Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .
Ṣé Gbogbo Kristẹni Olóòótọ́ Ló Ń Lọ sí Ọ̀run?
▪ Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti ka ọ̀rọ̀ ìtùnú tí Jésù sọ pé: “Nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Ṣé ohun tí Jésù ń sọ ni pé gbogbo olóòótọ́ tó ń jọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Bàbá òun ló máa lọ sí ọ̀run láti gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayọ̀ tòótọ́?
Fiyè sí gbólóhùn tó ń múni ronú jinlẹ̀ tí Jésù sọ, ó ní: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó ti gòkè re ọ̀run bí kò ṣe ẹni tí ó sọ kalẹ̀ láti ọ̀run, Ọmọ ènìyàn.” (Jòhánù 3:13) Èyí túmọ̀ sí pé àwọn olóòótọ́ tó ń jọ́sìn Ọlọ́run nígbà àtijọ́, irú bíi Nóà, Ábúráhámù, Mósè àti Dáfídì, kò lọ sí ọ̀run. (Ìṣe 2:34) Ibo wá ni gbogbo wọ́n lọ? Ní kúkúrú, àwọn olóòótọ́ ìgbà àtijọ́ wà nínú sàréè, wọ́n ń sùn, wọ́n kò mọ nǹkan kan, wọ́n ń retí ìgbà tí wọ́n máa jíǹde.—Oníwàásù 9:5, 6; Ìṣe 24:15.
Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Bíbélì, Jésù lẹ́ni tó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ pé àwọn kan máa lọ sí ọ̀run lẹ́yìn tí wọ́n bá ti kú. Ó sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé òun máa pèsè àyè sílẹ̀ fún wọn ní ọ̀run. (Jòhánù 14:2, 3) Nǹkan tuntun lèyí jẹ́ fún àwọn èèyàn Ọlọ́run. Nígbà tó yá, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé lẹ́yìn tí Jésù kú tó sì jíǹde sí ọ̀run, Jésù ṣe ‘ìfilọ́lẹ̀ ọ̀nà tuntun àti ọ̀nà ààyè fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀,’ ìyẹn ọ̀nà tí ẹnì kankan kò tọ̀ rí.—Hébérù 10:19, 20.
Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé látìgbà yẹn lọ, gbogbo olóòótọ́ ni yóò máa lọ sí ọ̀run? Rárá o, ìdí ni pé àwọn èèyàn díẹ̀ kan tí wọ́n gbé iṣẹ́ fún ni àjíǹde sí ọ̀run wà fún. Ní alẹ́ tí Jésù lò kẹ́yìn pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, ó sọ fún wọn pé wọ́n máa “jókòó lórí ìtẹ́ láti ṣèdájọ́” nínú Ìjọba òun lọ́run. Nítorí náà, iṣẹ́ tí wọ́n máa ṣe ni pé wọ́n á bá Jésù ṣàkóso ní ọ̀run.—Lúùkù 22:28-30.
Yàtọ̀ sí àwọn àpọ́sítélì, àwọn èèyàn míì tún máa láǹfààní iṣẹ́ àgbàyanu yìí. Nínú ìran kan, àpọ́sítélì Jòhánù rí Jésù pẹ̀lú àwọn tó jíǹde lọ sọ́run tí wọ́n ṣàpèjúwe pé wọ́n jẹ́ ‘ìjọba àti àwọn àlùfáà láti ṣàkóso lé ayé lórí.’ (Ìṣípayá 3:21; 5:10) Mélòó ni wọ́n? Gẹ́gẹ́ bó ṣe máa ń rí nínú gbogbo ìjọba, kìkì àwọn èèyàn díẹ̀ kan ló máa ń ṣàkóso. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe rí ní ti Ìjọba ọ̀run. Jésù tó jẹ́ Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run ń ṣàkóso pẹ̀lú ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tí “a rà lára aráyé.”—Ìṣípayá 14:1, 4, 5.
Ká sòótọ́, ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] kéré tí a bá fi wé iye àwọn olóòótọ́ tó wà láyé àtijọ́ àti lóde òní. Àmọ́, ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ yé wa, ìdí ni pé ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ní iṣẹ́ mímọ́ kan tí wọ́n fẹ́ ṣe lọ́run lẹ́yìn tí wọ́n bá jíǹde. Tí o bá fẹ́ kọ́ ilé kan, ṣé gbogbo kọ́lékọ́lé tó mọṣẹ́ dunjú tó wà ní àgbègbè rẹ lo máa pè kó wá kọ́lé náà? Rárá o. Àwọn tó o nílò fún iṣẹ́ yẹn nìkan lo máa pè. Bákan náà, kì í ṣe gbogbo olóòótọ́ ni Ọlọ́run fún ní àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ yìí, láti ṣàkóso pẹ̀lú Kristi ní ọ̀run.
Ìjọba ọ̀run yìí máa ṣe ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn nígbà tó dá èèyàn. Jésù àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tí wọ́n máa ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀ yóò bójú tó bí ayé ṣe máa yí pa dà di Párádísè, níbi tí ọ̀kẹ́ àìmọye olóòótọ́ èèyàn yóò wà láàyè títí láé, tí wọ́n á sì máa yọ̀. (Aísáyà 45:18; Ìṣípayá 21:3, 4) Àwọn tó wà nínú ìrántí Ọlọ́run máa wà lára wọn, ìyẹn àwọn tí wọ́n máa jíǹde.—Jòhánù 5:28, 29.
Gbogbo àwọn olóòótọ́ tí wọ́n jọ́sìn Jèhófà láyé àtijọ́ àtàwọn tí wọ́n ń jọ́sìn rẹ̀ lóde òní lè rí ìyè àìnípẹ̀kun tó jẹ́ ẹ̀bùn àgbàyanu gbà. (Róòmù 6:23) Àwọn díẹ̀ yóò gba ìyè ní ọ̀run nítorí iṣẹ́ pàtàkì kan tí wọ́n fẹ́ ṣe níbẹ̀, àwọn tó pọ̀ gan-an yóò sì gba ìyè nínú Párádísè tó kárí ayé.