Kíróníkà Kìíní
14 Hírámù+ ọba Tírè rán àwọn òjíṣẹ́ sí Dáfídì, ó kó igi kédárì ránṣẹ́, ó tún rán àwọn oníṣẹ́ òkúta* àti àwọn oníṣẹ́ igi láti kọ́ ilé* fún un.+ 2 Dáfídì wá mọ̀ pé Jèhófà ti fìdí ìjọba òun múlẹ̀ lórí Ísírẹ́lì,+ torí pé Ó ti gbé ìjọba Dáfídì ga nítorí àwọn èèyàn Rẹ̀ Ísírẹ́lì.+
3 Dáfídì fẹ́ ìyàwó sí i+ ní Jerúsálẹ́mù, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin púpọ̀ sí i.+ 4 Orúkọ àwọn ọmọ tí wọ́n bí fún un ní Jerúsálẹ́mù+ nìyí: Ṣámúà, Ṣóbábù, Nátánì,+ Sólómọ́nì,+ 5 Íbárì, Élíṣúà, Élípélétì, 6 Nógà, Néfégì, Jáfíà, 7 Élíṣámà, Béélíádà àti Élífélétì.
8 Nígbà tí àwọn Filísínì gbọ́ pé wọ́n ti fòróró yan Dáfídì ṣe ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì,+ gbogbo àwọn Filísínì bẹ̀rẹ̀ sí í wá Dáfídì.+ Bí Dáfídì ṣe gbọ́ báyìí, ó lọ gbéjà kò wọ́n. 9 Ìgbà náà ni àwọn Filísínì wọlé wá, wọ́n sì ń kó nǹkan àwọn èèyàn ní Àfonífojì* Réfáímù.+ 10 Dáfídì wádìí lọ́dọ̀ Ọlọ́run pé: “Ṣé kí n lọ gbéjà ko àwọn Filísínì? Ṣé wàá fi wọ́n lé mi lọ́wọ́?” Ni Jèhófà bá sọ fún un pé: “Lọ, ó dájú pé màá fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́.”+ 11 Torí náà, Dáfídì lọ sí Baali-pérásímù,+ ó sì pa wọ́n níbẹ̀. Dáfídì wá sọ pé: “Ọlọ́run tòótọ́ ti tipasẹ̀ ọwọ́ mi ya lu àwọn ọ̀tá mi, bí ìgbà tí omi bá ya lu nǹkan.” Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi pe ibẹ̀ ní Baali-pérásímù.* 12 Àwọn Filísínì fi àwọn ọlọ́run wọn sílẹ̀ níbẹ̀, a sì dáná sun+ wọ́n bí Dáfídì ṣe pa á láṣẹ.
13 Nígbà tó yá, àwọn Filísínì tún wá kó nǹkan àwọn èèyàn ní àfonífojì*+ náà. 14 Dáfídì tún wádìí lọ́dọ̀ Ọlọ́run, àmọ́ Ọlọ́run tòótọ́ sọ fún un pé: “Má ṣe dojú kọ wọ́n ní tààràtà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀yìn ni kí o gbà yọ sí wọn, kí o sì wá dojú kọ wọ́n níwájú àwọn igi bákà.+ 15 Tí o bá ti gbọ́ ìró tó ń dún bí ìró ẹsẹ̀ lórí àwọn igi bákà, kí o dojú ìjà kọ wọ́n, nítorí Ọlọ́run tòótọ́ yóò ti lọ ṣáájú rẹ láti ṣá àwọn ọmọ ogun Filísínì balẹ̀.”+ 16 Torí náà, Dáfídì ṣe ohun tí Ọlọ́run tòótọ́ pa láṣẹ fún un gẹ́lẹ́,+ wọ́n sì pa àwọn ọmọ ogun Filísínì láti Gíbíónì títí dé Gésérì.+ 17 Òkìkí Dáfídì kàn dé gbogbo àwọn ilẹ̀ náà, Jèhófà sì mú kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè máa bẹ̀rù rẹ̀.+