Ábúráhámù Jẹ́ Ẹni Tó Ní Ìgbàgbọ́
Ábúráhámù dúró síta ní alẹ́ ọjọ́ kan tí ojú ọjọ́ pa rọ́rọ́. Bó ṣe gbójú sókè tó ń wo àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run tó ń tàn yinrin, ó ń ronú nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún un pé irú-ọmọ rẹ̀ yóò pọ̀ rẹpẹtẹ bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run yẹn. (Jẹ́nẹ́sísì 15:5) Bí Ábúráhámù ṣe ń rí àwọn ìràwọ̀ yẹn, yóò máa rántí ìlérí tí Jèhófà ṣe fún un. Wọ́n jẹ́ ẹ̀rí tó ń mú kó dá a lójú pé ìlérí náà yóò ṣẹ. Ó ṣe tán, bí Jèhófà bá lágbára láti dá ayé àtọ̀run àtàwọn ohun tó wà nínú rẹ̀, ó dájú pé ó lè sọ Ábúráhámù àti Sárà di ọlọ́mọ. Ẹ ò rí i pé ìgbàgbọ́ Ábúráhámù lágbára gan-an!
KÍ NI ÌGBÀGBỌ́? Bí Bíbélì ṣe lo ọ̀rọ̀ náà “ìgbàgbọ́,” ó túmọ̀ sí pé kéèyàn gba ohun kan gbọ́ dájú bí kò tilẹ̀ rí i. Àmọ́ ṣá, onítọ̀hún á ti rí ẹ̀rí tó fìdí múlẹ̀ pé ohun náà wà. Ohun tí ẹni tó bá gba Ọlọ́run gbọ́ máa ń fọkàn sí ni bí àwọn ìlérí Jèhófà ṣe máa ṣẹ, torí ó mọ̀ dájú pé àwọn ìlérí Ọlọ́run kò ní yẹ̀ láé.
KÍ LÓ FI HÀN PÉ ÁBÚRÁHÁMÙ NÍ ÌGBÀGBỌ́? Ábúráhámù ṣe ohun tó fi hàn pé ó gba àwọn ìlérí Ọlọ́run gbọ́. Nítorí ìgbàgbọ́ tó ní, ó kúrò ní ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀, torí ó dá a lójú pé ìlérí tí Jèhófà ṣe pé òun yóò mú un lọ sí ilẹ̀ míì, kò ní yẹ̀. Nítorí ìgbàgbọ́ tí Ábúráhámù ní, ó ń ṣí láti ibì kan sí ibòmíì nílẹ̀ Kénáánì, torí ó dá a lójú pé irú-ọmọ rẹ̀ yóò jogún ilẹ̀ náà nígbà tó bá yá. Nítorí ìgbàgbọ́ tó ní, ó gbìyànjú láti fi Ísákì ọmọ rẹ̀ rúbọ bí Ọlọ́run ṣe sọ, torí ó dá a lójú pé Jèhófà yóò jí Ísákì dìde, tó bá yẹ bẹ́ẹ̀.—Hébérù 11:8, 9, 17-19.
Ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ló jẹ Ábúráhámù lógún kì í ṣe àwọn ohun tó fi sílẹ̀ sẹ́yìn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí nǹkan dẹrùn fún Ábúráhámù àti Sárà nílùú Úrì ju ìgbà tí wọ́n wà nílẹ̀ Kénáánì, síbẹ̀ wọn ò máa “ronú [nípa] ibi tí wọ́n ti jáde wá.” (Hébérù 11:15, Ìròhìn Ayọ̀) Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó jẹ wọ́n lógún ni bí Ọlọ́run ṣe máa bù kún àwọn àti àtọmọdọ́mọ wọn lọ́jọ́ iwájú.—Hébérù 11:16.
Ǹjẹ́ ìgbàgbọ́ tí Ábúráhámù ní yìí bọ́gbọ́n mu? Bẹ́ẹ̀ ni o. Gbogbo ìlérí tí Jèhófà ṣe pátá ló ṣẹ. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù di orílẹ̀-èdè tí a wá mọ̀ sí Ísírẹ́lì. Nígbà tó sì yá, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ní ilẹ̀ Kénáánì, ìyẹn ilẹ̀ tí Jèhófà ṣèlérí pé òun yóò fún Ábúráhámù.—Jóṣúà 11:23.
Ẹ̀KỌ́ WO LA RÍ KỌ́? Ó yẹ kó dá wa lójú pé Jèhófà yóò mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Lójú èèyàn, tó bá tiẹ̀ dà bíi pé àwọn kan lára ìlérí yìí kò lè ṣẹ, ó yẹ ká ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé “lọ́dọ̀ Ọlọ́run ohun gbogbo ṣeé ṣe.”—Mátíù 19:26.
Ẹ̀kọ́ míì tá a rí kọ́ lára Ábúráhámù ni pé, àwọn ohun tí a máa gbádùn lọ́jọ́ iwájú ni kó máa jẹ wá lógún dípò tí a ó fi máa ronú nípa bí nǹkan ṣe rí fún wa tẹ́lẹ̀. Ohun tí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jason ṣe nìyẹn. Àìsàn burúkú kan ló ṣe Jason tó sì sọ ọ́ dẹni tó rọ lápá rọ lẹ́sẹ̀. Jason sọ pé: “Ká sòótọ́, ìgbà míì wà tí màá kàn rí i pé mò ń ronú nípa bí nǹkan ṣe rí fún mi tẹ́lẹ̀. Ohun tó tiẹ̀ máa ń dùn mí jù ni àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tí mi ò lè ṣe mọ́ báyìí, irú bí èmi àti Amanda ìyàwó mi ṣe máa ń dì mọ́ra tá a bá ń kí ara wa.”
Àmọ́ ṣá o, Jason gbà gbọ́ dájú pé Jèhófà yóò mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ, títí kan ìlérí tó ṣe pé ilẹ̀ ayé wa yìí yóò di Párádísè láìpẹ́, àti pé àwọn olódodo yóò gba èrè ìyè àìnípẹ̀kun, wọn yóò sì ní ìlera pípé.a (Sáàmù 37:10, 11, 29; Aísáyà 35:5, 6; Ìṣípayá 21:3, 4) Jason sọ pé: “Mo máa ń rán ara mi létí pé ọ̀la ṣì ń bọ̀ wá dáa.” Àti pé: “Gbogbo ìnira, wàhálà, ìdààmú, ìbànújẹ́ àti ẹ̀dùn ọkàn tí mò ń ní báyìí máa tó di ohun ìgbàgbé títí láé.” Ẹ ò rí i pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára gan-an bíi ti Ábúráhámù!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa Párádísè orí ilẹ̀ ayé tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú, ka orí 3, 7, àti 8 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.