sìn Kátólíìkì, ẹ̀sìn Luther tàbí ẹ̀sìn Calvin, làwọn fẹ́ máa ṣe, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ sọ ilẹ̀ Yúróòpù di ibi tí ẹ̀sìn ti pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 18]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
SÍPÉÉNÌ
ILẸ̀ FARANSÉ
PARIS
Noyon
Orléans
Bourges
SWITZERLAND
GENEVA
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Ìwé “Institutes” tí Calvin kọ (1536) sọ ohun tí àwọn Alátùn-únṣe Ìsìn gbà gbọ́
[Credit Line]
© INTERFOTO/Alamy
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Pípa tí wọ́n pa Servetus kó ẹ̀gàn bá Calvin àti iṣẹ́ rẹ̀
[Credit Line]
© Àwòrán Ibi Ìkówèésí Mary Evans
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Bíbélì “Geneva Bible” (1560) ni Bíbélì àkọ́kọ́ lédè Gẹ̀ẹ́sì tó ní àwọn ẹsẹ tí wọ́n fi nọ́ńbà sí
[Credit Line]
Látọwọ́ American Bible Society
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 18]
Ìlú Faransé: © Àwòrán Ibi Ìkówèésí Mary Evans