Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
Ó Lo Ọgbọ́n àti Ìgboyà, Ó sì Yọ̀ǹda Ara Rẹ̀ Tinútinú
Ẹ́SÍTÉRÌ rọra ń bọ̀ níbi ìtẹ́ ọba Páṣíà ní Ṣúṣánì, bẹ́ẹ̀ làyà rẹ̀ ń lù kì-kì-kì. Fojú inú wo bí inú àgbàlá ńlá náà ṣe máa pa rọ́rọ́, débi pé tí abẹ́rẹ́ bá já bọ́ èèyàn máa gbọ́, kódà Ẹ́sítérì pàápàá ń gbọ́ ìró ẹsẹ̀ tó ń gbé lọ́kọ̀ọ̀kan àti ti aṣọ ìgúnwà tó wọ̀. Kò jẹ́ kí ẹwà ààfin náà, àwọn òpó mèremère ibẹ̀, àtàwọn igi kédárì aláràbarà láti Lẹ́bánónì tí wọ́n fi ṣe àjà àgbàlá náà lọ́ṣọ̀ọ́, gba àfiyèsí òun rárá. Ẹni tó wà lórí ìtẹ́ náà ló gbájú mọ́, ìyẹn ẹni tí ẹ̀mí rẹ̀ wà lọ́wọ́ rẹ̀.
Ọba yẹn ń wo Ẹ́sítérì bó ṣe ń sún mọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì na ọ̀pá aládé wúrà sí i. Ó kàn na ọ̀pá yẹn sí i ni o, síbẹ̀ ohun tó ṣe yẹn ló dá ẹ̀mí Ẹ́sítérì sí, torí ó fi hàn pé ọba forí jì í bó ṣe wá síwájú òun láìjẹ́ pé ọba ránṣẹ́ pè é. Bí Ẹ́sítérì ṣe dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó fọwọ́ kan orí ọ̀pá náà láti fi hàn pé òun mọrírì bí ọba ṣe ṣàánú òun.—Ẹ́sítérì 5:1, 2.a
Gbogbo nǹkan tí Ahasuwérúsì Ọba ní ló fi hàn pé ọrọ̀ àti agbára rẹ̀ bùáyà. Àwọn ọ̀mọ̀wé tiẹ̀ jẹ́ ká mọ̀ pé owó aṣọ ìgúnwà àwọn ọba ilẹ̀ Páṣíà ayé ìgbà yẹn máa ń tó nǹkan bí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀kẹ́ owó dọ́là. Síbẹ̀síbẹ̀, Ẹ́sítérì rí i lójú ọba tó jẹ́ ọkọ rẹ̀ yìí pé ó fẹ́ràn òun; ọba yìí sì fẹ́ràn rẹ̀ lóòótọ́. Ọba wá bi í pé: “Kí ni ìwọ ń fẹ́, Ẹ́sítérì Ayaba, kí sì ni ìbéèrè rẹ? Títí dé ìdajì ipò ọba—àní kí a fi fún ọ!”—Ẹ́sítérì 5:3.
Ẹ́sítérì lo ìgboyà àti ìgbàgbọ́ tó kọyọyọ ní ti pé ó wá sọ́dọ̀ ọba yìí láti lè gbẹ̀mí àwọn èèyàn rẹ̀ là lọ́wọ́ elétekéte tó fẹ́ pa gbogbo wọn run. Ní báyìí, ó ti dé ọ̀dọ̀ ọba ó sì rí ojú rere rẹ̀, àmọ́ iṣẹ́ ńlá ṣì wà níwájú rẹ̀. Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ kó yé ọba téèyàn ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ pa idà rẹ̀ lójú yìí pé, olubi ẹ̀dá ni agbani-nímọ̀ràn rẹ̀ tó fọkàn tán, pé ó ti dọ́gbọ́n tan ọba láti dájọ́ ikú fún gbogbo àwọn èèyàn òun. Báwo ló ṣe máa mú kí ọba gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́, ẹ̀kọ́ wo la sì lè rí kọ́ nínú bó ṣe lo ìgbàgbọ́?
Ó Fọgbọ́n Yan “Ìgbà Sísọ̀rọ̀”
Ṣé ó máa dáa kí Ẹ́sítérì gbẹ́nu lé gbogbo bí ìṣòro náà ṣe jẹ́ lójú àwọn ẹmẹ̀wà ọba yìí? Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn ì bá tàbùkù sí ọba yìí, ó sì tún lè jẹ́ kí Hámánì agbani-nímọ̀ràn rẹ̀ ráyè ta kò ó. Kí ni Ẹ́sítérì wá ṣe? Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú ìgbà yẹn ni Ọlọ́run ti mí sí Sólómọ́nì ọlọgbọ́n ọba láti kọ̀wé pé: “Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún, . . . ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbà sísọ̀rọ̀.” (Oníwàásù 3:1, 7) Ó dájú pé Módékáì, ọkùnrin olóòótọ́ tó jẹ́ alágbàtọ́ Ẹ́sítérì, yóò ti fi gbogbo irú ìlànà bẹ́ẹ̀ kọ́ ọmọbìnrin náà bó ṣe ń dàgbà. Èyí fi hàn pé Ẹ́sítérì máa mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn fara balẹ̀ yan “ìgbà” tó yẹ kó ‘sọ̀rọ̀.’
Ẹ́sítérì wá sọ fún ọba pé: “Bí ó bá dára ní ojú ọba, kí ọba àti Hámánì wá lónìí síbi àkànṣe àsè tí mo ti sè fún un.” (Ẹ́sítérì 5:4) Ọba gbà pé òun máa wá, ó sì ránṣẹ́ pe Hámánì wá síbẹ̀. Ẹ ò rí i pé Ẹ́sítérì sọ̀rọ̀ lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu. Ó fi ọ̀wọ̀ ọkọ rẹ̀ wọ̀ ọ́, ó sì wá ìgbà tó máa dáa láti sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún un.
Ó dájú pé yóò fara balẹ̀ se àkànṣe àsè náà kí ọkọ rẹ̀ lè jẹ ẹ́ ní àjẹgbádùn. Ọtí wáìnì tó jíire, tó máa jẹ́ kí inú ọba túbọ̀ dùn, wà lára ohun tó pèsè. (Sáàmù 104:15) Ahasuwérúsì gbádùn ara rẹ̀ dọ́ba, ló bá tún bi Ẹ́sítérì léèrè ohun tó ń fẹ́ gan-an. Ṣé àkókò ti wá tó wàyí kí Ẹ́sítérì tú kẹ̀kẹ́ ọ̀rọ̀?
Lójú Ẹ́sítérì, ọjọ́ ọ̀rọ̀ náà kò tíì pé. Ó tún bẹ ọba pé kí òun àti Hámánì wá síbi àkànṣe àsè míì tóun tún máa sè lọ́jọ́ kejì. (Ẹ́sítérì 5:7, 8) Kí ló wá ń dá a dúró? Rántí pé gbogbo èèyàn Ẹ́sítérì pátá lòfin ọba ti ní kí wọ́n pa. Torí àjálù tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ yìí, ó gbọ́dọ̀ rí i pé àsìkò to yẹ kóun sọ̀rọ̀ gẹ́lẹ́ lóun sọ ọ́. Ó wá ní sùúrù, kí ọkọ rẹ̀ lè rí i pé òun bọ̀wọ̀ fún un gan-an.
Sùúrù dáa o, àmọ́ kì í rọrùn láti ní in. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìdààmú bá Ẹ́sítérì, tó sì ń hára gàgà láti sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀, ó ní sùúrù di àsìkò tó yẹ gẹ́lẹ́ kó tó sọ̀rọ̀. Ẹ̀kọ́ púpọ̀ la lè rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ obìnrin yìí, torí gbogbo wa ló ti máa rí àwọn ohun àìdáa kan tó ń fẹ́ àtúnṣe. Nítorí náà, tá a bá fẹ́ kí ẹni tó wà nípò àṣẹ yanjú ìṣòro kan, ó lè gba pé ká ní sùúrù bíi ti Ẹ́sítérì. Ìwé Òwe 25:15 sọ pé: “Sùúrù ni a fi ń rọ aláṣẹ lọ́kàn, ahọ́n pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ sì lè fọ́ egungun.” Tá a bá ní sùúrù, tá a dúró de àkókò tó yẹ gẹ́lẹ́ ká tó sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́ bíi ti Ẹ́sítérì, àwa náà lè borí àtakò tó le bí egungun. Ǹjẹ́ Jèhófà, Ọlọ́run tí Ẹ́sítérì ń sìn mú kí ọ̀rọ̀ náà yọrí sí rere nítorí sùúrù àti ọgbọ́n tó lò?
Sùúrù Rẹ̀ Jẹ́ Kí Ìdájọ́ Òdodo Lè Wáyé
Sùúrù tí Ẹ́sítérì ní jẹ́ kí ọ̀pọ̀ nǹkan lè wáyé. Hámánì kúrò níbi àkànṣe àsè àkọ́kọ́ yẹn tòun ti “ìdùnnú àti àríyá ọkàn-àyà” pé òun ni ọba àti ayaba yẹ́ sí tó báyìí. Àmọ́ bí Hámánì ṣe ń kọjá ní ẹnubodè ààfin, ó rí Módékáì, Júù yẹn, tó ṣì kọ̀ láti wárí fún un. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìwà ọ̀yájú kọ́ ló mú kí Módékáì kọ̀ láti júbà rẹ̀ o, ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ àti àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run ni kò jẹ́ kó ṣe bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, ṣe ni Hámánì “kún fún ìhónú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.”—Ẹ́sítérì 5:9.
Nígbà tí Hámánì rojọ́ Módékáì fún aya rẹ̀ àti gbogbo ọ̀rẹ́ rẹ̀, wọ́n gbà á nímọ̀ràn pé kó jẹ́ kí wọ́n ṣe òpó igi kan tí ó ga ju mítà méjìlélógún lọ. Kó wá lọ gba àṣẹ lọ́dọ̀ ọba pé kí wọ́n gbé Módékáì kọ́ sórí rẹ̀. Ìmọ̀ràn wọn dára lójú Hámánì, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló sì ní kí wọ́n lọ ṣe òpó náà.—Ẹ́sítérì 5:12-14.
Àmọ́, ó ṣẹlẹ̀ pé lọ́jọ́ náà, ọba kò rí oorun sùn mọ́jú. Bíbélì sọ pé: “Oorun dá lójú ọba.” Ni ọba bá ní kí wọ́n ka àkọsílẹ̀ ohun tó ti ṣẹlẹ̀ nínú ìjọba òun sí òun létí. Ara ohun tí wọ́n kà sí Ahasuwérúsì Ọba létí ni ọ̀rọ̀ nípa àwọn kan tó dìtẹ̀ láti pa á. Ọba rántí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó sì rántí pé wọ́n mú àwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn, wọ́n sì pa wọ́n. Àmọ́ kò gbọ́ nǹkan kan nípa ohun tí wọ́n ṣe fún Módékáì tó tú àṣírí àwọn olubi náà. Bí ọ̀rọ̀ yẹn ṣe sọ sí i lọ́kàn, ó béèrè ohun tí wọ́n ṣe fún Módékáì. Wọ́n dá a lóhùn pé kò sí nǹkan kan tí wọ́n tíì ṣe fún un.—Ẹ́sítérì 6:1-3.
Ìyẹn ká ọba lára gan-an, ó wá béèrè òṣìṣẹ́ ààfin tó wà nítòsí táwọn lè jọ ronú ohun tó yẹ káwọn ṣe nípa àṣìṣe yẹn. Àfi bó ṣe jẹ́ pé Hámánì ló wà láàfin lásìkò náà. Ó jọ pé ṣe ló jí wá ní kùtùkùtù kó lè gbàṣẹ láti pa Módékáì. Àmọ́ kí Hámánì tó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ohun tó bá wá, ọba béèrè ohun tó máa dáa kí òun ṣe láti fi dá ẹnì kan tó rí ojú rere ọba lọ́lá. Hámánì rò pé òun gan-an ni ọba ní lọ́kàn. Ó wá dámọ̀ràn àwọn nǹkan ńláńlá tó yẹ kí ọba fi dá onítọ̀hún lọ́lá. Ó ní: Kí wọ́n fi aṣọ ọ̀ṣọ́ ọba wọ̀ ọ́, kí ọ̀kan nínú àwọn ìjòyè pàtàkì mú kí ó gun ẹṣin ọba yí ká ìlú Ṣúṣánì, kó sì máa yìn ín bó ṣe ń lọ. Wo bó ṣe máa rẹ Hámánì wá nígbà tó gbọ́ pé Módékáì ni ẹni tí ọba fẹ́ dá lọ́lá! Ta sì ni ọba yàn pé kó ṣe iṣẹ́ yìí? Hámánì gan-an ni!—Ẹ́sítérì 6:4-10.
Hámánì fìtìjú ṣe iṣẹ́ tó kà sí ìwọ̀sí ńlá yìí, ó wá fi ìbànújẹ́ sá lọ sílé. Aya rẹ̀ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sì sọ fún pé àmì burúkú gbáà lohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn; pé kò sí bí kò ṣe ní pòfo nídìí ìjà tó ń bá Módékáì tó jẹ́ Júù yẹn jà.—Ẹ́sítérì 6:12, 13.
Torí pé Ẹ́sítérì ní sùúrù, tó dúró fún ọjọ́ kan ṣoṣo sí i kó tó sọ ohun tó ń fẹ́ fún ọba, àyè ṣí sílẹ̀ fún Hámánì láti kúkú fọwọ́ ara rẹ̀ ṣe ara rẹ̀ gbáà. Tá a bá sì wò ó dáadáa, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Jèhófà Ọlọ́run ló mú kí oorun dá lójú ọba yẹn mọ́jú ọjọ́ náà. (Òwe 21:1) Abájọ tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi gbà wá níyànjú pé ká ní “ẹ̀mí ìdúródeni.” (Míkà 7:7) Tá a bá ní sùúrù, tá a dúró de Ọlọ́run, a lè rí i pé bó ṣe máa yanjú ìṣòro wa yóò ta yọ gbogbo ohun tí a rò pé a máa ṣe láti fi yanjú rẹ̀ fúnra wa.
Ó Fìgboyà Sọ̀rọ̀
Ẹ́sítérì máa mọ̀ pé èyí tí òun sún ọ̀rọ̀ náà síwájú ti tó gẹ́ẹ́, pé níbi àkànṣe àsè kejì yìí, òun gbọ́dọ̀ sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn òun. Àmọ́ báwo ló ṣe máa sọ ọ́? Ó ṣẹlẹ̀ pé, ọba fún un láyè láti sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ nígbà tí ọba tún béèrè ohun tó fẹ́ tọrọ gan-an. (Ẹ́sítérì 7:2) “Ìgbà sísọ̀rọ̀” tó wàyí fún Ẹ́sítérì.
Ó dájú pé ṣe ni Ẹ́sítérì máa kọ́kọ́ fọkàn gbàdúrà sí Ọlọ́run rẹ̀ kó tó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ pé: “Bí mo bá ti rí ojú rere ní ojú rẹ, ọba, bí ó bá sì dára ní ojú ọba, jẹ́ kí a fi ọkàn mi fún mi nípa ohun tí mo tọrọ àti àwọn ènìyàn mi nípa ìbéèrè mi.” (Ẹ́sítérì 7:3) Ṣàkíyèsí pé, ó fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sọ fún ọba pé òun gbà pé ó mọ ohun tó dára láti ṣe. Ẹ ò rí i pé gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ ni Ẹ́sítérì fi yàtọ̀ sí Fáṣítì tó jẹ́ aya ọba tẹ́lẹ̀, ẹni tó dìídì dójú ti ọkọ rẹ̀! (Ẹ́sítérì 1:10-12) Bákan náà, Ẹ́sítérì kò bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àṣìṣe ńlá tí ọba ṣe bó ṣe fọkàn tán Hámánì pátápátá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló bẹ ọba pé kó gba òun torí ẹ̀mí òun wà nínú ewu.
Ẹ̀bẹ̀ yìí ta ọba kìjí, ó sì yà á lẹ́nu gidigidi. Á máa rò ó pé, ta ló gbójú gbóyà tó fẹ́ gbẹ̀mí ayaba òun? Ẹ́sítérì wá ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “A ti tà wá, èmi àti àwọn ènìyàn mi, láti pa wá rẹ́ ráúráú, láti pa wá àti láti run wá. Wàyí o, ká ní a tà wá láti di ẹrúkùnrin lásán-làsàn àti ìránṣẹ́bìnrin lásán-làsàn ni, èmi ì bá dákẹ́. Ṣùgbọ́n wàhálà náà kò bá a mu nígbà tí yóò jẹ́ sí ìpalára ọba.” (Ẹ́sítérì 7:4) Kíyè sí i pé Ẹ́sítérì sọ ojú abẹ níkòó, ó sọ ìṣòro yẹn kedere, síbẹ̀ ó fi kún un pé, òun ì bá dákẹ́ ká ní ẹrú lásán ni wọ́n fẹ́ fi àwọn ṣe. Ṣùgbọ́n ìpalára tó máa jẹ́ fún ọba tí wọ́n bá pa ẹ̀yà yẹn run pọ̀ ré kọjá ohun tí òun lè mú mọ́ra.
A rí ẹ̀kọ́ gidi kọ́ lára Ẹ́sítérì nípa béèyàn ṣe lè sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ń yíni lọ́kàn pa dà. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé o fẹ́ sọ ìṣòro ńlá kan tó ń fẹ́ àtúnṣe fún ẹnì kan tó o fẹ́ràn, tàbí ẹnì kan tó wà nípò àṣẹ, ó máa dáa kó o lo sùúrù, kó o sì fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe jẹ́ gan-an.—Òwe 16:21, 23.
Ahasuwérúsì fi ìbínú béèrè pé: “Ta ni ẹni yìí, ibo gan-an sì ni ẹni náà wà, tí ó ki ara rẹ̀ láyà láti ṣe bẹ́ẹ̀?” Fojú inú wo bí Ẹ́sítérì ṣe máa nàka nígbà tó ń sọ gbólóhùn yìí: “Ọkùnrin náà, elénìní àti ọ̀tá náà, ni Hámánì búburú yìí.” Iná ràn wàyí! Ìpayà bá Hámánì. Wo bí ojú ọba tó ti ranko yìí ṣe máa pọ́n bó ṣe wá mọ̀ pé agbani-nímọ̀ràn tóun fọkàn tán ti tan òun láti fọwọ́ sí ìwé àṣẹ láti pa aya òun àtàtà! Ni ọba bá bínú jáde lọ sí ọgbà ààfin kí ara rẹ̀ lè balẹ̀ díẹ̀.—Ẹ́sítérì 7:5-7.
Bí àṣírí Hámánì ṣe wá tú pé olubi ẹ̀dá ni, ló bá gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ wá síbi ẹsẹ Ẹ́sítérì láti bẹ̀ ẹ́. Nígbà tí ọba pa dà wọlé, tó wá rí Hámánì níbi àga ìrọ̀gbọ̀kú tí Ẹ́sítérì wà, ó fìbínú sọ pé ṣe ni Hámánì tún fẹ́ fipá bá ayaba lò pọ̀ nínú ilé ọba. Bí Hámánì ṣe gba ìdájọ́ ikú rẹ̀ nìyẹn o. Ni wọ́n bá daṣọ bò ó lójú wọ́n sì mú un lọ. Ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ààfin wá sọ fún ọba pé Hámánì tiẹ̀ ti ri òpó igi gàgàrà kan sílé rẹ̀ tó fẹ́ gbé Módékáì kọ́ sí. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ọba pàṣẹ pé kí wọ́n gbé Hámánì alára kọ́ sórí rẹ̀.—Ẹ́sítérì 7:8-10.
Nínu ayé tí ìwà ìrẹ́jẹ ti gbòde kan yìí, èèyàn lè máa rò ó pé ìdájọ́ òdodo kò lè wáyé mọ́. Ṣé ó máa ń ṣe ìwọ náà bẹ́ẹ̀? Ẹ́sítérì kò sọ̀rètí nù, kò bẹ̀rẹ̀ sí í ta ọgbọ́n àrékérekè, bẹ́ẹ̀ ni ìgbàgbọ́ rẹ̀ kò yingin. Nígbà tí àkókò sì tó, kò fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ nípa ohun tó tọ́, ó wá fèyí tó kù lé Jèhófà lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ kí àwa náà ṣe bíi tirẹ̀! Jèhófà tó ṣèdájọ́ òdodo nígbà ayé Ẹ́sítérì kò tíì yí pa dà. Ṣìnkún ló ṣì máa ń mú àwọn aṣebi àti àwọn alárèékérekè, tí wọ́n á sì fọwọ́ ara wọn ṣe ara wọn gbáà gẹ́gẹ́ bíi ti Hámánì.—Sáàmù 7:11-16.
Ó Fínnú Fíndọ̀ Lo Ara Rẹ̀ fún Jèhófà Àtàwọn Èèyàn Rẹ̀
Níkẹyìn, ọba wá mọ ẹni tí Módékáì jẹ́ gan-an, pé yàtọ̀ sí bó ṣe jẹ́ olóòótọ́ èèyàn tó gba òun lọ́wọ́ àwọn apànìyàn, òun tún ni alágbàtọ́ Ẹ́sítérì. Ahasuwérúsì sì fi Módékáì jẹ igbá kejì ọba dípò Hámánì. Lẹ́yìn náà, ọba fún Ẹ́sítérì ní ilé Hámánì títí kan gbogbo dúkìá rẹ̀, Ẹ́sítérì sì wá fi ilé náà sí ìkáwọ́ Módékáì.—Ẹ́sítérì 8:1, 2.
Ní báyìí tí Ẹ́sítérì àti Módékáì ti bọ́ lọ́wọ́ ewu, ṣé kí ayaba yìí wá lọ sinmi pé ọ̀ràn ti parí nìyẹn? Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ a jẹ́ pé tara rẹ̀ nìkan ló mọ̀. Tórí lákòókò yẹn, òfin tí Hámánì ṣe pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn Júù ṣì ń jà ràn-ìn jákèjádò ilẹ̀ ọba Páṣíà. Ṣe ni Hámánì ṣẹ́ kèké tàbí Púrì, ìyẹn oríṣi ọ̀nà ìbẹ́mìílò kan, láti fi mọ àkókò tó yẹ gẹ́lẹ́ fún òun láti ṣe iṣẹ́ láabi yẹn. (Ẹ́sítérì 9:24-26) Lóòótọ́, ó ṣì máa tó oṣù mélòó kan kí ọjọ́ náà tó pé, àmọ́ ó ti dé tán. Ǹjẹ́ wọ́n á lè paná wàhálà tí Hámánì dá sílẹ̀ yìí?
Torí pé Ẹ́sítérì kò mọ tara rẹ̀ nìkan, ó tún fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu, ó pa dà lọ sọ́dọ̀ ọba láìjẹ́ pé ọba ní kó wá. Lọ́tẹ̀ yìí, ṣe ló sunkún bó ṣe ń bẹ ọkọ rẹ̀ nítorí àwọn èèyàn rẹ̀, pé kó yí òfin búburú yẹn pa dà. Ṣùgbọ́n òfin tí wọ́n bá ti ṣe ní orúkọ ọba Páṣíà kò ṣeé yí pa dà. (Dáníẹ́lì 6:12, 15) Ọba wá fún Ẹ́sítérì àti Módékáì láṣẹ pé kí wọ́n ṣe òfin tuntun míì. Wọ́n sì ṣe ìwé ìkéde kejì jáde, èyí tó fún àwọn Júù láṣẹ láti gbèjà ara wọn. Kíá, àwọn tó ń gun ẹṣin sáré tete lọ sí gbogbo ilẹ̀ ọba Páṣíà láti fún àwọn Júù ní ìròyìn ayọ̀ náà. Ìdùnnú wá ń ṣubú lu ayọ̀ fún ọ̀pọ̀ èèyàn nítorí ìgbàlà ti dé fún àwọn Júù. (Ẹ́sítérì 8:3-16) A lè fojú inú wo bí àwọn Júù tó wà ní gbogbo ilẹ̀ ọba Páṣíà náà yóò ṣe máa gbára dì fún ogun, èyí tí kì bá ṣeé ṣe fún wọn láìsí òfin tuntun yẹn. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun” yóò ti àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́yìn?—1 Sámúẹ́lì 17:45.
Nígbà tí ọjọ́ náà pé, àwọn Júù ti múra sílẹ̀. Kódà ọ̀pọ̀ nínú àwọn òṣìṣẹ́ ọba Páṣíà ló wà lẹ́yìn wọn, torí òkìkí ti kàn káàkiri pé Módékáì tó jẹ́ Júù ti di ìgbà kejì ọba. Jèhófà sì mú kí àwọn èèyàn rẹ̀ ṣẹ́gun lọ́nà tó kàmàmà. Ṣe ló jẹ́ kí wọ́n pa àwọn ọ̀tá wọn run yán-ányán, kó má bàa di pé wọ́n á pa dà wá foró yaró.b—Ẹ́sítérì 9:1-6.
Bákan náà, bí àwọn ọmọ mẹ́wàá tí Hámánì olubi ẹ̀dá yẹn bí bá ṣì wà láàyè, kò sí bí Módékáì ṣe máa ṣàkóso ilé Hámánì, tí ẹ̀mí rẹ̀ kò ní wà nínú ewu. Ni wọ́n bá pa àwọn náà. (Ẹ́sítérì 9:7-10) Bí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kan ṣe ní ìmúṣẹ nìyẹn, èyí tí Ọlọ́run ti sọ tipẹ́tipẹ́ pé wọ́n máa pa àwọn Ámálékì tó jẹ́ ọ̀tá àwọn èèyàn rẹ̀ run pátápátá. (Diutarónómì 25:17-19) Ó ṣeé ṣe kí àwọn ọmọ Hámánì yìí jẹ́ ara àwọn tó gbẹ́yìn nínú ẹ̀yà Ámálékì tí Ọlọ́run gégùn-ún fún yẹn.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ẹ́sítérì ṣì kéré lọ́jọ́ orí, ojúṣe ńlá já lé e léjìká. Bí àpẹẹrẹ, ó dẹni tó bá wọn ṣe òfin tó jẹ mọ́ ogun àti ìdájọ́ ikú láàfin. Ó dájú pé ìyẹn kò ní rọrùn fún un rárá. Ṣùgbọ́n ohun tí Jèhófà ń fẹ́ ni pé kí wọ́n dáàbò bo àwọn èèyàn òun; torí orílẹ̀-èdè yẹn ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí yóò ti wá, ìyẹn ẹnì kan ṣoṣo tó máa jẹ́ kí aráyé ní ìrètí tó dájú. (Jẹ́nẹ́sísì 22:18) Lóde òní, inú àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run dùn bí wọ́n ṣe mọ̀ pé, látìgbà tí Jésù tó jẹ́ Mèsáyà yẹn ti wá sí ayé, ló ti sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun kò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí ogun jíjà mọ́.—Mátíù 26:52.
Àmọ́ ṣá o, àwa Kristẹni ṣì ń ja ogun nípa tẹ̀mí, torí Sátánì ń wá gbogbo ọ̀nà tí á fi bomi paná ìgbàgbọ́ wa nínú Jèhófà Ọlọ́run. (2 Kọ́ríńtì 10:3, 4) Ẹ ò rí i pé ìbùkún ńlá gbáà ni àpẹẹrẹ Ẹ́sítérì jẹ́ fún wa! Ǹjẹ́ kí àwa náà ní ìgbàgbọ́ bíi tirẹ̀, ká jẹ́ni tó ń fi ọgbọ́n àti sùúrù sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ń yíni lọ́kàn pa dà, ká jẹ́ onígboyà, ká sì jẹ́ni tó ń múra tán láti fínnú fíndọ̀ gbèjà àwọn èèyàn Ọlọ́run.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, a rí i pé àwọn òbí Ẹ́sítérì ti kú àti pé mọ̀lẹ́bí rẹ̀ tó ti dàgbà, ìyẹn Módékáì, ló tọ́ ọ dàgbà kó tó wá di aya Ahasuwérúsì ọba Páṣíà. Hámánì tí ọba fi ṣe agbani-nímọ̀ràn sì pète láti pa gbogbo àwọn èèyàn Módékáì, ìyẹn àwọn Júù run. Módékáì wá rọ Ẹ́sítérì pé kó lọ bẹ ọba láti lè gbẹ̀mí àwọn èèyàn rẹ̀ là.—Wo àpilẹ̀kọ́ náà “Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn—Ó Gbèjà Àwọn Èèyàn Ọlọ́run,” nínú Ilé-ìṣọ́ October 1, 2011.
b Ọba yọ̀ǹda pé kí àwọn Júù tún lo ọjọ́ kejì láti fi pa àwọn ọ̀tá wọn yòókù run. (Ẹ́sítérì 9:12-14) Títí dòní, àwọn Júù ṣì ń ṣe ìrántí ìṣẹ́gun yẹn ní ìgbà ìrúwé. Wọ́n ń pe ayẹyẹ yẹn ní Púrímù, ìyẹn orúkọ kèké tí Hámánì ṣẹ́ nígbà tó pète láti run gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 28]
Ìbéèrè Nípa Ẹ́sítérì
Kí nìdí tí Módékáì fi gbà kí Ẹ́sítérì fẹ́ ẹni tí kì í ṣe ẹ̀sìn àwọn Júù tó sì tún jẹ́ abọ̀rìṣà?
Kò sí ẹ̀rí tó ti ohun tí àwọn kan sọ lẹ́yìn pé torí kí Módékáì lè gbayì ló ṣe jẹ́ kí Ẹ́sítérì fẹ́ ọba. Nítorí pé Júù olóòótọ́ ni, kò ní lọ́wọ́ sí irú ìgbéyàwó bẹ́ẹ̀. (Diutarónómì 7:3) Ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Júù ìgbàanì sọ pé Módékáì tiẹ̀ gbìyànjú kí ìgbéyàwó náà má ṣeé ṣe. Ó jọ pé kò fi bẹ́ẹ̀ sí ohun tí òun àti Ẹ́sítérì lè ṣe sí ọ̀ràn náà, torí pé àjèjì ni wọ́n ní ilẹ̀ tí ọba apàṣẹwàá yẹn ń ṣàkóso, ìyẹn ọba tí àwọn èèyàn ilẹ̀ náà kà sí ẹni àkúnlẹ̀bọ. Nígbà tó yá, ó wá hàn kedere pé ṣe ni Jèhófà jẹ́ kí Ẹ́sítérì fẹ́ ọba náà láti lè dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀.—Ẹ́sítérì 4:14.
Kí nìdí tí kò fi sí orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà, nínú ìwé Ẹ́sítérì?
Ẹ̀rí fi hàn pé Módékáì ni Ọlọ́run mí sí láti kọ ìwé Ẹ́sítérì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣe ni wọ́n kọ́kọ́ tọ́jú rẹ̀ pọ̀ mọ́ àwọn ìwé ìrántí ìjọba ilẹ̀ Páṣíà kó tó di pé wọ́n mú un wá sí Jerúsálẹ́mù. Bí wọ́n bá lo orúkọ Jèhófà nínú rẹ̀, ìyẹn lè jẹ́ kí àwọn tó ń bọ àwọn òrìṣà ilẹ̀ Páṣíà run ìwé náà pátápátá. Ṣùgbọ́n, ó hàn gbangba pé Jèhófà dìídì lọ́wọ́ sí ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn náà. Ó sì wá ṣẹlẹ̀ pé, láwọn ibì kan nínú ìwé Ẹ́sítérì tí wọ́n kọ lédè Hébérù àtijọ́, wọ́n dọ́gbọ́n fi ọ̀kọ̀ọ̀kan álífábẹ́ẹ̀tì mẹ́rin tó para pọ̀ túmọ̀ sí orúkọ Ọlọ́run lédè Hébérù, bẹ̀rẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ kan tó tẹ̀ léra, wọ́n sì tún fi parí ọ̀rọ̀ láwọn ibòmíì, lọ́nà tó jẹ́ pé téèyàn bá wò wọ́n pa pọ̀ á rí i pé orúkọ Ọlọ́run ni.
Ǹjẹ́ ìtàn inú ìwé Ẹ́sítérì ṣeé gbára lé?
Àwọn tó ń ṣe lámèyítọ́ sọ pé ìtàn inú ìwé yẹn kò ṣeé gbára lé. Ṣùgbọ́n, ohun tí àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ ni pé ẹni tó kọ ìwé náà ní òye tó kún rẹ́rẹ́ nípa ìdílé ọba Páṣíà, bí àwọn ará Páṣíà ṣe ń kọ́lé wọn àti àṣà wọn. Lóòótọ́, àwọn èèyàn kò tíì rí ìwé ìtàn ayé kankan tó mẹ́nu kan Ẹ́sítérì Ayaba, àmọ́ Ẹ́sítérì kọ́ ló máa jẹ́ àkọ́kọ́ lára àwọn aláṣẹ táwọn òpìtàn kan kọ̀ láti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, a sábà máa ń rí i nínú àwọn ìwé ìtàn pé ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Mardukâ, ìyẹn orúkọ Módékáì lédè Páṣíà, jẹ́ òṣìṣẹ́ ààfin Ṣúṣánì lásìkò tí wọ́n kọ ìwé Ẹ́sítérì.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 29]
Wọ́n Mú Àsọtẹ́lẹ̀ Kan Ṣẹ
Bí Ẹ́sítérì àti Módékáì ṣe jà fún àwọn èèyàn Ọlọ́run, ṣe ni wọ́n mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kan ṣẹ. Ní èyí tó ju ẹgbẹ̀fà [1,200] ọdún ṣáájú ìgbà tiwọn ni Jèhófà ti mí sí baba ńlá náà Jékọ́bù láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ọmọ rẹ̀ pé: “Bẹ́ńjámínì yóò máa fani ya bí ìkookò. Ní òwúrọ̀, òun yóò jẹ ẹran tí a mú, àti ní ìrọ̀lẹ́, òun yóò pín ohun ìfiṣèjẹ.” (Jẹ́nẹ́sísì 49:27) Ní “òwúrọ̀” tí Bíbélì sọ níbí, ìyẹn ìgbà tí ọba jíjẹ nílẹ̀ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀, ìlà ìdílé Bẹ́ńjámínì ni Sọ́ọ̀lù Ọba àtàwọn alágbára míì tó jagun fún àwọn èèyàn Jèhófà ti wá. Ní “ìrọ̀lẹ́,” ìyẹn ìgbà tí ọba jíjẹ nílẹ̀ Ísírẹ́lì fẹ́ dópin, Ẹ́sítérì àti Módékáì táwọn náà jẹ́ àtọmọdọ́mọ Bẹ́ńjámínì, bá àwọn ọ̀tá Jèhófà jà wọ́n sì ṣẹ́gun. Bákan náà, a tún lè sọ pé wọ́n pín ohun ìfiṣèjẹ ní ti pé gbogbo dúkìá Hámánì di tiwọn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ẹ́sítérì fi hàn pé òun mọrírì àánú ọba
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26, 27]
Ẹ́sítérì fìgboyà tú àṣírí ìwà ibi Hámánì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28, 29]
Ẹ́sítérì àti Módékáì fi ìwé ìkéde ránṣẹ́ sí àwọn Júù tó wà ní Ilẹ̀ Ọba Páṣíà