BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ
“Ìwà Mi Burú Jáì”
ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1960
ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: FINLAND
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: OLÓRIN RỌ́Ọ̀KÌ ONÍLÙ DÍDÚN KÍKANKÍKAN
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ:
Ìlú Turku tó ní ibùdókọ̀ òkun ni mo dàgbà sí. Àwọn tó wà níbẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ. Ọ̀gá ni bàbá mi láàárín àwọn tó ń kan ẹ̀ṣẹ́, èmi àti àbúrò mi ọkùnrin sì mọ ẹ̀ṣẹ́ kàn dáadáa. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń tọ́ ìjà mi nílé ìwé, èmi náà ò kì í yéé jà. Kí n tó pé ọmọ ogún ọdún, mo wọ ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ìta kan, èyí sì mú kí n máa ja ìjà ìgboro kiri. Mo tún bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ orin onílù dídún kíkankíkan, mo sì ń ronú pé mo máa di gbajúmọ̀ òṣèré olórin rọ́ọ̀kì lọ́jọ́ kan.
Mo ra àwọn ìlù, mo sì dá ẹgbẹ́ olórin kan sílẹ̀, mo wá di ọ̀gá ẹgbẹ́ olórin náà. Mo fẹ́ràn kí n máa ṣe bí ẹhànnà tí mo bá wà lórí ìtàgé. Torí pé ẹgbẹ́ wa ya oníjàgídíjàgan, tí a sì máa ń múra bí ewèlè, òkìkí wa bẹ̀rẹ̀ sí í kàn káàkiri. A bẹ̀rẹ̀ sí í kọ orín níwájú ọ̀pọ̀ èrò. A ṣe àwọn àwo orin mélòó kan, kódà àwọn tó gbọ́ èyí tí a ṣe gbẹ̀yìn sọ pé àwọn gbádùn rẹ̀ gan-an. Láàárín ọdún 1986 sí 1989, a lọ sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ká lè lọ polówó ẹgbẹ́ wa. A kọrin nígbà mélòó kan ní ìlú New York àti Los Angeles. Ibẹ̀ ni a ti pàdé àwọn kan tó ń ṣiṣẹ́ ní àwọn ilé iṣẹ́ tó ń ṣe onígbọ̀wọ́ fún àwọn olórin ká tó pa dà sí orílẹ̀-èdè Finland.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú mi dùn bí mo ṣe wà nínú ẹgbẹ́ wa, ó ṣì máa ń wù mí pé kí n wá nǹkan gidi tí màá fi ayé mi ṣe. Gbogbo bí àwọn olórin ṣe máa ń bá ara wọn díje, tí wọ́n sì máa ń bá ara wọn jà mú kí ọ̀rọ̀ iṣẹ́ orin yọ lẹ́mìí mi pátápátá. Ìgbé ayé ẹni tí kò bìkítà tí mò ń gbé tún wá tojú sú mi. Ṣe ló ń ṣe mí bíi pé èèyàn burúkú ni mí, ẹ̀rù sì ń bà mí torí mi ò fẹ́ lọ jóná nínú ọ̀run àpáàdì. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ka onírúurú ìwé ìsìn, bóyá màá rí ojútùú sí àwọn ìṣòro mi. Mo tún gbàdúrà tọkàntọkàn pé kí Ọlọ́run ràn mí lọ́wọ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń ṣe mí bíi pé mi ò yẹ lẹ́ni tó lè ṣe ìfẹ́ rẹ̀.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ:
Mo ń ṣiṣẹ́ ní ilé ìfìwéránṣẹ́ kan ní àdúgbò wa kí n lè máa rí owó gbọ́ bùkátà ara mi. Lọ́jọ́ kan, mo rí i pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ọ̀kan lára àwọn tí a jọ ń ṣiṣẹ́. Ni mo bá da ìbéèrè bò ó. Àmọ́ àwọn ìdáhùn tó fún mi kò lọ́jú pọ̀ rárá, wọ́n sì bá Ìwé Mímọ́ mu, èyí wú mi lórí gan-an. Bí mo ṣe gbà pé kó máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ tó ti ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́, ilé iṣẹ́ kan gbà láti ṣe onígbọ̀wọ́ ẹgbẹ́ wa, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n gbé àwo orin wa jáde ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó pé, tí mo bá sọ irú àǹfààní yìí nù pẹ́nrẹ́n, mo lè má tún rí irú rẹ̀ mọ́ láé.
Mo sọ fún Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ pé, ó wù mí kí n ṣe àwo orin kan sí i, lẹ́yìn ìyẹn màá jáwọ́, màá wá bẹ̀rẹ̀ sí í fi ohun tí mo ń kọ́ nínú Bíbélì sílò. Kò sọ́ pé kí n ṣe é tàbí kí n má ṣe é, ohun tó kàn sọ fún mi ni pé kí n lọ ka ohun tí Jésù sọ nínú Mátíù 6:24. Ẹsẹ yẹn sọ pé: “Kò sí ẹnì kan tí ó lè sìnrú fún ọ̀gá méjì.” Nígbà tí mo mọ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí, ó yà mí lẹ́nu gan-an ni. Àmọ́ lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, ẹni tó ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló kàn tí ẹnú wá yà, nígbà tí mo sọ fún un pé mo ti kúrò nínú ẹgbẹ́ olórin wa torí pé mo fẹ́ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù!
Ṣe ni Bíbélì dà bí dígí tó jẹ́ kí n rí gbogbo ibi tí mo kù sí. (Jákọ́bù 1:22-25) Èmi fúnra mi wá rí i pé ìwà mi burú jáì, ìgbéraga wọ̀ mí lẹ́wù, bí mo sì ṣe máa dé ipò ńlá ló gbà mí lọ́kàn. Ìsọkúsọ kún ẹnu mi, mo máa ń jà, mo ń mu sìgá, mo sì ń mutí lámujù. Nígbà tí mo rí bí ìgbé ayé mi ṣe ta ko àwọn ìlànà Bíbélì tó, ṣe ló dà bíi pé ọ̀rọ̀ mi ti kọjá àtúnṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn, mo pinnu pé màá ṣe gbogbo àtúnṣe tó yẹ.—Éfésù 4:22-24.
“Baba wa ọ̀run jẹ́ aláàánú, ó sì máa ń fẹ́ wo ọgbẹ́ ọkàn àwọn tó bá ronú pìwà dà sàn”
Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í yí ìgbé ayé mi pa dà, ṣe ni ọkàn mi ń dá mi lẹ́bi ṣáá nítorí àwọn ìwà ìbàjẹ́ tí mo ti hù sẹ́yìn. Ṣùgbọ́n Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ ràn mí lọ́wọ́ gan-an. Ó fi ohun tó wà nínú Aísáyà 1:18 hàn mí. Ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ pé: “Bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín tilẹ̀ rí bí aṣọ rírẹ̀dòdò, a ó sọ wọ́n di funfun gẹ́gẹ́ bí ìrì dídì.” Ẹsẹ yìí àti àwọn míì nínú Bíbélì ló mú un dá mi lójú pé Baba wa ọ̀run jẹ́ aláàánú, ó sì máa ń fẹ́ wo ọgbẹ́ ọkàn àwọn tó bá ronú pìwà dà sàn.
Bí mo ṣe wá mọ Jèhófà dáadáa, mo nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì wù mí kí n fi gbogbo ayé mi sìn ín. (Sáàmù 40:8) Mo ṣe ìrìbọmi ní ọdún 1992 ní ìpàdé àgbáyé kan tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní ìlú St. Petersburg, ní ilẹ̀ Rọ́ṣíà.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ:
Mo ti ní àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà láàárín àwọn tó ń sin Jèhófà. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a máa ń kóra jọ láti kọ orin aládùn tó tuni lára, tórí pé ẹ̀bùn Ọlọ́run ni orin jẹ́. (Jákọ́bù 1:17) Ọlọ́run tún ti bù kún mi lọ́nà àkànṣe bó ṣe jẹ́ kí n pàdé Kristina, ìyàwó mi àtàtà. Alábàárò gidi ló jẹ́ fún mi nígbà ìṣòro àti lásìkò ayọ̀, kódà gbogbo ohun tó wà lọ́kàn mi ni mo máa ń sọ fún un.
Ká ní mi ò di Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni, ó ṣeé ṣe kí n ti kú. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, mo máa ń tinú ìṣòro kan bọ́ sínú òmíràn, wàhálà kì í sì í tán lọ́rùn mi. Àmọ́ ní báyìí, mo ti ní nǹkan gidi tí mo ń fi ayé mi ṣe, èmi náà sì rí i pé gbogbo nǹkan ń lọ bó ṣe yẹ.