Jóòbù
11 Sófárì+ ọmọ Náámà fèsì pé:
2 “Ṣé o ò ní gba èsì gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ni,
Àbí ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ máa mú kí ẹnì kan jàre?*
3 Ṣé àwọn ọ̀rọ̀ rẹ tí kò nítumọ̀ máa pa àwọn èèyàn lẹ́nu mọ́?
Ṣé kò sẹ́ni tó máa bá ọ wí torí ọ̀rọ̀ ìfiniṣẹ̀sín rẹ?+
6 Ì bá sọ àwọn àṣírí ọgbọ́n fún ọ,
Torí ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ pín sí oríṣiríṣi ọ̀nà.
O máa wá mọ̀ pé ńṣe ni Ọlọ́run yàn láti gbàgbé àwọn àṣìṣe rẹ kan.
7 Ṣé o lè wá àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run rí,
Àbí o lè ṣàwárí gbogbo nǹkan nípa* Olódùmarè?
8 Ó ga ju ọ̀run lọ. Kí lo lè ṣe?
Ó jìn ju Isà Òkú* lọ. Kí lo lè mọ̀?
9 Ó gùn ju ayé lọ,
Ó sì fẹ̀ ju òkun lọ.
10 Tó bá kọjá lọ, tó sì ti ẹnì kan mọ́lé, tó wá pè é lẹ́jọ́,
Ta ló lè dá a dúró?
11 Torí ó mọ ìgbà tí àwọn èèyàn bá ń ṣẹ̀tàn.
Tó bá rí ohun tó burú, ṣé kò ní fiyè sí i?
12 Àfìgbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó bá bí èèyàn*
Ló máa tó yé òpònú èèyàn.
13 Ká ní o lè múra ọkàn rẹ sílẹ̀ ni,
Kí o sì na ọwọ́ rẹ sí i.
14 Bí ọwọ́ rẹ bá ń ṣe ohun tí kò dáa, mú un jìnnà,
Má sì jẹ́ kí àìṣòdodo kankan gbé inú àwọn àgọ́ rẹ.
15 Torí ìgbà yẹn ni wàá lè gbé ojú rẹ sókè láìsí àbùkù kankan;
Wàá lè dúró gbọn-in, ẹ̀rù ò sì ní bà ọ́.
16 Torí ìgbà yẹn lo máa gbàgbé ìṣòro rẹ;
O máa rántí rẹ̀ bí omi tó ti ṣàn kọjá rẹ.
17 Ayé rẹ máa mọ́lẹ̀ ju ọ̀sán gangan lọ;
Òkùnkùn rẹ̀ pàápàá máa dà bí àárọ̀.
18 Ọkàn rẹ máa balẹ̀ torí ìrètí wà,
O máa wò yí ká, o sì máa dùbúlẹ̀ láìséwu.
19 Wàá dùbúlẹ̀, ẹnì kankan ò sì ní dẹ́rù bà ọ́,
Ọ̀pọ̀ èèyàn á sì máa wá ojúure rẹ.